ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 3/1 ojú ìwé 20-23
  • Maimonides Ọkùnrin Náà Tí Ó Mú Ìsìn Júù ṣe Kedere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Maimonides Ọkùnrin Náà Tí Ó Mú Ìsìn Júù ṣe Kedere
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ni Maimonides?
  • Kí Ni Ó Kọ?
  • Kí Ni Ó Fi Kọ́ni?
  • Báwo Ni Ó Ṣe Nípa Lórí Ìsìn Júù àti Àwọn Èrò-Ìgbàgbọ́ Mìíràn?
  • Ta ni Ó Tọ́ Kí A Pè ní Rábì?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Naḥmanides—Ó Ha Fi Hàn Pé Èké Ni Ẹ̀sìn Kristẹni Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ayé Ń Lọ À Ń Tọ̀ Ọ́ Lọ̀rọ̀ Àwọn Dókítà
    Jí!—2005
  • Kí Ló Ń Jẹ́ Tórà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 3/1 ojú ìwé 20-23

Maimonides Ọkùnrin Náà Tí Ó Mú Ìsìn Júù ṣe Kedere

“LÁTI ìgbà ayé Mose títí di ìgbà ayé Mose, kò sí ẹnìkan tí ó dàbí Mose.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù yóò mọ ọ̀rọ̀ àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkansáárá sí ọlọgbọ́n-èrò-orí, aṣòfin, ati sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Júù lórí Talmud àti Ìwé Mímọ́ ní ọ̀rúndún kejìlá, Moses Ben Maimon—ẹni tí a tún mọ̀ sí Maimonides tí a sì mọ̀ sí Rambam.a Lónìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò mọ Maimonides, síbẹ̀ àwọn ìwé tí ó kọ ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìrònú àwọn Júù, Musulumi, àti ṣọ́ọ̀ṣì ní ìgbà ayé rẹ̀. Lọ́nà tí ó bá ìlànà ìpìlẹ̀ mu, ó mú ìsìn Júù ṣe kedere. Ta ni Maimonides, èésìtiṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù fi rí i gẹ́gẹ́ bíi “Mose kejì”?

Ta Ni Maimonides?

A bí Maimonides sí Córdoba, Spania, ní 1135. Bàbá rẹ̀, Maimon, ẹni tí ó pèsè èyí tí ó pọ̀ jù nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ìjímìjí nípa ìsìn, jẹ́ gbajúgbajà ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí ó wá láti inú ìdílé rabbi kan tí ó tayọlọ́lá. Nígbà tí àwọn Almohad ṣẹ́gun Córdoba ní 1148, àwọn Júù dojúkọ yíyàn náà láti di onísìn Islam tàbí kí wọ́n sálọ. Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ sáà gígùn tí ìdílé Maimonides fi ń sá káàkiri. Ní 1160 wọ́n fìdí kalẹ̀ sí Fez, Morocco, níbi tí ó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn. Ní 1165 ìdílé rẹ̀ níláti sálọ sí Palestine.

Bí ó ti wù kí ó rí, ipò nǹkan ní Israeli kò dúró sójúkan. Àwùjọ àwọn Júù kéréje náà dojúkọ ewu láti ọ̀dọ̀ àwọn Ajagun-Ìsìn Kristẹndọm bákan náà sì ni láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Musulumi. Lẹ́yìn nǹkan tí ó dín díẹ̀ ní oṣù mẹ́fà tí wọ́n ti wà ní “Ilẹ̀ Mímọ́” náà, Maimonides àti ìdílé rẹ̀ rí ibi ìsádi ní Fustat, Ìlú-Ńlá Àtijọ́ ti Cairo, ní Egipti. Níhìn-ín ni a ti wá mọ ẹ̀bùn Maimonides dunjú. Ní 1177 ó di aṣíwájú àwùjọ Júù, àti ní 1185 a yàn án gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn fún kóòtù Saladin tí ó jẹ́ ìlú-mọ̀ọ́ká olórí ìsìn Musulumi. Maimonides di àwọn ipò wọ̀nyí mú títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní 1204. Ìjáfáfá rẹ̀ nínú ìmọ̀ ìṣègùn di mímọ̀ káàkiri tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi sọ pé láti ibi jíjìnnà réré bíi England, Ọba Richard Ọlọ́kàn Kìnnìún gbìdánwò láti gba Maimonides gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn tirẹ̀ fúnra rẹ̀.

Kí Ni Ó Kọ?

Òǹkọ̀wé tí ó pójú owó ni Maimonides jẹ́. Nígbà tí ó ń sá fún inúnibíni àwọn Musulumi, bí ó ṣe ń sá síhìn sọ́hùn-ún, ó ṣàkójọ èyí tí ó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ rẹ̀ pàtàkì, Commentary on the Mishnah.b Ó kọ ọ́ ní èdè Lárúbáwá, ó sì làdí púpọ̀ lára àwọn ìpìlẹ̀-èrò àti ọ̀rọ̀ inú Mishnah, ó sì máa ń yà bàrá sínú ṣíṣàlàyé ọgbọ́n-èrò-orí Maimonides nípa ìsìn Júù nígbà mìíràn. Nínú abala tí ó ṣàlàyé tinú-tòde Sanhedrin, Maimonides gbé àwọn ìlànà pàtàkì 13 tí ìgbàgbọ́ Júù dálé lórí kalẹ̀. Ìsìn Júù kò fìgbàkanrí túmọ̀ ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tí a gbékarí ìlànà tí gbogbogbòò tẹ́wọ́gbà, tàbí ìjẹ́wọ́ èrò-ìgbàgbọ́. Wàyí o, Ìlànà Ìgbàgbọ́ 13 ti Maimonides wá di àwòṣe fún ìgbékalẹ̀ ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ àwọn Júù tí ó wáyé tẹ̀lé e.—Wo àpótí, ojú-ìwé 23.

Maimonides wá ọ̀nà láti mú bí gbogbo nǹkan ṣe wáyé ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé ṣe kedere, yálà nípa ti ara tàbí nípa ti ẹ̀mí. Ó kọ ìgbàgbọ́ yẹ̀bùyẹ́bù, ó ń béèrè fún àlàyé nípa ohun gbogbo lórí ìpìlẹ̀ ohun tí ó wò gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀rí tí ó bọ́gbọ́nmu tí ó sí lọ́gbọ́n-nínú. Ìtẹ̀sí tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu yìí jálẹ̀ sí kíkọ ìwé rẹ̀ tí ó lókìkí jùlọ—Mishneh Torah.c

Ní ìgbà ayé Maimonides àwọn Júù wo “Torah,” tàbí “Òfin,” gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò kan kìkì àwọn ọ̀rọ̀ tí Mose ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ bíkòṣe gbogbo ìtumọ̀ tí àwọn rabbi fún Òfin yìí jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún. Àwọn èrò wọ̀nyí ni a kọ sínú Talmud àti sínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìpinnu àti ìwé àwọn rabbi nípa Talmud. Maimonides mọ̀ pé ìtóbi bàǹbà-banba àti àìwàlétòlétò gbogbo ìsọfúnni yìí kò mú kí ó ṣeé ṣe fún Júù kan tí ó mọ̀wé níwọ̀nba láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó kan ìgbésí-ayé rẹ̀ ojoojúmọ́. Àwọn tí ó pọ̀ jùlọ kò sí ní ipò tí wọ́n ti lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé àwọn rabbi jálẹ̀ gbogbo ìgbésí-ayé wọn, púpọ̀ lára àwọn tí ó jẹ́ pé èdè Aramaic tí ó díjú ni a fi kọ ọ́. Ojútùú tí Maimonides rí ni láti ṣàtúnyẹ̀wò ìsọfúnni yìí, kí ó fa àwọn ìpinnu tí ó ṣeé múlò nínú rẹ̀ yọ, kí ó sì ṣètò rẹ̀ sí ìwé 14 tí a gbékalẹ̀ lọ́nà tí ó wà létòlétò, tí a pín sí ìṣọ̀rí-ìṣọ̀rí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn kókó tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ó kọ ọ́ lọ́nà tí ó yéni yékéyéké, ní èdè Heberu tí ó dùn ún gbọ́.

Mishneh Torah jẹ́ atọ́nà tí ó ṣeé múlò tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí àwọn aṣáájú Júù kan fi fòyà pé yóò gba ipò Talmud pátápátá. Síbẹ̀, àwọn tí wọ́n tilẹ̀ takò ó pàápàá jẹ́wọ́ pé iṣẹ́ náà gbé ọgbọ́n ìkọ̀wé tí ń ru ìmọ̀lára sókè yọ. Àkójọ òfin tí a ṣètò lọ́nà gígún régé yìí jẹ́ àṣeyọrí oníyìípadà tegbò-tigaga, tí ó fún ètò ìsìn Júù ní okun titun tí ẹnì kan tí ó mọ̀wé níwọ̀nba kò lè tẹ́wọ́gbà tàbí lóye tẹ́lẹ̀rí.

Lẹ́yìn náà, Maimonides dáwọ́lé kíkọ ìwé pàtàkì mìíràn—The Guide for the Perplexed. Pẹ̀lú títúmọ̀ àwọn ìwé Griki sí èdè Lárúbáwá, àwọn Júù púpọ̀ síi bẹ̀rẹ̀ sí di ojúlùmọ̀ Aristotle àti àwọn ọlọ́gbọ́n-èrò-orí mìíràn. Ó tojúsú àwọn kan, ó ṣòro fún wọn láti mú àwọn ọ̀rọ̀ olówuuru ti inú Bibeli bá ọgbọ́n-èrò-orí mu. Nínú The Guide for the Perplexed, Maimonides, ẹni tí ó kansáárá sí Aristotle gidigidi, gbìyànjú láti ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì Bibeli àti ìsìn Júù ní ọ̀nà kan tí ó bá èrò àti ọgbọ́n ti ọgbọ́n-èrò-orí mu.—Fiwé 1 Korinti 2:1-5, 11-16.

Ní àfikún sí àwọn iṣẹ́ pàtàkì wọ̀nyí àti àwọn ìwé ìsìn mìíràn, Maimonides kọ̀wé lọ́nà tí ó fi ọlá-àṣẹ hàn nínú ìmọ̀-ìṣègùn àti ìmọ̀ ojúde òfúúrufú. Apá mìíràn nínú àwọn ìwé rẹ̀ tí ó pójú owó ni a kò níláti gbójúfòdá. Ìwé gbédègbéyọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé: “Àwọn lẹ́tà tí Maimonides kọ sàmì sí sànmánì kan nínú lẹ́tà kíkọ. Òun ni Júù akọ̀wé àkọ́kọ́ tí a tí ì fi lẹ́tà rẹ̀ pamọ́ jùlọ. . . . Àwọn lẹ́tà rẹ̀ wọnú ọkàn àwọn tí ń kọ̀wéránṣẹ́ sí i ṣinṣin, ó sì ń yí àwọn ọ̀nà ìkọ̀wé rẹ̀ padà láti lè bá ipò wọn mu.”

Kí Ni Ó Fi Kọ́ni?

Nínú Ìlànà Ìgbàgbọ́ 13 rẹ̀, Maimonides pèsè ìlàlóye kedere nípa èrò-ìgbàgbọ́, díẹ̀ lára èyí tí a fìdí wọn múlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ìlànà keje àti ìkẹsàn-án tako ìjẹ́pàtàkì ìgbàgbọ́ nínú Jesu gẹ́gẹ́ bí Messia náà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu.d Bí a bá gbé àwọn ẹ̀kọ́ apẹ̀yìndà tí Kristẹndọm yẹ̀wò, irú bíi Mẹ́talọ́kan, àti àgàbàgebè pọ́nránún tí àwọn Ogun-Ìsìn afẹ̀jẹ̀wẹ̀ fi hàn, kò yani lẹ́nu pé Maimonides kò lọ jìnnà síwájú síi lórí ọ̀ràn ipò jíjẹ́ Messia Jesu.—Matteu 7:21-23; 2 Peteru 2:1, 2.

Maimonides kọ̀wé pé: “Òkúta ìkọ̀sẹ̀ kankan ha lè wà tí ó ju [ìsìn Kristian] lọ bí? Gbogbo àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ nípa Messiah gẹ́gẹ́ bí olùràpadà Israeli àti olùgbàlà rẹ̀ . . . [Ní òdìkejì pátápátá, ìsìn Kristian] mú kí a ti ipa idà pa àwọn Júù, kí a fọ́n àwọn àṣẹ́kù wọn ká kí a sì rẹ̀ wọ́n nípò sílẹ̀, kí a yí Torah padà, kí àwọn tí ó pọ̀ jù lára aráyé ṣìnà kí wọ́n sì sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Oluwa.”—Mishneh Torah, “Òfin Àwọn Ọba àti Ogun Wọn,” orí 11.

Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ọ̀wọ̀ tí wọ́n fi hàn fún Maimonides, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù yàn láti ṣá a tì lórí àwọn ọ̀ràn kan tí ó sọ̀rọ̀ lé lórí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n. Pẹ̀lú bí ipa ìdarí ìsìn aláwo ti Júù (Kabbalah) ṣe ń gbèrú síi, ìwòràwọ̀ ń gbajúmọ̀ síi láàárín àwọn Júù. Maimonides kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń lọ́wọ́ nínú ìwòràwọ̀ tí ó sì ń gbé ìwéwèé iṣẹ́ tàbí ìrìn-àjò rẹ̀ karí àkókò tí àwọn awòràwọ̀ dábàá yẹ ni nínà lẹ́gba . . . Irọ́ àti ẹ̀tàn ni gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí . . . Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àwọn nǹkan wọ̀nyí gbọ́ . . . jẹ́ òmùgọ̀ àti aláìlọ́pọlọ.”—Mishneh Torah, “Òfin Ìbọ̀rìṣà,” orí 11; fiwé Lefitiku 19:26; Deuteronomi 18:9-13.

Maimonides tún ṣe lámèyítọ́ mímúná nípa àṣà mìíràn: “[Àwọn rabbi] pinnu fúnra wọn bíbéèrè iye owo pàtó lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ẹgbẹ́ àwùjọ wọ́n sì mú kí àwọn ènìyàn máa ronú, lọ́nà òmùgọ̀ paraku, pé ọ̀ranyàn àti ohun tí ó yẹ ni ó jẹ́ . . . Gbogbo èyí ni kò tọ̀nà. Kò sí ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo yálà nínú Torah, tàbí nínú àwọn ọ̀rọ̀ orin arò tí ń bẹ nínú [Talmud], tí a lè fi tì í lẹ́yìn.” (Commentary on the Mishnah, Avot 4:5) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn rabbi wọ̀nyí, Maimonides ṣiṣẹ́ takuntakun láti gbọ́bùkátà ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn, kò gba owó rí fún ṣíṣe iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ ti ìsìn.—Fiwé 2 Korinti 2:17; 1 Tessalonika 2:9.

Báwo Ni Ó Ṣe Nípa Lórí Ìsìn Júù àti Àwọn Èrò-Ìgbàgbọ́ Mìíràn?

Ọ̀jọ̀gbọ́n Yeshaiahu Leibowitz ti Hebrew University, Jerusalem, sọ pé: “Maimonides ní ògúnná gbòǹgbò jùlọ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn ìsìn Júù, láti ìgbà sànmánì Àwọn Bàbáńlá Àwọn Heberu àti Àwọn Wòlíì títí di sànmánì lọ́ọ́lọ́ọ́.” Ìwé gbédègbéyọ̀ Encyclopaedia Judaica sọ pé: “Ipa ìdarí tí Maimonides ní lórí ìdàgbàsókè ọjọ́-ọ̀la ìsìn Júù kò ṣeé fẹnusọ. . . . C. Tchernowitz . . . lọ jìnnà débi sísọ pé bí kì í bá ṣe ọpẹ́lọpẹ́ Maimonides ìsìn Júù ìbá ti fọ́ yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí onírúurú ẹ̀ya ìsìn àti èrò-ìgbàgbọ́ . . . Àṣeyọrí ńláǹlà ni ó jẹ́ fún un láti so onírúurú ìtẹ̀sí èrò papọ̀.”

Maimonides tún ìsìn Júù ṣe, nípa ṣíṣe àtúnṣe ìrònú àwọn Júù láti bá bí àwọn nǹkan ṣe wà ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé àti létòlétò lójú ìwòye tirẹ̀ mu. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àti àwọn mẹ̀kúnnù pẹ̀lú rí i pé àtúnṣe titun yìí ṣeémúlò ó sì fanimọ́ra. Àní àwọn alátakò Maimonides pàápàá tẹ́wọ́gba púpọ̀ lára èrò rẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé rẹ̀ ni a pète pé kí o gba àwọn Júù sílẹ̀ lọ́wọ́ àìní náà láti yíjú sí àwọn àlàyé àṣeèṣetán, kò pẹ́ kò jìnnà tí a tún fi kọ àwọn àlàyé gígùn jàn-àn-ràn jan-an-ran nípa àwọn ìwé rẹ̀.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica ṣàlàyé pé: “Maimonides ni . . . Júù ọlọ́gbọ́n-èrò-orí tí ó jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ ní àwọn Sànmánì Agbedeméjì, ìwé rẹ̀ Guide of the Perplexed sì ni ìwé nípa ọgbọ́n-èrò-orí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a ti ọwọ́ Júù kan kọ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Lárúbáwá ni a fi kọ ọ́, a túmọ̀ ìwé The Guide for the Perplexed sí èdè Heberu ní ìgbà ayé Maimonides a sì túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Latin ní kété lẹ́yìn náà, tí ó mú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìkẹ́kọ̀ọ́ jákèjádò ilẹ̀ Europe. Ní ìyọrísí rẹ̀, ọ̀nà títayọ tí Maimonides gbà gbé ọgbọ́n-èrò-orí Aristotle jáde ní ìbámu pẹ̀lú èrò ìsìn Júù tètè rí àyè wọ àárín gbùngbùn ìrònú Kristẹndọm. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Kristẹndọm ní sáà yẹn, àwọn bí Albertus Magnus àti Thomas Aquinas, sábà máa ń tọ́ka sí ojú ìwòye Maimonides. Ó tún ní ìpa ìdarí lórí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti ìsìn Islam pẹ̀lú. Ọ̀nà tí Maimonides gbà gbé ọgbọ́n-èrò-orí kalẹ̀ ní ipa ìdarí lórí àwọn ọlọgbọ́n-èrò-orí Júù tí wọ́n dìde lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn bíi Baruch Spinoza, láti yapa pátápátá nínú ìsìn Júù tí gbogbogbòò tẹ́wọ́gbà.

A lè ka Maimonides sí Amòye-Olùmú-Ọ̀làjú-Sọjí tí ó ti gbé ayé ṣáájú Ìgbà-Ìmúsọjí-Ọ̀làjú. Ìrinkinkin rẹ̀ lórí pé kí ìgbàgbọ́ bá ìrònú mu délẹ̀délẹ̀ ṣì jẹ́ ìlànà kan tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ́ nínú òfin. Ìlànà yìí sún un láti fi ìkálára sọ̀rọ̀ lòdìsí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti ìsìn. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ búburú ti Kristẹndọm àti ipa tí ọgbọ́n-èrò-orí Aristotle ní kò yọ̀ǹda fún un láti dé ìparí èrò tí ó bá òtítọ́ Bibeli mu ní kíkún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò gba pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí a gbẹ́ sórí ibojì Maimonides—“Láti ìgbà ayé Mose títí di ìgbà ayé Mose, kò sí ẹnìkan tí ó dàbí Mose”—a gbọ́dọ̀ gbà pé ó mú ipa-ọ̀nà àti ìgbékalẹ̀ ìsìn Júù ṣe kedere.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Rambam” jẹ́ ọ̀rọ̀ ìgékúrú aṣeésọdorúkọ lédè Heberu, orúkọ kan tí a fàyọ láti inú àwọn lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ń bẹ nínú orúkọ náà “Rabbi Moses Ben Maimon.”

b Mishnah jẹ́ àkójọ àwọn àlàyé lórí ẹ̀kọ́ àwọn rabbi, tí a gbékarí ohun tí àwọn Júù kà sí òfin àtẹnudẹ́nu. A ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní apá ìparí ọ̀rúndún kejì àti apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ìkẹta C.E., ó sì di ìbẹ̀rẹ̀ Talmud. Fún ìsọfúnni síwájú síi, wo ìwé pẹlẹbẹ náà Will There Ever Be a World Without War? ojú-ìwé 10, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

c Orúkọ náà Mishneh Torah jẹ́ ọ̀rọ̀ Heberu kan tí a fàyọ láti inú Deuteronomi 17:18, ìyẹn ni, ẹ̀dà, tàbí àtúnkọ, Òfin.

d Fún àlàyé síwájú síi nípa ẹ̀rí tí ó fi Jesu hàn gẹ́gẹ́ bíi Messia náà tí a ṣèlérí, wo ìwé pẹlẹbẹ náà Will There Ever Be a World Without War? ojú-ìwé 24 sí 30, ti a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

ÌLÀNÀ ÌGBÀGBỌ́ 13 TI MAIMONIDES*

1. Ọlọrun ni Ẹlẹ́dàá àti Alákòóso ohun gbogbo. Òun nìkan ṣoṣo ní ó ti ṣe ohun gbogbo, ni ó ń ṣe é, tí yóò sì máa ṣe é.

2. Ọ̀kanṣoṣo ni Ọlọrun. Kò sí ìṣọ̀kan kan tí ó dàbí Tirẹ̀ lọ́nàkọnà.

3. Ọlọrun kò ní ara. Ìpìlẹ̀-èrò ti ohun tí a lè fojúrí kò ṣe é lò fún Un.

4. Ọlọrun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin.

5. Ó yẹ láti gbàdúrà sí Ọlọrun nìkanṣoṣo. Ẹnì kan lè má gbàdúrà sí ẹlòmíràn tàbí sí ohunkóhun mìíràn.

6. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì.

7. Òtítọ́ pọ́ńbélé ni àsọtẹ́lẹ̀ Mose. Òun ni olórí nínú gbogbo àwọn wòlíì, ṣáájú àti lẹ́yìn rẹ̀.

8. Odidi Torah tí a ní nísinsìnyí ni èyí tí a fifún Mose.

9. A kò ní yí Torah padà, Ọlọrun kò sì ní fúnni ní òmíràn.

10. Ọlọrun mọ gbogbo ìṣe àti èrò ènìyàn.

11. Ọlọrun ń san èrè fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́, ó sì ń jẹ àwọn tí wọ́n bá ṣẹ̀ Ẹ́ níyà.

12. Messia yóò wá.

13. A óò mú àwọn òkú padà wá sí ìyè.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

Maimonides ṣàlàyé àwọn ìlànà wọ̀nyí nínú ìwé rẹ̀ Commentary on the Mishnah, (Sanhedrin 10:1). Ìsìn Júù gbà wọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn gẹ́gẹ́ bí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tí gbogbogbòò tẹ́wọ́gbà tí a sì fàṣẹ sí. Ẹsẹ tí a fàyọ lókè yìí ni a ṣàkópọ̀ láti inú bí wọ́n ṣe farahàn nínú ìwé àdúrà àwọn Júù.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]

Jewish Division / The New York Public Library / Astor, Lenox, and Tilden Foundations

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́