Èéṣe tí Àwọn Ẹlẹ́rìí fi Ń Ṣèbẹ̀wò Lemọ́lemọ́?
‘WỌ́N tún dé nìyẹn! Ṣebí wọ́n wá síbí ní ọ̀sẹ̀ mélòókan sẹ́yìn!’ Ìyẹn ha ń wá sí ọ lọ́kàn nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá kàn sí ọ bí? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lónìí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń bẹ̀wò déédéé. Ìwọ lè béèrè pé, Èéṣe tí wọ́n fi tẹramọ́ ọn nígbà tí wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn ní ìsìn tiwọn tàbí pé wọn kò lọ́kàn-ìfẹ́ sí i? Ìbéèrè yẹn ń fẹ́ ìdáhùn.
Ẹrù-Iṣẹ́ Níwájú Ọlọrun
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Ìwé-Mímọ́ pé láti 1914, ọdún náà tí Ogun Àgbáyé I bẹ̀rẹ̀, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé ti ń mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ṣẹ nípa òpin ètò-ìgbékalẹ̀ ayé ìsinsìnyí àti Ìjọba Ọlọrun tí ń bọ̀ wá ṣàkóso lé ilẹ̀-ayé lórí. Ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún ọdún ìwà ipá, ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti ìkórìíra jọ bí èyí tí ó ti mú kí aráyé jìnnà sí rírí ojútùú lọ́nà ti ìṣèlú sí àwọn ìṣòro wọn ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àwọn ogun àti ìkópayàbáni tí ó ṣì ń pọ́n ìdílé ẹ̀dá ènìyàn lójú jẹ́ ẹ̀rí pé ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn ti kùnà láti yí ọkàn, èrò-inú, àti ìwà àwọn ènìyàn padà. Ìbínú jíjinlẹ̀ látàrí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ṣì ń ba ipò-ìbátan tí ń bẹ láàárín àwùjọ ẹ̀yà-ìran, ẹ̀yà-èdè, àti ìsìn jẹ́. Ìyẹn jẹ́ òtítọ́ ní àwọn àgbègbè jíjìnnà síra bí Afghanistan, India, Middle East, Northern Ireland, South Africa, àti Yugoslavia àtijọ́. Nígbà náà, kí ni ojútùú wíwàpẹ́títí náà?
Kí Ní Ń Sún Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣiṣẹ́?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ̀ pé ojútùú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun—àkóso Ìjọba rẹ̀ tí ó ṣèlérí nípasẹ̀ Kristi Jesu—ni ìdáhùn gbígbéṣẹ́ kanṣoṣo náà. Jesu tilẹ̀ fi ẹ̀bẹ̀ kan fún àkóso Ìjọba yẹn kún àdúrà àwòkọ́ṣe lílókìkí rẹ̀ pé: “Nítorí náà báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbàdúrà: Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run; Kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé; Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bí ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.” Àwọn Ẹlẹ́rìí gbàgbọ́ pé níti gidi ni àdúrà yìí ń rọ Ọlọrun láti dásí àlámọ̀rí aráyé.—Matteu 6:9, 10.
Nítorí náà èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fí ń nímọ̀lára pé ó pọndandan láti lọ láti ilé dé ilé láti gbìyànjú láti jẹ́ ìhìn-isẹ́ yẹn léraléra? Ó jẹ́ nítorí àṣẹ méjì tí Jesu tẹnumọ́: “Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ. Èyí ni èkínní àti òfin ńlá. Èkejì sì dàbí rẹ̀, Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”—Matteu 22:37-39.
Àwọn Ẹlẹ́rìí fẹ́ ìbùkún Ọlọrun fún araawọn, àti nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wọn, wọ́n fẹ́ ìbùkún kan náà yẹn fún wọn. Ní títipa báyìí tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jesu, ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan sún wọn láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn. Wọ́n fẹ́ láti nawọ́ àǹfààní náà sí wọn ó kérétán láti mọ ohun tí “Ọlọrun olùbùkún” ti ṣèlérí fún aráyé onígbọràn lórí ilẹ̀ ayé kan tí a fọ̀ mọ́.—1 Timoteu 1:11; 2 Peteru 3:13.
Míṣọ́nnárì tí o jẹ́ Kristian náà Paulu gbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọrun ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ kọ̀wé pé: “Paulu, ìránṣẹ́ Ọlọrun, àti Aposteli Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọrun, àti ìmọ̀ òtítọ́ tí ń bẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà-bí-Ọlọ́run, ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, tí Ọlọrun, Ẹni tí kò lè ṣèké, ti ṣe ìlérí ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.” Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọrun, “tí kò lè ṣèké,” “ti ṣe ìlérí” ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn wọnnì tí wọ́n fi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn wá láti mọ̀ ọ́n àti láti ṣiṣẹ́sìn ín.—Titu 1:1, 2; Sefaniah 2:3.
A Ha Ń Sanwó fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Bí?
Àwọn kan ti polongo láti ìgbà dé ìgbà pé a ń sanwó fún àwọn Ẹlẹ́rìí fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn. Èrò òdì gbáà ni èyí jẹ́! Wọ́n mú ọ̀rọ̀ Paulu sí ìjọ tí ó wà ní Korinti ní ọ̀kúnkúndùn pé: “Awa kì í ṣe akiri ta ọ̀rọ̀ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti jẹ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí pẹlu òtítọ́-inú, bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí a ti rán wa lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, ní iwájú Ọlọrun, ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu Kristi, ni awa ń sọ̀rọ̀.”—2 Korinti 2:17, NW.
Àwọn aṣáájú ìsìn kan ń wàásù nítorí owó, yálà kí ó jẹ́ owó sísan fún ààtò ìsìn tàbí gbígbé iṣẹ́ ìṣòwò lárugẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lórí tẹlifíṣọ̀n. Ọ̀pọ̀ jùlọ ìsìn ní àwọn àlùfáà tí wọ́n ń sanwó fún.
Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àwọn Ẹlẹ́rìí kò ní àwọn àlùfáà tí wọ́n ń sanwó fún, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì ń fi ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn lọ àwọn olùwá òtítọ́ kiri tinútinú láìdíyelé e, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ni a ń sún láti ṣe ìtọrẹ àtinúwá. Ìwọ̀nyí ni a ń lò láti gbọ́ bùkátà ìnáwó iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé yìí. Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Jesu pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fúnni,” àwọn Ẹlẹ́rìí ń fínnú fíndọ̀ yọ̀ọ̀da ohun-ìní, títíkan àkókò àti okun wọn, ní lílo àràádọ́ta wákàtí lọ́dọọdún fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọrun. Nípa báyìí, wọ́n ń kọ́ àwọn olùfìfẹ́hàn láti ilé dé ilé àti nípasẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé.—Matteu 10:8; 28:19, 20; Iṣe 20:19, 20.
Àwọn ẹ̀rí fihàn pé kìí ṣe jíjèrè owó ni ó ń sún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, àwọn ìjọ àdúgbò wọn, tàbí Watch Tower Society ṣiṣẹ́. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ń gba owó èyíkéyìí fún lílọ láti ilé dé ilé. Báwo ni a ṣe wá ń gbọ́ bùkátà iṣẹ́ náà? Nípa ọrẹ àtinúwá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn onímọrírì káàkiri ayé. A kìí gba ìdáwó.
Ipa tí Ìjẹ́rìí Wọn Ń Ní
Gbogbo ènìyàn ha ti mọ̀ nípa iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé àti ìwàásù aláìjẹ́-bí-àṣà tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe bí? Ẹ̀rí láti ọ̀dọ̀ àwọn ilé-isẹ́ agbéròyìnjáde dáhùn bẹ́ẹ̀ni dídún gbọnmọgbọnmọ sí ìbéèrè yẹn. A tí mẹ́nukan àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lórí àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá nígbà tí a bá fi ẹnìkan tí ń kan ilẹ̀kùn hàn. Àwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí. Ìgbòkègbodò onítara wọn ti di èyí tí a mọ̀ bí ẹní mowó tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwọn ayàwòrán ẹ̀fẹ̀ káàkiri ayé fi ń kọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Èyí lè dàbí ìfọgbọ́n fini ṣẹ̀fẹ̀, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni a máa ń gbé wọn ka orí àwọn ìlànà òtítọ́ tí ó ṣe tààrà—pé a mọ àwọn Ẹlẹ́rìí fún ìwàásù ilé-dé-ilé aláìdẹ́kun wọn.—Iṣe 20:20.
Àwòrán ẹ̀fẹ̀ kan láìpẹ́ yìí fi ọkùnrin kan hàn tí ń gòkè lọ láti wádìí ọ̀rọ̀ wò lọ́dọ̀ “guru” kan. Ó sọ pé: “Sọ àwọn ohun àgbàyanu tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún mi!” Báwo ni “guru” náà ṣe dáhùn? “Jẹ́ kí a wò ó ná . . . Ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò wà. Òòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá yóò sì di ẹ̀jẹ̀.” Olùṣèwádìí náà béèrè pé: “Ìhìnrere wo ni ó wà níbẹ̀?” Èsì “guru” náà ni pé: “Ọlọrun yóò nu omijé gbogbo nù kúrò . . . kì yóò sì sí ikú tàbí ọ̀fọ̀ tàbí ìrora mọ́!” Olùṣèbẹ̀wò náà béèrè pé: “Báwo ni o ṣe mọ̀ nípa irú àwọn nǹkan wọ̀nyí?” Kí ni ìdáhùn rẹ̀? “Kò sí ẹni tí ó bọ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa!” Ìyẹn sì ti níláti jẹ́ òtítọ́ nípa ayàwòrán ẹ̀fẹ̀ náà fúnraarẹ̀!
Kókó ṣíṣe pàtàkì nínú àwòrán yìí àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ ni pé kìí ṣe ìṣelemọ́lemọ́ ìbẹ̀wò àwọn Ẹlẹ́rìí nìkan ni ó ṣípayá bíkòṣe ìṣedéédéé ìhìn-iṣẹ́ wọn. Ní ìwọ̀nba ṣókí, ayàwòrán náà fi apá ṣíṣe kókó nínú ìjẹ́rìí ilé-dé-ilé wọn àti ẹsẹ ìwé mímọ́ tí wọ́n yàn hàn.—Fiwé Matteu 24:7, 29; Ìfihàn 21:3, 4.
Òtítọ́ náà pé ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn ń kọ ìhìn-iṣẹ́ wọn kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn Ẹlẹ́rìí náà tàbí kí ó dín ìtara wọn kù. Aposteli Peteru kìlọ̀ pé: “Nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn, wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn, wọn ó sì máa wí pé, Níbo ni ìlérí wíwá rẹ̀ gbé wà? láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ ìwà.” Láìka èyí sí, bí ìfẹ́ ti ń sún wọn ṣiṣẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí sì ń báa nìṣó láti máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn, wọn yóò sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí di ìgbà tí Ọlọrun yóò fi mú òpin débá ètò-ìgbékalẹ̀ dídíbàjẹ́ ti ìsinsìnyí.—2 Peteru 3:3, 4.
Jesu sọ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, a níláti kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà. Fún àyẹ̀wò síwájú síi nípa ìdí ati báwo ni a ṣe ń wàásù ìhìnrere náà, wo àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ méjì tí ó tẹ̀lé e.—Marku 13:10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò ní àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà tí ń gbowó oṣù—gbogbo wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni