Ọjọ Naa Lati Ranti
“Mo ti wí nǹkan wọnyi fun yin pe nipasẹ mi ki ẹ lè ni alaafia. Ninu ayé ẹyin ń ní ipọnju, ṣugbọn ẹ ni igboya! Mo ti ṣẹgun ayé.”—JOHANU 16:33, NW.
1, 2. Ọjọ kan wo ninu itan ni o tayọ gbogbo awọn ọjọ yooku, eesitiṣe?
AYÉ lonii ní ohun pupọ lati sọ nipa alaafia. Ni opin Ogun Agbaye Keji, alaafia ni a sopọ mọ Ọjọ V-E ati Ọjọ V-J.a Lọdọọdun, Keresimesi ń mu ki awọn eniyan ronu nipa ‘alaafia lori ilẹ̀-ayé.’ (Luuku 2:14) Ṣugbọn ọjọ kan wà ninu gbogbo ìtàn eniyan ti o tayọ gbogbo awọn miiran. Ó jẹ́ ọjọ ti Jesu Kristi sọ awọn ọrọ ti a fayọ loke yii. Ninu million meji ati ju bẹẹ lọ awọn ọjọ tí araye ti wà nihin-in lori ilẹ̀-ayé, ó jẹ ọjọ kan naa ti o yi ipa ọna iran eniyan pada fun rere rẹ̀ ayeraye.
2 Ọjọ ti o ṣe pataki gidi yẹn ni Nisan 14 lori kalẹnda awọn Juu. Ni ọdun 33 ti Sanmani Tiwa, Nisan 14 bẹrẹ ni ìgbà ti oòrun wọ̀ ni April 1. Ẹ jẹ ki a gbé awọn iṣẹlẹ ọjọ ti o ṣe pataki gan-an yẹn yẹwo.
Nisan 14!
3. Bawo ni Jesu ṣe ṣamulo awọn wakati ikẹhin wọnyi?
3 Bi ọjọ ti ń pofírí, oṣupa aranmọju ẹlẹwa kan ni o ṣeeṣe ki o ràn jade gẹgẹ bi irannileti pe Jehofa ń pinnu igba ati akoko. (Iṣe 1:7) Ki ni o sì ń ṣẹlẹ ninu yara oke yẹn nibi ti Jesu ati awọn apọsiteli rẹ̀ 12 pejọ si lati ṣayẹyẹ Ajọ-Irekọja ọdọọdun awọn Juu? Bi Jesu ti ń mura silẹ ‘lati jade kuro ninu ayé yii lọ sọdọ Baba, ó ń fi ifẹ han fun awọn tirẹ titi dé opin.’ (Johanu 13:1) Bawo ni o ṣe ń ṣe eyi? Nipa ọrọ ẹnu ati apẹẹrẹ, Jesu ń baa lọ lati tẹ awọn animọ ti yoo ran awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọwọ lati ṣẹgun ayé mọ́ wọn lọkan.
Gbigbe Irẹlẹ ati Ifẹ Wọ̀
4. (a) Bawo ni Jesu ṣe ṣaṣefihan animọ ipilẹ kan fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀? (b) Bawo ni a ṣe mọ pe Peteru mọ ijẹpataki irẹlẹ?
4 Awọn apọsiteli ṣì nilati gba araawọn silẹ lọwọ iwọn owú ati igberaga onilara. Nitori naa Jesu fi aṣọ ìnura di araarẹ lamure ó sì tẹsiwaju lati fọ ẹsẹ wọn. Eyi kii ṣe fifi irẹlẹ ẹlẹ́yà hàn, gẹgẹ bi poopu Kristẹndọmu ti ń ṣe e lọdọọdun ni Roomu. Dajudaju, bẹẹkọ! Irẹlẹ tootọ jẹ́ fifi ara-ẹni funni ti o wá lati inu ‘irẹlẹ ero-inu ti o ka awọn ẹlomiran si ẹni gigaju.’ (Filipi 2:2-5) Lakọọkọ ná, Peteru tàsé koko naa, ni kíkọ̀ lati jẹ ki Jesu wẹ ẹsẹ oun. Nigba ti a tọ́ ọ sọna, ó sọ fun Jesu lati wẹ gbogbo ara oun nù. (Johanu 13:1-10) Bi o ti wu ki o ri, Peteru gbọdọ ti kọ́ ẹkọ naa. Ni ọpọ ọdun lẹhin naa, a rí i ti o ń gba awọn ẹlomiran nimọran lọna titọ. (1 Peteru 3:8, 9; 5:5) Ó ti ṣe pataki tó lonii pe ki gbogbo wa ṣe ẹrú fun Kristi pẹlu irẹlẹ!—Tun wo Owe 22:4; Matiu 23:8-12.
5. Ofin Jesu wo ni o fi ijẹpataki animọ ipilẹ siwaju sii han?
5 Ọ̀kan lara awọn 12 naa kò janfaani lati inu imọran Jesu. Ẹni yii ni Judasi Isikariotu. Bi ounjẹ Ajọ-Irekọja ti ń lọ, Jesu di ẹni ti a daamu ninu ẹmi, ó fi Judasi han gẹgẹ bi olutaṣiiri rẹ̀, ó sì ni ki o maa lọ. Kiki lẹhin eyi ni Jesu tó sọ fun awọn oluṣotitọ ọmọ-ẹhin rẹ̀ 11 pe: “Ofin titun kan ni mo fifun yin, ki ẹyin ki o fẹ́ ọmọnikeji yin; gẹgẹ bi emi ti fẹran yin, ki ẹyin ki o sì lè fẹran ọmọnikeji yin. Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin iṣe, nigba ti ẹyin bá ni ifẹ si ọmọnikeji yin.” (Johanu 13:34, 35) Eyi jẹ́ ofin titun kan nitootọ, ti apẹẹrẹ didara julọ Jesu funraarẹ ṣapejuwe! Bi wakati iku irubọ rẹ̀ ti ń sunmọ, Jesu fi ifẹ titayọ han. Ó lo gbogbo iṣẹju ṣiṣeyebiye lati kọ́ kí ó sì fun awọn ọmọ-ẹhin wọnni niṣiiri. Lẹhin naa, ó tẹnumọ ijẹpataki ifẹ, ni sisọ pe: “Eyi ni ofin mi, pe ki ẹyin ki o fẹran araayin, gẹgẹ bi mo ti fẹran yin. Kò si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi ju eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmi rẹ̀ lélẹ̀ nitori awọn ọrẹ rẹ̀.”—Johanu 15:12, 13.
“Ọna ati Otitọ ati Ìyè”
6. Gongo wo ni Jesu fi siwaju awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ timọtimọ?
6 Jesu sọ fun awọn oluṣotitọ 11 naa pe: “Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn yin dàrú: ẹ gba Ọlọrun gbọ́ ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu. Ninu ile Baba mi ọpọlọpọ ibugbe ni o wà: ìbá maṣe bẹẹ, emi ìbá ti sọ fun yin. Nitori mo ń lọ pese àyè silẹ fun yin.” (Johanu 14:1, 2) Àyè yii ni yoo nilati jẹ́ ninu “ijọba ọrun.” (Matiu 7:21) Jesu sọ bi ọwọ́ awujọ timọtimọ ti awọn ọmọ-ẹhin aduroṣinṣin yii ṣe lè tẹ gongo wọn. Ó sọ pe: “Emi ni ọna, ati otitọ, ati ìyè: kò si ẹnikẹni ti o lè wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.” (Johanu 14:6) Eyi tun kan awọn araye wọnni ti wọn jere ìyè ainipẹkun lori ilẹ̀-ayé.—Iṣipaya 7:9, 10; 21:1-4.
7-9. Eeṣe ti Jesu fi ṣapejuwe araarẹ gẹgẹ bi “ọna ati otitọ ati ìyè”?
7 Jesu ni “ọna.” Ọna kanṣoṣo gíro naa lọ sọdọ Ọlọrun ninu adura jẹ́ nipasẹ Jesu Kristi. Jesu funraarẹ mu un dá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ loju pe Baba yoo fun wọn ni ohun yoowu ki wọn beere ni orukọ Jesu. (Johanu 15:16) Adura ti a dari si awọn ère tabi “awọn ẹni mímọ́” isin tabi ti o kún fún Mo Kí Ọ Maria ati orin alakọtunkọ—kò si ọ̀kankan ninu iwọnyi ti Baba gbọ́ ti o sì gbà. (Matiu 6:5-8) Siwaju sii, nipa Jesu, a kà ni Iṣe 4:12 pe: “Kò sì sí igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miiran labẹ ọrun ti a fifunni ninu eniyan, nipa eyi ti a lè fi gbà wá là.”
8 Jesu ni “otitọ.” Apọsiteli Johanu sọ nipa rẹ̀ pe: “Ọrọ naa sì di ara, oun sì ń bá wa gbé, (awa sì ń wo ogo rẹ̀, ogo bii ti ọmọ bibi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) ó kún fun oore-ọfẹ ati otitọ.” (Johanu 1:14) Jesu di otitọ ọgọrọọrun awọn asọtẹlẹ ninu Iwe Mímọ́ lede Heberu nipa mimu wọn ṣẹ. (2 Kọrinti 1:20; Iṣipaya 19:10) Ó sọ otitọ di mímọ̀ ni bíbá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ati awọn ogunlọgọ ti o fetisilẹ sí i sọrọ, ninu ṣiṣe gbolohun asọ̀ pẹlu awọn awujọ alufaa alagabagebe, ati nipa ọna ìgbà gbé igbesi-ayé rẹ̀.
9 Jesu ni “ìyè.” Gẹgẹ bi Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu wi pe: “Ẹni ti ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ni ìyè ainipẹkun: ẹni ti kò bá sì gba Ọmọ, gbọ́, ki yoo ri ìyè; ṣugbọn ibinu Ọlọrun ń bẹ lori rẹ̀.” (Johanu 3:36) Igbagbọ ti a mulo ninu ẹbọ Jesu ń ṣamọna si ìyè ainipẹkun—iwalaaye láìkú ninu ọ̀run fun “agbo kekere” kan ti awọn Kristẹni ẹni ami ororo ati ìyè ayeraye lori paradise ilẹ̀-ayé fun awọn ogunlọgọ ńlá ti “agutan miiran.”—Luuku 12:32; 23:43; Johanu 10:16.
Fifarada Inunibini
10. Eeṣe ti a fi nilati ‘ṣẹgun ayé,’ iṣiri wo sì ni Jesu fifunni niti eyi?
10 Awọn wọnni ti wọn nireti lati gbé ninu eto igbekalẹ titun ti Jehofa gbọdọ wọ̀jà pẹlu ayé ti “ó wà labẹ agbara ẹni buburu nì,” Satani Eṣu. (1 Johanu 5:19) Iru iṣiri wo, nigba naa, ni awọn ọrọ Jesu ni Johanu 15:17-19 jẹ́! O kéde pe: “Nǹkan wọnyi ni mo palaṣẹ fun yin pe, ki ẹyin ki o fẹran araayin. Bi ayé bá koriira yin, ẹ mọ pe, o ti koriira mi ṣaaju yin. Ìbáṣepé ẹyin iṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ awọn tirẹ; ṣugbọn nitori ti ẹyin kii ṣe ti ayé, ṣugbọn emi ti yàn yin kuro ninu ayé, nitori eyi ni ayé ṣe koriira yin.” Awọn Kristẹni tootọ ni a ti koriira jalẹjalẹ titi dé ọdun 1992 yii, awa sì ti layọ tó ninu apẹẹrẹ rere ti awọn wọnni ti ń baa lọ lati duro gbọnyingbọnyin, ti wọn ń fi irẹlẹ wá okun labẹ apá alagbara ti Ọlọrun! (1 Peteru 5:6-10) Gbogbo wa lè farada awọn adanwo nipa mimu igbagbọ lò ninu Jesu, ẹni ti o pari ijiroro rẹ̀ pẹlu awọn ọrọ amunilọkanyọ wọnyi: “Ninu ayé ẹyin ń ní ipọnju, ṣugbọn ẹ ni igboya! Mo ti ṣẹgun ayé.”—Johanu 16:33, NW.
Dídá Majẹmu Titun Silẹ
11. Ki ni Jeremaya sọtẹlẹ nipa majẹmu titun kan?
11 Ni alẹ́ yẹn, lẹhin ti ayẹyẹ Ajọ-Irekọja ti wá si opin, Jesu sọrọ nipa majẹmu titun kan. Wolii Jeremaya sọ asọtẹlẹ eyi ni ọpọ ọrundun ṣaaju, ni sisọ pe: “Wò ó, ọjọ ń bọ̀, ni Oluwa [“Jehofa,” NW] wi, ti emi yoo bá ile Isirẹli ati ile Juda dá majẹmu titun . . . Emi yoo fi ofin mi si inu wọn, emi yoo sì kọ ọ́ si àyà wọn; emi yoo sì jẹ́ Ọlọrun wọn, awọn yoo sì jẹ́ eniyan mi. . . . Emi yoo dárí aiṣedeedee wọn jì, emi ki yoo sì ranti ẹṣẹ wọn mọ.” (Jeremaya 31:31-34) Ni Nisan 14, 33 C.E., irubọ ti o fidii majẹmu titun yii mulẹ ni a o nilati ṣe!
12. Bawo ni Jesu ṣe dá majẹmu titun silẹ, ki ni o sì ṣaṣepari rẹ̀?
12 Jesu sọ fun awọn oluṣotitọ 11 naa pe oun ti fẹ́ gidigidi lati jẹ Ajọ-Irekọja yii pẹlu wọn. Lẹhin naa ó mu akara, ó dupẹ, ó bù ú, ó sì fifun wọn, ni wiwi pe: “Eyi ni araami ti a fifun yin: ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.” Ni ọna kan naa, ó gbe ago ti o ni ọtí waini pupa ninu fun wọn, ni wiwi pe: ‘Ago yii ni majẹmu titun, ẹ̀jẹ̀ mi ti a ta silẹ fun yin.’ (Luuku 22:15, 19, 20) Majẹmu titun ni a mú wà lẹnu iṣẹ nipasẹ “ẹ̀jẹ̀ iyebiye” Jesu, ti o niyelori ju ẹ̀jẹ̀ ẹran ti a fọ́n kaakiri ninu fifidii majẹmu ofin Isirẹli mulẹ! (1 Peteru 1:19; Heberu 9:13, 14) Awọn wọnni ti a mú wọnu majẹmu titun naa gbadun idariji ẹ̀ṣẹ̀ kikun. Fun idi yii, wọn lè tootun lati jẹ́ apakan 144,000, ti o gba ogún ainipẹkun kan gẹgẹ bii Isirẹli tẹmi.—Galatia 6:16; Heberu 9:15-18; 13:20; Iṣipaya 14:1.
“Ni Iranti Mi”
13. (a) Lori ki ni a gbọdọ ronu siwa-sẹhin ni akoko Iṣe-iranti? (b) Kiki awọn wo ni wọn gbọdọ ṣajọpin ninu awọn ohun iṣapẹẹrẹ naa, eesitiṣe?
13 Iṣe-iranti iku Jesu ọdọọdun ti ìgbà 1,960 bọ́ si April 17, 1992. Bi ọjọ yẹn ti ń sunmọ, ó dara ki a ronu siwa-sẹhin lori gbogbo ohun ti ẹbọ pípé Jesu ti ṣaṣepari. Iṣeto yii gbé ọgbọn Jehofa ati ifẹ rẹ̀ jijinlẹ fun araye leke. Iwatitọ alailabawọn Jesu, ani titi dé ojú iku onirora paapaa, dá Jehofa láre lodisi ẹ̀gàn Satani pe iṣẹda eniyan Rẹ̀ lálèéébù ati pe yoo kùnà labẹ idanwo. (Joobu 1:8-11; Owe 27:11) Pẹlu ẹ̀jẹ̀ irubọ rẹ̀, Jesu ṣe alarina majẹmu titun, ohun eelo Jehofa fun yíyan “ẹ̀yà-ìran ayanfẹ kan, ẹgbẹ́ alufaa ọlọba, orilẹ-ede mímọ́ kan, eniyan kan fun akanṣe ìní.” Nigba ti wọn ṣì wà lori ilẹ̀-ayé, awọn wọnyi “polongo kaakiri awọn itayọlọla” Ọlọrun wọn, Jehofa, ẹni ti o ti ‘pe wọn jade lati inu okunkun sinu imọlẹ agbayanu rẹ̀.’ (1 Peteru 2:9, NW; fiwe Ẹkisodu 19:5, 6.) Lọna ti o bojumu, awọn nikan ni ń ṣalabaapin ninu awọn ohun iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti lọdọọdun.
14. Bawo ni a ṣe sọ araadọta-ọkẹ awọn oluworan di ọlọ́rọ̀?
14 Ni ìgbà Iṣe-iranti ọdun ti o kọja, 10,650,158 pesẹ yika ilẹ̀-ayé, ṣugbọn laaarin awọn wọnyi kìkì 8,850—ó kere si ìdá kan ninu mẹwaa ipin 1 ninu ọgọrun-un—ni o ṣalabaapin ninu awọn ohun iṣapẹẹrẹ. Anfaani wo, nigba naa, ni ayẹyẹ yii ṣe fun araadọta-ọkẹ awọn oluworan? Ó ṣanfaani ńláǹlà! Bi o tilẹ jẹ pe wọn kò ṣalabaapin, a sọ wọn dọlọrọ nipa tẹmi nipa ibakẹgbẹ pẹlu ẹgbẹ́ ará kari ayé jantirẹrẹ yii, bi wọn ti ń gbọ gbogbo awọn ohun agbayanu ti Jehofa ṣaṣepari nipasẹ ẹbọ Ọmọkunrin rẹ̀.
15. Bawo ni awọn miiran yatọ si awọn aṣẹku ẹni ami ororo ṣe janfaani lati inu ẹbọ Jesu?
15 Siwaju sii, apọsiteli naa fi tó wa leti ni 1 Johanu 2:1, 2 pe: “Awa ní alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo: Oun sì ni ètùtù fun ẹṣẹ wa: kii sii ṣe fun tiwa nikan, ṣugbọn fun ti gbogbo araye pẹlu.” Bẹẹni, ẹbọ Jesu, nigba ti o ń ṣe ẹgbẹ́ Johanu ti a muwọnu majẹmu titun naa lanfaani lakọọkọ, pese fun idariji ẹṣẹ “gbogbo araye” pẹlu. Ó jẹ́ “ètùtù” fun ẹṣẹ gbogbo awọn miiran ti wọn mu igbagbọ lo ninu ẹ̀jẹ̀ Jesu ti a ta silẹ ninu ayé araye, eyi ti o ṣí ọna ireti alayọ ti ìyè ayeraye lori paradise ilẹ̀-ayé silẹ fun wọn.—Matiu 20:28.
“Ni Ijọba Baba Mi”
16. (a) Ninu ki ni ó farahan pe Jesu ati awọn ajumọjogun rẹ̀ ń ṣajọpin nisinsinyi? (b) Ki ni a beere fun lonii lọwọ awọn aṣẹku ẹni ami ororo ati awọn ogunlọgọ ńlá?
16 Ni biba a lọ lati maa fun awọn apọsiteli rẹ̀ niṣiiri, Jesu tọka si ọjọ naa nigba ti ní ọna iṣapẹẹrẹ kan yoo mu imujade àjàrà titun pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ninu Ijọba Baba rẹ̀. (Matiu 26:29) Ó sọ fun wọn pe: “Ẹyin ni awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi. Mo sì yan ijọba fun yin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi; ki ẹyin ki o lè maa jẹ́, ki ẹyin ki o sì lè maa mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹyin ki o lè jokoo lori ìtẹ́, ati ki ẹyin ki o lè maa ṣe idajọ fun awọn ẹ̀yà Isirẹli mejila.” (Luuku 22:28-30) Niwọn bi Jesu ti gba agbara Ijọba ni ọrun ni 1914, a lè pari ero pe pupọ ju ninu awọn ajumọ jogun pẹlu Jesu, ti a ti kójọ lati ọpọ ọrundun wá, ni a ti jí dide ṣaaju isinsinyi, lati “jokoo lori ìtẹ́” pẹlu rẹ̀. (1 Tẹsalonika 4:15, 16) Ọjọ naa fun awọn angẹli lati tú “afẹfẹ mẹrẹẹrin aye” ti “ipọnju ńlá” naa silẹ ń sunmọle pẹlu ìyára kánkán! Nigba naa, fifi èdídí dí 144,000 Isirẹli tẹmi ati kiko araadọta-ọkẹ ti awọn ogunlọgọ jọ yoo ti pé pérépéré. Gbogbo awọn wọnyi gbọdọ pa iwatitọ mọ, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe, ki wọn baà lè gba ẹbun ìyè ainipẹkun naa.—Iṣipaya 2:10; 7:1-4, 9.
17 ati apoti. (a) Bi a bá nilati kọ ẹni ami ororo kan silẹ gẹgẹ bi alaiduroṣinṣin, ta ni o ba ọgbọn mu pe ó lè rọpo rẹ? (b) Awọn ọrọ-ẹkọ ti ó jade ninu Ilé-Ìṣọ́nà 1938 tan imọlẹ onifẹẹ wo sori ìgbéró ati imugbooro eto-ajọ iṣakoso Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé?
17 Ki ni bi awọn ẹni ami ororo diẹ bá kuna lati jẹ́ olupa iwatitọ mọ? Ni akoko ti o ti lọ tan yii, iye iru awọn alaiduroṣinṣin bẹẹ ni yoo mọniwọn laiṣiyemeji. Lọna ti o ba ọgbọn mu, ìfidípò eyikeyii yoo wá, kii ṣe lára awọn ẹni titun ti a ṣẹṣẹ bamtisi, ṣugbọn lára awọn wọnni ti wọn ti wà pẹlu Jesu ninu idanwo rẹ̀ nipasẹ ọpọlọpọ ọdun iṣẹ-isin iṣotitọ. Titan yòò imọlẹ tẹmi ti o wá nipasẹ Ilé-Ìṣọ́nà ni awọn ọdun 1920 ati 1930 fihan pe ikojọ awọn aṣẹku ti ẹni ami ororo ni o ti pé pérépéré ni saa akoko yẹn. Awọn wọnni ti ‘nfọ aṣọ wọn ti wọn sì ń sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọdọ-agutan’ lati ìgbà naa ní ireti alayọ ti o yatọ. Nipasẹ Kristi, ẹmi Jehofa ṣamọna wọn si “orisun omi ìyè” ninu Paradise ilẹ̀-ayé.—Iṣipaya 7:10, 14, 17.
Adura Onígbòóná-Ọkàn Julọ
18. Awọn ẹkọ alagbara wo ni a kọ́ lati inu adura Jesu ni Johanu ori 17?
18 Jesu pari apejọ Iṣe-iranti rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nipa gbigba adura onígbòóná-ọkàn ti a kọsilẹ ni Johanu 17:1-26. Ó gbadura lakọọkọ pe ki Baba oun lè ṣe oun logo gẹgẹ bi oun ti pa iwatitọ mọ titi de opin. Ni ọna yii Jehofa pẹlu ni a ó ṣe logo, ti a o sọ orukọ rẹ̀ di mímọ́—ti a ó sì mu gbogbo ẹ̀gàn kuro lori rẹ̀. Nitori, nitootọ, Jesu eniyan pípé fihan niti gidi pe iṣẹda eniyan ti Ọlọrun lè jẹ́ aláìlálèébù, ani labẹ idanwo ti o lekoko julọ paapaa. (Deutaronomi 32:4, 5; Heberu 4:15) Siwaju sii, iku irubọ Jesu ṣí anfaani titobilọla silẹ fun iran ọmọ Adamu. Jesu wi pe: “Ìyè ainipẹkun naa sì ni eyi, ki wọn ki o lè mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ ran.” Ó ti pọndandan tó lati gba ìmọ̀ pipeye nipa Jehofa Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹni ti o fi ẹmi rẹ̀ lélẹ̀ fun idalare Jehofa ati igbala araye! (Johanu 1:29; 1 Peteru 2:22-25) Iwọ ha mọriri ẹbọ onifẹẹ julọ yẹn de iwọn yíya araarẹ si mímọ́ patapata fun Jehofa ati iṣẹ-isin ṣiṣeyebiye rẹ̀ bi?
19. Bawo ni awọn aṣẹku ati awọn ogunlọgọ ńlá ṣe lè gbadun iṣọkan ṣiṣeyebiye?
19 Siwaju sii, Jesu gbadura si Baba rẹ̀ Mímọ́ pe ki Ó maa ṣọ́ awọn ọmọ-ẹhin naa bi wọn ti ń fi araawọn han lati maṣe jẹ apakan ayé, rọ̀mọ́ ọrọ Rẹ̀ gẹgẹ bi otitọ, ti wọn sì pa iṣọkanṣoṣo ṣiṣeyebiye mọ pẹlu Baba ati Ọmọkunrin naa. A kò ha ti dahun adura yii lọna agbayanu jalẹ titi di ọjọ oni yii bi aṣẹku ẹni ami ororo ati awọn ogunlọgọ ńlá ti ń ṣiṣẹsin papọ pẹlu iṣọkan ninu ìdè ifẹ, nigba ti wọn ń pa aidasi tọtun-tosi mọ́ niti ayé, iwa ipá rẹ̀, ati iwa buburu rẹ̀ bi? Awọn ọrọ ipari Jesu sí Baba rẹ̀, Jehofa ti ṣeyebiye tó! “Mo ti sọ orukọ rẹ di mímọ̀ fun wọn, emi yoo sì sọ ọ́ di mímọ̀,” ni Jesu sọ, “ki ifẹ ti iwọ fẹran mi, lè maa wà ninu wọn, ati emi ninu wọn.”—Johanu 17:14, 16, 26.
20. Eeṣe ti o fi daju pe Nisan 14, 33 C.E., jẹ́ ọjọ naa lati ranti?
20 Bi o ti ń jade lọ sinu ọgba Getisemani, Jesu siwaju sii ni ifararora ṣoki, ti ń gbeniro pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Lẹhin naa awọn ọ̀tá rẹ̀ kàn án lara! Ọrọ kò lè ṣapejuwe irora Jesu lọna ti ara, ikarisọ bibanininujẹ nitori ẹ̀gàn ti a mú wá sori Jehofa, ati iwatitọ awofiṣapẹẹrẹ rẹ̀ la gbogbo rẹ̀ já. Jesu farada a dopin, la gbogbo oru já ati jalẹ ọpọ julọ ninu wakati ọsan ti ọjọ naa. O fi Ijọba rẹ̀ han kedere pe ki i ṣe apakan ayé. Ati pẹlu èémí ikẹhin rẹ̀, o kigbe pe: “O pari!” (Johanu 18:36, 37; 19:30) Ó pari ṣiṣẹgun ayé. Dajudaju Nisan 14, 33 C.E., jẹ ọjọ naa lati ranti!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọjọ Ijagunmolu ni Europe ati Ọjọ Ijagunmolu lori Japan.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni Jesu kọni nipa irẹlẹ ati ifẹ?
◻ Bawo ni Jesu ṣe di “ọna ati otitọ ati ìyè”?
◻ Ki ni ète majẹmu titun?
◻ Iṣọkan ati ifẹ wo ni awọn aṣẹku ẹni ami ororo ati awọn ogunlọgọ ṣajọpin rẹ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
Ọgbọn Solomọni Titobi Ju Naa
Awọn ọrọ-ẹkọ naa ti a pe ni “Eto-ajọ” ninu itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ti June 1 ati June 15, 1938 (èdè Gẹẹsi), fi idi iṣeto iṣakoso Ọlọrun pataki naa mulẹ tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹle titi fi di oni yii. Wọn mú saa pipẹtẹri kan ti iṣatunṣebọsipo ẹkọ igbagbọ ati ti eto-ajọ ti o bẹrẹ ni 1919 wá si òtéńté. (Aisaya 60:17) Ni fifi saa 20 ọdun yẹn wé 20 ọdun ti Solomọni fi kọ́ tẹmpili ati ile ọba ni Jerusalẹmu, Ilé-Ìṣọ́nà sọ pe: “Iwe Mímọ́ fihan pe, lẹhin ogún ọdun itolẹsẹẹsẹ ikọle Solomọni . . . , o lọwọ ninu ìdáwọ́lé ilé kíkọ́ kan jakejado orilẹ-ede. (1 Ọba 9:10, 17-23; 2 Kro. 8:1-10) Lẹhin naa ni ọbabinrin Ṣeba ‘lati awọn apa ìkángun patapata ilẹ̀-ayé wá lati gbọ ọgbọn Solomọni’. (Mat. 12:42; 1 Ọba 10:1-10; 2 Kro. 9:1-9, 12) Eyi ṣokunfa ibeere naa pe: Ki ni ó wà ni ọjọ-ọla ti o wọle dé tan fun awọn eniyan Jehofa lori ilẹ aye? Pẹlu igbọkanle kikun awa yoo duro, awa yoo sì rí i.” Igbọkanle yẹn ni a kò fi sibi ti kò yẹ. Labẹ eto-ajọ iṣakoso Ọlọrun itolẹsẹẹsẹ ìkọ́lé gbigbooro tẹmi kan kari ayé ti ṣakojọ iye ti o ju million mẹrin awọn ogunlọgọ ńlá. Bii ọbabinrin Ṣeba, awọn wọnyi ti wá lati awọn apa ìkángun patapata ilẹ̀-ayé lati gbọ ọgbọn Solomọni Titobiju naa, Kristi Jesu—ti a mu dé ọdọ wọn nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa.”—Matiu 24:45-47, NW.