Ayé Dídára Jù Kan—Àlá kan Lásán Ha Ni Bí?
BÍ ÌWỌ bá ti jẹ́ ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́ pé Mazda ni Ọlọrun gíga jùlọ gẹ́gẹ́ bí Zoroaster, wòlíì ilẹ̀ Iran náà ti wàásù rẹ̀, ìwọ ti níláti dúró de ọjọ́ náà nígbà tí ilẹ̀-ayé yóò padà sí ẹwà rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bí ìwọ bá ti gbé ní Greece ìgbàanì, ó ṣeéṣe kí o ti lálàá pé o dé Àwọn Erékùṣù Agbérekoni fífanimọ́ra tàbí pé o rí ìpadà Sànmánì Aláásìkí tí Hesiod akéwì ní ọ̀rúndún kẹjọ B.C.E. ṣàpèjúwe. Guaraní kan tí ó jẹ́ ará India ní Gúúsù America ṣì lè máa wá Ilẹ̀ Aláìníbi. Ní gbígbé ní àkókò wa, bóyá o nírètí pé ayé yóò sunwọ̀n síi nítorí ìdábàá òṣèlú tàbí nítorí wíwà tí àwọn ẹ̀dá alààyè wà lójúfò sí ibùgbé wọn ní òde ìwòyí.
Sànmánì Aláásìkí, Àwọn Erékùṣù Agbérekoni, Ilẹ̀ Aláìníbi—ìwọ̀nyí wà lára àwọn orúkọ tí a ń lò láti ṣàpèjúwe ìyánhànhàn kan náà, ìrètí nípa ayé dídára jù kan.
Dájúdájú ayé yìí, ayé wa, kìí ṣe ibi kan tí ó rọrùn. Ìwà-ọ̀daràn lọ́nà rírorò tí ń ga síi, àwọn ogun ṣíṣekúpa mọ̀lẹ́bí-ẹni jẹ́ ti oníwà-ipá lọ́nà tí kò ṣẹlẹ̀ rí, pípa àwọn ẹ̀yà run, dídágunlá sí ìjìyà àwọn ẹlòmíràn, òṣì, àti ebi, àìríṣẹ́ṣe àti àìsí ìsowọ́pọ̀ṣọ̀kan, ìṣòro ibùgbé àwọn ohun alààyè, àwọn àmódi tí kò gbóògùn tí ń pọ́n àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ lójú—àkọsílẹ̀ àwọn àjálù lọ́ọ́lọ́ọ́ dàbí ẹni pé kò lópin. Ní ríronú lórí àwọn ogun tí a ń jà ni lọ́ọ́lọ́ọ́, akọ̀ròyìn ilẹ̀ Italy kan sọ pé: “Ìbéèrè tí ó lè dìde lọ́nà tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu ni pé bóyá ẹ̀tanú kọ́ ni àròdùn-ọkàn lílágbára jù ní àkókò wa.” Ní gbígbé ipò náà yẹ̀wò, ìwọ ha rò pé ó bọ́gbọ́nmu láti lépa ohun kan tí ó yàtọ̀, ohun kan tí ó dára jù? Tàbí irú ìlépa bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ìyánhànhàn fún Ibi Aláìlálèébù kan, àlá kan tí kì yóò ṣẹ láé bí? Àwa ha ń gbé nínú èyí tí ó dára jùlọ nínú àwọn ayé tí ọwọ́ lè tẹ̀ bí?
Ìwọ̀nyí kìí ṣe àníyàn titun. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún àwọn ènìyàn ti ń lálàá ayé kan nínú èyí tí ìṣọ̀kan, ìdájọ́-òdodo, aásìkí, àti ìfẹ́ yóò ti jọba. Nígbà tí ó ṣe, àwọn ọlọ́gbọ́n-èrò-orí mélòókan ṣàlàyé èròǹgbà wọn nípa Ìjọba Orílẹ̀-Èdè dídárawẹ́kú kan ní kíkún, àwọn ayé dídára jù. Ṣùgbọ́n, ó baninínújẹ́ pé, kò tíì ṣeéṣe fún wọn láti ṣàlàyé bí wọn yóò ṣe mú un ṣẹ.
Ǹjẹ́ àkọsílẹ̀ tí ó ti wà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún nípa àwọn àlá, Ibi Aláìlálèébù, àti ìdàníyàn ènìyàn fún àwùjọ dídára jù kan ha kọ́ wa ní ohunkóhun bí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ǹjẹ́ èyí ni ó dára jùlọ nínú àwọn ayé tí ọwọ́ lè tẹ̀ bí?