Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ onkọwe Owe 30:19 nimọlara pe ọ̀nà ti ọkunrin kan gbà fi ọgbọ́n wẹ́wẹ́ yí wundia kan lero pada ṣagbere jẹ́ “iyanu” nitootọ bi?
Iyẹn jẹ́ itumọ ti o ṣeeṣe ti Owe 30:19, eyi ti a gbà pe kì í ṣe ẹsẹ kan ti o rọrun lati loye.
Ni wíwá òye ẹsẹ yii, a kò gbọdọ ṣainaani ayika ọrọ. Gan-an ṣaaju ayọka yii, onkọwe ti a mísí naa to awọn ohun mẹrin ti kò ṣee tẹlọrun lẹsẹẹsẹ ni ọ̀nà kan. (Owe 30:15, 16) Lẹhin naa ni o bẹrẹ itolẹsẹẹsẹ yii: “Ohun mẹta ni ń bẹ ti o ṣe iyanu fun mi, nitootọ, mẹrin ni emi kò mọ̀. Ipa idì loju ọ̀run; ipa ejò lori apata: ipa ọkọ̀ loju òkun; ati ìwà ọkunrin pẹlu wundia.”—Owe 30:18, 19.
Ki ni ìbá ti jẹ́ “iyanu” ninu awọn nǹkan mẹrin wọnyi?
Boya nipa níní imọlara pé “iyanu” gbọdọ dọgbọn tumọsi ohun ti ó daniloju tabi jẹ́ rere, awọn ọmọwe kan ṣalaye pe ọkọọkan ninu awọn ohun mẹrin naa fi ọgbọn iṣẹda Ọlọrun hàn: iyanu nipa bi ẹyẹ titobi kan ṣe lè fò, bi ejò ti kò lẹ́sẹ̀ kan ṣe lè rìn kọja ori apata, bi ọkọ̀ oju-omi wiwuwo kan ṣe lè léfòó téńté lori omi òkun oníjì, ati bi ọ̀dọ́ kan ti o taagun ṣe lè ṣubu sinu ifẹ lọna ainireti ki o sì gbé wundia ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan niyawo, ki wọn sì wá bí ọmọ eniyan agbayanu kan. Ọjọgbọn kan ri ijọra miiran ninu awọn nǹkan mẹrin naa, pe ọkọọkan ń rin ipa ọ̀nà kan ti ó jẹ́ titun lọjọ gbogbo—ìrìn idì kan, ejò, ati ọkọ̀ oju-omi nibi ti kò ti sí ipa ọ̀nà ati ìjẹ́ titun ifẹ tọkọtaya kan ti ń gbèrú.
Bi o ti wu ki o ri, awọn ohun mẹrin naa ni kò nilati jẹ́ “iyanu” ni èrò itumọ rere, gẹgẹ bi ẹni pe ohun ti wọn jumọ jọ ní jẹ́ ohun kan ti o daniloju. Owe 6:16-19 ṣe itolẹsẹẹsẹ ‘awọn ohun ti Jehofa koriira.’ Gẹgẹ bi a sì ti kiyesi i, gan-an ṣaaju awọn ẹsẹ ti o wà labẹ igbeyẹwo naa, Owe 30:15, 16 ṣe itolẹsẹẹsẹ awọn ohun (Isa-oku, inú àgàn, ilẹ ti kì í kun fun omi, ati iná ti ń jó) ti ki i sọ pe, “Ó tó” lae. Dajudaju wọn kò dara lọna agbayanu.
Ọ̀rọ̀ Heberu naa ti a tumọsi “iyanu” ni Owe 30:18 tumọsi “lati yasọtọ, lati dá fihan yatọ; lati mú dá yatọ, aramanda-ọtọ, iyanu.” Ohun kan le jẹ eyi ti a damọ yatọ, aramanda-ọtọ, tabi ṣe kayefi nipa rẹ̀ laijẹ ohun rere. Danieli 8:23, 24 sọ asọtẹlẹ ọba rírorò kan ti yoo fa iparun “ni ọ̀nà iyanu” ti yoo sì “mú awọn ẹni alagbara wá si iparun,” papọ pẹlu awọn ẹni mimọ.—Fiwe Deuteronomi 17:8; 28:59; Sekariah 8:6.
Ẹsẹ ti o tẹle Owe 30:18, 19 lè pese ojutuu kan nipa ohun ti onkọwe naa ri ti ó ṣoro lati loye. Ẹsẹ 20 mẹnukan obinrin agbere kan ẹni ti o “jẹun, o sì nu ẹnu rẹ̀ nù, o si wi pe, emi kò ṣe buburu kan.” Boya ni bookẹlẹ ati pẹlu ọgbọn arekereke ó ti dẹṣẹ, ṣugbọn niwọn bi kò ti sí itọpasẹ iwa-ọdaran rẹ̀, ó lè jẹwọ jíjẹ́ alaimọwọmẹsẹ.
Ifarajọra kan wà fun itolẹsẹẹsẹ ti iṣaaju. idì kan fò lọ sókè réré ni ofuurufu, ejò kan kọja lori apata, ọkọ̀ oju-omi kan la ìgbì òkun kọja—kò si eyi ti o fi ipa ami silẹ, yoo sì ṣoro lati tọpa ọ̀nà eyikeyii ninu awọn mẹtẹẹta. Bi eyi bá jẹ́ ohun ti o wọpọ si awọn mẹtẹẹta, ki ni nipa ti ikẹrin, “ìwà ọkunrin pẹlu wundia”?
A kò lè tọpa eyi pẹlu. Ọdọmọkunrin kan lè lo arekereke, ẹnu dídùn, ati ọ̀nà ọgbọn alumọkọrọyi lati dọgbọn ti araarẹ sinu awọn ifẹni wundia alaimọwọmẹsẹ kan. Bi o ti jẹ́ alainiriiri, oun lè má mọ ẹ̀tàn rẹ̀. Ani lẹhin ti o ti jẹ́ ẹni ti a yí lero pada ṣagbere paapaa, ó le má lè ṣalaye bi [ọmọkunrin] naa ṣe mú oun; awọn olùṣàkíyèsí paapaa lè ri pe ó ṣoro lati ṣalaye. Sibẹ, ọpọlọpọ awọn ọdọmọbinrin ti padanu iwa mimọ wọn fun olùtannijẹ alarekereke. Ó ṣoro lati tọpa ọ̀nà iru awọn ọkunrin ẹlẹtan bẹẹ, sibẹ wọn ni gongo kan, gẹgẹ bi idì kan tí ń fò, ejò ti ń yọ́ bẹ̀rẹ́, tabi ọkọ̀ oju-omi kan ni okun ti ní. Pẹlu awọn olùtannijẹ, gongo naa ni ikonifa niti ibalopọ takọtabo.
Ninu imọlẹ yii kókó Owe 30:18, 19 kì í ṣe nipa imọ ijinlẹ tabi awọn ohun iṣẹ ẹ̀rọ ninu iṣẹda. Kaka bẹẹ, ayọka naa pese ikilọ iwarere, gan-an gẹgẹ bi Owe 7:1-27 ti kilọ nipa yiyẹra fun awọn ewu aṣẹwo ti ń yinilero pada kan. Ọ̀nà kan ti awọn Kristian arabinrin lè gbà fi ikilọ Owe 30:18, 19 sọkan ni nipa awọn ọkunrin ti wọn fẹnujẹwọ ọkàn-ìfẹ́ ninu kikẹkọọ Bibeli. Bí ọkunrin kan ti o jẹ́ ẹni bi ọ̀rẹ́, ani oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ ẹni kan paapaa, ba jọbi ẹni ti o fi iru ọkàn-ìfẹ́ bẹẹ hàn, arabinrin kan gbọdọ dari rẹ̀ si arakunrin kan ninu ijọ. Arakunrin naa lè tẹ́ ojulowo ọkàn-ìfẹ́ eyikeyii lọrun laisi awọn ewu ti “ipa ọkunrin pẹlu wundia.”