Fífúnni A Ha Retí Rẹ̀ Bí?
ÓṢEÉ ṣe kí o mọ̀ dájú pé, fífúnni lẹ́bùn sábà máa ń sinmi lórí àṣà ìbílẹ̀. Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ tí ó pọ̀ jù lọ, àwọn ìgbà kan wà tí a ń retí ẹ̀bùn. Irú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ fífi ọ̀wọ̀ tàbí ìfẹ́ hàn. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀bùn náà ni àwọn tí a fún kì í lò; àwọn mìíràn ń ṣèrànwọ́ láti kúnjú àìní ní ti gidi, a sì máa ń mọrírì wọn gidigidi.
Nígbà tí a bá bí ọmọ kékeré jòjòló ní Denmark, àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan yóò ṣèbẹ̀wò, wọn yóò sì mú ẹ̀bùn tí wọ́n rò pé yóò wúlò fún ìkókó náà lọ́wọ́. Ní àwọn ilẹ̀ míràn, àwọn ọ̀rẹ́ lè pe àpèjẹ, níbi tí wọn óò ti fúnni ní irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ ní ìfojúsọ́nà fún ìbímọ náà.
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn àkókò tí a máa ń retí ẹ̀bùn máa ń jẹ́ ọ̀ràn ọdọọdún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn Kristian ìjímìjí kò ṣe irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀, wọ́n ti lókìkí púpọ̀ láàárín àwọn Kristian aláfẹnujẹ́ àti àwọn tí kì í ṣe Kristian pẹ̀lú. Àṣà fífúnni lẹ́bùn ọjọ́ ìbí lè pòórá ní àwọn àṣà ìbílẹ̀ míràn bí àwọn ọmọ ṣe ń dàgbà sí i, ṣùgbọ́n àṣà ìbílẹ̀ láàárín àwọn Griki gbé ohun mìíràn yọ. Ní ilẹ̀ Griki, a darí àfiyèsí púpọ̀ sí ọjọ́ ìbí. Wọ́n tún máa ń fún ẹnì kan lẹ́bùn ní “ọjọ́ orúkọ” rẹ̀. Èwo tún nìyẹn? Tóò, àṣà ìsìn so “ẹni mímọ́” ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ọdún, a sì sọ ọ̀pọ̀ ènìyàn lórúkọ “àwọn ẹni mímọ́” náà. Nígbà tí ọjọ́ “ẹni mímọ́” náà bá kò, àwọn tí ń jẹ́ orúkọ náà yóò gba ẹ̀bùn.
Ní àfikún sí ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí fún àwọn ọmọ wọn, àwọn ará Korea ní họlidé orílẹ̀-èdè, tí a mọ̀ sí Ọjọ́ Àwọn Èwe. Ó jẹ́ àkókò kan tí àwọn ìdílé máa ń ṣeré jáde, tí a sì ń fún àwọn ọmọdé ní ẹ̀bùn, láìka ọjọ́ tí a bí wọn sí. Àwọn ará Korea tún ní Ọjọ́ Àwọn Òbí, nígbà tí àwọn ọmọ máa ń fún àwọn òbí wọn ní ẹ̀bùn, àti Ọjọ́ Àwọn Olùkọ́, nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń bọlá fún àwọn olùkọ́ wọn, tí wọ́n sì ń fún wọn lẹ́bùn. Gẹ́gẹ́ bí àṣà ìbílẹ̀ àwọn aráa Korea, nígbà tí ẹnì kan bá di ẹni 60 ọdún, a óò ṣe ayẹyẹ híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ kan. Ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ yóò pawọ́ pọ̀ ní nínawọ́ ìkíni fún ẹ̀mí gígùn àti ayọ̀ sí i, wọn óò sì fún ẹni náà, tí ó ti dé ipò yẹn nínú ìgbésí ayé, lẹ́bùn.
Ìgbéyàwó tún jẹ́ àkókò míràn tí àṣà ìbílẹ̀ lè béèrè fún ẹ̀bùn. Ní Kenya, nígbà tí àwọn ẹni méjì bá ṣègbéyàwó, a retí pé kí ìdílé ọkọ fún ìdílé ìyàwó lẹ́bùn. Àwọn àlejò pẹ̀lú yóò mú ẹ̀bùn wá. Bí ìyàwó àti ọkọ bá tẹ̀ lé àṣà, wọn yóò jókòó sórí pèpéle kan, nígbà tí àwọn àlejò yóò sì máa mú ẹ̀bùn wọn wá síwájú. Bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ti ń mú ẹ̀bùn rẹ̀ wá, a óò máa kéde pé, “Lágbájá mu ẹ̀bùn wá fún tọkọtaya.” Inú yóò bí ọ̀pọ̀ àwọn olùfúnni lẹ́bùn, bí wọn kò bá rí irú ìkanisí bẹ́ẹ̀ gbà.
Láàárín àwọn ará Lebanon, nígbà tí ẹnì kan bá gbéyàwó, àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò, àní àwọn tí kì í ṣe ojúlùmọ̀ wọn pàápàá, yóò mú ẹ̀bùn wá lẹ́yìn ọjọ́ ìgbéyàwó náà. Láti kékeré, a ti kọ́ wọn pé fífúnni lẹ́bùn jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe, bíi sísan gbèsè. Ọkùnrin ará Lebanon kan wí pé: “Bí o kò bá ṣe é, inú rẹ kò ní dùn. Ìṣẹ̀dálẹ̀ ni.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, Kérésìmesì ni ó gba ipò iwájú jù lọ nínú gbogbo ayẹyẹ tí a ti máa ń retí fífúnni lẹ́bùn. Kò ha rí bẹ́ẹ̀ níbi tí ò ń gbé bí? Láìpẹ́ yìí ní 1990, a ṣírò rẹ̀ pé, àwọn ará America ń ná iye tí ó tó 40 bílíọ̀nù dọ́là lórí ẹ̀bùn Kérésìmesì. Àwọn onísìn Buddha àti Shinto ní Japan pẹ̀lú ń ṣayẹyẹ họlidé náà pẹ̀lú ìtara ọkàn, onírúurú ọ̀nà ìgbàṣayẹyẹ náà ni a ń rí ní Europe, South America, àti àwọn agbègbè kan ní Africa.
Kérésìmesì jẹ́ ìgbà kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń retí láti láyọ̀, ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń rí i pé, gbígba wèrè ríra ẹ̀bùn àti àníyàn lórí sísan gbèsè tí a jẹ ń bo àwọn sáà amóríyá tí wọ́n lè nírìírí rẹ̀ mọ́lẹ̀.
Síbẹ̀, Bibeli sọ pé ayọ̀ wà nínú fífúnni. Ní tòótọ́, ó wà, ó sinmi lórí ẹ̀mí tí a bá fi fúnni.—Ìṣe 20:35.