Wíwá Isọtẹlẹ Ti O Ṣeegbarale Kiri
“ẸNI ti ó bá lè rí àrítẹ́lẹ̀ awọn alamọri ni ọjọ mẹta ṣaaju yoo di ọlọ́rọ̀ fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun.” Bẹẹ ni owe ilẹ China kan sọ.
Awọn eniyan fẹ́ lati mọ ohun ti ọjọ-ọla yoo mú wá, ọpọlọpọ yoo sì fi inudidun san owó gọbọi fun iru isọfunni ti o ṣeegbarale bẹẹ. Wọn ṣewakiri awọn isọtẹlẹ ti o ṣeegbarale. Gẹgẹ bi a ti ri i lati ori àsọbádé nipa oju-ọjọ ati awọn ohun ti ń sọ nipa bi ètò ọrọ̀ ajé ti rí, a ni ọkàn-ìfẹ́ ninu awọn iṣẹlẹ ti ń bẹ niwaju. Siwaju sii, ìmọ̀ ti o ṣeegbarale nipa ọjọ-ọla yoo mu ki o ṣeeṣe fun wa lati lè wewee ki a sì ṣeto igbesi-aye wa.
Ìfẹ́-ọkàn lati mọ ohun ti ọjọ-ọla ní ní ipamọ ń sún ọpọlọpọ lati lọ bẹ awọn alakiyesi ìgbà, guru, awòràwọ̀, ati awọn adáhunṣe wò. Awọn ile ìtàwé ati awọn pẹpẹ iwe-irohin kun fun awọn iwe ayé atijọ ati ti ode-oni ti wọn sọ pe awọn ń sọ asọtẹlẹ nipa ọjọ-ọla. Ṣugbọn iyemeji yí iru awọn isọtẹlẹ wọnyi ká. Aṣaaju-oṣelu ara Romu naa Cato ni a rohin rẹ̀ pe ó sọ bayii pe: ‘Ó yà mi lẹnu pe alafọṣẹ kìí rẹ́rìn-ín nigbakigba ti o bá ri alafọṣẹ miiran.’
Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn isọtẹlẹ oriṣiriṣi ni o wà. Ní 1972 ẹgbẹ́ awọn akẹkọọ ati oniṣowo jakejado awọn orilẹ-ede ti a mọ̀ si Club of Rome tẹ iwadii kan jade ti ń sasọtẹlẹ pe laipẹ awọn alumọọni ti kò ṣee sọ di titun yoo tán ninu ayé. Yoo wà laisi wúrà ni 1981, mẹ́kúrì ni 1985, zinc ni 1990, epo rọ̀bì ni 1992, ati bẹẹ bẹẹ lọ. A ti rí i nisinsinyi pe awọn isọtẹlẹ wọnyi kò ṣẹ.
Ọpọlọpọ isọtẹlẹ ni a ti gbekari oju-iwoye isin. Lati ṣapejuwe: Wulfstan biṣọọbu ọmọ ilẹ̀ Saxony gbagbọ pe ikọlu awọn ara Denmark lori England ni ibẹrẹ ọrundun kọkanla jẹ́ ami kan pe opin ilẹ̀-ayé ti sunmọle. Ní 1525, Thomas Münzer ṣe olori iṣọtẹ awọn àgbẹ̀ arokojẹ ilẹ Germany nitori pe ninu iran kan oun rí awọn angẹli ti wọn ń pọ́n awọn dòjé fun ohun ti oun lero pe yoo jẹ́ ikore nla kan. Lọna ti o ṣe kedere, awọn isọtẹlẹ wọnyi kò péye.
Gẹgẹ bi o ti lè mọ̀, Bibeli ní awọn isọtẹlẹ ninu. Siwaju sii, awọn onkọwe Bibeli sọ pe Ọlọrun ni o mísí wọn. Kristian aposteli Peteru wi pe: “Kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu iwe mimọ ti o ni itumọ ìkọ̀kọ̀. Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ eniyan wá rí; ṣugbọn awọn eniyan ń sọrọ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun bi a ti ń dari wọn lati ọwọ́ ẹmi mimọ wá.”—2 Peteru 1:20, 21.
Pẹlu awọn nǹkan miiran, Bibeli sasọtẹlẹ oniruuru idagbasoke eyi ti ń fi iran ti yoo ni iriri wíwàníhìn-ín Jesu Kristi ninu agbara Ijọba ọrun hàn. Ogun, ìyàn, isẹlẹ, ati iwolulẹ okun iwarere ti kò tii si iru rẹ̀ rí yoo jẹ́ ami pataki ohun ti Bibeli ṣapejuwe gẹgẹ bi “ikẹhin ọjọ.” (2 Timoteu 3:1-5; Matteu 24:3-14, 34) Gẹgẹ bi Bibeli ti wi, imukuro eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi yoo lànà silẹ fun ayọ iran eniyan ninu ayé titun kan ti ibukun alailopin.—2 Peteru 3:13; Ìfihàn 21:1-4.
Oju wo ni iwọ fi wo iru awọn isọtẹlẹ Bibeli bẹẹ? Bii ti pupọ awọn àsọbádé, wọn ha jẹ kìkì ìgbèrò kan lasan bi? A le dán ìṣeégbáralé awọn asọtẹlẹ Bibeli ti kò tii ni imuṣẹ sibẹ wò nipa pipinnu boya awọn isọtẹlẹ Bibeli nipa awọn iṣẹlẹ ti o ti kọja ṣeegbarale. Ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e, awa yoo gbe diẹ ninu iwọnyi yẹwo.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Iyọnda Oninuure ti National Weather Service