ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/15 ojú ìwé 3
  • Ọlọrun Ha Ndahun Awọn Adura Rẹ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun Ha Ndahun Awọn Adura Rẹ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ki Ni Awọn Kan Ngbadura Fun?
  • Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Adura Awọn Wo Ni A Ndahun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Láǹfààní Tádùúrà Gbígbà Ń Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/15 ojú ìwé 3

Ọlọrun Ha Ndahun Awọn Adura Rẹ Bi?

“EMI ko tii nimọlara ti rírí i ki a dahun awọn adura mi rí,” ni obinrin kan ti ngbe ni Hokkaido, Japan wi. Ni ọna yii kii ṣe oun nikan. Ọpọlọpọ awọn eniyan nimọlara pe adura wọn ni a ko dahun rí. Nitootọ, iwọ le maa ṣe kayefi bi Ọlọrun ba ndahun awọn adura rẹ.

Araadọta ọkẹ ndari ailonka adura si ainiye awọn ọlọrun. Eeṣe ti o fi dabi ẹni pe ọpọlọpọ awọn adura ni a ko dahun? Lati ridii rẹ̀, jẹ ki a kọkọ ṣayẹwo iru awọn adura ti a ńgbà.

Ki Ni Awọn Kan Ngbadura Fun?

Lakooko Ọdun Titun, idameji ninu mẹta awọn olùgbé Japan, tabi nǹkan bii 80 million eniyan, maa ngbadura ninu ile oriṣa Shinto tabi tẹmpili Buddha. Wọn a maa pese awọn owo ẹyọ gẹgẹ bi ohun irubọ wọn a si maa gbadura fun àrìnnàkore ati idaabobo idile.

Ni January ati February—kété ṣaaju awọn idanwo ti wọn beere akitiyan ti awọn akẹkọọ nṣe lati wọ ile-ẹkọ giga—awọn akẹkọọ maa ńtúyáyá lọ si awọn ile oriṣa bii iru ọ̀kan ti o wa ni Tokyo ti a mọ dunju fun ọlọrun imọ ẹkọ rẹ̀. Wọn yoo kọ idaniyan wọn sara okuta adura pẹlẹbẹ wọn a si fi wọn kọ́ sara awọn ọ̀pá onigi ti wọn wà yika ilẹ ile oriṣa naa. O kere tan 100,000 awọn okuta pẹlẹbẹ wọnyi ni wọn ṣe ayika ile oriṣa ti a mọ daradara kan ni Tokyo lọṣọọ ni saa idanwo ẹkọ ti 1990.

Ọpọlọpọ awọn adura wémọ́ ilera. Ni ile oriṣa kan ni Kawasaki, Japan, awọn eniyan ngbadura fun idaabobo kuro lọwọ AIDS. “Ijẹpataki gbigbadura lodisi AIDS, ni pe yoo mu ki awọn eniyan jẹ ọlọgbọn inu ninu iwa wọn,” ni alufaa ile oriṣa naa ṣalaye. Ṣugbọn ṣe gbogbo ohun ti o wà nipa adura niyẹn bi?

Ni tẹmpili miiran, obinrin arugbo kan gbadura fun “iku ojiji.” Eeṣe? Nitori pe o fẹ lati yẹra fun ijiya ati aisan ọlọjọ gbọọrọ kò si fẹ lati di ẹrù inira ru idile rẹ̀.

Ni orilẹ-ede kan ti a fẹnu lasan pe ni ti Kristẹni, balogun ẹgbẹ agbabọọlu kan gbadura fun iṣẹgun ati aabo kuro lọwọ ifarapa awọn ẹgbẹ rẹ̀. Awọn Katoliki ni Poland gbadura fun alaafia araawọn wọn a si fi awọn ohun ọ̀ṣọ́ iyebiye ṣe Madonna wọn lọṣọọ nigba ti wọn ba gbagbọ pe adura wọn ni a ti gbọ́. Ọpọlọpọ eniyan dàgììrì lọ si ṣọọṣi iru bii Guadalupe olokiki ti o wa ni Mexico City, ati Lourdes, ni France, ni bibẹbẹ fun iwosan oniṣẹ iyanu.

Yala ni Ila-oorun tabi Iwọ-oorun, awọn eniyan ngbadura fun ọpọ ati oniruuru idi ti o jẹ́ ti ara ẹni. Lọna ti o han gbangba, wọn nfẹ ki adura wọn di eyi ti a gbọ́ ti a si dahun. Bi o ti wu ki o ri, o ha gbeṣẹ lati reti pe gbogbo awọn adura ni a o fi oju rere gbọ bi? Ki ni nipa awọn adura tirẹ funraarẹ? A ha ndahun wọn bi? Nitootọ, njẹ Ọlọrun ndahun awọn adura lọnakọna bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́