Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
“Òtítọ́ ni Gbogbo Àṣẹ Rẹ”
KÉTÉ ṣáájú ikú rẹ̀, Mose rọ àwọn ọmọ Israeli láti ṣègbọràn sí gbogbo àṣẹ Jehofa. Ó wí pé: “Ẹ gbé ọkàn yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ láàárín yín ní òní; tí ẹ̀yin óò pa láṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti máa kíyè sí àtiṣe gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí. Nítorí pé kì í ṣe ohun asán fún yin; nítorí pé ìyè yín ni.”—Deuteronomi 32:46, 47.
Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, onipsalmu náà tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbogbo ẹ̀kọ́ Ọlọrun, nígbà tí ó wí pé: “Oluwa, ìwọ́ wà ní itòsí: òtítọ́ sì ni gbogbo àṣẹ rẹ.” (Orin Dafidi 119:151) Ní ọ̀rúndún kìíní, Jesu fúnra rẹ̀ tọ́ka sí ìjẹ́pàtàkì “gbogbo gbólóhùn àsọjáde tí ń jáde wá lati ẹnu Jehofa.” (Matteu 4:4) Lábẹ́ ìdarí Ọlọrun pẹ̀lú, aposteli Paulu kọ̀wé pé, “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní.”—2 Timoteu 3:16.
Ó hàn gbangba pé, Jehofa Ọlọrun ń fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ gbé gbogbo ìhìn iṣẹ́ tí ó fún wọn nínú ojú ìwé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò gidigidi. Kò sí àyọkà kan nínú Bibeli tí kò ṣe pàtàkì. Èrò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nìyẹn nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí láti Mauritius ti fi hàn.
Ọ̀gbẹ́ni D—— ń gbé ní abúlé jíjìnnà réré kan, níbi tí ó ti ń ṣe ọdẹ aṣọ́de. Fún ìgbà pípẹ́, ó ti ń fi tọkàntọkàn wá ọ̀nà tòótọ́ láti jọ́sìn Ọlọrun. Lákòókò tí ó fi ń ṣọ́de lóru, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bibeli. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó kà á tán láti páálí dé páálí. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé Jehofa ni orúkọ Ọlọrun—orúkọ kan tí ó fara hàn ní ọ̀pọ̀ ìgbà nínú Bibeli èdè Hindi. Ó rí i pé, ìwé Ìṣípayá fani mọ́ra lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.
Nígbà náà, ó béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ bóyá ìsìn kan ń bẹ tí ń tẹ̀ lé Bibeli látòkèdélẹ̀. Ó ṣàkíyèsí pé àwọn ìsìn tí òun ti mọ̀ dáradára, lábẹ́ àyíká ipò tí ó bá ṣeé ṣe jù lọ, ń wulẹ̀ tẹ̀ lé apá kan Bibeli. Àwọn ìsìn kan tẹ́wọ́ gba Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, wọ́n sì kọ Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì. Àwọn ìsìn mìíràn kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, wọ́n sì fi hàn pé Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì nìkan ni ó ní ìníyelórí pàtàkì.
Lọ́jọ́ kan Ọ̀gbẹ́ni D—— rí tọkọtaya kan tí òjò ń pa, ó sì pè wọ́n wọ inú ilé rẹ̀. Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọ́n. Èyí ìyàwó mú ìwé náà, Revelation—Its Grand Climax At Hand!,a dání. Lójú ẹsẹ̀ Ọ̀gbẹ́ni D—— béèrè fún ìwé náà lọ́wọ́ wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà rò pé, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a gbé karí àsọtẹ́lẹ̀ Ìṣípayá kò lè tètè yé e, nítorí náà wọn fi ìtẹ̀jáde mìíràn lọ̀ ọ́ dípò ìyẹn. Ṣùgbọ́n Ọ̀gbẹ́ni D—— takú pé ìwé Revelation ni òún ń fẹ́.
Nígbà tí ó gba ẹ̀dà rẹ̀, kíá ni ó parí ìwé náà. Lẹ́yìn náà, ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Kò pẹ́ púpọ̀, òkodoro òtítọ́ náà pé àwọn Ẹlẹ́rìí kò kóyán Bibeli látòkèdélẹ̀ kéré wú u lórí. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí àwọn ìpàdé déédéé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, níbi tí wọ́n ti ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu àti Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì. Ó ti di olùpòkìkí Ìjọba náà tí ó sì ti ṣe batisí nínú ìjọ Kristian nísinsìnyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.