ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìtọ́sọ́nà Ẹ̀dá-Ènìyàn Ha Ti Kùnà Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtọ́sọ́nà Ẹ̀dá-Ènìyàn Ha Ti Kùnà Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn
    Jí!—1998
  • Níbo Ni Ìwọ Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà Tí Ó Ṣeé Gbáralé?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsapá Àwọn Èèyàn Láti Fòpin sí Ipò Òṣì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/15 ojú ìwé 3-4

Ìtọ́sọ́nà Ẹ̀dá-Ènìyàn Ha Ti Kùnà Bí?

TA NI ó dá ohun gbogbo? Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ “Ọlọrun,” nígbà náà ìwọ fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Ọlọrun Bibeli, Ẹlẹ́dàá.

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú Ọlọrun ni ó ṣòro fún láti gbà pé òun ń ṣiṣẹ́ kárakára ní yíyanjú àwọn ìṣòro aráyé. Ó ha lọ́gbọ́n nínú láti ronú pé Ọlọrun ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí ń lọ lọ́wọ́ tí yóò mú ìtura wá fún aráyé bí? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò rí ẹ̀rí tí ó yèkooro tó pé èyí rí bẹ́ẹ̀.

Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, ẹ̀dá-ènìyàn ti dán àìmọye àwọn ọ̀nà ìgbà ran ara-ẹni lọ́wọ́ wò nínú ìwákiri fún ojútùú, láìfi ti Ọlọrun kún un. Ṣùgbọ́n ẹ̀dá-ènìyàn ha ti rí ojútùú náà bí? Tàbí ńṣe ni àwọn ìṣòro náà túbọ̀ ń burú síi tí wọ́n sì túbọ̀ ń lekoko síi láti yanjú? Báwo ni aráyé ṣe ń kojú àwọn ìṣòro tí ń béèrè àfiyèsí kíákíá nínú ayé lónìí?

Ògbógi kan sọ ọ́ ní ọ̀nà yìí: “Láti ìgbà Ìyípadà Pátápátá sí Lílo Ẹ̀rọ, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà ti kófà àwọn ọrọ̀ ayé ní ìkókúkòó nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà ìgbàṣe àwọn nǹkan jáde ati ìlò wọn láìdá wọ́n padà, ní bíba àyíká àgbáyé jẹ́, sí ìpalára àwọn orílẹ̀-èdè tí ń gòkè àgbà.”

Aráyé ń bá a lọ láti run ilẹ̀-ayé. Ìwé-ìròyìn Argentina náà, Clarín sọ pé: “Ní apá ìlàjì tí ó gbẹ̀yìn ọ̀rúndún yìí, ojúkòkòrò ọrọ̀-ajé, àìkíyèsára, àti ìwà àìnáání ni ó ṣokùnfà àwọn ìjábá ńláǹlà tí kìí wulẹ̀ ṣe pé ó fa ikú àwọn ènìyàn nìkan ni ṣùgbọ́n tí ó tún ba àyíká jẹ́ dé ìwọ̀n tí kò ṣeédíwọ̀n.”

Ó jọ pé òṣì paraku ti wá di apákan ẹgbẹ́ àwùjọ ti òde-òní. Kódà àwọn orílẹ̀-èdè tí a ń pè ní ọlọ́rọ̀ nínú ayé pàápàá ni ẹrù òṣì ti wọ̀ lọ́rùn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìròyìn The Globe and Mail ti Toronto, Canada ti wí, a fojú díwọ̀n rẹ̀ pé “ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn ará Canada ni yóò tòṣì lákòókò kan nínú ìgbésí-ayé wọn nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ọjọ́ orí tí ó yẹ láti ní iṣẹ́ lọ́wọ́.” Ìwé-ìròyìn náà fikún un pé “ìwólulẹ̀ ìdílé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdí pàtàkì fún òṣì, tí ìtẹ̀sí náà sì ń gbòòrò síi ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.”

Àṣìlò oògùn jẹ́ àmì mìíràn ti ń fi ẹgbẹ́ àwùjọ tí ó túbọ̀ ń bàjẹ́ hàn. Kí ni aráyé lè ṣe nípa rẹ̀? Ó hàn gbangba pé ìwọ̀nba ni wọ́n lè ṣe ní gbogbogbòò. Àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ kò dẹ́kun láti máa bàjẹ́ níti ara-ìyára, èrò-orí, àti ìwà gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí tààràtà tí àṣìlò àwọn oògùn tí ń panilọ́bọlọ̀. Ìṣòro náà sì ń búrẹ́kẹ́.

Ó dàbí ẹni pé àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ń pàdánù nínú ogun tí wọ́n ń gbé ti àrùn. Òtítọ́ ni pé ọgbọ́n ìmọ̀-ẹ̀rọ òde-òní ti ṣẹ́gun àwọn àrùn kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà tí àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ fúnraawọn ń gbà ṣe nǹkan ti dákún ìrujáde irú àwọn kòkòrò tín-⁠ìn-⁠tìn-tín inú ara kan tí ń fa àrùn tí kò gbóògùn.

Ìjọba ẹ̀dá-ènìyàn kò lè fi òpin sí ìtànkálẹ̀ títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú. Fún àpẹẹrẹ, láìka ọ̀pọ̀ ẹ̀jẹ́ àti òfin tí a gbékalẹ̀ láti dí ìmúnisìnrú lọ́wọ́ sí, a fojúdíwọ̀n rẹ̀ pé kárí-ayé iye tí ó ju ọgọ́rùn-⁠ún million ènìyàn ni a ń fi tipátipá mú láti ṣiṣẹ́ lábẹ́ àwọn ipò tí ó jásí ìmúnisìnrú pátápátá.

Ṣùgbọ́n èéṣe tí ìtọ́sọ́nà ẹ̀dá-ènìyàn fi kùnà? Gbé àwọn ìdí abájọ wọ̀nyí yẹ̀wò. Ìtọ́sọ́nà ẹ̀dá-ènìyàn wá láti ọwọ́ àwọn ènìyàn​—⁠àwọn ènìyàn tí agbára wọn ní ààlà gidigidi. Ìrírí wọn nínú ìgbésí-ayé kò tó nǹkan, àwọn àṣà-ìbílẹ̀ àti àyíká kan pàtó sì mú kí wọ́n kéré jọjọ ní gbogbogbòò. Ìmọ̀ wọn pẹ̀lú ní ibi tí ó mọ. Ìtọ́sọ́nà èyíkéyìí tí wọ́n lè fúnni ń fi àwọn ààlà wọ̀nyẹn hàn. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti sọ, “gbogbo ènìyàn ni ó sáà ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì ti kùnà ògo Ọlọrun.”​—⁠Romu 3:⁠23.

Níti gidi èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ìṣòro àti ìnira tí apá tí ó pọ̀ jù nínú aráyé ń faragbá jẹ́ ìyọrísí tààràtà tàbí aláìjẹ́ tààràtà ti ṣíṣàìka ìtọ́sọ́nà Ọlọrun sí. Bí ó ti wù kí ó rí, níbo ni a ti lè rí irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀? Báwo ni Ọlọrun ṣe ń pèsè ìtọ́sọ́nà fún wa lónìí? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò gbé àwọn ìdáhùn náà yẹ̀wò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́