O Ha Níláti Gbàdúrà sí Jesu Bí?
ÀWỌN ènìyàn kan kà á sì ohun yíyẹ láti gbàdúrà sí Jesu. Ní Germany a ti kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbà ọmọdé láti káwọ́ mọ́ra kí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jesu Kristi ṣáájú kí wọ́n tó jẹun.
Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti wí, níti tòótọ́ ni Jesu gba ipò tí o ga púpọ̀ ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n, ìyẹn ha túmọ̀sí pé a níláti gbàdúrà sí i bí? Ìwọ lè wà lára àwọn wọnnì tí wọ́n ń darí àdúrà sí Jesu, nítorí ìfẹ́ wọn fún un, ṣùgbọ́n kí ni ohun tí Jesu fúnraarẹ̀ rò nípa irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kí ni ó tilẹ̀ gbé irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí dìde? Nítorí pé Bibeli sọ pé Jehofa Ọlọrun ni “Olùgbọ́ àdúrà.” Kò lè yanilẹ́nu, nígbà náà, pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní àkókò ìjímìjí, irú bí àwọn ọmọ Israeli, gbàdúrà sí Jehofa Ọlọrun, Olodumare nìkan ṣoṣo.—Orin Dafidi 5:1, 2; 65:2, NW.
Àwọn nǹkan ha yípadà nígbà tí Jesu, Ọmọkùnrin Ọlọrun, wá sórí ilẹ̀-ayé láti dá aráyé nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú bí? Rárá, a ṣì ń darí àdúrà sí Jehofa. Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé Jesu fúnraarẹ̀ gbàdúrà lemọ́lemọ́ sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, ó sì kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣáà ronú nípa àdúrà àwòkọ́ṣe náà, tí a sábà máa ń pè ní Àdúrà Oluwa tàbí Baba Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àdúrà tí ó gbajúmọ̀ jùlọ nínú ayé. Jesu kò kọ́ wa láti gbàdúrà sí òun; ó fún wa ní àwòkọ́ṣe yìí: “Baba wa ní awọn ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọdimímọ́.”—Matteu 6:6, 9; 26:39, 42 NW.
Wàyí o ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ wo kókó-ẹ̀kọ́ náà dáradára nípa yíyẹ ohun tí àdúrà jẹ́ níti gidi wò.
Kí Ni Àdúrà Jẹ́?
Gbogbo àdúrà jẹ́ ọ̀nà ìgbàjọ́sìn kan. Ìwé gbédègbéyọ̀ The World Book Encyclopedia jẹ́rìí sí èyí, ní sísọ pé: “Àdúrà jẹ́ ọ̀nà ìgbàjọ́sìn nínú èyí tí ẹnì kan ti lè fi ìfọkànsìn, ọpẹ́, ìjẹ́wọ́, tàbí ẹ̀bẹ̀ hàn sí Ọlọrun.”
Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan Jesu wí pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jehofa Ọlọrun rẹ ni iwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, oun nìkanṣoṣo sì ni iwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún.’” Jesu tòròpinpin mọ́ òtítọ́ ìpìlẹ̀ náà pé ìjọsìn—fún ìdí èyí àdúrà—ní a níláti darí rẹ̀ sí kìkì Bàbá òun, Jehofa Ọlọrun.—Luku 4:8; 6:12, NW.
Jíjẹ́wọ́ Jesu Nínú Àwọn Àdúrà Wa
Jesu kú gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà fún aráyé, a jí i dìde nípasẹ̀ Ọlọrun, a sì gbé e ga sí ipò gíga jùlọ. Bí ìwọ ṣe lè ronú, gbogbo èyí mú ìyàtọ̀ kan wá nípa àwọn àdúrà tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà. Ní ọ̀nà wo?
Aposteli Paulu ṣàpèjúwe agbára ìdarí tí ó lágbára tí ipò Jesu ń ní lórí àdúrà bí èyí: “Fún ìdí yii gan-an pẹlu ni Ọlọrun fi gbé e sí ipò gíga tí ó sì fi inúrere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó baà lè jẹ́ pé ní orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ba ti awọn wọnnì tí ń bẹ ní ọ̀run ati awọn wọnnì tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé ati awọn wọnnì tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ fihàn ní gbangba wálíà pé Jesu Kristi ni Oluwa fún ògo Ọlọrun Baba.”—Filippi 2:9-11, NW.
Àwọn ọ̀rọ̀ náà “ní orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ba” ha túmọ̀ sí pé a níláti gbàdúrà sí i bí? Rárá. Àpólà ọ̀rọ̀ Griki tí èyí wémọ́ túmọ̀ sí “orúkọ náà tí ó pa àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ̀ba lórí eékún wọn pọ̀, lórí èyí tí gbogbo wọn parapọ̀ (πᾶν γόνυ) ń jọ́sìn. Orúkọ náà tí Jesu ti gbà ń sún gbogbo wọn láti parapọ̀ bọlá fún un.” (A Grammar of the Idiom of the New Testament, láti ọwọ́ G. B. Winer) Níti tòótọ́, kí àdúrà kan tó lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà, a níláti gbà á “ní orúkọ Jesu,” ṣùgbọ́n, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a níláti darí rẹ̀ sí Jehofa Ọlọrun kí ó sì ṣiṣẹ́ fún ìyìnlógo rẹ̀. Nítorí ìdí èyí, Paulu sọ pé: “Ninu ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà ati ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ papọ̀ pẹlu ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ awọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọrun.”—Filippi 4:6, NW.
Gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà kan ṣe ń sinni lọ sí ibìkan, bẹ́ẹ̀ ni Jesu jẹ́ “ọ̀nà” tí ń sinni lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọrun Olodumare. Jesu kọ́ àwọn aposteli rẹ̀ pé: “Emi ni ọ̀nà ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni kan tí ó ń wá sọ́dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.” (Johannu 14:6, NW) Nípa bẹ́ẹ̀, a níláti gba àwọn àdúrà wa sí Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu kì í sìí ṣe sí Jesu fúnraarẹ̀.a
Àwọn kan lè béèrè pé, ‘Ṣùgbọ́n ṣebí Bibeli ròyìn pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjèèjì Stefanu àti aposteli Johannu bá Jesu sọ̀rọ̀ ní ọ̀run?’ Òtítọ́ ni ìyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí kò wémọ́ àdúrà, níwọ̀n bí Stefanu àti Johannu ti rí Jesu nínú ìran tí wọ́n sí bá a sọ̀rọ̀ ní tààràtà. (Iṣe 7:56, 59; Ìṣípayá 1:17-19; 22:20) Rántí pé wíwulẹ̀ bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ pàápàá kò túmọ̀sí àdúrà nínú araarẹ̀. Adamu àti Efa bá Ọlọrun sọ̀rọ̀, ní ṣíṣe àwáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wọn, nígbà tí Ó dá wọ́n lẹ́jọ́ lẹ́yìn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní Edeni. Bí wọn ṣe bá a sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà yẹn kì í ṣe àdúrà. (Genesisi 3:8-19) Fún ìdí èyí, yóò jẹ́ ohun tí kò tọ̀nà láti tọ́kasí ọ̀rọ̀ ti Stefanu tàbí Johannu bá Jesu sọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé a níláti gbàdúrà sí i níti gidi.
Báwo Ni A Ṣe ‘Ń Ké Pe’ Orúkọ Jesu?
Ìwọ ha ṣì ń bá a lọ láti máa ṣiyèméjì, tí o sì ń kà á sí oun tí ó tọ̀nà láti gbàdúrà sí Jesu bí? Obìnrin kan kọ lẹ́tà sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society kan pé: “Ó ṣeni láàánú pé, n kò tí ì gbà pé àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò gbàdúrà sí Jesu.” Àwọn ọ̀rọ̀ Paulu ní 1 Korinti 1:2 (NW), níbi tí ó ti mẹ́nukan “gbogbo awọn tí ń ké pe orúkọ Oluwa wa, Jesu Kristi níbi gbogbo,” ni ó ní lọ́kàn. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnì kan níláti kíyèsíi pé nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀, gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “láti ké pè” lè túmọ̀ sí ohun mìíràn tí ó yàtọ̀ sí àdúrà.
Báwo ni orúkọ Kristi ṣe di èyí tí a ‘ń ké pè’ níbi gbogbo? Ọ̀nà kan ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu ti Nasareti jẹ́wọ́ ní gbangba pé òun ni Messiah náà àti “Olùgbàlà ayé,” ní ṣíṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́-ìyanu ní orúkọ rẹ̀. (1 Johannu 4:14, NW; Iṣe 3:6; 19:5) Nítorí náà, The Interpreter’s Bible sọ pé àpólà ọ̀rọ̀ náà “láti ké pe orúkọ Oluwa wa . . . túmọ̀ sí láti jẹ́wọ́ ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Oluwa dípò gbígbàdúrà sí i.”
Gbígba Kristi àti lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a ta sílẹ̀, èyí tí ó mú kí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ṣeéṣe, tún parapọ̀ jẹ́ ‘kíképe orúkọ Oluwa wa, Jesu Kristi.’ (Fi Iṣe 10:43 wé 22:16.) A sì máa ń dárúkọ Jesu níti gidi nígbàkígbà tí a bá ń gbàdúrà sí Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí ó ń fihàn pé a lè ké pe orúkọ Jesu, Bibeli kò fihàn pé a níláti gbàdúrà sí i.—Efesu 5:20; Kolosse 3:17.
Ohun Tí Jesu Lè Ṣe Fún Wa
Jesu ṣèlérí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere pé: “Ohun yòówù kí ó jẹ́ tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, emi yoo ṣe èyí dájúdájú.” Èyí ha béèrè fún gbígbàdúrà sí i bí? Rárá. Ìbéèrè náà ni a darí rẹ̀ sí Jehofa Ọlọrun—ṣùgbọ́n ní orúkọ Jesu. (Johannu 14:13, 14; 15:16, NW) A ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun pé kí Ọmọkùnrin Rẹ̀, Jesu, lo agbára ńlá àti ọlá-àṣẹ rẹ̀ nítorí wa.
Báwo ni Jesu ṣe ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ sọ̀rọ̀ lónìí? Bí Paulu ṣe ṣàpèjúwe ìjọ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àkàwé kan. Ó fiwé ara kan ó sì fi Jesu Kristi wé orí. “Orí” náà ń fún gbogbo àwọn mẹ́ḿbà ara tẹ̀mí ní àwọn ohun tí wọ́n nílò nípasẹ̀ “awọn oríkèé ati awọn iṣan adeegunpọ̀,” tàbí àwọn ọ̀nà àti ìṣètò fún fífún ìjọ rẹ̀ ní oúnjẹ tẹ̀mí àti ìtọ́sọ́nà tí ń ṣaralóore. (Kolosse 2:19, NW) Ní ọ̀nà kan náà, lónìí Jesu ń lo “awọn ẹ̀bùn ninu ènìyàn,” tàbí àwọn ọkùnrin tí wọ́n tóótun, láti mú ipò iwájú nínú ìjọ, ní títọ́nisọ́nà pàápàá bí ó bá pọndandan. Kò sí àyè pé kí mẹ́ḿbà kan nínú ìjọ máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Jesu ní tààràtà tàbí láti gbàdúrà sí i, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ̀n níláti—bẹ́ẹ̀ni, wọ́n gbọ́dọ̀—gbàdúrà sí Bàbá Jesu, Jehofa Ọlọrun.—Efesu 4:8-12, NW.
Báwo Ni O Ṣe Ń Bọlá fún Jesu?
Ẹ wo irú ipa pàtàkì tí Jesu kó, nínú ọ̀ràn ìgbàlà ẹ̀dá ènìyàn! Aposteli Peteru sọ pẹ̀lú ìyàlẹ́nu pé: “Kò sí ìgbàlà kankan ninu ẹnikẹ́ni mìíràn, nitori kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín awọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a gbọ́dọ̀ fi gbà wá là.” (Iṣe 4:12, NW) Ìwọ ha mọ ìjẹ́pàtàkì orúkọ Jesu bí?
Nípa ṣíṣàì darí àwọn àdúrà sí Jesu ní tààràtà, a kò bu ipò rẹ̀ kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ń bọlá fún Jesu nígbà tí a bá gbàdúrà ní orúkọ rẹ̀. Àti gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ṣe ń bọlá fún àwọn òbí wọn nípa jíjẹ́ onígbọràn, a ń bọlá fún Jesu Kristi nípa ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀, ní pàtàkì àṣẹ titun náà láti nífẹ̀ẹ́ ẹnìkínní kejì.—Johannu 5:23; 13:34.
Àwọn Àdúrà Tí Ó Ṣètẹ́wọ́gbà
Ìwọ ha lọ́kàn-ìfẹ́ láti gba àwọn àdúrà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà bí? Nígbà náà darí wọn sí Jehofa Ọlọrun, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu. Wá láti mọ ìfẹ́-inú Ọlọrun, kí o sì jẹ́ kí àwọn àdúrà rẹ̀ fi òye yẹn hàn. (1 Johannu 3:21, 22; 5:14) Gba okun láti inú àwọn ọ̀rọ̀ inú Orin Dafidi 66:20 pé: “Olùbùkún ni Ọlọrun, tí kò yí àdúrà mi padà kúrò, tàbí àánú rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi.”
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, àwọn àdúrà jẹ́ ọ̀nà ìjọsìn tí a yàsọ́tọ̀ gedegbe kan tí ó wà fún Ọlọrun Olodumare. Nípa dídarí gbogbo àwọn àdúrà wa sí Jehofa Ọlọrun, a ń fihàn pé a ti gba ìtọ́sọ́nà Jesu sí inú ọkàn-àyà wa láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa ní awọn ọ̀run.”—Matteu 6:9, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn kan lè gbàdúrà sí Jesu nítorí pé wọ́n gbàgbọ́ pé òun ni Ọlọrun. Ṣùgbọ́n Ọmọkùnrin Ọlọrun ní Jesu jẹ́, òun fúnraarẹ̀ sì jọ́sìn Jehofa, Bàbá rẹ̀. (Johannu 20:17) Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé síi lórí kókó-ẹ̀kọ́ yìí, wo Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.