Àpéjọpọ̀ “Àwọn Onídùnnú-ayọ̀ Olùyìn” Ìwọ Yóò Ha Wà Níbẹ̀ Bí?
ÌDÙNNÚ-AYỌ̀! Ọ̀rọ̀ yẹn ha ṣàjèjì tí a kì í sì í sábà gbọ́ ọ ní àkókò tí wàhálà kùn dẹ́nu yìí bí? Dájúdájú àwọn ìwé agbéròyìnjáde kò fún wa ní ìdí púpọ̀ láti mú kí a kún fún ìdùnnú-ayọ̀. Ogun ẹ̀yà, ebi tí ó tànkálẹ̀, àìníṣẹ́lọ́wọ́, bíba àyíká jẹ́ lọ́nà tí o léwu, ètò ìṣèlú tí kò dúró sójú kan, ìwà ọ̀daràn—àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í ṣe ohun tí ó lè mú kí ọkàn-àyà kún fún ìdùnnú-ayọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ ni?
Àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jùlọ lónìí ń já ìgbádùn èyíkéyìí tí wọ́n bá lè rí gbà mọ́ ìgbésí-ayé lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ìdùnnú-ayọ̀ ń kọ́? A ti ṣàpèjúwe ìdùnnú-ayọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ipò ayọ̀; ayọ̀ àṣeyọrí.” Kì í ṣe ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ti ní ìrírí àyọ̀ tòótọ́, nígbà tí wọ́n bà sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ń jẹ́ fún ìgbà díẹ̀.
Síbẹ̀, ní ìfojúsọ́nà fún ọjọ́ wa, Bibeli sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Báyìí ni Oluwa Jehofa wí, Kíyèsí i àwọn ìránṣẹ́ mi óò yọ. Kíyèsí i àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrin fún inúdídùn.” (Isaiah 65:13, 14) Báwo ni ìyẹn yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Láti rí ìdáhùn, a késí ọ láti wa sí ọ̀kan lára àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a óò ṣe ní 1995. Ẹṣin-ọ̀rọ̀ àwọn àpéjọpọ̀ náà ni “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn,” ọ̀fẹ́ sí ni ìjókòó. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà yóò ní nínú àwọn ọ̀rọ̀-àwíyé tí a gbé karí Bibeli, àwọn àṣefihàn, àwọn ìjíròrò, àti púpọ̀ síi. Jálẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìdùnnú-ayọ̀ ni a óò pé àfiyèsí sí.
Àwọn àpéjọpọ̀ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ni United States ní June yóò sì máa bá a nìṣó ní àwọn ìlú-ńlá káàkiri ayé títí di ìbẹ̀rẹ̀ 1996. Ó ṣeé ṣe, kí ọ̀kan wà nítòsí rẹ. Èéṣe tí o kò béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa tí ń gbé ní agbègbè rẹ? A fi tọ̀yàyà késí ọ láti wà níbẹ̀.