Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ọlọrun Kìí Ṣe Ojúsàájú
NÍ ÈYÍ tí ó ju 1,900 ọdún sẹ́yìn, aposteli Peteru jẹ́rìí fún ọ̀gágun náà Korneliu, ní sísọ pé: “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọrun kìí ṣe ojúsàájú ènìyàn: ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Iṣe 10:34, 35) Korneliu fi ìbẹ̀rù Ọlọrun àti ìfẹ́ fún òdodo hàn. Ó tẹ́wọ́gba ìjẹ́rìí tí Peteru fún un, ó sì di Kristian kan.
Bákan náà ni ọ̀ràn rí lónìí—Ọlọrun kìí ṣe ojúsàájú. Èyí ni a kíyèsí láti inú ìrírí kan láti Germany. Ìròyìn náà sọ pé:
“Bárékè títóbi ti àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Russia wà nínú ìpínlẹ̀ ìjọ wa. Ní 1989, kété lẹ́yìn tí Ògiri Berlin wó lulẹ̀, àwọn alàgbà béèrè bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn akéde bá gbọ́ èdè Russian. Díẹ̀ lára wa gbọ́, a sì lọ láti ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ yìí, èyí tí ó sì ti jẹ́ ayọ̀ tòótọ́. Èyí tí ó tẹ̀lé e jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn ìrírí.
“Mo wà pẹ̀lú akéde kan tí kò tíì ṣèrìbọmi (ẹni tí ó sì ti ṣèrìbọmi lẹ́yìn ìgbà náà) nígbà tí a bá apàṣẹ ológun kan sọ̀rọ̀. Apàṣẹ ológun náà fetísílẹ̀ sí ohun tí a fẹ́ sọ ó sì pè wá lẹ́yìn náà láti bá àwọn ṣójà rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ó sọ pé àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ gbọ́ nípa Ọlọrun àti Bibeli, nítorí náà a ṣàdéhùn láti padà wá.
“A sọ fún arábìnrin kan tí ó gbọ́ èdè Russian dáradára láti bá wa lọ gẹ́gẹ́ bí ògbufọ̀. Nínú yàrá ìpàdé inú bárékè náà, a pàtẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ ó sì ṣeéṣe fún wa láti bá ṣójà 68 sọ̀rọ̀ kí a sì dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Lópin rẹ̀ wọ́n fi ayọ̀ gba ìwé 35 àti ìwé ìròyìn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 100. Bí a ṣe ń fi iyàrá ìpàdé náà sílẹ̀, a rí àwọn àwùjọ kéékèèké tí wọ́n ń jíròrò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
“A ṣàdéhùn láti padà wá ní July 4, 1992. Bí a ṣe débẹ̀ ní aago 10:50 òwúrọ̀, ẹ̀ṣọ́ tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà bárékè náà sọ fún wa pé àwọn ṣójà náà ti ń retí wa. Méjọ̀ kan mú wa lọ sí iyàrá ìpàdé, a sí ríi pé ọmọge kan, tí ó ti gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ wa fún ibi àkójọ ìwé-kíkà, ti ṣèfilọ̀ bíbọ̀ wa nípa lilẹ àwọn páálí ìsọfúnni mọ inú bárékè náà. Àwọn arákùnrin mẹ́ta sọ ọ̀rọ̀ àsọyé kúkúrú nípa iṣẹ́ wa kárí ayé tí wọ́n sì fi bí a ṣe lè ní ìgbọ́kànlé nínú Bibeli hàn. Lẹ́yìn náà a fàyègba àwọn ìbéèrè láti ọ̀dọ̀ àwùjọ, tí a sì ń dáhùn wọn láti inú Bibeli. Lára àwọn ìbéèrè náà ni pé, Kí ni ìdúró àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú ọ̀ràn ṣíṣiṣẹ́ ológun, àti pé ǹjẹ́ èyíkéyìí nínú wọn ha jẹ́ ṣójà bí? Èyí fún akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi tí ó tẹ̀lé mi wá níṣàájú ní àǹfààní láti ṣàlàyé ọdún 25 tí ó fi jẹ́ ọmọ ogun Ìlà-Oòrùn Germany, àwọn ọdún tí ó lò kẹ́yìn ni ó fi sìn gẹ́gẹ́ bí balógun ọmọ ogun ojú òfuurufú. Ó sọ bí òun ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun àti Bibeli tí òun sì fẹ́ láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nísinsìnyí. Inú àwọn ṣójà náà dùn nípa ohun tí wọ́n gbọ́. Láàárín ìṣẹ́jú méje gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a kó wá ti wà ní ọwọ́ àwọn ṣójà náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ń fẹ́ Bibeli. Ní ilé ìtàwé kan ó ṣeéṣe fún wa láti gba Bibeli méje tí a kọ ní èdè Russian, èyí tí wọ́n fi ìmọrírì gbà. Ó jẹ́ ayọ̀ tòótọ́ láti fún àwọn tí ebi tẹ̀mí ń pa wọ̀nyí ní ìsọfúnni nípa Bibeli, a sì ṣèrètí pé wọn yóò ṣiṣẹ́ lé e lórí.”
Níti tòótọ́, Ọlọrun kìí ṣe ojúsàájú. Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ń rọ àwọn ènìyàn aláìlábòsí-ọkàn èyíkéyìí àti ní ibikíbi tí wọ́n lè wà. Ó ń pè wọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun àti Ọmọkùnrin òun, Jesu Kristi, ọ̀pọ̀ láti inú apá ìgbésí-ayè gbogbo sì ń ṣe bẹ́ẹ̀.—Johannu 17:3.