ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 17-18
Àwọn Tó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́
Kí ètò Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú, àwọn arákùnrin tó nírìírí máa ń fìfẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ dá àwọn tó kéré lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n á faṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́. Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
Fara balẹ̀ kíyè sí àwọn tó lẹ́mìí tó dáa, tí wọ́n sì ń nàgà fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn
Fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tẹ́ ẹ bá yàn fún wọn láṣeyọrí
Fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò fún iṣẹ́ náà
Máa kíyè sí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú, kó o sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé o fọkàn tán wọn
BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn iṣẹ́ wo ni mo lè fà lé àwọn míì lọ́wọ́?’