Ọ̀nà Ìgbésí-Ayé kan Tí Ó Ní Ète Nínú
GẸ́GẸ́ BÍ MELVA A. WIELAND ṢE SỌ Ọ́
Ní March 1940, oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, Phyllis àbúrò mi obìnrin wá sọ́dọ̀ mi ó sì béèrè pé: “Èéṣe tí ẹ kò fi máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà?” “Ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà kẹ̀?” ni mo béèrè. “Ṣe wíwàásù fún àkókò kíkún, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lójoojúmọ́ ni o ní lọ́kàn?”
MO RONÚ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pẹ̀lú ìmọ̀ ráńpẹ́ tí mo ní nínú Bibeli àti owó àfipamọ́ tí kò tilẹ̀ tó nǹkan kan rárá ti mo ní sí báńkì?’ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìbéèrè Phyllis mú kí n tún bẹ̀rẹ̀ síí ronú. Mo sì gbàdúrà púpọ̀ nípa rẹ̀.
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ mo ronú pé, ‘Èéṣe tí n kò fi lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun níwọ̀n ìgbà tí ó ti ṣèlérí láti bójútó wa bí a bá kọ́kọ́ wá Ìjọba rẹ̀?’ (Matteu 6:33) Nítorí náà ní June 1940, mo kọ̀wé láti fí iṣẹ́ aṣọ rírán tí mo ń ṣe sílẹ̀. Lẹ́yìn náà ni mo kọ̀wé sí ọ́fíìsì ẹ̀ka ti Watch Tower Society ní Australia, ní bíbèèrè fún iṣẹ́ àyànfúnni aṣáájú-ọ̀nà.
Iṣẹ́ Àyànfúnni Ìgbésí-Ayé Mi
Ní ìwọ̀n ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo gba èsì, tí ó fi tó mi létí pé a óò fún mi ní iṣẹ́-àyànfúnni kan lẹ́yìn lílọ sí àpéjọpọ̀ tí yóò wáyé ní ilẹ̀ ibi tí a óò kọ́ orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí ní Strathfield, agbègbè kan lẹ́yìn òde ìlú-ńlá tí ó tóbi jùlọ ní Australia, Sydney. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ó tẹ̀lé àpéjọpọ̀ náà, mo lọ sí ọ́fíìsì láti lọ gba iṣẹ́ àyànfúnni mi.
Ẹni tí ó wà ní ọ́fíìsì ṣàlàyé pé: “Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ọwọ́ wa dí púpọ̀ ní ilé-ìfọṣọ. Ìwọ yóò ha lè dúró kí o sì ràn wá lọ́wọ́ fún ìwọ̀nba ọ̀sẹ̀ díẹ̀ bí?” Ìyẹn jẹ́ ní August 1940—mo ṣì ń ṣiṣẹ́ ní ilé-ìfọṣọ náà! Nígbà yẹn lọ́hùn-ún àwọn 35 péré ni wọ́n wà nínú ìdílé orílé-iṣẹ́ náà; nísinsìnyí 276 ni wọ́n.
Ṣùgbọ́n o lè ṣe kàyéfì nípa ìdí rẹ̀ tí mo fi ka ṣíṣiṣẹ́ ní ilé-ìfọṣọ sí “ọ̀nà ìgbésí-ayé kan tí ó ní ète nínú,” ní pàtàkì níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ isẹ́ mi fún ohun tí ó ju 50 ọdún lọ báyìí. Ṣáájú kí n tó ṣàlàyé, jẹ́ kí n sọ fún ọ nípa àwọn ìlépa mi ní ìbẹ̀rẹ̀.
Eré-Ìdárayá Di Ọ̀nà Ìgbésí-Ayé Kan
A bí mi ní Melbourne ní January 1, 1914, àkọ́bí nínú àwọn ọmọ márùn-ún. A ní àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà gíga tí wọ́n sì ń lo ìbáwí nígbà tí a bá nílò rẹ̀. A tún ní ohun tí a lè pè ní ìtọ́dàgbà ṣákálá lọ́nà ti ìsìn, nítorí pé àwọn òbí wa kìí ṣe olùreṣọ́ọ̀ṣì. Ṣùgbọ́n, wọ́n fi dandan lé e pé kí àwa ọmọ wọn máa lọ sí kíláàsì ilé-ẹ̀kọ́ ọjọ́ Sunday ti Ṣọ́ọ̀ṣì England.
Nígbà tí mo jáde ilé-ẹ̀kọ́ ní 1928 tí mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aránṣọ, mo pinnu láti lo èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àkókò tí ọwọ́ mi bá dilẹ̀ fún ṣíṣe eré-ìdárayá, ní gbígbàgbọ́ pé èyí lè ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìtìjú mi. Mo darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agbátẹníìsì kan mo sì ń gbá a yípo ọdún. Lákòókò ọ̀gìnnìtìn mo gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ àti bọ́ọ̀lù àfigigbá ẹlẹ́ni mẹ́sàn-án, àti lákòókò ẹ̀rùn mo ń bá ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfigigbá ẹlẹ́ni mọ́kànlá ti àwọn obìnrin gbá bọ́ọ̀lù. Bọ́ọ̀lù àfigigbá ẹlẹ́ni mọ́kànlá wá di ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí níti gidi, mo sì sakun gidigidi láti mú kí òye mi jáfáfá síi gẹ́gẹ́ bí ayáwọ́ju-bọ́ọ̀lù láti lè tóótun fún ìdíje láàárín ìpínlẹ̀ kan sí òmíràn.
Ète Kan tí Ó Yàtọ̀ Sí ti Eré-Ìdárayá
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé mo ní ìdààmú nípa ẹ̀kọ́ náà pé Ọlọrun ìfẹ́ kan ní ibì kan tí a ń pè ní hẹ́ẹ̀lì níbi tí a óò ti da àwọn wọnnì tí wọ́n hùwà búburú lóró láìlópin. Èyí kò mọ́gbọ́n dání lójú tèmi. Nítorí náà ronú bí inú mi ti dùn tó nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ohun tí “hẹ́ẹ̀lì” túmọ̀sí láti inú Bibeli láìròtẹ́lẹ̀. Ọ̀nà tí ó gbà ṣẹlẹ̀ nìyí:
Phyllis àbúrò mi obìnrin, ẹni tí mo gba ọdún márùn-ún lọ́wọ́ rẹ̀, gbádùn ṣíṣe eré-ìdárayá pẹ̀lú, a sì jọ wà nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àfigigbá ẹlẹ́ni mọ́kànlá ti àwọn obìnrin. Ní 1936 agbábọ́ọ̀lù ẹlẹgbẹ́ mi kan fi Phyllis han ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jim ẹni tí a mọ̀ pé ó jẹ́ ẹlẹ́mìí ìsìn gidigidi. Kò pẹ́ kò jìnnà Jim bẹ̀rẹ̀ sí bá Phyllis sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli. A ru ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ sókè. Ó máa ń sọ fún mi pé: “Ó bá ọgbọ́n ìrònú mu ó sì lọ́gbọ́n nínú.”
Nígbà yẹn èmi àti Phyllis ń gbé inú iyàrá kan náà ní ilé, ó sì gbìyànjú láti mú kí ń lọ́kàn-ìfẹ́ nínú ohun tí Jim ń sọ fún un nípa Ìjọba Ọlọrun. Pẹ̀lú ayọ̀-ṣìnkìn ni ó fi sọ fún mi pé, “Yóò ṣe ohun tí àkóso ènìyàn ti kùnà láti ṣe.” Bí ó ti wù kí ó rí, mo bá a jiyàn, ní sísọ pé èyí wulẹ̀ jẹ́ ìsìn mìíràn láti dà wá lọ́kàn rú àti pé kò sí ẹnì kan tí ó mọ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la níti gidi. Ṣùgbọ́n Phyllis kò dẹ́kun títẹnumọ́ ọn ó sì ń fi ìwé sílẹ̀ káàkiri inú iyàrá, ní ìrètí pé bóyá mo lè kà á.
Ìdí tí Phyllis fi ní ìtara-ọkàn tóbẹ́ẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ titun yìí mú kí n ní ìfẹ́ ìtọpinpin, nítorí náà ní ọjọ́ kan mo mú ìwé-pẹlẹbẹ kan. Ó ní àkọlé fífanimọ́ra náà Hereafter. Ó ‘ru àfiyèsí mi sókè’ bí mo ṣe ń ṣí àwọn ojú-ìwé rẹ̀ tí mo sì rí ọ̀rọ̀ náà “hẹ́ẹ̀lì.” Sí ìyàlẹ́nu mi, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ọ̀rọ̀ Bibeli náà “hẹ́ẹ̀lì” túmọ̀ níti gidi sí isà-òkú gbogbo aráyé àti pé gbogbo ènìyàn rere àti búburú ní ń lọ síbẹ̀. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé hẹ́ẹ̀lì kì í ṣe ibi ìdálóró ayérayé; àwọn òkú kò mọ ohunkóhun wọ́n kó sì lè nímọ̀lára kankan.—Oniwasu 9:5, 10; Orin Dafidi 146:3, 4.
Èyí bọ́gbọ́nmu lójú tèmi, ní pàtàkì nígbà tí ìwé-pẹlẹbẹ náà ṣàlàyé pé Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ àti alágbára ti ṣèlérí láti mú àwọn òkú padà wá nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kan tí a ń pè ní àjíǹde. (Johannu 5:28, 29) Nísinsìnyí èmi náà ń fẹ́ láti wádìí nípa ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tí Jim ti ń sọ fún Phyllis. Mo rí Bibeli King James Version kékeré tí bàbá mi ti fún mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé mo sì yẹ àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé-pẹlẹbẹ náà wò. Èyí jẹ́rìí sí ohun tí a ti sọ nípa hẹ́ẹ̀lì àti ipò tí àwọn òkú wà.
Ìyàlẹ́nu fífanimọ́ra mìíràn fún mi ni láti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọrun ní orúkọ ara-ẹni kan, Jehofa. (Orin Dafidi 83:18) Mo tún lè rí i pé Ọlọrun ní ète, tàbí ìdí kan, fún gbogbo ohun tí ó ti ṣe tàbí tí ó ti fàyègbà pé kí ó ṣẹlẹ̀. Èyí mú kí n bi araàmi pé, ‘Kí ni ète mi níti gidi nínú ìgbésí-ayé?’ Láti ìgbà náà lọ mo bẹ̀rẹ̀ síí ṣe kàyéfì bóyá yóò ṣàǹfààní fún mi jùlọ láti ka eré-ìdárayá sí ohun tí ó ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀—débi tí èmi yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ fi pa àwọn nǹkan mìíràn gbogbo tì.
Gbígbé Ìgbésẹ̀ Tẹ̀lé Ìpinnu
Jim àti Phyllis kò mọ̀ rárá pé ojú-ìwòye mi nípa ìgbésí-ayé ti yípadà, ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ nígbà tí a késí ìdílé wa síbi àpèjẹ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ kan. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lákòókò irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n bá pésẹ̀ yóò dìde dúró, wọn yóò sì fi ife gbá ife ní àyẹ́sí Ọba England, gbogbo wọn yóò sì na ife wọn síwájú láti mu ọtí ní ṣíṣàyẹ́sí ọba náà. Bí ó ti wù kí ó rí, mo pinnu láti wà lórí ìjókòó pẹ̀lú Jim àti Phyllis. Wọn kò lè gba ohun tí wọ́n rí gbọ́ nígbà tí wọ́n rí i pé mo ṣì wá lórí ìjókòó! Àmọ́ ṣáá o, àwa kò ní in lọ́kàn láti hùwà àfojúdi èyíkéyìí, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Kristian a nímọ̀lára pé a níláti wà láìdásí tọ̀tún-tòsì kí a má sì lọ́wọ́ nínú irú àwọn ayẹyẹ onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni bẹ́ẹ̀.—Johannu 17:16.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn òbí mi àti ìyókù lára àwọn ìdílé mi ń bẹ̀rù. Wọ́n sọ pé a jẹ́ aláìdúróṣinṣin, tàbí pé a ń ṣiwèrè—tàbí kí ó jẹ́ méjèèjì! Lẹ́yìn náà, nígbà tí èmi àti Phyllis pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ìfúnnilẹ́bùn ti ọdọọdún fún ẹgbẹ́ afigigbábọ́ọ̀lù ẹlẹ́ni mọ́kànlá ti àwọn obìnrin, ohun kan náà wáyé lákòókò ayẹyẹ onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni kan. Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé àwa méjèèjì kọ̀wé fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀. Èyí kò nira tó bí mo ṣe rò pé yóò rí, nítorí mo ti wá mọ̀ pé ìtúúbá àti ìdúróṣinṣin mi wà fún Kristi Jesu, Ọba Ìjọba ọ̀run ti Ọlọrun.
Phyllis wá ṣàlàyé pé mo níláti máa lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa déédéé láti lè fi ìmọ̀ Bibeli púpọ̀ síi gbé ìgbàgbọ́ mi ró. Nígbà yẹn ìjọ kanṣoṣo ni ó wà ní Melbourne, nítorí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé níbẹ̀ ní ọ̀sọ̀ọ̀sán ọjọ́ Sunday. Láìpẹ́ a mú un dá mi lójú pé èyí ni ètò-àjọ tòótọ́ ti Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé.
Kò pẹ́ púpọ̀ a késí mi láti nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò ìwàásù láti ilé-dé-ilé. Lákọ̀ọ́kọ́ ná mo lọ́tìkọ̀, ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ Sunday kan mo pinnu láti bá wọn lọ kí n wulẹ̀ rí bí wọ́n ti ń ṣe é. Inú mi dùn nígbà tí a yàn mí láti bá Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ onírìírí ṣiṣẹ́ ẹni tí ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìfọkànbalẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́ tí onílé náà sì gbà á tọwọ́tẹsẹ̀. Mo rò ó nínú araàmi pé, ‘Ó dára, ìyẹn kò nira jù, ṣùgbọ́n èmi yóò nílò ìfidánrawò púpọ̀ kí n tó lè ṣe dáradára bí ìyẹn.’ Nítorí náà wo bí ẹnu ṣe yà mí tó nígbà tí, lẹ́yìn kíkúrò ní ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́ yẹn, Ẹlẹ́rìí náà sọ fún mi pé, “Ìwọ lè máa dá wàásù nísinsìnyí.”
“Dá wàásù kẹ̀?” ni mo fi ìyàlẹ́nu béèrè! “Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí ni n óò sọ bí ẹnì kan bá béèrè ìbéèrè kan tí n kò sì mọ ìdáhùn rẹ̀?” Ṣùgbọ́n alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi fi dandan lé e. Nítorí náà, pẹ̀lú ìbẹ̀rù níti gidi, mo dá lọ nígbà tí òun ṣì ń jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀gbẹ́ kejì òpópónà. Lọ́nà kan ṣáá mo la òwúrọ̀ àkọ́kọ́ yẹn já.
Láti ìgbà yẹn lọ mo bẹ̀rẹ̀ sí nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù ní òròòwúrọ̀ Sunday. Nígbà tí ẹnì kan ní ẹnu ọ̀nà bá bi mí ní ìbéèrè tí n kò lè dáhùn, èmi yóò sọ pé, “N óò lọ ṣèwádìí nípa rẹ̀ n óò sì padà wá rí ọ.” Ó dùn mọ́ mi pé, Jehofa ń bá a nìṣó ní fífún mi ní okun àti ìgboyà láti máa bá ọ̀nà ìgbésí-ayé mi tí ó ní ète nínú nìṣó. Mo ya ìgbésí-ayé mi sí mímọ́ fún un, nígbà tí ó sì di October 1939, mo ṣèrìbọmi níbi ìkùdu ìlú-ńlá Melbourne. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà Phyllis, ẹni tí ó ti fẹ́ Jim nígbà náà, béèrè ìdí tí n kò fi lè bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà.
Iṣẹ́-Ìsìn ní Ẹ̀ka
Ní January 1941, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní Beteli, bí a ti máa ń pe ọ́fíìsì ẹ̀ka, a fòfinde iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Australia. Lẹ́yìn náà àwọn ológun gba Ilé Beteli wa ní Strathfield, a sì rán mi lọ sí oko Society ni Ingleburn, nǹkan bíi kìlómítà 48 lẹ́yìn òde ìlú-ńlá náà. Ní June 1943 kóòtù dá Watch Tower Society láre wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí ìfòfindè náà. Nígbà tí yóò fi di òpin ọdún yẹn, a pe 25 lára wa padà sí Beteli ti Strathfield. Mo ṣì ń ba ṣíṣiṣẹ́ ní ilé-ìfọṣọ nìṣó níbẹ̀, àti nínípìn-ín nínú àwọn iṣẹ́-òpò mìíràn láyìíká ilé náà.
Ó dàbí ẹni pé ẹ̀wádún tí ó tẹ̀lé e yára kọjá lọ. Lẹ́yìn náà ní 1956, mo fẹ́ òṣìṣẹ́ Beteli ẹlẹgbẹ́ mi kan, Ted Wieland. Ted jẹ́ ọkùnrin oníwàtútù, onísùúrù, inú wa sì dùn nígbà tí wọ́n fọwọ́sí pé kí a máa gbé nìṣó ní Beteli gẹ́gẹ́ bí tọkọ-taya. Àwa méjèèjì ṣìkẹ́ ọ̀nà ìgbésí-ayé wa tí ó ní ète nínú, a láyọ̀ fún àǹfààní náà láti ṣiṣẹ́sìn ní ẹ̀ka ti Australia. Àmọ́ ṣáá o, ní àfikún sí iṣẹ́ Beteli wa, a ní ìdùnnú ti ṣíṣiṣẹ́ papọ̀ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti di ọmọ-ẹ̀yìn Kristi. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan, ìwọ lè kà nípa ìdílé Weekes nínú ìtẹ̀jáde Ji! ti October 22, 1993.
Ìbísí tí ń báa nìṣó nínú ìwàásù Ìjọba náà béèrè fún fífi kìkì ẹni 10 tàbí 12 kún àwùjọ àwọn òṣìṣẹ́ wa láàárín 30 ọdún àkọ́kọ́ mi ní Beteli. Ṣùgbọ́n ipò nǹkan yí padà lọ́nà bíbùáyà ní àwọn ọdún 1970 nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí tẹ Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! jáde níhìn-ín. Iṣẹ́ kíkọ́ ilé ìtẹ̀wé titun kan bẹ̀rẹ̀ ní January 1972. Láìpẹ́ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé oní-40 tọ́ọ̀nù dé láti Japan, nígbà tí yóò sì fi di 1973 a ti ń tẹ 700,000 ìwé ìròyìn ní oṣù kan. Ìdílé Beteli wa wá bẹ̀rẹ̀ sí tóbi síi níti gidi.
Àwọn ọdún 1970 tún mú ìbànújẹ́ ara-ẹni wá fún mi. Lákọ̀ọ́kọ́, ọkọ mi olùfẹ́, Ted, kú ní 1975 ni ẹni 80 ọdún. Lẹ́yìn náà, kò tó ọdún kan sí i, bàbá mi tí ó ti darúgbó tún sùn nínú oorun ikú. Mo rí ọ̀pọ̀ ìtùnú gbà láti ọ̀dọ̀ Jehofa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi nípa tẹ̀mí. Ó tún ràn mí lọ́wọ́ gidigidi láti mú kí ọwọ́ mi dí fún ìgbòkègbodò mi tí ó ní ète nínú ní Beteli láàárín àkókò oníbànújẹ́ yìí nínú ìgbésí-ayé mi.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìgbésí-ayé ń báa nìṣó, lẹ́ẹ̀kan síi pẹ̀lú mo bẹ̀rẹ̀ sí nírìírí ìtẹ́lọ́rùn àti ìbùkún, gẹ́gẹ́ bí opó kan nísinsìnyí. Ní 1978, mo lọ sí àpéjọpọ̀ ti London, England, àti lẹ́yìn náà mo ṣèbẹ̀wò sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti Watch Tower Society ní Brooklyn, New York. Rírí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi tí ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣiṣẹ́ ní Beteli ti Brooklyn ti jẹ́ ìṣírí fún mi títí di òní olónìí.
Bí àwọn ọdún 1970 ṣe ń parí lọ, a gbọ́ pé a ń wéwèé ìmúgbòòrò síwájú síi fún àpapọ̀ ilé Beteli ti Australia. Bí ó ti wù kí ó rí, ìmúgbòòrò náà kò ní wáyé ní Strathfield, níbi tí àyè ti ń tán lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpapọ̀ ilé titun, tí ó túbọ̀ tóbi ju ti ìṣáájú ni a óò kọ́ sórí dúkíà wa ní Ingleburn, níbi tí mo ti ṣiṣẹ́ nígbà ìfòfindè ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940.
Ọ̀nà Ìgbésí-Ayé tí Ó Ní Ète Nínú Tí Ń Bá a Nìṣó
Ẹ wo bí ayọ̀-ṣìnkìn náà ti pọ̀ tó ní January 1982 nígbà tí a ṣí lọ sí ilé wa titun! Lóòótọ́, lákọ̀ọ́kọ́ ìbànújẹ́ ráńpẹ́ wà nípa fífi àyíká tí ó ti mọ́nilára sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò pẹ́ púpọ̀ tí ilé wa titun oníyàrá 73 rírẹwà fi fi ayọ̀ kún inú wa. Nísinsìnyí dípò yíyọjúwo àwọn ilé oníbíríkì àti àwọn àdúgbò lẹ́yìn òde ìlú-ńlá, a ń rí àwọn pápá àti igi tútù-yọ̀yọ̀, àwọn màlúù tí ń jẹko, àti yíyọ àti wíwọ̀ oòrùn fífanimọ́ra—ìran kan tí ó gbádùnmọ́ni jùlọ.
Ní March 19, 1983, a ṣe ìyàsímímọ́ gbígbádùnmọ́ni ti àpapọ̀ ilé titun náà lábẹ́ oòrùn ríràn-yẹ́ríyẹ́rí rírẹwà ti ìgbà ìwọ́wé. Lloyd Barry ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sọ ọ̀rọ̀-àwíyé kan tí ó tanijí. Èmi fúnraàmi mọrírì wíwà níbẹ̀ òun àti aya rẹ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ náà, níwọ̀n bí mo ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn ní Beteli ti Strathfield nígbà tí gbogbo wa ṣì kéré.
Ìbísí tí ń bá a nìṣó nínú ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba náà mú kí ó pọndandan síwájú síi láti ṣe ìmúgbòòrò àwọn ilé wa ní Ingleburn. Ní 1987 a mú ọ́fíìsì náà gbòòrò síi. Lẹ́yìn náà, ní November 25, 1989, ilé gbígbé titun alájà márùn-ún àti àfikún ilé ìtẹ̀wé alájà mẹ́ta titun ni a yàsímímọ́. Ẹ wo bí a ti ṣe bísíi—láti iye tí ó fi díẹ̀ dín sí 4,000 òjíṣẹ́ ní Australia nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ mi sí nǹkan bíi 59,000!
Láìpẹ́ yìí a ti sọ ẹ̀ka Australia di ọ̀kan lára àwọn ọ́fíìsì mẹ́ta ti Society fún Ìṣekòkáárí Ìmọ̀-Iṣẹ́-Ẹ̀rọ Ẹlẹ́kùn-Jẹkùn, pẹ̀lú ti Japan àti Germany. Èyí ti mú kí ìmúgbòòrò síwájú síi ti àpapọ̀ ilé Beteli pọndandan. Ilé ọ́fíìsì alájà mẹ́ta mìíràn ti parí báyìí, iṣẹ́ sì ń bá a lọ lórí ilé gbígbé alájà márùn-ún, èyí tí yóò ni 80 yàrá síi láti gba ìdílé wa tí ó túbọ̀ ń tóbi síi.
Ní ilé-ìfọṣọ, a ní àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ láti mójútó ẹrù iṣẹ́, ṣùgbọ́n mo sábà máa ń rántí ọjọ yẹn ní August 1940 nígbà tí a késí mi láti wá ṣèrànwọ́ ní ẹ̀ka-iṣẹ́ yìí fún ọ̀sẹ̀ méjì. Mo dúpẹ́ gidigidi pé àwọn ọ̀sẹ̀ méjì yẹn ti gùn ju ohun tí ó lè ní 50 ọdún àti pé Jehofa Ọlọrun ti darí ipasẹ̀ mi sí irú ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó ní ète nínú bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Nígbà tí mo jẹ ẹni ọdún 25
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọjọ́ ìgbéyàwó wa ní 1956
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ní 1938 èmi àti àbúrò mi fara jìn fún eré-ìdárayá lọ́pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n ìgbésí-ayé mi nísinsìnyí jẹ́ èyí tí ó túbọ̀ ń mésojáde