Iwọ Ha Ń Tọ Jehofa Lẹhin Lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ Bi?
“OLÓDODO láyà bi kinniun.” (Owe 28:1) Wọn ń lo igbagbọ, wọn ń fi igbọkanle gbarale Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, wọn sì ń fi ìgboyà lọ siwaju ninu iṣẹ-isin Jehofa ni oju ewu eyikeyii.
Nigba ti awọn ọmọ Israeli wà ni Sinai lẹhin ti Ọlọrun dá wọn nídè kuro ninu oko-ẹrú Egipti ni ọrundun kẹrindinlogun B.C.E., awọn ọkunrin meji ni pataki fihàn pe awọn láyà bi kinniun. Wọn tun fi iṣotitọ si Jehofa labẹ awọn ipo lilekoko hàn. Ọ̀kan lara awọn ọkunrin wọnyi ni Joṣua ara Efraimu, ẹni ti o jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ Mose ti a sì wá yàn lẹhin naa gẹgẹ bi agbapò rẹ̀. (Eksodu 33:11; Numeri 13:8, 16; Deuteronomi 34:9; Joṣua 1:1, 2) Ẹnikeji ni Kalebu ọmọkunrin Jefunne ti ẹya Judah.—Numeri 13:6; 32:12.
Kalebu fi iduroṣinṣin ati ìtara ṣe ifẹ-inu Jehofa. Igbesi-aye gigun ti iṣẹ-isin tootọ rẹ̀ si Ọlọrun mu ki o ṣeeṣe fun un lati sọ pe oun ti “tọ Jehofa lẹhin lẹ́kùun-ún-rẹ́rẹ́.” (Joṣua 14:8, NW) “Mo jẹ́ aduroṣinṣin patapata si OLUWA Ọlọrun mi,” ni The New American Bible sọ. Kalebu “fi iṣotitọ ṣegbọran,” tabi “fi iduroṣinṣin mú ète,” Jehofa Ọlọrun “ṣẹ.” (Today’s English Version; The New English Bible) Ní sísọ ọ́ ni ọ̀nà miiran, Kalebu polongo pe: “Mo . . . ti tẹle OLUWA Ọlọrun mi tọkantọkan.” (New International Version) Iwọ ń kọ́? Iwọ ha ń tọ Jehofa lẹhin lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ bi?
Ṣiṣe Amí Ilẹ̀ Naa
Foju wo araarẹ laaarin awọn ọmọ Israeli ni kété lẹhin ti Jehofa ti dá wọn silẹ lominira kuro ninu isinru fun awọn ọmọ Egipti. Wo bi wolii Mose ṣe fi iṣotitọ tẹle awọn itọni ti Ọlọrun fifun un. Bẹẹni, sì ṣakiyesi igbọkanle Kalebu pe Jehofa wà pẹlu awọn eniyan Rẹ̀.
Ọdun keji lẹhin Ijadelọ kuro ni Egipti ni, awọn ọmọ Israeli sì pàgọ́ ni Kadeṣi-barnea ninu aginju Parani. Wọn wà ni imurasilẹ ni ibode Ilẹ Ileri. Tẹle àṣẹ Ọlọrun, Mose ti fẹ́ rán awọn amí 12 wọnu ilẹ Kenaani lọ. Ó sọ pe: “Ẹ gba ọ̀nà iha guusu [“Negebu,” NW] yii, ki ẹ sì lọ sori òkè nì. Ki ẹyin sì wo ilẹ [naa], bi o ti rí; ati awọn eniyan ti ń gbé inu rẹ̀, bi wọn ṣe alagbara tabi alailagbara, bi diẹ ni wọn, tabi pupọ; Ati bi ilẹ naa ti wọn ń gbé ti rí, bi didara ni bi buburu ni; ati bi ilu ti wọn ń gbé ti rí, bi ninu àgọ́ ni, tabi ninu ilu-odi; Ati bi ilẹ naa ti rí, bi ẹlẹtu ni tabi bi aṣálẹ̀, bi igi bá ń bẹ ninu rẹ̀, tabi kò sí. Ki ẹyin ki o sì mú ọkàn le, ki ẹyin si mú ninu eso ilẹ naa wá.”—Numeri 13:17-20.
Awọn ọkunrin 12 naa bẹrẹ irin-ajo elewu wọn. Irin-ajo wọn gba 40 ọjọ gbako. Ní Hebroni wọn rí awọn ọkunrin ti wọn tobi ni iwọn. Ní afonifoji Eṣkolu, wọn ṣakiyesi imesojade ilẹ naa wọn sì pinnu lati mú diẹ lara awọn eso rẹ̀ pada. Ṣíírí ajara kan wuwo debi pe awọn gende meji nilati fi ọ̀pá gbé e!—Numeri 13:21-25.
Ní pipada si ibi ti awọn ọmọ Israeli pàgọ́ si, awọn amí naa rohin pe: “Awa dé ilẹ naa nibi ti iwọ gbé rán wa lọ, nitootọ ni o ń ṣàn fun wàrà ati fun oyin; eyi sì ni eso rẹ̀. Ṣugbọn alagbara ni awọn eniyan ti ń gbé inu ilẹ naa, ilu olódi sì ni ilu wọn, wọn tobi gidigidi: ati pẹlupẹlu awa rí awọn ọmọ Anaki nibẹ. Awọn ara Amaleki sì ń gbé ilẹ iha guusu: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ń gbé ori-oke: awọn ara Kanaani sì ń gbé ẹ̀bá òkun, ati ni agbegbe Jordani.” (Numeri 13:26-29) Awọn amí mẹwaa kò ṣetan lati tẹwọgba àṣẹ Ọlọrun ki wọn sì yan wọnu Ilẹ Ileri.
“Jehofa Wà Pẹlu Wa”
Pẹlu igbagbọ ninu Jehofa Ọlọrun, bi o ti wu ki o ri, amí ti kò bẹru naa Kalebu rọni pe: “Ẹ jẹ ki a goke lọ lẹẹkan, ki a sì gbà á; nitori pe awa lè ṣẹ́ ẹ.” Ṣugbọn awọn amí mẹwaa fàáké kọ́rí, ni sisọ pe awọn olugbe Kenaani lagbara ju awọn ọmọ Israeli lọ. Awọn amí ti a ti dáyà já ti wọn sì jẹ́ alainigbagbọ naa wo araawọn gẹgẹ bi ẹlẹ́ǹgà lásán làsàn ni ifiwera.—Numeri 13:30-33.
“OLUWA wà pẹlu wa: ẹ maṣe bẹru wọn,” ni Kalebu ati Joṣua rọni. Wọn kọ etí ikún si awọn ọ̀rọ̀ wọn. Nigba ti awọn eniyan naa sọrọ nipa sísọ wọn ni okuta, Ọlọrun dá si i ó sì paṣẹ idajọ sori awọn oniraahun naa pe: “Ẹyin kì yoo dé inu ilẹ naa, ti mo ti bura lati mu yin gbé inu rẹ̀, bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, ati Joṣua ọmọ Nuni. Ṣugbọn awọn ọmọ wẹ́wẹ́ yin, . . . awọn ni emi o mú wọ̀ ọ́, awọn ni yoo sì mọ ilẹ naa ti ẹyin gàn. . . . Awọn ọmọ yin yoo sì maa rìn kiri ni aginju ni ogoji ọdun, . . . titi oku yin yoo fi ṣòfò tán ni aginju. Gẹgẹ bi iye ọjọ ti ẹyin fi rin ilẹ naa wò, àní ogoji ọjọ, ọjọ kan fun ọdun kan, ni ẹyin ó ru ẹṣẹ yin, àní ogoji ọdun.”—Numeri 14:9, 30-34.
Wọn Jẹ́ Oluṣotitọ Sibẹ Ni Ọpọ Ọdun Lẹhin Naa
Àṣẹ idajọ ologoji ọdun naa bẹrẹ lati ibẹrẹ titi de opin, iku sì pa gbogbo iran awọn oníràáhùn naa. Ṣugbọn Kalebu ati Joṣua jẹ́ oluṣotitọ si Ọlọrun sibẹ. Ní pẹtẹlẹ Moabu, Mose ati Olori Alufaa Eleasari ti ka awọn ọkunrin ológun ti wọn jẹ́ ẹni 20 ọdun soke. Ọlọrun darukọ ọkunrin kan lati inu ẹya Israeli kọọkan lati di ẹni ti a fi pipin Ilẹ Ileri lé lọwọ. Kalebu, Joṣua, ati Eleasari wà lara wọn. (Numeri 34:17-29) Bi o tilẹ jẹ pe o jẹ́ ẹni ọdun 79 nisinsinyi, Kalebu ṣì jẹ́ alagbara, aduroṣinṣin, ati onigboya.
Nigba ti Mose ati Aaroni ka awọn eniyan naa ni Sinai ni kété ṣaaju ki wọn tó fi ibẹru kọ̀ lati wọ ilẹ Kenaani, awọn jagunjagun ọkunrin Israeli parapọ jẹ́ 603,550. Lẹhin ẹwadun mẹrin ninu aginju, ọmọ-ogun kikere ju kan ti 601,730 ni o wà. (Numeri 1:44-46; 26:51) Sibẹ, pẹlu Joṣua ti ń ṣaaju wọn ati Kalebu oluṣotitọ ninu agbo wọn, awọn ọmọ Israeli wọ Ilẹ Ileri wọn sì gbadun iṣẹgun kan tẹle omiran. Gẹgẹ bi Joṣua ati Kalebu ti sábà maa ń reti, Jehofa ń ṣẹgun fun awọn eniyan rẹ̀.
Ní sídọdá Odò Jordani pẹlu awọn jagunjagun ọkunrin Israeli, Joṣua ati Kalebu ti wọn ti dagba ru ẹrù-ìnira wọn ninu awọn ija-ogun ti ń jẹyọ. Lẹhin ọdun mẹfa ti ogun jíjà, bi o ti wu ki o ri, ọpọ ilẹ ni ó ṣì wà ti a kò tíì gbà. Jehofa yoo lé awọn olugbe naa jade ṣugbọn nisinsinyi ó pàṣẹ pe ki a pín ilẹ naa nipasẹ ìbò laaarin ẹya Israeli.—Joṣua 13:1-7.
Ó Tọ Jehofa Lẹhin Lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́
Gẹgẹ bi ẹni ti o ti jà ninu ọpọlọpọ ogun, Kalebu duro niwaju Joṣua ó sì sọ pe: “Ẹni ogoji ọdun ni mi nigba ti Mose iranṣẹ OLUWA rán mi lati Kadeṣi-barnea lọ ṣamí ilẹ naa; mo sì mú ìhìn fun un wá gẹgẹ bi o ti wà ni ọkàn mi. Ṣugbọn awọn arakunrin mi ti o goke lọ já awọn eniyan ni àyà: ṣugbọn emi tọ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin [lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, NW].” (Joṣua 14:6-8) Bẹẹni, Kalebu ti tọ Jehofa lẹhin lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, ó ń fi iduroṣinṣin ṣe ifẹ-inu Ọlọrun.
Kalebu fikun un pe, “Mose sì bura ni ọjọ naa wi pe, nitootọ ilẹ ti ẹsẹ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ̀-ìní rẹ ni yoo jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ laelae, nitori ti iwọ tọ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin [lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, NW]. Ǹjẹ́ nisinsinyi, kiyesi i, OLUWA dá mi sí gẹgẹ bi o ti wi, lati ọdun marunlelogoji yii wá, lati ìgbà ti OLUWA ti sọ ọ̀rọ̀ yii fun Mose, nigba ti Israeli ń rìn kiri ni aginju: sì kiyesi i nisinsinyi, emi di ẹni arundinlaadọrun-un ọdun ni oni. Sibẹ emi ni agbara ni oni gẹgẹ bi mo ti ní ní ọjọ ti Mose rán mi lọ: gẹgẹ bi agbara mi ti rí nigba naa, àní bẹẹ ni agbara mi rí nisinsinyi, fun ogun, ati lati jade ati lati wọle. Ǹjẹ́ nitori naa fi òkè yii fun mi, eyi ti OLUWA wi ni ọjọ naa; nitori ti iwọ gbọ́ ni ọjọ naa bi awọn ọmọ Anaki ti wà nibẹ, ati ilu ti o tobi, ti o sì ṣe olódi: boya OLUWA yoo wà pẹlu mi, emi ó sì lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi.” Kalebu wá gba Hebroni gẹgẹ bi ogún-ìní.—Joṣua 14:9-15.
Kalebu arugbo ti gba iṣẹ-ayanfunni ti o nira julọ—ẹkùn kan ti o kun fun awọn àdàmọ̀di ọkunrin. Ṣugbọn eyi kò le jù fun jagunjagun ẹni ọdun 85 yii. Bi akoko ti ń lọ awọn òṣìkà abúmọ́ni ti ń gbé Hebroni ni a rẹ́hìn wọn. Otnieli, ọmọkunrin aburo Kalebu ọkunrin ti o jẹ́ onidaajọ kan ni Israeli, jà gba Debiri. Awọn ilu mejeeji ni awọn ọmọ Lefi gbé lẹhin naa, Hebroni sì di ilu aabo kan fun olupaniyan laipetepero tẹlẹ.—Joṣua 15:13-19; 21:3, 11-16; Onidajọ 1:9-15, 20.
Maa Tọ Jehofa Lẹhin Lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ Nigba Gbogbo
Kalebu ati Joṣua jẹ alaipe eniyan. Sibẹ, wọn fi iṣotitọ ṣe ifẹ-inu Jehofa. Igbagbọ wọn kò jórẹ̀hìn nigba 40 ọdun ìnira ninu aginju eyi ti o jẹ abajade ikuna Israeli lati ṣegbọran si Ọlọrun. Bakan naa, awọn iranṣẹ Jehofa lode-oni kìí jẹ́ ki ohunkohun dí iṣẹ-isin wọn si iyin Ọlọrun lọwọ. Ní mímọ̀ pe ìjà kan ń lọ lọwọ laaarin eto-ajọ Ọlọrun ati ti Satani Eṣu, wọn jẹ aduroṣinṣin, wọn ń fi iṣedeedee delẹ wá ọ̀nà lati wu Baba wọn ọrun ninu ohun gbogbo.
Fun apẹẹrẹ, ọpọ ninu awọn eniyan Jehofa ti fẹ̀mí wewu ìbálò rírorò ati iku paapaa lati ṣayẹyẹ Ounjẹ Alẹ Oluwa, tabi Iṣe-iranti iku Jesu Kristi. (1 Korinti 11:23-26) Ní ọ̀nà yii obinrin Kristian kan ti a hámọ́ ninu àgọ́ iṣẹniniṣẹẹ Nazi nigba Ogun Agbaye II rohin pe:
“Gbogbo eniyan ni a sọ fun lati wà ninu ile ifọṣọ ni agogo 11 alẹ́. Ní agogo 11 géérégé a kó wa jọ, gbogbo wa jẹ́ 105 ni iye. A nàró sunmọra pẹkipẹki ni agbo kan, laaarin [eyi ti] apoti-itisẹ kan ti a da aṣọ funfun bò ti a gbé awọn ohun-iṣapẹẹrẹ lé wà. Àbẹ́là kan tanmọlẹ sinu yàrá naa, niwọn bi iná manamana ti lè tú wa fó. A dabi awọn Kristian ìjímìjí ninu awọn iboji abẹ́lẹ̀. Àsè aláyẹyẹ isin kan ni o jẹ́. A sọ ẹ̀jẹ́ agbonajanjan si Baba wa jade lakọtun lati lo gbogbo okun wa fun idalare orukọ mimọ Rẹ̀, lati fi iṣotitọ duro fun Iṣakoso Ọlọrun Naa.”
Laika awọn adanwo wa sí gẹgẹ bi iranṣẹ Jehofa ti a ń ṣe inunibini si, a lè gbarale okun ti Ọlọrun ń fifunni lati fi igboya ṣiṣẹsin in ki a sì mú ọlá wá fun orukọ mimọ rẹ̀. (Filippi 4:13) Bi a ti ń sakun lati wu Jehofa, yoo ṣe wá ni rere lati ranti Kalebu. Apẹẹrẹ rẹ̀ ninu titẹle Jehofa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ wú ọdọmọkunrin kan ti ó kowọnu iṣẹ iwaasu alakooko kikun tipẹ tipẹ sẹhin ni 1921 lori. Ó kọwe pe:
“Bi o tilẹ jẹ pe didi aṣaaju-ọna kan tumọsi fifi iṣẹ mi tí ó rọ̀ mi lọ́rùn ni ibi iṣẹ itẹwe ni Coventry [England] silẹ, kò sí àbámọ̀ kankan. Iyasimimọ mi ti yanju ọ̀ràn naa ṣaaju akoko yii; igbesi-aye mi ni mo yasimimọ fun Ọlọrun. Mo ranti Kalebu, ẹni ti o wọ Ilẹ Ileri pẹlu Joṣua ti a sì sọ nipa rẹ pe, ‘Ó tọ Jehofa lẹhin lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.’ (Joṣua 14:8) Iyẹn jọbi iṣarasihuwa ti a nilati fẹ́ fun mi. Mo mọ̀ pe ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun ‘lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́’ yoo mú ki igbesi-aye mi ti mo yasimimọ tubọ ṣekoko; yoo yọnda anfaani pupọ sii fun mi lati mu eso ti n sami si Kristian kan jade.”
Kalebu ni a bukun fun dajudaju fun fifi iduroṣinṣin tọ Jehofa lẹhin lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, ni wíwá ọ̀nà nigba gbogbo lati ṣe ifẹ-inu atọrunwa. Bii tirẹ̀, awọn miiran ti ní ayọ ńlá ati ibukun jingbinni ninu iṣẹ-isin Ọlọrun. Ǹjẹ́ ki iyẹn jẹ́ iriri rẹ gẹgẹ bi ẹnikan ti ń tọ Jehofa lẹhin lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ laidawọduro.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kalebu ati Joṣua jẹ oluṣotitọ si Jehofa labẹ idanwo. Iwọ ha ń ṣe bẹẹ bi?