Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ẹni tó kọ Òwe 30:18, 19 sọ pé “ọ̀nà ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀dọ́bìnrin” ‘kọjá òye òun.’ Kí ló ń sọ?
Ọ̀pọ̀ èèyàn làwọn ọ̀rọ̀ yẹn kò yé títí kan àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó mọ Bíbélì dáadáa. Nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àwọn ẹsẹ náà kà pé: “Ohun mẹ́ta wà tó kọjá òye mi, [tàbí “tó jẹ́ àgbàyanu fún mi,” àlàyé ìsàlẹ̀], àní ohun mẹ́rin tí kò yé mi: Ọ̀nà ẹyẹ idì lójú ọ̀run, ọ̀nà ejò lórí àpáta, ọ̀nà ọkọ̀ òkun lójú agbami, àti ọ̀nà ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀dọ́bìnrin.”—Òwe 30:18, 19.
Òye tá a ní tẹ́lẹ̀ ni pé ìwà tí ò dáa ni “ọ̀nà ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀dọ́bìnrin” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ẹsẹ míì nínú orí Bíbélì yẹn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ò dáa tí kì í sọ pé “ó tó.” (Òwe 30:15, 16) Yàtọ̀ síyẹn, ẹsẹ ogún (20) sọ nípa “obìnrin alágbèrè” tó sọ pé ohun tóun ń ṣe ò burú. Torí náà, èrò wa ni pé ẹsẹ yìí ń sọ nípa àwọn nǹkan tá ò lè rí ipa wọn tí wọ́n bá gba ibì kan kọjá, bí àpẹẹrẹ, ẹyẹ idì tó ń fò lójú ọ̀run, ejò tó ń lọ lórí àpáta, ọkọ̀ òkun tó ń lọ lójú agbami, tá a sì fi wé béèyàn ò ṣe lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín ọkùnrin kan àti ọ̀dọ́bìnrin kan. Nítorí àfiwé yẹn, a rò pé “ọ̀nà ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀dọ́bìnrin” nínú ẹsẹ yẹn ń sọ nípa ohun tí kò dáa, ìyẹn bí ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe fi ẹ̀tàn mú ọ̀dọ́bìnrin tí kò gbọ́n láti bá a lòpọ̀.
Àmọ́ ìdí pàtàkì wà tó mú ká gbà pé ohun tó dáa ni ẹsẹ yìí ń sọ. Ẹni tó kọ ẹsẹ Bíbélì yìí kàn ń sọ àwọn nǹkan àgbàyanu tó jọ ọ́ lójú ni.
Àwọn ìwé mímọ́ lédè Hébérù tí wọ́n fọwọ́ kọ fi hàn pé ohun tó dáa ni ẹsẹ yìí ń sọ. Ìwé Theological Lexicon of the Old Testament sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “kọjá òye mi” nínú Òwe 30:18 “ń sọ nípa ohun tí ẹnì kan gbà pé ó ṣàrà ọ̀tọ̀, nǹkan tó dà bíi pé kò ṣeé ṣe tàbí ohun tó yani lẹ́nu gan-an.”
Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nílé ìwé Harvard University lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ń jẹ́ Crawford H. Toy náà gbà pé ẹsẹ Bíbélì yìí kò sọ nípa ohun tí ò dáa. Ó sọ pé: “Ẹni tó kọ ẹṣẹ Bíbélì yìí kàn ń sọ nípa bí àwọn nǹkan náà ṣe yani lẹ́nu tó ni.”
Torí náà, ó dáa tá a bá gbà pé ohun tí Òwe 30:18, 19 ń sọ ni àwọn nǹkan tó yani lẹ́nu gan-an, ìyẹn àwọn nǹkan tó kọjá òye wa. Bíi tẹni tó kọ ẹsẹ Bíbélì náà, ó ya àwa náà lẹ́nu gan-an bí ẹyẹ idì ṣe ń fò lójú ọ̀run, bí ejò tí ò lẹ́sẹ̀ ṣe ń lọ lórí àpáta, bí ọkọ̀ òkun ràgàjì ṣe ń lọ lójú agbami àti bí ìfẹ́ ṣe ń kó sí ọ̀dọ́kùnrin kan àti ọ̀dọ́bìnrin kan lórí, tí wọ́n á sì jọ máa gbádùn ayé wọn.