Bá A Ṣe Lè Nírètí Nínú Ayé Tó Kún fún Ìpọ́njú
NÍBI àpérò kan tó wáyé nílùú Ottawa lórílẹ̀-èdè Kánádà ní oṣù March ọdún 2006, ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀rí, Bill Clinton, sọ pé: “Àwọn èèyàn láwùjọ ti ní ẹ̀mí àtiṣe ohun tó máa ṣe aráàlú láǹfààní kí wọ́n sì máa yanjú ìṣòro tó bá bá aráàlú ju ti ìgbàkígbà rí lọ.” Ó sọ pé látìgbà tí omíyalé ńlá kan ti wáyé lọ́dún 2004 làwọn èèyàn jákèjádò ayé ti ń ní ẹ̀mí ìranra-ẹni-lọ́wọ́, ó tún fi ìdánilójú sọ pé, “ní àkókò tá a wà yìí àwọn èèyàn jákèjádò ayé ń gbára lé ara wọn ju ti ìgbàkígbà rí lọ.”
Ǹjẹ́ a lè retí pé káwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí omíyalé, ìmìtìtì ilẹ̀ àti irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn bẹ́ẹ̀ mú káwọn èèyàn níbi gbogbo lágbàáyé bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó máa mú kí ọjọ́ ọ̀la dára? Ǹjẹ́ bí “àwọn èèyàn jákèjádò ayé ṣe ń gbára lé ara wọn ju ti ìgbàkígbà rí lọ” yìí jẹ́ ohun tá a lè tìtorí ẹ̀ nírètí pé àlàáfíà tòótọ́ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ títí lọ máa wà lọ́jọ́ iwájú?
Ibi Téèyàn Ti Lè Rí Ojúlówó Ìrètí
Gbogbo ìsapá ọmọ aráyé látohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún sẹ́yìn fi hàn kedere pé ńṣe lọmọ aráyé máa ń já ara wọn kulẹ̀. Abájọ tí Ìwé Mímọ́ fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 146:3) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àjọ inú ayé, tàbí àwọn nǹkan tara inú ayé tàbí àwọn ohun tí ayé ń gbèrò àtiṣe, ìjákulẹ̀ ló máa yọrí sí fún wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—1 Jòhánù 2:17.
Ṣùgbọ́n láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá làwọn olóòótọ́ èèyàn ti ń nírètí nínú Ọlọ́run, kò sì já wọn kulẹ̀ rí. Bíbélì pe Ọlọ́run ní “ìrètí Ísírẹ́lì [ìgbàanì],” àti “ìrètí àwọn baba ńlá [Ísírẹ́lì].” Ọ̀pọ̀ gbólóhùn bẹ́ẹ̀ ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni tá a lè nírètí nínú rẹ̀ tá a sì lè gbọ́kàn lé. (Jeremáyà 14:8; 17:13; 50:7) Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé ká “ní ìrètí nínú Jèhófà.”—Sáàmù 27:14.
Òwe 3:5, 6 rọ̀ wá pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Kò sídìí kankan tó fi yẹ kó o ṣiyèméjì nípa ìlérí yẹn nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run kì í yí padà, ó ṣeé gbára lé, kì í sì í ṣèlérí kó má mú un ṣẹ. (Málákì 3:6; Jákọ́bù 1:17) Ó fẹ́ kó dáa fún ẹ, tó o bá sì ń tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn yóò ṣamọ̀nà rẹ la ayé tó kún fún ìpayà yìí já.—Aísáyà 48:17, 18.
Ẹni tó bá ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí rẹ̀, pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 41:10) Bí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run dénú ṣe ń gbàdúrà àtọkànwá tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lórí ìlérí yìí, ó máa ń tù wọ́n nínú, nítorí pé irú àdúrà àti àṣàrò bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí wọ́n lè borí àwọn ipò tí kò rọgbọ, ó sì ń gbà wọ́n lọ́wọ́ àníyàn ṣíṣe.
Wo àpẹẹrẹ obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Andrea tó ní ọmọ méjì. Ó sọ pé: “Àdúrà gbígbà àti àṣàrò tí mo máa ń ṣe lórí àwọn ìlérí Jèhófà ló máa ń fún mi lókun nígbàkigbà tí gbogbo nǹkan bá dojú rú fún mi. Tí mo bá ti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tí kì í jáni kulẹ̀, ó máa túbọ̀ ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.”
Jẹ́ Kí Ìrètí Rẹ Nínú Jèhófà Túbọ̀ Dájú
Nígbà tí onísáàmù kan ń sọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn nírètí nínú Jèhófà, ó ní: “Ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ, kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.” (Sáàmù 119:165) Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọkàntọkàn, ọkàn rẹ yóò kún fún ‘àwọn ohun tí ó jẹ́ òótọ́, ohun tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun tí ó jẹ́ òdodo, ohun tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun tí ó dára ní fífẹ́, àti ohun tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa.’ Ìwọ̀nyí á gbé ọ ró, á sì jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ dára. Tó o bá sapá láti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, tó o sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn, tó o tẹ́wọ́ gbà wọ́n, tó o sì ń fi wọ́n ṣèwà hù, ‘Ọlọ́run àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú rẹ.’—Fílípì 4:8, 9.
Arákùnrin John tó ti ń sin Ọlọ́run bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ ìrírí ara rẹ̀, ó ní: “Láti lè yí èrò mi nípa ọjọ́ ọ̀la padà, mo rí i pé mo ní láti ṣàtúnṣe nínú ọ̀nà tí mo gbà ń hùwà àti ọ̀nà tí mo gbà ń ronú kí n tó lè sọ pé mo fẹ́ ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run tí í ṣe ẹni pípé tá ò lè fojú rí. Ọ̀nà kan ṣoṣo tí mo sì lè gbà ní àjọṣe yẹn ni pé kí n jẹ́ ẹni tó lẹ́mìí Ọlọ́run, tó ń fi ti Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé. Èyí gba pé kí n máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí n sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀.”
Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́, èyí tí ń fúnni níyè tó sì ń tuni lára, ìyẹn jẹ́ ohun tó dára tí ẹ̀rí tó dájú sì fi hàn pé o lè fi dènà àwọn ohun burúkú tí wọ́n ń gbé jáde lọ́pọ̀ yanturu lójoojúmọ́ nínú tẹlifíṣọ̀n, rédíò tàbí ìwé ìròyìn. Tó o bá ń fi ohun tí Bíbélì sọ sílò, okùn ìfẹ́ tó so ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé pọ̀ yóò máa yi sí i, o ò sì ní máa ṣàníyàn jù. Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun múra tán láti “fi okun [òun] hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ [òun].” (2 Kíróníkà 16:9) Ọlọ́run yóò bójú tó gbogbo nǹkan lọ́nà tí nǹkan kan ò fi ní máa kó ọ láyà sókè.
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Phinehas tó wà níbi tí ogun ti jà rí, tó sì tún rí bí wọ́n ṣe pa àwọn èèyàn nípakúpa sọ pé: “Gbogbo àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ wọ̀nyẹn ti jẹ́ kí n fọ̀rọ̀ mi lé Jèhófà lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ti fò mí dá nítorí pé mò ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì.” Tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run láìṣe iyèméjì, Jèhófà yóò jẹ́ kó o lè borí àwọn ìṣòro tó dà bíi pé ó ju agbára rẹ lọ. (Sáàmù 18:29) Tí àjọṣe àárín ọmọdé kan àtàwọn òbí rẹ̀ bá dán mọ́rán, ọmọ náà yóò gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òbí rẹ̀, ọkàn rẹ̀ á sì balẹ̀ pé àwọn òbí òun á tọ́jú òun àní nígbà tóun bá ṣàìsàn tàbí tóun níṣòro mìíràn. Ọkàn tìẹ náà lè balẹ̀ bíi ti ọmọdé yẹn tó o bá gbìyànjú láti ṣe ohun tí Bíbélì rọ̀ wá pé ká ṣe, ìyẹn ni pé ká nírètí nínú Jèhófà.—Sáàmù 37:34.
Ohun Tó Dájú Pé Ó Máa Fún Wa Nírètí
Jésù Kristi sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’” (Mátíù 6:9, 10) Ìjọba ọ̀run yìí tí Jésù Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀ ni Ọlọ́run máa lò láti fi hàn pé òun, Jèhófà, ni Ọba Aláṣẹ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.—Sáàmù 2:7-12; Dáníẹ́lì 7:13, 14.
Onírúurú nǹkan tó ń kó ìpayà bá àwa ọmọ èèyàn lónìí fi hàn kedere pé a nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, pé kó bá wa dá sí ọ̀rọ̀ wa. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ aráyé! Ní báyìí, Ọlọ́run ti fi Jésù Kristi jẹ Mèsáyà Ọba, ó sì fún un láṣẹ pé kó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun, Jèhófà, ló tọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, kó sì tún ya orúkọ òun sí mímọ́. (Mátíù 28:18) Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ ayé, yóò sì mú gbogbo ohun tó ń fa ìbẹ̀rù àti àníyàn kúrò. Aísáyà 9:6 sọ àwọn ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ Alákòóso tó lè mú àwọn ohun tí ò jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ kúrò. Bí àpẹẹrẹ, ó pe Jésù ní “Baba Ayérayé,” “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn” àti “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.”
Ìwọ wo orúkọ fífanimọ́ra tí ẹsẹ Bíbélì yìí fún Jésù, ìyẹn “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” ó ní agbára àti àṣẹ láti fún àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé lọ́lá ẹbọ tó fẹ̀mí ara rẹ̀ rú. Kì í ṣe pé ó lágbára rẹ̀ nìkan ni, ó tún jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn onígbọràn máa bọ́ nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé téèyàn jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́. (Mátíù 20:28; Róòmù 5:12; 6:23) Kristi tún máa lo àṣẹ tí Ọlọ́run fún un láti jí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kú dìde.—Jòhánù 11:25, 26.
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun jẹ́ “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn.” Ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní àti òye àrà ọ̀tọ̀ tó ní nípa ẹ̀dá èèyàn jẹ́ kó mọ bó ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro téèyàn máa ń ní. “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn” náà ló ṣì jẹ́ látìgbà tí Ọlọ́run ti gbé e gorí ìtẹ́ lọ́run, òun sì ni Jèhófà ń lò ní pàtàkì láti bá aráyé sọ̀rọ̀. Àwọn ìtọ́ni Jésù tó wà nínú Bíbélì kún fún ọgbọ́n, kò sì lábùkù kankan. Tó o bá mọ àwọn ìtọ́ni wọ̀nyí tó o sì gbà pé wọ́n wúlò, o ò ní wà láìní ìrètí, wàá sì bọ́ nínú ìbẹ̀rùbojo.
Aísáyà 9:6 tún sọ pé Jésù jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Ipò yìí ni Kristi yóò ti lo agbára rẹ̀ láìpẹ́ láti mú gbogbo kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láwùjọ kúrò, ì báà jẹ́ èyí tí ètò ìṣèlú tàbí ètò ọrọ̀ ajé ń fà. Ọ̀nà wo ló máa gbà ṣèyẹn? Yóò ṣe èyí nípa mímú kí ìjọba kan ṣoṣo tó jẹ́ ti àlàáfíà, ìyẹn Ìjọba Mèsáyà, máa ṣàkóso gbogbo aráyé.—Dáníẹ́lì 2:44.
Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso ayé, àlàáfíà yóò wà kárí ayé títí láé. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú? Aísáyà 11:9 sọ ọ́, ó ní: “Wọn [ìyẹn àwọn tí yóò wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run] kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátá yóò ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, gbogbo wọn ni yóò sì máa ṣègbọràn sí i. Ǹjẹ́ èyí kò múnú rẹ dùn? Tó bá múnú rẹ dùn, má ṣe jáfara láti ní “ìmọ̀ Jèhófà” tó ṣeyebíye.
Ó lè ní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run, èyí tó ń mú kéèyàn nígbàgbọ́ tó sì ń fúnni níyè tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní àti nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì pé òun máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Nítorí náà, a rọ̀ ọ́ pé kó o tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn ládùúgbò rẹ lọ́fẹ̀ẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù, wàá sì ní ìrètí tòótọ́ nínú ayé tí ìṣòro kúnnú rẹ̀ yìí.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìdí Tí Ìjọba Ọlọ́run Fi Lè Mú Kéèyàn Nírètí
Jèhófà ti fún Jésù Kristi, Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ní agbára àti àṣẹ láti ṣàkóso gbogbo ayé. (Mátíù 28:18) Jésù yóò mú kí ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun abẹ̀mí inú rẹ̀ padà sípò tó dára bí Ọlọ́run ṣe dá wọn níbẹ̀rẹ̀. Ó tún máa mú gbogbo àìsàn àti àrùn kúrò. Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ bíńtín nìyẹn wulẹ̀ jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣe nínú Ìjọba rẹ̀ níwọ̀n bó ti jẹ́ Ọba pípé, tó ṣeé gbára lé. Èwo ló wù ọ́ jù nínú àwọn ànímọ̀ Mèsáyà Ọba tá a tò sísàlẹ̀ yìí?
▪ Ó ṣeé sún mọ́.—Máàkù 10:13-16.
▪ Afòyebánilò ni, kì í ṣojúsàájú.—Máàkù 10:35-45.
▪ Ó ṣeé gbára lé, kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan.—Mátíù 4:5-7; Lúùkù 6:19.
▪ Olódodo àti olóòótọ́ ni.—Aísáyà 11:3-5; Jòhánù 5:30; 8:16.
▪ Ó jẹ́ olóye, olùgbatẹnirò, àti onírẹ̀lẹ̀.—Jòhánù 13:3-15.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Bíbélì kíkà àti ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tó o kà níbẹ̀ á mú kó o nírètí nínú Jèhófà