ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/15 ojú ìwé 3
  • Idi Ti Wọn Fi Nlo Awọn Ohun Iranti Ninu Ijọsin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Idi Ti Wọn Fi Nlo Awọn Ohun Iranti Ninu Ijọsin
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ifọwọsi Ti Poopu
  • Ifọkansin Fun Awọn Ohun Iranti Ha Wu Ọlọrun Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àwọn Èèyàn Ń Kan Sáárá Sáwọn “Ẹni Mímọ́” Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ibojì Peteru—Ní Vatican Kẹ̀?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run” àti Àwọn Òrìṣà ní Ilẹ̀ Gíríìsì Ha Fohùn Ṣọ̀kan Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/15 ojú ìwé 3

Idi Ti Wọn Fi Nlo Awọn Ohun Iranti Ninu Ijọsin

ILU Naples, Italy. Fi oju inu wò ó pe o wà nibẹ ni awọn ọdun ibẹrẹ ọgọrun-un ọdun Kejidinlogun ninu Sanmani Tiwa. Ninu katidira rẹ̀, George Berkeley ẹlẹkọọ isin ara Ireland duro niwaju ohun iranti isin olokiki kan. Ó ńwo ohun ti o jọ ìsọdomi ẹ̀jẹ̀ “San Gennaro” pẹlu iyèméjì, Januarius, “ẹni mímọ́” Katoliki naa.

Diẹ ni ilu Naples tii yipada niti ọran yii. Fun apẹẹrẹ, laika oju ọjọ ti kò dara si ni akoko kan ni awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́ yii, ṣọọṣi naa ńgbáyìì fun awọn eniyan lẹẹkansii, ohun ti ó sì farajọ iṣẹ iyanu ti ṣẹlẹ. Ohun iranti naa ati ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ tí olori awọn biṣọọbu jẹ́ aṣiwaju rẹ̀ ni a gbà pẹlu àtẹ́wọ́ ọlọyaya. Bẹẹni, eyi ni akoko miiran ninu ọpọlọpọ awọn akoko ti ó jọ bi ẹni pe ẹ̀jẹ̀ “San Gennaro” di omi. Awọn iṣẹ iyanu ti ó wémọ́ awọn ohun iranti isin yii ni a ti rohin pe ó nṣẹlẹ lati ọ̀rúndún Kẹrinla.

Gẹgẹ bi ẹkọ atọwọdọwọ Katoliki ti wi, ohun iranti kan (lati inu ọrọ Latin naa relinquere, ti ó tumọsi “lati fi silẹ sẹhin”) jẹ́ ohun kan ti ẹnikan ti a kà si ẹni mímọ́ fi silẹ. Gẹgẹ bi Dizionario Ecclesiastico ti fihan, awọn ohun iranti “ni a tumọ ni wẹ́kú bii ara tabi apakan ara ati eérú Ẹni mímọ́ naa, ni itumọ gbigbooro kan ohun naa ti ó fara kan ara ẹni mímọ́ naa ti ó sì di ohun ti ó yẹ fun ifọkansin nititori bẹẹ.”

Ifọwọsi Ti Poopu

Laiṣiyemeji, ọpọlọpọ nfi ìlòsí ọlọ́wọ̀ fun awọn ohun iranti isin nitori awọn iṣẹ iyanu ti ó farahan gbangba pe wọn ni isopọ pẹlu wọn. Ifọwọsi ti Poopu ni kedere jẹ́ okunfa miiran ninu ìlókìkí wọn.

Ó keretan awọn poopu mẹrin ni 70 ọdun ti o kọja ti fi afiyesi akanṣe fun awọn ohun iranti. Iwe atigbadegba ti Katoliki kan sọ ọ́ di mímọ̀ pe bii aṣaaju rẹ̀ Pius Kọkanla, Pope Pius Kejila “tọju ohun iranti Lisieux ẹni mímọ́ naa sí ara oun funraarẹ.” Paul Kẹfa “tọju ìka apọsiteli [Tomasi] sori apoti ikọwe ninu ibi ikẹkọọ rẹ̀,” John Paul Keji sì “tọju awọn àjákù . . . ara kíkú “Benedict Mímọ́” ati “Andrew Mímọ́,” sinu ìyẹ̀wù rẹ̀.”—30 giorni, March 1990, oju-iwe 50.

Ni oju iwoye iru ifọwọsi ti Poopu bẹẹ, kò yanilẹnu pe ibeere awọn ohun iranti fun lilo fun ifọkansin adaṣe ati ti gbogbogboo npọ sii. Ṣugbọn ifọkansin fun awọn ohun iranti ha wu Ọlọrun bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ìkóhun iranti pamọ si kan, ohun kan ninu eyi ti a nko awọn ohun iranti pamọ si

[Credit Line]

Courtesy of the British Museum

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́