Àpéjọpọ̀ “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọrun” Ti 1996
NÍ ÀKÓKÒ ìgbàanì, àwọn ènìyàn Jehofa máa ń ṣe ayẹyẹ mẹ́ta pàtàkì lọ́dọọdún. Bákan náà, ní òde òní, àwọn ènìyàn tí ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jehofa ń pàdé nígbà mẹ́ta lọ́dún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aláyẹyẹ. Wọ́n ń gbádùn pípàdé pọ̀ fún àpéjọ àkànṣe ọlọ́jọ́ kan, àpéjọ àyíká ọlọ́jọ́ méjì, àti àpéjọpọ̀ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta tàbí mẹ́rin. Ní ọdún yìí, ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ àgbègbè náà ni “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọrun.”
Ẹ wo bí ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn ti ṣe wẹ́kú tó! Ọlọrun wa, Jehofa, ni “Ọlọrun àlàáfíà,” bẹ́ẹ̀ ni, “Ọlọrun tí ń fúnni ní àlàáfíà.” Aṣáájú wa, Jesu Kristi, ni “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” ìhìn iṣẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa sì ń mú wá jẹ́ ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà Ọlọrun. (Filippi 4:9; Romu 15:33; Isaiah 9:6; Nahumu 1:15) A ti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ àtàtà kan tí yóò ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọrírì ìjẹ́pàtàkì àlàáfíà Ọlọrun.
Ní ọdún yìí, ní Nàìjíríà nìkan, 104 àpéjọpọ̀ yóò wà. Ó ṣeé ṣe kí àpéjọpọ̀ kan wà nítòsí rẹ. Èé ṣe tí o kò wádìí lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń bẹ ní àdúgbò rẹ, nípa àkókò náà gan-an àti ibi tí a óò ti ṣe é, kí o sì wéwèé láti wà níbẹ̀? Gbogbo ẹni tí ó bá ní ọkàn ìfẹ́ sí ojúlówó àlàáfíà tí yóò wà pẹ́ títí, ni a óò fi tìfẹ́tìfẹ́ kí káàbọ̀.