Iwọ Lè Kojú Ìjákulẹ̀!
GBÉ ọran ipo-iṣoro ti ọkunrin ẹni ọdun 23 kan yẹwo. Kò kàwé pupọ owó ti ó sì ń gbà lẹnu iṣẹ kò tó-nǹkan. Ironu nipa gbigbeyawo ati igbesi-aye titẹnilọrun kan dabi ohun ti kò tilẹ ṣee ronu kàn fun un. Abajọ ti iya rẹ̀ fi sọ pe: “Ó ni ibanujẹ ati ìjákulẹ̀ tí ó lé kenkà.” Ọran ọkunrin yii jẹ apẹẹrẹ ti araadọta-ọkẹ miiran. Fun idi kan tabi omiran, awọn eniyan lati inu oniruuru ipo igbesi-aye ní ijákulẹ̀.
Ìjákulẹ̀ ni “imọlara jijinlẹ onigba pípẹ́ tabi ipo ailaabo, irẹwẹsi, ati ainitẹẹlọrun ti ń jẹyọ lati inu ìfẹ́-ọkàn ti o foriṣanpọn, awọn ijakadi inu lọhun-un, tabi awọn iṣoro alailojutuu miiran.” (Webster’s Third New International Dictionary) A maa ń ni iriri ìjákulẹ̀ nigba ti a ba gbiyanju kárakára lati ṣaṣepari ohun kan ṣugbọn ti a kò kẹsẹjari. A maa ń nimọlara pe a sé wa mọ́ gádígádí, bi ẹni pe a ń lu ori wa mọ ògiri olokuuta kan, laisi ṣiṣeeṣe kan fun kikẹsẹjari. Gbogbo wa ni a mọ imọlara naa.
Awọn oṣiṣẹ ti o dabi pe wọn ń ṣe awọn iṣẹ alaitẹnilọrun lè ni imọlara aijamọ-nǹkan. Bi a ba fọwọ́ tẹtẹrẹ mu wọn, awọn iyawo tabi awọn ìyá ti ń jijakadi pẹlu awọn aniyan ojoojumọ ati awọn ẹrù-iṣẹ́ ti ń tannilokun lè nimọlara ailaṣeyọri, pe a kò mọriri wọn. Awọn ọdọ ti wọn ń dojukọ adanwo ni ilé-ẹ̀kọ́ lè nimọlara ìjákulẹ̀ ninu isapa lati ni ìmọ̀-ẹ̀kọ́. Awọn mẹmba ẹgbẹ awọn eniyan ti wọn kere julọ ni wọn lè nimọlara ọkan-gbigbọgbẹ, ni nini igbagbọ pe wọn jẹ ojiya fifi aitọ huwa sini lọna òdì. Awọn ọkunrin oniṣowo ti wọn ń gbiyanju lọna ailabosi lati pese awọn ohun amujade tabi awọn ipese ti o pójú-owó ni a lè jẹrun lati ọdọ awọn abanidije alaitẹle-ilana ati alabosi. Iwọnyi ati awọn iriri ti o farajọ ọ ń fa ìjákulẹ̀ o si ń fi ọpọlọpọ silẹ pẹlu imọlara ainireti.
Ọkunrin ọlọgbọn kan ti o gbé ayé ni ọpọ ọrundun sẹhin ni o ṣeeṣe fun lati kọ awọn ìjákulẹ̀ rẹ̀ silẹ ni ọ̀rọ̀ ti a lè loye. Solomoni ọba Israeli sọ pe: “Nigba ti mo wo gbogbo iṣẹ ti ọwọ mi ṣe, ati làálàá ti mo ṣe làálàá lati ṣe: si kiyesi i, asán ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo, kò si si èrè kan labẹ oorun. Nitori pe ki ni eniyan ni ninu gbogbo làálàá rẹ̀ ti o fi ń ṣe làálàá labẹ oorun? Nitori pe ọjọ rẹ̀ gbogbo, ikaaanu ni, ati iṣẹ rẹ̀, ibinujẹ, nitootọ àyà rẹ̀ kò sinmi ni oru. Eyi pẹlu asan ni.” (Oniwasu 2:11, 22, 23) Awọn ọ̀rọ̀ Solomoni ṣalaye ainireti ti ọpọlọpọ ń nimọlara ni gbigbiyanju lati koju ìjákulẹ̀ ti o ń jà wọn lólè igbesi-aye titẹnilọrun kan.
Awọn eniyan ti a jákulẹ̀ paapaa lè di agbekuta. Ninu awọn ọran lilekoko awọn diẹ ti pa ijakadi naa tì, ni didi aláìbẹ́gbẹ́ṣe ti ń gbe igbesi-aye alaibawujọmu. Lati ri ohun ti wọn nimọlara pe awọn lẹ́tọ̀ọ́ si gbà, awọn kan ti yiju si iwa-ọdaran ati iwa-ipa. Awọn ikimọlẹ ti kò dáwọ́ duro ti fọ́ awọn ìdè idile ati ti igbeyawo túútúú.
Ọpọlọpọ ninu wa lè nilati lo isapa pupọ ni wíwá awọn ọ̀nà lati kojú ìjákulẹ̀ kiri. Laika ohun ti a ṣe si, awọn nǹkan lè dabi eyi ti o tubọ ń buru sii. Owe 13:12 sọ pe: “Ireti pipẹ mu ọkan ṣaisan.” Ipo ilera wa nipa ti ara ati tẹmi ni a lè wu lewu. Ipo naa ha jẹ ti ainireti bi? Awa ha gbọdọ maa gbe pẹlu ìjákulẹ̀ igba gbogbo gẹgẹ bi ijiya fun awọn aitootun ati aṣiṣe wa bi? Ǹjẹ́ a ha lè gbe awọn igbesẹ ti o bọgbọn mu kan lati kojú ìjákulẹ̀ ki a baa lè gbadun igbesiaye kan ti o tubọ tẹnilọrun bi? Ẹ jẹ ki a wòó ná.
Awọn Ọ̀nà Diẹ Lati Gbà Kojú Ìjákulẹ̀
Nigba ti a ba ni iṣoro kan ti a sì nilo imọran, a sábà maa ń lọ sọdọ ẹnikan ti o jẹ onimọ, oniriiri ti a lè gbọkanle. Owe 3:5, 6 damọran pe: “Fi gbogbo àyà rẹ̀ gbẹkẹle Oluwa [“Jehofa,” NW]; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ̀ ara rẹ. Mọ̀ ọ́ ni gbogbo ọ̀nà rẹ: oun o si maa tọ́ ipa-ọna rẹ.” Awọn imọran ti o bọgbọn mu ni a lè ri ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Ṣagbeyẹwo awọn apẹẹrẹ diẹ ninu awọn ìjìnlẹ̀-òye ti o pese.
Ìjákulẹ̀ lè nii ṣe pẹlu wiwa ounjẹ oojọ. Fun apẹẹrẹ, iṣẹ wa nipa ti ara lè jẹ eyi ti ń tẹnilọrun, ṣugbọn owó-iṣẹ́ ti kò tó-nǹkan lè jẹ orisun isorikọ kan. A fẹran awọn idile wa a si ń fẹ ohun ti o dara julọ fun wọn. Sibẹ, o dabii pe kò si opin si aniyan nipa kíkojú awọn ẹrù-iṣẹ́ ìṣúnná-owó wa. Awa lè ṣe àlékún wakati iṣẹ ki a tilẹ tun maa ṣe iṣẹ keji pẹlu. Lẹhin akoko diẹ igbesi-aye wá dabi iyipoyipo amú-nǹkan-súni ti jíjẹ, sísùn, ati ṣiṣiṣẹ. Sibẹ, awọn ìwé-owó ti a o san a maa ga sii, gbèsè a maa ṣẹ́jọ, ti ìjákulẹ̀ a si maa korajọ pelemọ.
Ète akọkọ fun ṣiṣe iṣẹ ti ara ni lati pese fun awọn aini wa. Ṣugbọn bawo ni ohun ti a nilo ti pọ̀ tó? Aposteli naa Paulu kọwe pe: “Nitori a kò mu ohun kan wá si ayé, bẹẹ ni a kò si lè mu ohunkohun jade lọ. Bi a ba si ni ounjẹ ati aṣọ iwọnyi yoo tẹ́ wa lọrun.” Awa ha ń gbiyanju lati ní ohun ti o ju iyẹn lọ ki a baa lè ní tó awọn ẹlomiran tabi ṣe ohun ti wọn lè ṣe bi? Bi ọran ba ri bẹẹ, a le maa kórè awọn abajade rẹ̀ pẹlu ijakulẹ. Paulu kilọ pe: “Ṣugbọn awọn ti ń fẹ di ọlọrọ a maa bọ́ sinu idanwo ati idẹkun, ati sinu wèrè ifẹkufẹ pupọ ti i panilara, iru eyi ti i maa ri eniyan sinu iparun ati ègbé. Nitori ifẹ owó ni gbòǹgbò ohun buburu gbogbo: eyi ti awọn miiran ń lepa ti a si mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ, wọn si fi ibinujẹ pupọ gún ara wọn ni ọ̀kọ̀.” (1 Timoteu 6:7-10) Idiyele alailabosi nipa awọn ilepa wa nipa ti ara lè ṣí awọn ohun kan ti a kò nilo niti gidi paya. Awọn atunṣebọsipo lilọgbọninu diẹ siha ṣíṣọ́ owó ná ati ọ̀nà igba gbe igbesi-aye ti o jẹ́ ti oniwọntunwọnsi lè ṣe iranlọwọ pupọ siha didin ìjákulẹ̀ wa kù.
Awọn ìfẹ́-ọkàn adanida ti a kò tii muṣẹ ti ṣokunfa ọpọ ìjákulẹ̀. Fun apẹẹrẹ, ó jẹ́ iwa-ẹda fun ọdọbinrin kan lati ni iharagaga lilagbara lati ni ọkọ ki o si ni aabo ati ifẹni ọlọyaya ti ń wá pẹlu igbesi-aye idile. Ó lè lọ jinna debi mímú araarẹ jojúnígbèsè pẹlu awọn àṣà-ìwọṣọ ti ó lòde tabi awọn aranṣe iṣaraloge ó sì lè di olufitaratara ka awọn iwe-irohin atigbadegba ti ń fun awọn ti ń ṣòjòjò ifẹ ni imọran. Obinrin naa lè lọ si aimọye awọn ikorajọpọ ẹgbẹ-oun-ọgba pẹlu ireti pipade ẹnikan ti ọ̀rọ̀ wọn jìjọ wọ̀—gbogbo rẹ̀ lori asán. Bi ọdun ti ń gori ọdun, ìjákulẹ̀ naa ń di alaiṣeemumọra mọ́. Ninu igbekuta a lè dẹ ẹ́ wò lati fẹ́ ẹnikan ti kò yẹ. Lọna ti o buru ju sibẹ, lati tẹ́ iyanhanhan rẹ̀ fun ifẹni lọrun, ó lè lọwọ ninu iwa palapala.
Ninu iru ọran bẹẹ, suuru ati idajọ rere ni o ṣe pataki. Igbeyawo pẹlu ẹnikan ti kò yẹ—ni pataki ẹnikan ti kò ni igbagbọ ninu Jehofa—yoo jẹ aṣiṣe wiwuwo kan. (1 Korinti 7:39; 2 Korinti 6:14, 15) Iwa palapala laiṣeeyẹsilẹ kò ṣamọna si ohunkohun bikoṣe ẹ̀dùn-ọkàn jijinlẹ ati ainireti. (Owe 6:32, 33) Iṣayẹwo-ara-ẹni alailabosi, papọ pẹlu iṣabojuto ọran naa lọna lilọgbọn-ninu, lè ṣeranwọ. “Ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu” lè fa alábàáṣègbéyàwó títọ́ kan mọra daradara ju bi awọn aṣọ oge tabi awọn ohun iṣẹsọ arabara ti lè ṣe lọ. (1 Peteru 3:3, 4) Dipo gbigbarale awọn imọran ògbógi ayé ti o ń figba gbogbo jẹ alairiran jinna tabi alainilaaari, o ṣekoko lati lọ sọdọ Olupilẹṣẹ igbeyawo lati kẹkọọ ohun ti a nilo lati jẹ iyawo kan ti a fẹran ti a si ṣìkẹ́. (Owe, ori 31) Awọn ọkunrin ati obinrin ti kò tii gbeyawo nilati gbiyanju lati fi awọn animọ ti wọn yoo fẹ́ ninu alábàáṣègbéyàwó kan hàn. Bawo ni o ti lọgbọn-ninu tó lati wá ibakẹgbẹpọ rere pẹlu awọn eniyan ti wọn bọwọ fun awọn ilana Bibeli. Bi a ba fi awọn wọnyi silo ninu igbesi-aye, ṣiṣeeṣe igbeyawo alayọ kan laipẹ-laijinna yoo jẹ eyi ti o sanju lọna ti kò láàlà. Koda bi igbeyawo kò ba tilẹ ṣeeṣe ni bayii, gbigbegbeesẹ ni ibamu pẹlu Iwe Mimọ yoo mu ayọ wa yoo si mu igbesi-aye wíwà ní àpọ́n jẹ eyi ti o lérè pupọ jọjọ.
Ẹrù wiwuwo tí awọn iṣẹ-aigbọdọmaṣe lè mu wa dori kókó níní ibinu kikoro. Ikimọlẹ lè wá lati ìhà gbogbo. A ń ṣaniyan nipa awọn aini kanjukanju idile wa, o si lè má ṣeeṣe lati tẹ́ agbanisiṣẹ wa lọrun lae. Awọn ibatan lè ṣereti pe ki a nawọ iranwọ si wọn nigba gbogbo ti wahala ba ti ṣẹlẹ. Nitori ọpọ ikimọlẹ, akọsilẹ jàn-ànràn ti awọn ọran ara-ẹni ti a ti fi silẹ laibojuto yoo maa beere fun afiyesi. O lè dabi ẹni pe gbogbo akoko ati okun wa ni a nilati dari si ọpọ oniruuru ìhà lẹẹkan-naa. Ìjákulẹ̀ lè yipada si ibinu kikoro, ti a si lè nimọlara jijuwọsilẹ. Nitori naa, kí ni ohun ti a nilati ṣe?
Awa yoo jẹ ọlọgbọn lati tun idiyele awọn ohun akọmuṣe wa ṣe. Niwọn bi a ti lè ṣe kiki ohun ti agbara wa ká, kò ṣeeṣe lati raye gba gbogbo ohun ti awọn ẹlomiran ń beere fun. A nilati dín awọn nǹkan kù si ‘awọn ohun ti o ṣe pataki jù.’ (Filippi 1:10) O ṣetan, “àyè aja san jù oku kinniun lọ.” (Oniwasu 9:4) Awọn ẹrù-iṣẹ́ melookan ṣekoko kò si ṣee patì, nigba ti o jẹ pe awọn wọnni ti kò fi bẹẹ ṣekoko lè nilati duro ná. A lè ti tẹ́rígba awọn ẹrù-iṣẹ́ kan ti o yẹ ki a ṣajọpin rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran. Awọn ẹru-iṣẹ melookan ni o lè beere pe ki a yọ danu patapata bi wọn kò ba ṣe pataki. Bi o tilẹ jẹ pe eyi lè fa airọgbọ nibẹrẹ tabi ki o já awọn ẹlomiran kulẹ̀, o yẹ ki a bọwọ fun awọn ààlà tiwa funraawa niti ara iyara ati ero imọlara.
Aisan kan ti ń wónilára lè mu ìjákulẹ̀ mimuna wá, nitori ti o lè mu wa dubulẹ aisan fun ọjọ pipẹ tabi awọn ọsẹ melookan lẹẹkan-naa. Irora biburu jai lè sọ wa di onidaamu-ọkan. Ni ṣiṣe iwakiri fun iwosan, a lè lọ lati ọdọ dokita kan si omiran tabi ki a lo ọpọ oogun tabi awọn vitamin ni ireti pe wọn yoo lè ṣe rere diẹ. Sibẹ, a lè maa baa niṣo lati jiya ki a si bẹrẹ sii ṣe kayefi bi igbesi-aye ba tilẹ toye fun ijakadi ti a ń ṣe.
Eyi lè jẹ iṣoro kan ti a o wá ojútùú si kiki ninu ayé titun Ọlọrun. (2 Peteru 3:13; fiwe Isaiah 33:24.) Niwọn bi awọn eniyan ti jẹ alaipe, awọn dokita ati awọn egboogi lè ṣe kiki ohun ti agbara wọn ká. Ni awọn aaye ipo kan o le beere pe ki a tewọgba ijiya wa gẹgẹ bi apakan igbesi aye. Aposteli Paulu ni “ẹ̀gún kan . . . lara” boya ipọnniloju kan ninu oju rẹ̀ tabi ẹya miiran ninu ara rẹ̀, o yọ ọ lẹnu gan an debi pe o gbadura leralera fun itura. (2 Korinti 12:7-10) Ṣugbọn Ọlọrun kò mu Paulu larada, boya aposteli naa ti nilati jijakadi pẹlu ipọnniloju naa titi di akoko iku rẹ̀. Ó gbé pẹlu awọn ijiya rẹ̀, kò beere fun ìkáàánú, kò si figbakanri padanu ayọ rẹ̀. (2 Korinti 7:4) Bi o tilẹ jẹ pe Jobu ọkunrin olododo naa jiya ipọnniloju titobi, o pa igbagbọ rẹ̀ ninu Jehofa mọ́, eyi si ṣamọna si èrè jìngbìnnì. (Jobu 42:12, 13) Bi a ba jẹ iranṣẹ Ọlọrun, a lè ri okun lati maa baa lọ nipa rironu lori awọn apẹẹrẹ wọnyi ati gbigbadura fun iranlọwọ Jehofa.—Orin Dafidi 41:1-3.
Jijẹ Alagbara Laika Ìjákulẹ̀ Sí
Awọn eniyan Jehofa lè jẹ alagbara nipa tẹmi laika ìjákulẹ̀ eyikeyii si. Fun apẹẹrẹ, bi o tilẹ jẹ pe a lè nilati farada amodi, a ṣi lè jẹ “ẹni ti o yè kooro ni igbagbọ” nipa lilo awọn ipese Ọlọrun nipa tẹmi lẹkun-unrẹrẹ. (Titu 2:1, 2) Nigba ti a lè jẹ́ alaini nipa ti ara lọna ti ń jánikulẹ̀, a lè jẹ ọlọrọ nipa tẹmi lọna agbayanu.
Nipa gbigbarale Ọlọrun fun ọgbọn ati okun, a lè kojú awọn ìjákulẹ̀ ti o lè dide lati inu awọn ipo abẹle. Fun apẹẹrẹ, gbe ọran Abigaili, iyawo Nabali yẹwo. Ọkunrin naa jẹ “onroro ati oniwa buburu,” ti orukọ rẹ̀ gan-an si tumọsi “Òpònú; Dìndìnrìn.” Bawo ni yoo ti jánikulẹ̀ tó lati gbé pẹlu iru ọkunrin bẹẹ! Sibẹ, Abigaili jẹ “olóye obinrin” oun kò si sọretinu. Niti tootọ, awọn ọ̀rọ̀ ati iṣe rẹ̀ jẹ ti ọlọgbọn tobẹẹ debi pe laaarin wahala kan o yi Dafidi lọ́kàn pada lati maṣe gbẹsan iwọsi ati aimoore Nabali nipa tita ẹ̀jẹ̀ silẹ ki o si tipa bẹẹ kuna lati gbọkanle Jehofa.—1 Samueli 25:2-38.
Koda bi ipo ọran kan ti o kan ẹnikan ti ń darapọ mọ ijọ Kristian ba ń fa ìjákulẹ̀ bá wà, a lè farada ninu okun naa ti Jehofa ń fifun wa. Eyi ni a fihàn nipa otitọ naa pe iwa Diotrefe ti o ṣeeṣe lati jánikulẹ̀ ni kò dá Gaiu ọkunrin oniwa-bi-Ọlọrun naa duro ni ṣiṣe rere ti o si tipa bẹẹ ká ayọ ati awọn èrè tẹmi didọṣọ.—Iṣe 20:35; 3 Johannu 1-10.
Ìjákulẹ̀ lè jẹyọ bi a ba daniyan lati ṣiṣẹsin awọn arakunrin ẹlẹgbẹ wa ninu ijọ ṣugbọn ti a fò wá dá nigba ti a ń yan awọn ẹlomiran gẹgẹ bi alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ. Dipo ki a gba ìjákulẹ̀ laaye lati bò wa mọ́lẹ̀, bi o ti wu ki o ri, ẹ jẹ ki a wá ọ̀nà lati fun araawa lokun nipa tẹmi ki a si gba ẹmi Ọlọrun laaye lati so awọn eso rere rẹ̀ ninu wa titi de àyè ti o tubọ pọ̀ sii. (Galatia 5:22, 23) Laaarin 40 ọdun ti Mose lò ni Midiani, Ọlọrun mu iwapẹlẹ, suuru, ati awọn animọ miiran ti o nilo lati koju awọn inira ati ìjákulẹ̀ ti oun yoo ba pade gẹgẹ bi aṣaaju awọn ọmọ Israeli dàgbà ninu rẹ̀ de iwọn ti o tubọ pọ̀ sii. Ni ifarajọra, Jehofa lè maa mura wa silẹ fun awọn anfaani iṣẹ-isin ọjọ-ọla ti o lè kan wá bi a ba ṣì wa bi alagbara nipa tẹmi ti a kò si juwọsilẹ fun ìjákulẹ̀.
Itura Kuro Lọwọ Ìjákulẹ̀—Laipẹ!
Iyoowu ki o jẹ́, awọn ìjákulẹ̀ wa yoo ha dopin lae bi? Fun wa, ipo ọran wa lè dabi alainireti ṣugbọn kò rí bẹẹ fun Ẹlẹdaa wa, Jehofa Ọlọrun. Oun kìí ṣe ẹni ti ìjákulẹ̀ ń bá. Nipasẹ wolii Isaiah, Ọlọrun sọ pe: “Bẹẹni ọrọ mi ti o ti ẹnu mi jade yoo ri: kì yoo pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yoo ṣe eyi ti o wù mi, yoo si maa ṣe rere ninu ohun ti mo rán an.” (Isaiah 55:11) Niwọn bi Jehofa ti jẹ alagbara ati alaṣẹ gbogbo, kò si ohun ti kò ṣeeṣe fun un. (Marku 10:27) Awọn ileri rẹ̀ lati mu awọn ibukun alailopin wá fun awọn eniyan rẹ̀ ni o daju pe a o mu ṣẹ.—Joṣua 21:45.
Iyemeji ati aidaniloju ni awọn ohun ti o ń ṣe okunfa ìjákulẹ̀ julọ. Ni odikeji, bi o ti wu ki o ri, “igbagbọ ni idaniloju ohun ti a ń reti.” (Heberu 11:1) Igbagbọ ninu Ọlọrun ń pese idaniloju kan pe gbogbo awọn ireti wa ti a gbekari Bibeli ni a o ri gba lẹkun-unrẹrẹ. Ẹṣin-ọrọ Bibeli latokedelẹ tẹnumọ ileri Jehofa fun iṣakoso Ijọba, labẹ eyi ti ayé yoo di paradise pipe nibi ti awọn eniyan olododo yoo ti walaaye titilae pẹlu idunnu. (Orin Dafidi 37:11, 29) Ohunkohun ti o jẹ buburu—titikan ìjákulẹ̀—yoo ti rekọja lọ, nitori Ọlọrun yoo “tẹ́ ifẹ gbogbo ohun alaaye lọrun.”—Orin Dafidi 145:16.
Titi di igba ti awọn ibukun wọnni yoo di eyi ti ọwọ́ tẹ̀, gbogbo wa ni yoo ni ipin tiwa ninu ìjákulẹ̀. Ṣugbọn ireti Iwe Mimọ lè fun wa ni igboya ati ifayaran lati foriti. Imọran pipeye naa ti a ri ninu Bibeli lè fi hàn wá bi a ṣe lè lo idajọ rere ati ilọgbọn-ninu ni ọ̀nà kan ti o lè mu idurodeedee ba igbesi-aye wa ati alaafia bá ọkàn wa. Laika awọn ìjákulẹ̀ wa si, a lè niriiri “alaafia Ọlọrun, ti o ju imọran gbogbo lọ.” (Filippi 4:6, 7) Nitori naa ijakadi naa lodisi ìjákulẹ̀ kìí ṣe alainireti. Pẹlu iranwọ Jehofa a lè kojú rẹ̀ lonii ki a si ṣẹgun rẹ̀ lọla.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]
Ọlọrun lè ràn ọ́ lọwọ lati kojú ìjákulẹ̀, paapaa gẹgẹ bi o ti ṣeranwọ fun Jobu, Mose, Abigaili, ati Paulu