ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 8/1 ojú ìwé 25
  • Jíjẹ́ Ki Ìmọ́lẹ̀ Wọn Tàn ni India

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ́ Ki Ìmọ́lẹ̀ Wọn Tàn ni India
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn” Kẹ́ Ẹ Lè Fògo fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • ‘Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Jíjẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Wá Máa Tàn Ṣáá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 8/1 ojú ìwé 25

Awọn Olupokiki Ijọba Rohin

Jíjẹ́ Ki Ìmọ́lẹ̀ Wọn Tàn ni India

IHINRERE Ijọba naa ni 11,524 Awọn Ẹlẹ́rìí alayọ ni India ti waasu. (Matteu 24:14) Awọn 1,066 ti a baptisi laaarin ọdun iṣẹ isin 1991 jẹ́ olupokiki Ijọba, wọn ń jẹ́ ki imọlẹ wọn tàn si awọn ẹlomiran. Ẹ wo bi gbogbo wọn ti layọ to lati rí i ti 28,866 pésẹ̀ si ibi ayẹyẹ Iṣe-iranti iku Kristi!

◻ Ọpọ ni wọn kọkọ kẹkọọ nipa ireti Ijọba naa nipasẹ ijẹrii aijẹ-bi-aṣa. Fun apẹẹrẹ, Ẹlẹ́rìí kan sọrọ nipa Ijọba naa fun awọn oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ̀, ti awọn pẹlu jẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan dahun pada o si bẹrẹ sii jẹ́ ki imọlẹ rẹ̀ tàn si idile ati awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Awọn wọnyi fi idunnu gbe ihin-iṣẹ Ijọba agbayanu yii kọja si ọdọ awọn ẹlomiran. Gẹgẹ bi irohin naa ti wi, ni kiki ọdun diẹ ‘eyi ti o ju 30 eniyan lọ ni wọn ti gba otitọ.’ Jehofa bukun fun oun ati awọn arakunrin rẹ̀ tẹmi titun fun jíjẹ́ ki imọlẹ wọn tàn.

◻ Arakunrin ọ̀dọ́ kan ní ìjọ miiran jẹ́ ki imọlẹ rẹ̀ tàn nipa jijẹrii fun awọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ ni ile-ẹkọ lọna aijẹ-bi-aṣa. Awọn diẹ ninu wọn lọkan-ifẹ ninu ireti Ijọba naa, oun si sábà maa ń ṣalaye Bibeli fun wọn titi di ọ̀gànjọ́ òru. Katoliki kan mú iduro gbọnyingbọnyin fun otitọ bi o tilẹ jẹ pe alufaa ti kilọ fun un nipa iyọrisi lilekoko ti ó ba ń baa lọ ni didarapọ mọ Awọn Ẹlẹ́rìí. Bi o ti wu ki o ri, o dá akẹkọọ naa loju pe ń ṣe ni oun ń kẹkọọ otitọ Bibeli lati ọdọ Awọn Ẹlẹ́rìí, o si ń baa lọ ni gbigba imọ. Lẹ́hìn-ọ̀-rẹhìn, o ṣe iribọmi ó si ń sìn nisinsinyi gẹgẹ bi iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ninu ìjọ. Ó yọ̀ ninu ireti ti o wá lati inú imọlẹ agbayanu otitọ naa!—Romu 12:12.

◻ Ẹlomiran ti o fetisilẹ si ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí yii ni akẹkọọ ti a mọ̀ daradara kan, alaigbagbọ ninu wíwà Ọlọrun, ẹni ti o maa ń fi awọn ti wọn jẹwọ igbagbọ ninu Ọlọrun ni gbangba ṣẹ̀sín, ṣugbọn ni ọjọ kan oun darapọ ninu ijiroro naa o si beere ọpọ ibeere. Ó yà á lẹnu nigba ti o ri awọn idahun ti o lọ́gbọ́n ninu si gbogbo awọn ibeere rẹ̀ o si wa sori ipari ero naa pe Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. O tẹsiwaju ninu imọ Bibeli o si ṣe iribọmi nikẹhin. Baba rẹ̀ ti o jẹ́ onisin Hindu ṣodi si i dori lile e jade kuro ninu ile rẹ̀. Sibẹsibẹ, iduro gírí ọdọmọkunrin yii fun otitọ ni a san èrè fun nigba ti meji ninu awọn arakunrin rẹ̀ nipa ti ara ati meji ninu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gba otitọ ti wọn si ṣe iribọmi. Ọ̀kan ninu awọn arakunrin rẹ ń ṣiṣẹsin nisinsinyi ni ẹka ile-iṣẹ ni India.

◻ Oluṣetojọ awọn akẹkọọ kan pẹlu darapọ ninu ijiroro pẹlu ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí naa. Oun jẹ́ amusiga afìkanrànkan ati ọmuti paraku. Ni akoko kan, oun ti fẹ́ lati lu awọn akẹkọọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ meji kan ti wọn ti kẹkọọ otitọ lati ọdọ Awọn Ẹlẹ́rìí. Nitori gbigba otitọ, wọn ti kọ̀ jálẹ̀ lati darapọ ninu síso ìpàǹpá ni ile-ẹkọ naa ati pẹlu wọn kò fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ lakooko ikede iṣakojọ ẹ̀jẹ̀ tí oluṣetojọ awọn akẹkọọ naa ṣe agbatẹru rẹ̀. Ọdọmọkunrin yii layọ nisinsinyi lati jẹ́ Ẹlẹ́rìí olutan imọlẹ ti Jehofa.

◻ Ninu gbogbo rẹ̀, akẹkọọ naa ti o kọkọ jẹ ki imọlẹ rẹ̀ tàn ti jẹ́ irinṣẹ ninu ríran 15 ninu awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ lọwọ si iyasimimọ ati iribọmi nipa jijẹrii fun wọn laijẹ-bi-aṣa.

Ohun ayọ ni lati ri ọpọlọpọ ni orilẹ-ede nla yẹn ti wọn ń tẹwọgba ireti Bibeli ti ayé titun Ọlọrun ti wọn si ń darapọ mọ ẹgbẹ ará kari ayé tí Jehofa Ọlọrun ń kójọ lati walaaye titilae labẹ Ijọba rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́