Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
A Ó Sì Wàásù Ìhìnrere Ìjọba Yìí
FÚN ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún olórí ọ̀tá Ọlọrun, Satani Èṣù, ti fi ọgbọ́n àrékérekè lo àwọn ìjọba òṣèlú àti ìsìn èké nínú ìsapá rẹ̀ láti ṣèdíwọ́ fún ìtànkálẹ̀ ìsìn Kristian tòótọ́. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n yìí yóò kùnà. Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé “a óò sì wàásù [kì í ṣe, “ni ó ṣeé ṣe kí a wàásù” tàbí, “ni a lè wàásù”] ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.”—Matteu 24:14, NW.
A ti rí ẹ̀rí ṣíṣe kedere nípa ìkùnà Satani ní Greece. Ní ilẹ̀ yẹn Ṣọ́ọ̀ṣì Greek Orthodox ti gbìdánwò láti ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ́wọ́ kò láti máṣe wàásù ìhìnrere Ìjọba náà. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí ti tẹnumọ́ ọn, ní àkókò tí ó tọ́ òtítọ́ Bibeli dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ọkàn-àyà títọ́ láìka inúnibíni sí.
Ní nǹkan bí 30 ọdún sẹ́yìn, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Greek Orthodox kan tẹ́wọ́gba ìhìnrere ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìbátan rẹ̀ ṣàtakò lílekoko sí ìgbésẹ̀ yìí wọ́n sì dojú ìkìmọ́lẹ̀ kọ ọ́ kí ó baà lè dẹ́kun ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Kí ó baà lè tẹ́ ìdílé rẹ̀ lọ́rùn, ó ń báa lọ láti máa lépa iṣẹ́ ìgbésí-ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà; síbẹ̀, nígbà gbogbo ni ó máa ń gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ran òun lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti pé òun ti fi í ṣe pàṣípààrọ̀ fún ipò-ọlá nínú ìsìn èké.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó máa ń sọ̀rọ̀ gbe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà mìíràn, tí àǹfààní bá jẹyọ. Ó tilẹ̀ gba àwọn ènìyàn níyànjú lọ́pọ̀ ìgbà pé bí wọ́n bá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bibeli, wọ́n níláti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá àwọn kan ti tẹ̀lé ìdámọ̀ràn rẹ̀ níti gidi.
Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí àlùfáà náà ṣàìsàn gidigidi ó sì mọ̀ pé òun lè kú láìpẹ́. Nígbà tí ó wà ní ilé-ìwòsàn, ó pe àwọn ọmọ rẹ̀ jọpọ̀, gbogbo wọn sì kórajọ sí ẹ̀gbẹ́ ibùsùn rẹ̀.a Nígbà náà ni ó ṣàlàyé fún wọn pé bí òun bá kú, wọ́n tún lè rí òun lẹ́ẹ̀kan síi. Ó sọ fún wọn nípa ẹ̀kọ́ tí Bibeli fi kọ́ni pé Jehofa lè jí ẹ̀dá ènìyàn dìde láti gbé nínú paradise lórí ilẹ̀-ayé, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá fẹ́ láti rí i kí èyí ṣẹlẹ̀ nítòótọ́, wọ́n níláti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti inú Bibeli kí wọ́n sì dẹ́kun àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìsìn èké. Ó pàrọwà fún wọn láti darapọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe lè di ojúlówó Kristian lọ́dọ̀ wọn.
Ní kété lẹ́yìn náà ni àlùfáà náà kú. Bí ó ti wú kí ó rí, ìmọ̀ràn ìdágbére tí ó fifún àwọn ọmọ rẹ̀ mú àbájáde rere wá. Gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn ìbátan rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ ti ṣàtakò gidigidi sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti iṣẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n kò lè kọ ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá bàbá rẹ̀ tí ń kú lọ, nítorí náà ó tọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ kíákíá ó sì bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Láìpẹ́ yìí, òun fúnra rẹ̀ di Ẹlẹ́rìí, ó ya ìgbésí-ayé ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa Ọlọrun ó sì fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi.
Ní Greece, àti ní àwọn ilẹ̀ mìíràn tí ó ju 230 lọ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbáralé agbára ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun. Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn kíkún láti ọwọ́ ẹ̀mí mímọ́ ni wọ́n fi ń nípìn-ín nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jesu pé: “Ẹ̀yin yoo gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá dé sórí yín, ẹ óò sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalemu ati ní gbogbo Judea ati Samaria ati títí dé apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.”—Iṣe 1:8, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ṣọ́ọ̀ṣì Greek Orthodox yọ̀ọ̀da fún àwọn àlùfáà rẹ̀ láti gbéyàwó.