ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 10/15 ojú ìwé 32
  • Ẹ Káàbọ̀ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun”!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Káàbọ̀ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun”!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpéjọpọ̀ “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọrun” Ti 1996
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 10/15 ojú ìwé 32

Ẹ Káàbọ̀ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun”!

BẸ́Ẹ̀NI, àkókò náà ti dé fún àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti 1994. Láti June 1994 títí di January 1995, ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà ni a óò gbọ́ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìlú-ńlá káàkiri àgbáyé​—⁠lákọ̀ọ́kọ́ ní North America, lẹ́yìn náà ní Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn Europe, Asia, Central àti South America, Africa, Australia, àti ní àwọn erékùṣù òkun.

Ẹ wo bí èyí ṣe jẹ́ ẹṣin-ọ̀rọ̀ kan tí ń múnironú jinlẹ̀ tó​—⁠“Ìbẹ̀rù Ọlọrun”! Èyí kìí ṣe ìbẹ̀rù ojora nípa ẹnìkan tí ìgbésí-ayé rẹ̀ ń bẹ nínú ewu bíkòṣe ìbẹ̀rù fún Ọlọrun, ìbẹ̀rù kan tí ń fúnni ní àlàáfíà ọkàn àti ayọ̀. Òwe inú Bibeli sọ pé: “Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Oluwa ni ọrọ̀, ọlá, àti ìyè.” (Owe 22:⁠4) Báwo ni bíbẹ̀rù Ọlọrun ṣe lè yọrísí “ọ̀rọ̀, ọlá, àti ìyè”? Ìyẹn yóò ṣe kedere bí a ti ń ṣe ìgbékalẹ̀ ẹṣin-ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ náà ní àwọn ọjọ́ mẹ́ta náà tí ó kún fún àwọn ọ̀rọ̀-àwíyé, ìjíròrò, àṣefihàn, àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan.

Aposteli Paulu kọ̀wé pé kí a máṣe “ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì.” (Heberu 10:25, NW) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú ìyẹn, ní pípàdé lẹ́ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìjọ àti ìjọsìn. Bí ó ti wù kí ó rí, àpéjọpọ̀ àgbègbè ọdọọdún jẹ́ àkànṣe. Wọ́n ń fojúsọ́nà fún un pẹ̀lú ìháragàgà wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù lẹ́yìn náà. A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà késí ọ, ìsìn yòówù kí tìrẹ jẹ́, láti darapọ̀ mọ́ wọn ní àpéjọpọ̀ wọn kí o sì gbádùn ìfararora Kristian ọlọ́yàyà àti ìsọfúnni tẹ̀mí tí ó ṣekókó. Mẹ́ḿbà ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ní àdúgbò yóò láyọ̀ láti sọ ibi tí a ó ti ṣe àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ọ jùlọ àti ìgba tí a ó ṣe é fún ọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́