ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 12/15 ojú ìwé 24-25
  • “Mo Ṣe Iyebíye Lójú Jehofa!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Mo Ṣe Iyebíye Lójú Jehofa!”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Ṣeyebíye Gan-an Lójú Jèhófà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ẹ Ṣe Iyebíye Lójú Ọlọrun!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 12/15 ojú ìwé 24-25

“Mo Ṣe Iyebíye Lójú Jehofa!”

Ọ̀PỌ̀ àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jehofa ń fara da ìjàkadì léraléra pẹ̀lú èrò àìjámọ́ nǹkan kan ní “awọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bálò,” wọ̀nyí. (2 Timoteu 3:1) Èyí kò yani lẹ́nu, nítorí ọ̀kan lára “ọgbọ́n ẹ̀wẹ́” Satani ni láti mú kí a rò pé a kò nífẹ̀ẹ́ wa, àní láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa pàápàá! (Efesu 6:11, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti April 1, 1995, ní ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ méjì tí a pe àkòrí wọn ní, “Ẹ Ṣe Iyebíye Lójú Ọlọrun!” àti “Ẹ Máa Ru Ara Yín Lọ́kàn Sókè sí Ìfẹ́ àti sí Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà—Báwo?” fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìjọ. A pète àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí láti rán wa létí pé Jehofa mọrírì àwọn ìsapá wa. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìmọrírì tí a rí gbà:

“Kò tí ì sí ìgbà kankan rí láti ọdún 27 tí mo ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí ìwé ìròyìn kan tí ì nípa lórí mi tó bẹ́ẹ̀. Mo kàn bú sẹ́kún ni—àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí mú ìtura àlàáfíà wá fún mi. Wàyí o, mo nímọ̀lára pé Jehofa nífẹ̀ẹ́ mi. Ṣe ni ó dà bíi pé a gbé ẹrù ìnira fàkìàfakia kan kúrò lórí mi.”—C. H.

“Mo ka ìwé ìròyìn yìí lẹ́ẹ̀mẹ́rin lọ́jọ́ kan ṣoṣo. Mo gbádùn ọ̀nà tí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà gbà sọ pé a ti kọ́ ọ nírọ́ bí o bá gbà gbọ́ pé o kò já mọ́ nǹkan kan. Èmi yóò lo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí fún iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti ìwàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà.”—M. P.

“Satani ti ṣe arabaríbí iṣẹ́ ti mímú kí àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa pàápàá ronú pé àwọn kò já mọ́ nǹkan kan tàbí pé a kò nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀kan lára àwọn ohun afúnniníṣìírí tí mo tí ì kà ni pé, ẹgbẹ́ ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà rán wa létí pé Jehofa nífẹ̀ẹ́ wa délẹ̀délẹ̀, àti pé ó mọrírì gbogbo ohun kéékèèké tí a ń ṣe fún un. Mo ti nímọ̀lára tí ẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí fún ọ̀pọ̀ ọdún. N kò lérò pé mo yẹ ni ẹni tí Jehofa ń nífẹ̀ẹ́ rí, nítorí náà, mo gbìyànjú láti túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti jèrè ìfẹ́ náà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀bi àti ìtìjú ní ń sún mi sí i. Nítorí náà, láìka iye wákàtí tí mo lè lo nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sí, tàbí iye ènìyàn tí mo lè ràn lọ́wọ́, mo lérò pé kò tí ì tó. Kìkì àìdójú ìwọ̀n tí ń bẹ nínú mi ni mo rí. Wàyí o, nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ sin Jehofa pẹ̀lú ìfẹ́, mo ń ronú pé ó ń rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì ń fi mí yangàn. Èyí mú kí ìfẹ́ mi fún un túbọ̀ máa pọ̀ sí i, ó sì mú kí n fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i. Mo ń nírìírí ayọ̀ kíkọyọyọ láti inú iṣẹ́ ìsìn mi sí Jehofa nísinsìnyí.”—R. M.

“Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ títayọ tí ó gbún ọkàn ní kẹ́ṣẹ́, tí ó dára jù lọ, tí ó gbéni ró jù lọ, tí mo tí ì kà rí! Mo ti ń ka Ilé-Ìṣọ́nà fún ọdún 55, ọ̀pọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde gbankọgbì sì ti wà. Ṣùgbọ́n ìtẹ̀jáde yìí tayọ ohunkóhun tí a tí ì rí gbà rí láti pẹ̀rọ̀ sí èrò òdì wa, ìméfò wa, àti ìbẹ̀rù wa pé a kò ‘já mọ́ nǹkan kan’ àti pé a kò ‘nífẹ̀ẹ́’ wa, àti pé a kò lè ṣe tó láé láti ‘rí’ ìfẹ́ Jehofa ‘gbà.’ Ilé-Ìṣọ́nà yìí ní irú ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ nípa tẹ̀mí tí àwọn ará wa nílò ní kíákíá nínú. Èrò mi ni láti lo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí léraléra nígbà iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn.”—F. K.

“Lójú àwa tí a ń bá ìmọ̀lára iyì ara ẹni dídínkù, tàbí ìmọ̀lára ìkórìíra ara ẹni jìjàkadì, ó lè nira gan-an láti ṣe gírí láti máa bá òtítọ́ nìṣó. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí fi bí ìyọ́nú àti òye náà ti jinlẹ̀ tó hàn, ṣe ni ó dà bíi fífi ìkunra atunilára ra ọkàn-àyà gan-an. Ẹ wo bí ó ti tuni nínú tó láti ka irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú Ilé-Ìṣọ́nà àti láti mọ̀ pé láìsí tàbí ṣùgbọ́n, Jehofa lóye wa ní tòótọ́! Ẹ ṣeun fún rírán wa létí pé Jehofa kò gbìyànjú láti fi ẹ̀bi, ìtìjú tàbí ìbẹ̀rù sún àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣiṣẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipa tí mo ń kó nínú iṣẹ́ ìwàásù kò tó nǹkan ní lọ́ọ́lọ́ọ́ nítorí wàhálà ìnáwó àti ìṣòro àìlera nínú ìdílé wa, mo ṣì ń rí ìtẹ́lọ́rùn nínú ohun tí mo lè ṣe. Mo rí i pé, mo ń láyọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn nígbà tí mo bá gbìyànjú láti jẹ́ kí ìfẹ́ jẹ́ ipá tí ń sún mi ṣiṣẹ́.”—D. M.

“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka ‘Ẹ Ṣe Iyebíye Lójú Ọlọrun!’ tán ni. Ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan mú mi da omi lójú. Mo wá láti inú ìdílé tí ó fi ìfẹ́ bíńtín hàn. A fojú kéré mi, a tàn mí, a fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Nítorí náà, ní kùtùkùtù ìgbésí ayé mo nímọ̀lára àìjámọ́-nǹkan-kan. Mo ṣì ń nímọ̀lára rírinlẹ̀ láti inú ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí mi sẹ́yìn, tí ń rìn mí mọ́lẹ̀ nígbà tí mo bá nírìírí àjálù. Nígbà tí mo ṣíwọ́ ṣíṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń rí, mo nímọ̀lára pé mo já—Ọlọrun, ìdílé mi, àwọn arákùnrin mi nínú ìjọ—kulẹ̀. Àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí kì í déédé pòórá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó bọ́ sákòókò yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti jèrè ìwọ̀n ìwà déédéé padà. Ó ti tún ojú ìwòye mi ṣe.”—D. L.

“Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ‘Ẹ Ṣe Iyebíye Lójú Ọlọrun!’ Mo ń kojú ìmọ̀lára ìkórìíra ara ẹni gbígbóná janjan àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ ti àìjámọ́-nǹkan-kan, tí ó pilẹ̀ nínú fífìyà jẹ ọmọdé. Dájúdájú, ó bá a mu wẹ́kú láti wo ìrònú tí ó lọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Satani fúnra rẹ̀. Ó tilẹ̀ lè pa ìfẹ́ inú ẹni láti wà láàyè run. Ní tòótọ́, mo gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́ láti dènà irọ́ náà pé a kò nífẹ̀ẹ́ mi. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí nítumọ̀ sí mi ju bí ẹ ti lè mọ̀ lọ.”—C. F.

“Lónìí, àwọn ará ní pàtàkì ń dáhùn padà sí ìrònú náà pé, Jehofa mọrírì àwọn ìṣe tí ìfẹ́ súnni ṣe dípò èyí tí a fipá múni ṣe tàbí tí a kàn nípá. Gbígbé ànímọ́ onífẹ̀ẹ́ àti ìfẹ́ni Jehofa yẹ̀ wò, ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, àti ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ tí ó gbà ń fi ara rẹ̀ fúnni ń tuni lára, ó sì ń súnni ṣiṣẹ́. Nítorí èyí, gbàrà tí a ti gba ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, ‘Ẹ Ṣe Iyebíye Lójú Ọlọrun!’ ọ̀pọ̀ fi ìmọrírì hàn. Ó dà bíi pé, ó ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti túbọ̀ mú ipò ìbátan ara ẹni dàgbà pẹ̀lú Jehofa. Èmi àti aya mi fẹ́ láti fi ìmọrírì wa hàn fún ọ̀nà ìkọ̀wé àti mímọ ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn tí ẹ fi hàn nínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà ti lọ́ọ́lọ́ọ́. A ń ṣiṣẹ́ láti fi ọ̀pọ̀ kókó wọ̀nyí sílò bí a ti ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ.”—Láti ọwọ́ alábòójútó arìnrìn àjò kan.

“Mo ti jẹ́ ẹni tí ń kàwé yìí déédéé fún nǹkan bí 30 ọdún, ṣùgbọ́n ń kò tí ì ka ohunkóhun tí ó runi sókè, tí ó sì gbéni ró tó bẹ́ẹ̀ rí. Àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ lílágbára tí a fi òye lò, ràn mí lọ́wọ́ láti kó àwọn irọ́ tí a sé mọ́ inú ìmọ̀lára mi fúnra mi dà nù, ní yíyọ̀ọ̀da mi láti túbọ̀ sún mọ́ Jehofa pẹ́kípẹ́kí. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ẹ̀bi ni ó sún mi ṣisẹ́ sin Jehofa. Mo ní kìkì òye orí lásán nípa ìràpadà àti ìfẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣeun fún irú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó kún fún òye inú àti ìrònú jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀. Mo ń retí láti ka ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹ́ẹ̀.”—M. S.

“Ní gbogbo ọdún 29 tí mo ti wà nínú òtítọ́, n kò lè rántí ìgbà tí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan mú mi ní irú ìhùwàpadà onímoore àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ńláǹlà ni a fi tọ́ mi dàgbà, tí ó sì jẹ́ láti ọwọ́ ìdílé tí ó bìkítà, n kò tí ì nímọ̀lára jíjẹ́ ẹni yíyẹ láti wà láàyè rí, kí a má tilẹ̀ sọ ti ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí, mo kúnlẹ̀, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa pẹ̀lú ẹkún gidigidi. Títí láé ni n óò máa ṣìkẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí. Èmi yóò wo ara mi lọ́nà tí ó yàtọ̀, nítorí pé nísinsìnyí, mo lóye pé mo ṣe iyebíye lójú Jehofa.”—D. B.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́