ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 2/1 ojú ìwé 28-31
  • O Lè Borí Iyèméjì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Borí Iyèméjì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Fa Àwọn Ipò Tí Kò Dáni Lójú
  • ‘Níní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìdánilójú Ìrètí Náà’
  • Àwọn Ìbùkún Tí Ìfọ̀kànbalẹ̀ Tẹ̀mí Ń Fúnni Nísinsìnyí
  • Ẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Bí Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ààbò Tòótọ́ Nísinsìnyí àti Títí Láé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Bá A Ṣe Lè Nírètí Nínú Ayé Tó Kún fún Ìpọ́njú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Jèhófà, ‘Odi Agbára Wa Ní Àkókò Wàhálà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 2/1 ojú ìwé 28-31

O Lè Borí Iyèméjì

“Ó DÁJÚ hán-ún!” “Kò lè yẹ̀!” “Mìmì kan ò lè mì ín!” Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Àmọ́, ohun tó dání lójú kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Ìgbésí ayé ó dáni lójú rárá, ó tiẹ̀ máa ń ṣe wá ní kàyéfì bóyá ohunkóhun wà tá a lè sọ pé ó dá wa lójú hán-únhán-ún. Iyèméjì àti àìdánilójú dà bí ohun tó ti di apá kan ìgbésí ayé wa.

Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ààbò àti ayọ̀ fún ara wọn àti fún ìdílé wọn. Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ àṣekára kí wọ́n lè ní àwọn nǹkan tí wọ́n gbà pé ó lè fáwọn ní ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀, èyí sì sábà máa ń jẹ́ owó àti ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Àmọ́, ìsẹ̀lẹ̀, ìjì líle, jàǹbá, tàbí ìwà ọ̀daràn tó burú jáì lè mú kí gbogbo nǹkan ìní wọ̀nyẹn pòórá lójijì. Àìsàn líle koko, ìkọ̀sílẹ̀, tàbí àìríṣẹ́ṣe lè yí ìgbésí ayé ẹni padà ní ọ̀sán-kan-òru-kan. Lóòótọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè má ṣẹlẹ̀ sí ìwọ gan-an alára. Síbẹ̀, mímọ̀ téèyàn mọ̀ pé irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà máa ń bani nínú jẹ́, ó sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ni ìṣòro tó wà níbẹ̀ o.

Ohun kan náà ni àìdánilójú àti iyèméjì túmọ̀ sí, a sì sọ pé iyèméjì jẹ́ ìgbàgbọ́ tàbí èrò kan tí kò dání lójú, tó sábà máa ń nípa lórí ìpinnu téèyàn fẹ́ ṣe. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé Managing Your Mind sọ pé, “ṣíṣe iyèméjì nípa ohun kan tó ṣe pàtàkì ni olórí ohun tó ń fa hílàhílo àti ìdààmú.” Téèyàn ò bá borí iyèméjì tó ní, ó lè dẹni tó ń ṣàníyàn, kó máa ní ìjákulẹ̀, kó sì máa bínú. Àní, ṣíṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tàbí èyí tí kò lè ṣẹlẹ̀ lè ṣèpalára fún ọpọlọ àti ìlera wa.

Nítorí ìdí èyí, àwọn kan ti wá ti àṣejù bọ ọ̀ràn náà. Wọ́n ń ṣe bíi ti ọ̀dọ́ ará Brazil tó sọ pé: “Èwo ni tèmi láti máa ṣàníyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́la? Òní ni òní ń jẹ́, ẹ fọ̀la sílẹ̀ fún ọ̀la.” Irú àṣà “ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu” bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí ìjákulẹ̀, ìrora ọkàn, ó tiẹ̀ lè yọrí sí ikú níkẹyìn pàápàá. (1 Kọ́ríńtì 15:32) Ohun tó dára jù lọ ni pé ká yíjú sí Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí Bíbélì sọ pé “kò sì sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:17) Bí a bá ń ṣàyẹ̀wò Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a óò rí àwọn ìmọ̀ràn àti ìtọ́sọ́nà tó gbéṣẹ́ lórí bá a ó ṣe borí àwọn iyèméjì tá a ní nínú ìgbésí ayé wa. Ó sì tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí àwọn ipò tí kò dáni lójú fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.

Ohun Tó Fa Àwọn Ipò Tí Kò Dáni Lójú

Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ bí ìgbésí ayé ṣe rí gan-an, ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí tó dára nípa àwọn ohun tó ń kọ wá lóminú àti ipò nǹkan tó ń yí padà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọṣe àárín ìdílé, ipò téèyàn wà láwùjọ, làákàyè, ìlera, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lè fini lọ́kàn balẹ̀ dé àyè kan, síbẹ̀ Bíbélì fi hàn pé a ò lè retí pé bí nǹkan á ṣe máa rí lọ nìyẹn tàbí ká rò pé ìgbésí ayé tó dùn bí oyin la ó máa gbé. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ìjà ogun kì í ṣe ti àwọn alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kì í ṣe ti àwọn ọlọ́gbọ́n pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti àwọn olóye pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá.” Kí nìdí? “Nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” Ìdí nìyẹn tí Sólómọ́nì fi sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹja tí a ń fi àwọ̀n búburú mú, àti bí àwọn ẹyẹ tí a ń fi pańpẹ́ mú, bẹ́ẹ̀ ni a ń dẹkùn mú àwọn ọmọ ènìyàn alára ní ìgbà oníyọnu àjálù, nígbà tí ó bá já lù wọ́n lójijì.”—Oníwàásù 9:11, 12.

Jésù Kristi náà tún sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tí àníyàn àti ipò àìdánilójú tó lé kenkà yóò dé bá gbogbo ìran ènìyàn. Ó fi àkànlò èdè sọ pé: “Àwọn àmì yóò wà nínú oòrùn àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, àti lórí ilẹ̀ ayé làásìgbò àwọn orílẹ̀-èdè, láìmọ ọ̀nà àbájáde nítorí ìpariwo omi òkun àti ìrugùdù rẹ̀, nígbà tí àwọn ènìyàn yóò máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé; nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì.” Àmọ́, Jésù wá mẹ́nu kan ohun tó fi àwọn tó jẹ́ ọlọ́kàn tútù lóde òní lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:25, 26, 31) Bákan náà, dípò tá a ó fi máa bẹ̀rù ọjọ́ iwájú tí kò dáni lójú, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ láti ríran kọjá àwọn ipò àìdánilójú ayé yìí ká sì máa wo ọjọ́ ọ̀la aláàbò tó jẹ́ àgbàyanu.

‘Níní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìdánilójú Ìrètí Náà’

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tá a ń gbọ́, tàbí èyí tá a ń kà, tàbí èyí tá ń fojú rí pàápàá la lè gbà gbọ́, síbẹ̀ ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ẹlẹ́dàá wa. Kì í ṣe pé ó jẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ nìkan, àmọ́ ó tún jẹ́ Baba onífẹ̀ẹ́ tó máa ń bójú tó àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ọ̀rọ̀ tí ó bá ti ẹnu òun fúnra rẹ̀ jáde ni pé: “Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.

Jésù Kristi fi òtítọ́ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá kọ́ni, ọ̀pọ̀ tó sì fetí sílẹ̀ sí i ló tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ láìṣiyèméjì. Bí àpẹẹrẹ, àwùjọ àwọn ọlọ́kàn tútù kan tí wọ́n jẹ́ ará Samáríà sọ fún obìnrin tó ti kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Kì í tún ṣe ní tìtorí ọ̀rọ̀ rẹ ni àwa fi gbà gbọ́ mọ́; nítorí pé àwa tìkára wa ti gbọ́, a sì mọ̀ pé ọkùnrin yìí dájúdájú ni olùgbàlà ayé.” (Jòhánù 4:42) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò eléwu la wà, síbẹ̀ a kò ní láti máa ṣiyèméjì nípa ohun tó yẹ ká gbà gbọ́.

Nígbà tó bá kan ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìsìn, àwọn kan máa ń rò pé dípò káwọn gbìyànjú láti lóye ohun tó wà níbẹ̀, ó kúkú sàn káwọn ṣáà gbà á bẹ́ẹ̀. Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì kò fara mọ́ èrò yẹn rárá. Ó ṣe ìwádìí, ó sì pèsè ìsọfúnni tó péye kí àwọn ẹlòmíràn lè “mọ̀ ní kíkún, ìdánilójú àwọn ohun” tí ó kọ. (Lúùkù 1:4) Níwọ̀n bí àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ tí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yàtọ̀ sí tiwa ti lè máa bẹ̀rù pé àìnírètí àti ìjákulẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa yóò já sí, ó ṣe pàtàkì pé ká gbèjà ìgbàgbọ́ wa. (1 Pétérù 3:15) Kìkì ìgbà tá a bá mọ ìdí pàtàkì tá a fi fara mọ́ ohun tá a gbà gbọ́ la tó lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà rèé, ó ní: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; Olódodo àti adúróṣánṣán ni.”—Diutarónómì 32:4.

Ronú nípa gbólóhùn tó kẹ́yìn yẹn, pé: “Olódodo àti adúróṣánṣán ni.” Ẹ̀rí wo ló lè mú kí èyí dá wa lójú? Kókó yìí dá àpọ́sítélì Pétérù lójú bí nǹkan míì. Ó sọ fún ará Róòmù kan tó wà nípò àṣẹ àti agbo ilé rẹ̀ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Pétérù sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nítorí pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fojú ara rẹ̀ rí i bí Ọlọ́run ṣe fúnra rẹ̀ darí àwọn ọ̀ràn tó fi jẹ́ pé ìdílé Kèfèrí kan tí wọ́n kà sí aláìmọ́ àti ẹni tí kò lè rí ìtẹ́wọ́gbà tẹ́lẹ̀ ti wá di ẹni ìtẹ́wọ́gbà fún Un. Bíi ti Pétérù, ó lè dá àwa náà lójú pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú àti pé olódodo ni nígbà tá a bá fi ojú ara wa rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn èèyàn—tí wọ́n ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà báyìí—látinú orílẹ̀-èdè tó lé ní igba ó lé ọgbọ̀n [230] káàkiri ayé tí wọ́n ti pa ọ̀nà ìgbésí ayé wọn tẹ́lẹ̀ tì, tí wọ́n sì ń rìn ní ọ̀nà òdodo nísinsìnyí.—Ìṣípayá 7:9; Aísáyà 2:2-4.

Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́, a kò fẹ́ jẹ́ aláṣejù tàbí apàṣẹwàá, bí kò ṣe onírẹ̀lẹ̀ àti olóye. Síbẹ̀, a kò ṣe iyèméjì rárá nípa ohun tá a gbà gbọ́ àti ohun tí à ń retí lọ́jọ́ iwájú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé: “A fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin.” (Hébérù 6:11) Bákan náà ni ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì ti fún wa ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà.” Ìrètí yẹn tá a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, “kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù náà ṣe ṣàlàyé.—Róòmù 5:5.

Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún dá wa lójú pé kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nípa tẹ̀mí, kódà ní ti ìmí ẹ̀dùn àti nípa ti ara pẹ̀lú. A lè dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù ní sísọ pé: “Ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú agbára pẹ̀lú àti nínú ẹ̀mí mímọ́ àti ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.”—1 Tẹsalóníkà 1:5.

Àwọn Ìbùkún Tí Ìfọ̀kànbalẹ̀ Tẹ̀mí Ń Fúnni Nísinsìnyí

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè retí pé kí ọkàn wa balẹ̀ tán pátápátá nínú ayé òde òní, síbẹ̀ àwọn ohun kan wà tá a lè ṣe tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó dára tó sì fini lọ́kàn balẹ̀ dé àyè kan. Bí àpẹẹrẹ, bíbá ìjọ Kristẹni ṣe ìpàdé déédéé lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ dúró dáadáa nípa tẹ̀mí nítorí pé ibẹ̀ ni wọ́n ti ń kọ́ wa ní àwọn ìlànà tó tọ́ tó sì pegedé. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.” (1 Tímótì 6:17) Kíkọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kí wọn má sì gbẹ́kẹ̀ lé àwọn nǹkan ti ara tí kì í pẹ́ pòórá ti mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti já ara wọn gbà lọ́wọ́ hílàhílo àti ìjákulẹ̀ tó wọ̀ wọ́n lọ́rùn tẹ́lẹ̀.—Mátíù 6:19-21.

A tún máa ń gbádùn ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ ọlọ́yàyà nínú ìjọ, èyí tó máa ń pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́yìn ní onírúurú ọ̀nà. Ní àkókò kan lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù, òun àti alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò bá ara wọn nínú “ìdààmú dé góńgó” wọn ò sì “ní ìdánilójú rárá nípa ìwàláàyè [wọn].” Ibo ni Pọ́ọ̀lù ti wá rí ìtìlẹ́yìn àti ìrànlọ́wọ́ gbà? Ó dájú pé ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Ọlọ́run kò yẹ̀. Síbẹ̀ náà, àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó wá ràn án lọ́wọ́ ló fún un níṣìírí tí wọ́n sì tù ú nínú. (2 Kọ́ríńtì 1:8, 9; 7:5-7) Nígbà tí ìjábá tàbí àwọn àjálù mìíràn bá ṣẹlẹ̀ lóde òní, gbogbo ìgbà ló jẹ́ pé àwọn Kristẹni arákùnrin wa ló máa ń kọ́kọ́ débẹ̀ láti ṣèrànwọ́ nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn títí kan àwọn ẹlòmíràn tó tún nílò ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú.

Àdúrà tún jẹ́ ohun mìíràn tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àìdánilójú inú ayé yìí. Gbogbo ìgbà la lè yíjú sí Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ nígbà tá a bá bá ara wa nínú pákáǹleke tí a kò retí. “Jèhófà yóò sì di ibi gíga ààbò fún ẹni tí a ni lára, ibi gíga ààbò ní àwọn àkókò wàhálà.” (Sáàmù 9:9) Àwọn òbí lè kùnà láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Àmọ́, Ọlọ́run múra tán láti ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ohun tó ń bà wá lẹ́rù àti ìmí ẹ̀dùn tá a ní nítorí àwọn ohun tí kò dá wa lójú. Tá a bá kó àwọn àníyàn wa lé Jèhófà lọ́wọ́ nínú àdúrà, a lè ní ìdánilójú pé ó lè ‘ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò, ní ìbámu pẹ̀lú agbára rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.’—Éfésù 3:20.

Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé? Ṣé ó dá ọ lójú pé Ọlọ́run ń gbọ́ àwọn àdúrà rẹ? Ọ̀dọ́mọbìnrin kan ní São Paulo sọ pé: “Màmá mi sọ fún mi pé kí n máa gbàdúrà sí Ọlọ́run. Àmọ́ mo bi ara mi pé: ‘Kí nìdí tí máa fi máa bá ẹni tí mi ò mọ̀ sọ̀rọ̀?’ Ṣùgbọ́n, Òwe 18:10 ràn mi lọ́wọ́ láti lóye pé a nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a sì ní láti bá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn sọ pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” Ká sòótọ́, báwo la ṣe lè fọkàn tán Jèhófà ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e, tá a ò bá sọ ọ́ di àṣà láti máa bá a sọ̀rọ̀? Tá a bá fẹ́ ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nípa tẹ̀mí, a ní láti sọ gbígba àdúrà àtọkànwá lójoojúmọ́ di àṣà. Jésù sọ pé: “Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.”—Lúùkù 21:36.

Nǹkan mìíràn tó tún lè dá wa lójú ni Ìjọba Ọlọ́run tá a ń retí. Kíyè sí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44, tó sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ìrètí yẹn lágbára, ó sì jẹ́ ohun kan tó yẹ kó dá wa lójú hán-únhán-ún. Ìlérí àwọn èèyàn máa ń kùnà, àmọ́ a lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí kò ṣeé gbára lé, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló dà bí àpáta tá a lè gbára lé. A lè ṣe bíi ti Dáfídì, ẹni tó sọ pé “Ọlọ́run mi ni àpáta mi. Èmi yóò sá di í, apata mi àti ìwo ìgbàlà mi, ibi gíga ààbò mi, àti ibi ìsásí mi, Olùgbàlà mi; ìwọ gbà mí là kúrò nínú ìwà ipá.”—2 Sámúẹ́lì 22:3.

Ìwé Managing Your Mind tá a mẹ́nu kan ṣáájú tún sọ pé: “Béèyàn bá ṣe ń ronú nípa ohun búburú tó rò pé ó lè ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń dà bíi pé ó ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́kàn onítọ̀hún, tá a sì máa ronú pé kò ní rọrùn fún òun láti borí wọn.” Nítorí náà, èé ṣe tí a ó fi jẹ́ kí àwọn àníyàn àti iyèméjì inú ayé máa dà wá láàmù? Dípò ìyẹn, fi àwọn ohun tó dáni lójú tí Ọlọ́run ń pèsè rọ́pò àwọn ohun tí kò dáni lójú nínú ayé. Nípa níní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run tí kò lè yẹ̀, a ní ìdánilójú pé: “Kò sí ẹni tí ó gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e tí a óò já kulẹ̀.”—Róòmù 10:11.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dáni lójú pé a ò bù kún ìràn ènìyàn lọ́jọ́ iwájú

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

“Kò sí ẹni tí ó gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e tí a óò já kulẹ̀”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìhìn rere Ìjọba náà ń fi àwọn èèyàn lọ́kàn balẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́