ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 10/15 ojú ìwé 20-23
  • Ẹyin Alagba—Ẹ Yan Iṣẹ́ Funni!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹyin Alagba—Ẹ Yan Iṣẹ́ Funni!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iniyelori Dídá Awọn Ẹlomiran Lẹ́kọ̀ọ́
  • Ki Ni Ó Tumọsi Lati Yan Iṣẹ́ Funni?
  • Bi A O Ṣe Yan Iṣẹ́ Funni
  • Fífaṣẹ́lénilọ́wọ́—Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Báwo Ló sì Ṣe Yẹ Ká Ṣe É?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Tó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Ẹ̀yin Alàgbà—Ẹ Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Láti Gbé Ẹrù Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Fi ‘Nǹkan Wọ̀nyí Lé Àwọn Olùṣòtítọ́ Lọ́wọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 10/15 ojú ìwé 20-23

Ẹyin Alagba—Ẹ Yan Iṣẹ́ Funni!

OUN jẹ́ ọkunrin onisuuru, ati onirẹlẹ kan, ti ó ní òye idajọ-ododo tí awọn iriri rẹ̀ ninu igbesi-aye mú wà ni iwọntunwọnsi. Nipa bayii, iye ti ó ju million mẹta awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde fi igbọkanle yiju si ọ̀dọ̀ rẹ̀ fun amọran. Ó gbiyanju lati maṣe já wọn kulẹ. Lati òwúrọ̀ titi di àṣálẹ́, ó fi ironujinlẹ gbé awọn iṣoro wọn yẹwo ó sì fi suuru ràn wọ́n lọwọ lati rí bi awọn ofin Ọlọrun ṣe tanmọ́ ipo wọn. Bẹẹni, fun sáà akoko kukuru kan, ní nnkan bii 3,500 ọdun sẹhin, ẹ̀yà 12 ti Israeli ni a ṣe onidaajọ fun laisi iranlọwọ lati ọ̀dọ̀ awọn ẹlomiran nipasẹ ọkunrin kan—Mose.

Bi o ti wu ki o ri, Jetro, baba iyawo Mose, ṣe àníyàn-ọkàn. Bawo ni Mose ṣe lè reti lae pe oun yoo lè maa baa lọ ninu iru ìgbésẹ̀ kan bẹẹ? Nitori naa Jetro polongo pe: “Eyi ti iwọ ń ṣe nì kò dara. Dajudaju iwọ o dá ara rẹ lagara, ati iwọ, ati awọn eniyan yii ti ó pẹlu rẹ: nitori ti nǹkan yii wúwo jù fun ọ; iwọ nikan kì yoo lè ṣe é tikaraarẹ.” (Eksodu 18:17, 18) Ki ni ojutuu naa? Jetro fun Mose ni amọran lati yan diẹ lara awọn ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀ fun awọn ẹlomiran. (Eksodu 18:19-23) Amọran tó sunwọn!

Laaarin ijọ Kristian lonii, ọpọlọpọ awọn alagba ni wọn wà, awọn ẹni ti, bíi Mose, wọn ń gbiyanju lati bojuto ohun ti ó pọ̀ ju eyi ti ó ṣeeṣe pe ki wọn danikan ṣaṣepari rẹ̀ lọ. Wọn ń seto awọn ipade bakan naa wọn ń murasilẹ ati lẹhin naa wọn ń gbé awọn apá itolẹsẹẹsẹ kalẹ ni ọ̀nà ti ó wà letoleto, ti ó si gbéṣẹ́. (1 Korinti 14:26, 33, 40; 1 Timoteu 4:13) Awọn alagba tún ń bojuto aini awọn mẹmba kọọkan ninu ijọ. (Galatia 6:1; 1 Tessalonika 5:14; Jakọbu 5:14) Wọn ń mú ipo iwaju ninu iṣẹ ti ó ṣe pataki ju naa ti o jẹ ti wiwaasu ihinrere Ijọba naa. (Matteu 24:14; Heberu 13:7) Pẹlupẹlu, wọn ń ṣeto fun ipese iwe-ikẹkọọ ti a o mú wà larọọwọto fun ijọ fun ipinkiri fun gbogbo eniyan.

Ni afikun, awọn alagba kan ni a ń yan apakan lara awọn itolẹsẹẹsẹ apejọ ayika ati apejọpọ agbegbe fun. Wọn ń ṣiṣẹ ninu iṣetojọ apejọ wọ́n sì ń ṣiṣẹsin lara awọn igbimọ alárinà ile-iwosan. Awọn kan ń ṣetilẹhin pẹlu kíkọ́ Gbọngan Ijọba. Gbogbo eyi sì jẹ́ ni afikun si ẹrù-iṣẹ́ idile wọn ati ojuṣe wọn lati bọ́ araawọn nipa tẹmi. (Fiwe Joṣua 1:8; Orin Dafidi 110:3; 1 Timoteu 3:4, 5; 4:15, 16.) Bawo ni iru awọn Kristian ọkunrin bẹẹ ṣe ń ṣe gbogbo rẹ̀? Bii Mose wọn gbọdọ gba iranlọwọ. Wọn gbọdọ kọ́ lati yan iṣẹ funni. Nitootọ, ẹnikan ti kò bá yan iṣẹ funni kìí ṣe oluṣeto rere.

Iniyelori Dídá Awọn Ẹlomiran Lẹ́kọ̀ọ́

Awọn idi siwaju sii wà fun yíyan ẹrù-iṣẹ́ funni. Ninu àkàwé Jesu nipa awọn talẹnti, ọ̀gá naa, ṣaaju ki ó tó lọ si irin-ajo ọ̀nà jíjìn, pe awọn ẹrú rẹ̀ ó sì yan oniruuru ìwọ̀n ẹrù-iṣẹ́ fun wọn. (Matteu 25:14, 15) Nipa ṣiṣe bẹẹ, ọwọ́ ọ̀gá naa lè tẹ gongo melookan. Ekinni, nigba ti kò sí nile, awọn ẹrú rẹ̀ ṣiṣẹ ni ipo rẹ̀ iṣẹ ti ó pọndandan kò sì wọ́lẹ̀ nigba ti ó ti lọ tan. Ekeji, niwọn bi ihuwasi ti sọrọ soke ju awọn ọ̀rọ̀ lasan lọ, ọ̀gá naa lè kiyesi agbara-iṣe ati iduroṣinṣin awọn ẹrú rẹ̀. Ẹkẹta, ọ̀gá naa fun awọn ẹrú rẹ̀ ni anfaani lati jere ìmọ̀ ti wọn nilo gidigidi.

Àkàwé yii ní itumọ fun wa lonii. Nigba ti Jesu fi ori ilẹ̀-ayé silẹ, ó gbé ẹrù-iṣẹ́ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ẹni-ami-ororo. Aṣẹku ninu awọn wọnyi ni wọn ṣì ní ẹrù-iṣẹ́ fun ire Ijọba naa kari-aye. (Luku 12:42) Ni akoko ipò-ìríjú awọn ẹni-ami-ororo ti ode-oni, ibukun Jehofa ti farahan gbangba lori eto-ajọ rẹ̀. Gẹgẹ bi iyọrisi, ó ti pọ̀ sii lọna agbayanu. Họwu, ní kìkì ọdun marun-un sẹhin, iye ti o fi pupọpupọ ju million kan awọn ẹni titun ti fi àmì iyasimimọ wọn hàn nipasẹ iribọmi ninu omi! Eyi ti yọrisi ẹgbẹẹgbẹrun ijọ titun ati ọgọrọọrun awọn ayika titun.

Gan-an gẹgẹ bi Jesu Kristi ti yan ẹrù-iṣẹ́ fun “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu,” awọn pẹlu ní apá ọdọ tiwọn ti yan ẹrù-iṣẹ́ ijọ fun awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ninu “awọn agutan miiran.” (Matteu 24:45-47, NW; Johannu 10:16) Bi o tilẹ ri bẹẹ, ọpọ awọn ọkunrin pupọ sii tí wọn ti ṣeyasimimọ ni a nilo lati bojuto idagbasoke ńláǹlà naa. Nibo ni wọn yoo ti wa? Awọn alagba gbọdọ dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ṣugbọn bawo ni awọn alagba ṣe lè dá iru awọn ọkunrin bẹẹ lẹ́kọ̀ọ́ bi wọn kò bá yan ẹrù-iṣẹ́ ti o yẹ fun awọn ẹnikọọkan ti wọn fi ẹ̀rí títóótun hàn? Ọ̀nà miiran wo ni awọn alagba lè gbà ni anfaani lati kiyesi agbara ati iduroṣinṣin awọn ọdọkunrin?

Ki Ni Ó Tumọsi Lati Yan Iṣẹ́ Funni?

Fun awọn kan, “yíyan iṣẹ́ funni” tumọsi jíjá ẹrù-iṣẹ́ wọn kalẹ̀, yiyẹra fun un, pípa á tì, tabi jíjáwọ́ ninu rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a bá lò ó lọna bibojumu, “yíyan iṣẹ́ funni” jẹ́ ọ̀nà lati bojuto awọn ẹrù-iṣẹ́ niti gidi. Ọ̀rọ̀-ìṣe èdè Gẹẹsi naa “lati yan iṣẹ́ funni” ni a tumọsi, “lati fi lé ẹlomiran lọwọ; lati yàn gẹgẹ bi aṣoju ẹni; lati yan ẹrù-iṣẹ́ tabi ọla-aṣẹ.” Bi o tilẹ ri bẹẹ, olùyanṣẹ́ funni naa ṣì jẹ́ ẹni ti yoo jihin fun ohun ti a ṣe naa.

Awọn kan lè yẹra fun yíyan iṣẹ́ funni nitori pe wọn ń bẹru pe awọn yoo padanu agbara-idari wọn. Sibẹ, yíyan iṣẹ́ funni kò tumọsi pipadanu agbara idari. Bi o tilẹ jẹ́ alaiṣeefojuri ti ó sì ń ṣakoso lati ọrun wá, Kristi Jesu ń dari ijọ Kristian lọpọlọpọ gan-an. Oun, ni ipa tirẹ̀, fi ijọ si itọju awọn ọkunrin oniriiri.—Efesu 5:23-27; Kolosse 1:13.

Awọn miiran lè má ní ìtẹ̀sí lati yan iṣẹ́ funni nitori pe wọn nimọlara pe awọn lè ṣe iṣẹ́ naa kiakia funraawọn. Bi o ti wu ki o ri, Jesu rí iniyelori dídá awọn miiran lẹ́kọ̀ọ́. Kò sí ẹni naa ni ori ilẹ̀-ayé ti ó kọni lọna ti ó gbéṣẹ́ ju Jesu lọ. (Johannu 7:46) Sibẹ, lẹhin fifun 70 ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni itọni, ó rán wọn jade sinu iṣẹ́ wiwaasu. Bi o tilẹ jẹ pe wọn kò lè bá Jesu dọgba ninu òye ikọnilẹkọọ, wọn pada pẹlu ayọ àkúnwọ́sílẹ̀ nitori awọn aṣeyọrisirere wọn. Jesu bá wọn yọ ó sì gboriyin fun wọn, nitori ti ó mọ̀ pe wọn yoo maa ba iṣẹ́ naa lọ fun ìgbà pipẹ lẹhin ìgbà ti oun bá lọ ati pe bópẹ́-bóyá wọn yoo ṣaṣepari pupọpupọ sii ju eyi ti oun lè ṣe ni didanikan ṣiṣẹ́ lọ.—Luku 10:1-24; Johannu 14:12.

Yíyan iṣẹ́ funni tun tumọsi rírí iranlọwọ gbà fun awọn kulẹkulẹ ti ó pọndandan. Nigba ti ó ku ọ̀la ki Jesu kú, ó yan Peteru ati Johannu lati ṣe awọn eto ti ó pọndandan fun ounjẹ Ajọ-irekọja rẹ̀ ti o kẹhin. (Luku 22:7-13) Jesu kò nilati ṣeyọnu nipa ríra ọdọ-agutan kan, waini, akara alaiwu, ati ewébẹ̀ kikoro; bẹẹni oun kò nilati kó awọn ohun eelo ìdáná, igi-ìdáná, ati awọn nǹkan miiran bẹẹbẹẹ jọ. Peteru ati Johannu bojuto awọn kulẹkulẹ wọnyẹn.

Awọn alagba lonii lè gbadun awọn anfaani ti ó jọra bi wọn bá ṣafarawe apẹẹrẹ Jesu. Fun apẹẹrẹ, ẹni tí ń bojuto iwe ikẹkọọ ni a lè sọ fun pe ki ó ṣe ibeere fun ipese ti a nilo fun igbetaasi ti ń bọ̀ lọna. Oun ni a lè fun ni itọni lati ṣe ayẹwo awọn akọsilẹ rẹ̀ lati pinnu bi a ṣe lo iru awọn nǹkan bẹẹ ni ìgbà igbetaasi ti ó kọja. Ó sì tun lè ṣagbeyẹwo bi ipinlẹ ijọ ṣe rí ṣaaju ki ó tó ṣeto fọọmu ti o yẹ fun ibeere iwe. Oun yoo wá fi fọọmu naa lé akọwe ijọ lọwọ lẹhin naa fun àyẹ̀wò. Gbàrà ti iranṣẹ ti ń bojuto iwe ikẹkọọ bá ti mọ iṣẹ rẹ̀, kò nilati pọndandan fun akọwe lati tun àyẹ̀wò ṣe ninu awọn akọsilẹ ti ó ti kọja niwọn ìgbà ti awọn aropọ ti ó wà lori fọọmu ibeere ẹrù bá ti bá ọgbọn mu. Ni kedere, igbesẹ rirọrun ti yíyan iṣẹ́ funni yii yoo mú ki bibeere fun iwe ikẹkọọ tubọ rọrùn yoo sì tubọ mú nǹkan rọrùn fun awọn ti ọ̀ràn kàn.

Ni oju-iwoye iru awọn anfaani ti o ṣeeṣe bẹẹ, bawo ni ẹnikan ṣe lè yan iṣẹ́ funni lọna ti ó gbéṣẹ́?

Bi A O Ṣe Yan Iṣẹ́ Funni

Ṣalaye iṣẹ́ naa. Lakọọkọ, jẹ́ ki ohun ti a ń reti ṣe kedere. “Ẹ maa ṣòwò titi emi ó fi dé” ni “ọkunrin ọlọ́lá” naa ninu àkàwé Jesu nipa mina sọ fun awọn ẹrú rẹ̀ mẹwaa. (Luku 19:12, 13) Ọ̀gá naa reti pe ki awọn ẹrú naa fi mina rẹ̀ ṣòwò ní àṣejèrè ki wọn sì fi èrè wọn jíṣẹ́ nigba ti oun bá pada dé. Wọn mọ ohun ti wọn nilati ṣe. Bawo ni ilana yii ṣe lè kan ìwéwèédáwọ́lé Gbọngan Ijọba ode-oni kan? Gẹgẹ bi apẹẹrẹ kan, arakunrin ti a yàn lati tún òrùlé ṣe ni a sábà maa ń sọ fun nipa ohun eelo ti yoo lò, ibi ti ó ti lè rí wọn, ati ìgbà ti iṣẹ nilati bẹrẹ, ti oju-ọjọ bá yọnda. Iru awọn itọsọna pàtó bẹẹ ń yọrisi iṣetojọ rere.

Ó ṣe pataki lati ṣalaye kìí ṣe kìkì ohun ti iṣẹ́ kan ní ninu ṣugbọn awọn ipinnu ti a yọnda fun ẹnikan lati ṣe ati awọn ọ̀ràn ti a nilati dari sí ẹlomiran kan. Mose sọ fun awọn ti ó yàn pe wọn nilati ṣe idajọ awọn ọ̀ràn kekeke, ṣugbọn awọn ọ̀ràn ti ó ṣoro ni wọn nilati mu wá si ọdọ oun.—Eksodu 18:22.

Nigba ti o bá ń yan ẹrù-iṣẹ́, ṣọra lati maṣe yan iṣẹ́ kan-naa fun ẹni meji. Nigba ti a bá yan iṣẹ́ kan-naa fun eyi ti ó ju ẹnikan lọ, idarudapọ ni ó ń yọrisi. Ronuwoye ohun ti ó lè ṣẹlẹ ni apejọpọ ńlá ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bi ó bá wáyé pe, a fun Ẹ̀ka ti Ń Bojuto Imọtoto ati Ẹ̀ka Ipese Ounjẹ ni ẹrù-iṣẹ́ lati gbá ìsọ̀ ti a ti ń ta ounjẹ mọ́, tabi ti a yan Ẹ̀ka Iṣabojuto-ero ati Ẹ̀ka Iribọmi lati dari awọn òǹwòran nigba baptism.

Yan awọn ọkunrin ti wọn tootun. Jetro gba Mose nimọran pe: “Iwọ funraarẹ gbọdọ wá awọn ọkunrin titootun, olubẹru Ọlọrun rí laaarin gbogbo awọn eniyan naa, awọn ọkunrin alailabosi ati alaiṣeesọdibajẹ, ki o sì yàn wọn lé awọn eniyan naa lori.” (Eksodu 18:21, The New English Bible) Ni kedere, ọkunrin kan gbọdọ kọ́kọ́ dójú àmì itootun tẹmi ná. Lati pinnu bi ẹnikan bá “tootun” lati ṣe iṣẹ́ kan ti ń bẹ nilẹ, a gbọdọ gbé awọn kókó-abájọ bii ìwà animọ, iriri, ìdálẹ́kọ̀ọ́, ati awọn ẹbun yẹwo. Nipa bayii, Kristian kan ti ó ní itẹsi ẹni-bí-ọ̀rẹ́, ọlọ́yàyà, arannilọwọ ni ó ṣeeṣe ki ó ṣe daadaa nidii káńtà iwe-irohin tabi gẹgẹ bi oluṣabojuto-ero. Ní ìlà ironu kan-naa, nigba ti a bá ń yan ẹnikan lati ran akọwe ijọ lọwọ, a o fi ọgbọ́n gbé bi oun ti wà letoleto si yẹ̀wò. Ó ha ń fi afiyesi si kulẹkulẹ bí, ó ha ṣeé gbarale bí, oun ha sì lè pa aṣiiri mọ́ bí? (Luku 16:10) Fífún iru awọn kókó-abájọ bẹẹ ni igbeyẹwo ni afikun si awọn àmì itootun tẹmi yoo ṣeranwọ ninu fifi ẹni ti ó tọ́ sẹnu iṣẹ naa.

Pese awọn ohun àmúṣiṣẹ́ ti ó pọ̀ tó. Ẹni naa tí ń ṣiṣẹ yoo nilati ní awọn ohun àmúṣiṣẹ́ kan bayii ni ìkáwọ́ rẹ̀ ki ó baa lè pari iṣẹ́ kan ti a yàn fun un. Boya oun yoo nilo ohun-eelo, owó-àkànlò, tabi itilẹhin. Pese awọn ohun àmúṣiṣẹ́ ti ó pọ̀ tó. Fun apẹẹrẹ, arakunrin kan ni a lè sọ fun lati ṣe awọn atunṣe kan lara Gbọngan Ijọba. Ni kedere, a ó sọ ohun ti ó nilo atunṣe fun un, ṣugbọn oun tun lè nilo tọ́rọ́-kọ́bọ̀ lati ra awọn ohun eelo pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Boya oun yoo nilo iranlọwọ. Nitori naa awọn alagba lè sọ fun awọn ẹlomiran lati ṣetilẹhin fun un tabi ki wọn ṣe ifilọ fun ijọ nitori rẹ̀ pe ‘Arakunrin Lagbaja yoo maa ṣe iṣẹ kan bayii-bayii lara gbọngan, oun sì lè maa tọ̀ diẹ ninu yin wá lati beere fun iranlọwọ.’ Iru ironu-ṣaaju bẹẹ kò ni jẹ ki ẹnikan yan iṣẹ́ kan lai pese awọn ohun àmúṣiṣẹ́ ti ó pọ̀ tó. “Maṣe yan iṣẹ́ funni láàbọ̀” ni ọ̀nà tí ogbontarigi olugbaninimọran ajọ-ẹgbẹ kan gbà sọ ọ́.

Nigba ti o bá ń yan awọn ẹrù-iṣẹ́, sọ fun awọn miiran pe ẹni naa ń ṣiṣẹ dipo rẹ. Ọla-aṣẹ lati ṣiṣẹ ni ipo rẹ tún jẹ́ ohun àmúṣiṣẹ́ kan. Joṣua ni a faṣẹ fun niṣẹ gẹgẹ bi aṣaaju titun ti Israeli niwaju “gbogbo ijọ.” Mose ni a fun ni itọni lati “fi ninu ọlá [rẹ̀] si i lara.” (Numeri 27:18-23) Ninu igbekalẹ ti ijọ, ohun kan-naa ni a lè ṣaṣepari nipa wiwulẹ lẹ itolẹsẹẹsẹ orukọ awọn wọnni ti a yan iṣẹ́ fun mọ́ oju patako isọfunni.

Ti ipinnu wọn lẹhin. Nisinsinyi ẹni naa ti a yàn lè maa bá iṣẹ́ ti ó wà nilẹ lọ. Bi o ti wu ki o ri, ranti, iwọ lè jẹ́ orisun iṣiri gidi fun un bi o bá ti awọn ipinnu rere ti ó ń ṣe lẹhin. Fun apẹẹrẹ, iwọ gẹgẹ bi alagba kan lè ní ìyànláàyò tirẹ nipa bi a ṣe nilati gbé ẹ̀rọ gbohungbohun ati àga lori pepele Gbọngan Ijọba, boya lọna kan ti ó yatọ bakan ṣáá si bi arakunrin ti a yàn ṣe ń ṣe e. Bi o ti wu ki o ri, bi a bá fun arakunrin naa ti ń bojuto pepele ni iwọn ominira yíyàn ninu iṣẹ́ rẹ̀, oun ni ó ṣeeṣe ki o jere igbọkanle ati iriri. Yatọ si eyi, oun tilẹ lè mú awọn ọ̀ràn sunwọn sii. Ogbontarigi olugbaninimọran iṣẹ́-ajé kan sọ pe: “Yan iṣẹ́ naa funni, kìí ṣe ọ̀nà ti a ó gbà ṣe e. . . . Niye ìgbà, ẹbun ìhùmọ̀ ni a ń gbeyọ.”

Siwaju sii, arakunrin ti a gbé iṣẹ́ lé lọwọ naa ti èèkù àdá wà lọwọ rẹ̀, ki a sọ bẹẹ, ni ó sábà maa ń sunmọ ipo ọ̀ràn pàtó kan jù ati nipa bẹẹ ó lè loye awọn iṣoro ti ó sopọ mọ́ ọn jù. Oun ni ó ṣeeṣe ki ó dahunpada si awọn iṣoro naa pẹlu ojutuu ti ó ṣiṣẹ niti gidi. Oun tun lè maa bojuto awọn kókó-abájọ ti ó lè má ṣe kedere si awọn ti ń wò ó. Nitori naa, Kristian oluṣabojuto kan sọ nipa olurannilọwọ oniriiri kan pe: “Bi ó bá sọ pe iṣẹ́ naa takoko diẹ, emi yoo fọkàn tán an.”

Bẹẹni, ohun àmúṣiṣẹ́ ti ó ṣeyebiye julọ ti ó wà larọọwọto fun awọn Kristian alagba ni awọn ọkunrin ati obinrin oluṣeyasimimọ ti wọn muratan ti wọn sì lè ṣetilẹhin ninu ọ̀nà yoowu ti a bá dari wọn si. Ẹyin alagba, ẹ lo awọn eelo ṣiṣeyebiye titayọ yii lọna rere! Yíyan iṣẹ́ funni jẹ́ àmì iwọntunwọnsi ó sì lè mú masunmawo ati ijakulẹ dinku. Kìí ṣe pe ẹyin yoo lè tipa bayii ṣe pupọ sii nikan ni ṣugbọn ẹyin yoo yoo fun awọn miiran ni anfaani lati jere iriri ti wọn nilo.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́