ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 5/1 ojú ìwé 20-21
  • Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kà Á àti Bí Wọ́n Ṣe Ń Jàǹfààní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kà Á àti Bí Wọ́n Ṣe Ń Jàǹfààní
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ní Alẹ́:
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Gbádùn Bíbélì Kíkà Sí I?
    Jí!—2001
  • Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Púpọ̀ Látinú Bíbélì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 5/1 ojú ìwé 20-21

Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kà Á àti Bí Wọ́n Ṣe Ń Jàǹfààní

Lówùúrọ̀ Kùtùkùtù:

Tọkọtaya kan, tí àwọn méjèèjì ń ṣiṣẹ́ lóde ilé wọn, pinnu láti máa jí ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré ṣáájú lóròòwúrọ̀ kí wọ́n sì lo àkókò náà láti ka Bibeli papọ̀ ṣáájú kí wọ́n tó kánjú kúrò nílé. Ohun tí wọ́n kà máa ń pèsè ìpìlẹ̀ fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó gbámúṣé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kúrò nílé.

Alàgbà kan ní Nigeria máa ń lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a là sílẹ̀ fún Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún Bibeli kíkà ìdílé nínú agbo-ilé rẹ̀. Wọ́n máa ń ka apákan rẹ̀ lójoojúmọ́ lẹ́yìn jíjíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní òwúrọ̀. Àwọn ọmọ ni a máa ń ní kí wọ́n ka apákan tí a ti yàn fún wọn ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé. Lẹ́yìn náà a óò késí wọn láti béèrè ìbéèrè lórí àwọn ẹsẹ̀ tí wọ́n ti kà.

Ìyàwó ilé kan ní Japan ti ka gbogbo odindi Bibeli lẹ́ẹ̀kan lọ́dún bẹ̀rẹ̀ láti 1985. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ ni láti kà á fún 20 sí 30 ìṣẹ́jú bẹ̀rẹ̀ láti agogo 5:00 òwúrọ̀ lójoojúmọ́. Nípa àǹfààní rẹ̀, ó wí pé: “Ìgbàgbọ́ mi ni a ti fún lókun. Ó ń ràn mí lọ́wọ́ láti gbàgbé àìsàn mi ki n sì kọjú mọ́ ìrètí Paradise.”

Arábìnrin kan tí ó ti jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún 30 ọdún ṣùgbọ́n tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ń dìde ní agogo márùn-ún lóròòwúrọ̀ láti ka Bibeli rẹ̀. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ béèrè pé kí ó ka nǹkan bí ojú-ìwé mẹ́rin láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, orí kan láti inú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki, àti ẹsẹ̀ kan láti inú ìwé Owe. Ó ti ń ka gbogbo odindi Bibeli lọ́dọọdún bẹ̀rẹ̀ láti 1959. Ó sọ pé: “Nítorí kíkà tí mo ń kà á, mo nímọ̀lára pé Jehofa fẹ́ràn mi . . . mo ń rí ìṣírí, ìtùnú, àti ìtọ́sọ́nà gbà.” Ó fi kún-un pé: “Kíka Bibeli dàbíi pé Jehofa ń fún mi lókun lójoojúmọ́.”

Arábìnrin kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ilẹ̀ kan tí a ti fi òfin de ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pẹ̀lú ní ọkọ tí ó ń ṣàtakò sí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe fún un láti ka Bibeli rẹ̀ láti Monday sí Friday, láàárín agogo 6:00 àti agogo 7:00 òwúrọ̀. Èyí ti fún-un ní okun inú. Nígbà tí ó ń rántí bí kíka Bibeli rẹ̀ ti nípa lórí rẹ̀, ó sọ pé: “A kẹ́kọ̀ọ́ láti fẹ́ràn Jehofa àti Jesu àti láti gbé tayọ̀tayọ̀, àní pàápàá pẹ̀lú àwọn ìṣòro àti ìnira, ní mímọ̀ pé àwọn ìlérí Jehofa kì í yẹ̀.”

Arábìnrin kan tí ó ti lọ sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà pinnu láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn tí a fún wọn níbẹ̀ láti fi Bibeli kíkà ṣe àṣà lójoojúmọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè ṣe é láàárín agogo 5:00 àti agogo 6:00 òwúrọ̀. Nígbà tí ìyípadà iṣẹ́ nípa lórí èyí, ó yí i padà sí láàárín agogo 9:00 àti agogo 10:00 alẹ́. Nígbà tí ìpènijà ipò-ọ̀ràn mìíràn dìde, ó sọ pé, “Mo ń bá a lọ láti máa yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ mi padà ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ipò mi.”

Ní Ìrọ̀lẹ́:

Àwọn arábìnrin tẹ̀gbọ́ntàbúrò méjì kan tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ìdílé Beteli ní Brazil ní àṣà láti máa ka Bibeli papọ̀ fún nǹkan bí 20 ìṣẹ́jú lójoojúmọ́ lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán. Wọ́n ti ka gbogbo Bibeli tán ní nǹkan bí ìgbà 25; síbẹ̀ wọ́n kọ̀wé pé: “A máa ń rí ohun titun nígbà gbogbo, nítorí náà Bibeli kíkà kì í súni.”

Omidan kan ní Japan, rí i pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tọ́ òun dàgbà gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí, òun kò mọ Ìwé Mímọ́ dáradára; nígbà tí ó di aṣáájú-ọ̀nà, ó pinnu láti máa ka Bibeli déédéé. Ó máa ń ka Bibeli fún Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun nígbà tí ó bá ń rìnrìn-àjò lọ sí ilé-ìwòsàn fún ìtọ́jú ní ọjọ́ kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn náà, ní ilé, ó tún máa ń ṣe ìwádìí síwájú síi. Bí ó bá ti ń di ìparí ọ̀sẹ̀, ó máa ń ka Bibeli síwájú síi, ó máa ń yan àwọn ìwé ní ìtòtẹ̀léra bí a ṣe kọ wọ́n.

Ọmọ ọdún 13 kan tí ó ti ka gbogbo odindi Bibeli tán ní ìgbà mẹ́ta máa ń ka orí kan lójoojúmọ́ nígbà tí ó bá dé láti ilé-ẹ̀kọ́. Ó sọ pé, èyí ti ran òun lọ́wọ́ “láti túbọ̀ nímọ̀lára ìfẹ́ tí ó pọ̀ síi fún Jehofa.”

Ẹlẹ́rìí kan tí ọwọ́ rẹ̀ dí púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ kan, alàgbà, ọkọ kan, àti bàbá kan máa ń tẹ́tísílẹ̀ sí Bibeli tí a ti kà sínú kásẹ́ẹ̀tì nígbà tí ó bá ń rìnrìn-àjò lọ sí ibi iṣẹ́ nínú ọkọ̀ ojú-irin. Lẹ́yìn náà ní ilé ó máa ń ṣe àtúnkà àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ kan náà.

Ní àfikún sí kíkà á fúnra rẹ̀, aṣáájú-ọ̀nà kan ní France máa ń tẹ́tí sí Bibeli tí a ti kà sínú kásẹ́ẹ̀tì nígbà tí ó bá ń se oúnjẹ, nígbà tí ó bá ń wakọ̀, nígbà tí ó bá ń dojúkọ àwọn àkókò tí ó le koko, tàbí fún ìgbádùn lásán.

Aṣáájú-ọ̀nà kan ní Japan ọmọ ọdún 21 rántí pé ìyá òun sọ ọ́ di dandan pé òun gbọ́dọ̀ gba oúnjẹ tẹ̀mí sínú lójoojúmọ́, ó sì ti ń ka Bibeli lójoojúmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní ìgbà kan náà, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn tí ó bá ti ka apá tí ó ti yàn fún ọjọ́ náà tán, ó sọ ọ́ di àṣà láti tún àwọn ẹsẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì kà, lẹ́yìn náà ni yóò máa ronú lórí ohun tí ó ti kà.

Ẹlẹ́rìí mìíràn, tí ó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ti ka gbogbo odindi Bibeli tán ní nǹkan bí ìgbà mẹ́wàá ni ọdún 12 tí ó ti kọjá. Ọkọ rẹ̀ jẹ́ aláìgbàgbọ́, nítorí náà ó ṣètò kíkà tirẹ̀ sí ọ̀sán.

Ní Alẹ́:

Alàgbà kan tí ó tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní Japan tí ó máa ń kà Bibeli rẹ̀ lálaalẹ́ ṣáájú kí ó tó lọ sùn ti ṣe èyí fún ọdún mẹ́jọ tí ó ti kọjá. Ó sọ pé: “Mo máa ń ní inú dídùn sí ìwé mímọ́ tí ó ń fi bí Jehofa ṣe ń ronú hàn, irú ìmọ̀lára tí ó ń ní nípa nǹkan, àti bí ó ṣe ń mójútó àwọn ipò-ọ̀ràn. Nípa ṣíṣàṣàrò lórí ìwé mímọ́ wọ̀nyí, a ti ràn mí lọ́wọ́ láti sọ ọ̀nà tí Jehofa gbà ń ronú di tèmi àti láti ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin mi àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé mi.”

Alàgbà kan ní France ti ń ka Bibeli fún wákàtí kan ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti 1979. Ó sábà máa ń ní ìtumọ̀ márùn-ún tàbí mẹ́fà tí yóò gbé sí iwájú rẹ̀ fún ìfiwéra. Ó sọ pé fífi ìṣọ́ra ka Bibeli ti ran òun lọ́wọ́ láti wòye “bí òun ti lè lo ìmọ̀ Bibeli nínú ipò-ọ̀ràn ojoojúmọ́.” Èyí ti mú kí ó ṣeé ṣe fún un láti di ògbóṣáṣá nínú fífún àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ràn láti inú Ìwé Mímọ́.

Fún ọdún 28 tí ó ti kọjá, arákùnrin kan ní Nigeria ti sọ ọ́ di àṣà láti máa ka ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí ó wà fún ìjíròrò ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ní alẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti pèsè rẹ̀ sínú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Papọ̀ pẹ̀lú èyí, ó máa ń ka gbogbo odindi orí Bibeli ti a ti mú ẹsẹ̀ náà jáde. Lẹ́yìn tí ó ṣe ìgbéyàwó, ó ń bá àṣà yìí lọ, ní kíkà àti jíjíròrò àkójọpọ̀ náà pẹ̀lú aya rẹ̀.

Ọ̀dọ́ kan tí kò tí ì pé ogún ọdún tí àwọn òbí rẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ ọ́ di àṣà láti máa kà á fún ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá ṣáájú kí ó tó lọ sùn. Àwọn ìṣẹ́jú tí ó ṣeyebíye fún-un nìyí, ó sì máa ń gbàdúrà ṣáájú àti lẹ́yìn kíkà á. Góńgó rẹ̀ ni láti mọ ìhìn-iṣẹ́ tí Jehofa darí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òǹkọ̀wé Bibeli láti kọ sílẹ̀.

Arákùnrin kan tí ó ti ṣègbéyàwó, tí ó wà nínú iṣẹ́ ìsìn Beteli, sọ pé òun ti ń ka Bibeli lẹ́ẹ̀kan lọ́dún fún ọdún mẹ́jọ tí ó ti kọjá. Ó máa ń kà á fún 20 sí 30 ìṣẹ́jú ṣáájú kí ó tó sùn. Nígbà tí ó bá ti rẹ̀ ẹ́ gan-an pàápàá, ó máa ń rí i pé bí òun bá lọ sùn láì kà á, òun kò ní lè sùn. Ó níláti dìde kí ó sì bójútó àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí yẹn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́