Ẹpafíródítù—Òjíṣẹ́ Aṣojú Àwọn Ará Fílípì
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Fílípì pé: “Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí àṣà nínú Olúwa pẹ̀lú ìdùnnú ayọ̀ gbogbo; ẹ sì máa ka irú awọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.” Kò sí àní-àní pé inú wa yóò dùn bí Kristẹni alábòójútó kan bá lè sọ̀rọ̀ nípa wa lọ́nà rere bẹ́ẹ̀. (Fílípì 2:29) Ṣùgbọ́n, ta ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Kí sì ni ẹni náà ti ṣe, tí ó fi yẹ fún irú ọ̀rọ̀ rere bẹ́ẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀?
Ìdáhùn sí ìbéèrè àkọ́kọ́ ni, Epafíródítù. Láti dáhùn ìkejì, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn àyíká ipò tí ó sún Pọ́ọ̀lù láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Ní nǹkan bí ọdún 58 Sànmánì Tiwa, àwọn ará Fílípì gbọ́ pé àwùjọ ènìyànkénìyàn òǹrorò kan wọ́ Pọ́ọ̀lù tuurutu jáde kúrò nínu tẹ́ḿpìlì, wọ́n sì lù ú, àwọn aláṣẹ sì fàṣẹ ọba mú un, àti pé, lẹ́yìn títì í mọ́lé láìtíì dórí ìpinnu kan nípa ọ̀ran rẹ̀, a fi ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n dè é, a sì ti gbé e lọ sí Róòmù. (Ìṣe 21:27-33; 24:27; 27:1) Níwọ̀n bí wọ́n ti ń ṣàníyàn nípa ire rẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ ti béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, kí ni àwọn lè ṣe fún un. Wọ́n tòṣì nípa ti ara, wọ́n sì jìnnà rere sí Pọ́ọ̀lù, nítorí náà ìba ni ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n lè ṣe fún un mọ. Síbẹ̀, ìmọ̀lára onífẹ̀ẹ́ tí ó sún àwọn ará Fílípì láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó ti kọjá ṣì ń sún wọn ṣiṣẹ́; àní ní pàtàkì, níwọ̀n bí ó ti wà ní ipò líle koko.—Kọ́ríńtì Kejì 8:1-4; Fílípì 4:16.
Àwọn ará Fílípì yóò ti ní láti ṣàgbéyẹ̀wò nípa bóyá ẹnì kan nínú wọn lè bẹ Pọ́ọ̀lù wò, kí wọ́n fi ẹ̀bùn ṣọwọ́ sí i, kí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ bí ó bá nílò ohunkóhun. Ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ìrìn àjò gígùn tí ń tánni lókun ríràn án lọ́wọ́ sì lè léwu! Joachim Gnilka sọ pé: “Ó ń béèrè ìgboyà láti bẹ ẹlẹ́wọ̀n kan wò, àní ní pàtàkì, bí a kò bá tí ì sọ ‘ẹ̀ṣẹ̀’ tí ẹni náà dá ní pàtó.” Òǹkọ̀wé Brian Rapske sọ pé: “Ewú mìíràn tí ó tún wà ni ti níní ìfararora pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú ẹlẹ́wọ̀n náà tàbí fífi àánú hàn sí i tàbí ojú ìwòye rẹ̀. . . . Ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan ṣèèṣì sọ tàbí ìwà tí ó ṣèèṣì hù lè yọrí sí ikú, kì í ṣe fún ẹlẹ́wọ̀n náà nìkan ṣùgbọ́n fún agbọ̀ràndùn rẹ̀ pẹ̀lú.” Ta ni àwọn ará Fílípì yóò rán?
A lè fojú inú wò ó pé irú ìrìn àjò yìí ti lè ru àníyàn àti iyè méjì sókè, ṣùgbọ́n Ẹpafíródítù (kí a má rò pé Ẹpafírásì ti Kólósè ni a ń sọ) múra tán láti ṣe iṣẹ́ líle koko yẹn. Bí a bá ronú lórí orúkọ rẹ̀, tí ó ní Áfíródítù nínú, ó ti lè jẹ́ Kèfèrí tí a yí lọ́kàn padà sí ìsìn Kristẹni—ọmọkùnrin tí àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ olùfọkànsin abo-ọlọ́run ìfẹ́ àti afúnnilọ́mọ. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Fílípì láti dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún ìwà ọ̀làwọ́ wọn, ó tọ́ fún un láti júwe Ẹpafíródítù gẹ́gẹ́ bí “òjíṣẹ́ aṣojú yín àti ìránṣẹ́ ara ẹni fún àìní mi.”—Fílípì 2:25.
Láti inú ohun tí Bíbélì sọ nípa Ẹpafíródítù, a lè lóye pé láìka ìmúratán rẹ̀ láti lo ara rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn yìí fún Pọ́ọ̀lù àti fún ìjọ rẹ̀ tí ó yẹ fún oríyìn sí, Ẹpafíródítù ní irú ìṣòro kan náà tí a lè ní. Ẹ jẹ́ kí a gbé àpẹẹrẹ rẹ̀ yẹ̀ wò.
“Ìránṣẹ́ Ara Ẹni fún Àìní Mi”
A kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n a lè ronú pé àárẹ̀ mú Ẹpafíródítù nígbà tí ó ti ìrìn àjò rẹ̀ dé Róòmù. Ó ṣeé ṣe kí ó ti rìnrìn àjò gba Via Egnatia, ọ̀na Róòmù kan tí ó gba Makedóníà kọjá. Ó ti lè ré òkun Adriatic kọjá sí “gìgísẹ̀” ìyawọlẹ̀ òkun Ítálì, kí ó sì gòkè lọ sí Ọ̀na Ápíà sí Róòmù. Ó jẹ́ ìrìn àjò kan tí ó lè mú kí ó rẹni (1,200 kìlómítà ní àlọ nìkan) tí ó ṣeé ṣe kí ó gbà ju oṣù kan lọ.—Wo àpótí ní ojú ìwé 29.
Ẹ̀mí wo ni Ẹpafíródítù fi bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà? A ti rán an láti ṣe “iṣẹ́ ìsìn ti ara ẹni,” tàbí lei·tour·giʹa, fún Pọ́ọ̀lù. (Fílípì 2:30) Ọ̀rọ Gíríìkì yìí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ tọ́ka sí iṣẹ́ tí aráàlú kan fínnúfíndọ̀ ṣe fún Orílẹ̀-Èdè. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó wá túmọ̀ sí irú iṣẹ́ kan tí Orílẹ̀-Èdè ń fi dandan gbọ̀n béèrè lọ́wọ́ àwọn aráàlú tí wọ́n ti tóótun ní pàtàkì láti ṣe é. Lórí ọ̀nà tí a gbà lo ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Kristẹni ni ọkùnrin kan tí ń ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run àti ènìyàn, lákọ̀ọ́kọ́, nítorí pé ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀, àti èkejì, nítorí pé a fi dandan mú un láti ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ìfẹ́ Kristi mú un lápàpàǹdodo.” Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ wo irú ẹ̀mí títayọ lọ́lá tí Ẹpafíródítù fi hàn!
“Ó Fi Ọkàn Rẹ̀ Wewu”
Ní lílo ọ̀rọ̀ kan tí a yá láti inú èdè tẹ́tẹ́ títa, Pọ́ọ̀lù sọ pé Ẹpafíródítù ti “fi [pa·ra·bo·leu·saʹme·nos] ọkàn rẹ̀ wewu,” tàbí ní òwuuru, “fi” ìwàláàyè rẹ̀ “ta tẹ́tẹ́” fún iṣẹ́ ìsìn Kristi. (Fílípì 2:30) Kò yẹ kí a ronú pé Ẹpafíródítù hùwà òmùgọ̀ rárá; kàkà bẹ́ẹ̀, ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ rẹ̀ kún fún ewu. Òún ha gbìdánwò iṣẹ́ ìrànwọ́ náà ní àkókò tí ojú ọjọ́ kò dára nínú ọdún bí? Òún ha lo ìforítì nínú ìgbìdánwò rẹ̀ láti parí rẹ̀ lẹ́yìn tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn lẹ́nu bí ó ṣe ń bá a bọ̀ bí? Lọ́nà kan ṣá, Ẹpafíródítù “dùbúlẹ̀ àìsàn títí ó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ojú ikú.” Bóyá ó ní in lọ́kàn láti dúró díẹ̀ sí i lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù láti bá a ṣiṣẹ́, nítorí náà ó hàn gbangba pé àpọ́sítélì náà fẹ́ ṣàlàyé ìdí tí Ẹpafíródítù yóò fi tètè padà ju bí a ti retí lọ.—Fílípì 2:27.
Síbẹ̀, Ẹpafíródítù jẹ́ onígboyà tí ó múra tán láti lo ara rẹ̀ láìmọ tara rẹ̀ nìkan láti baà lè mú ìpèsè ìrànwọ́ lọ fún àwọn tí wọ́n ṣaláìní.
A lè bi ara wa pé, ‘Àyè wo ni mo lè lo ara mi dé láti ran àwọn arákùnrin mi nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà ní ipò ìṣòro lọ́wọ́?’ Irú ẹ̀mí ìmúratán bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọ̀ran yàn-bí-o-bá-fẹ́ fún àwọn Kristẹni. Jésù wí pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kíní kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kíní kejì.” (Jòhánù 13:34) Ẹpafíródítù ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ “títí dé ojú ikú.” Nígbà náà, Ẹpafíródítù jẹ́ àpẹẹrẹ ẹnì kan tí ó ní “ẹ̀mí ìrònú” tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Fílípì níṣìírí láti ní. (Fílípì 2:5, 8, 30, Kingdom Interlinear) Àwa yóò ha múra tán láti lọ jìnnà tó bẹ́ẹ̀ yẹn bí?
Síbẹ̀, Ẹpafíródítù sorí kọ́. Èé ṣe?
Ìsoríkọ́ Rẹ̀
Fi ara rẹ sí ipò Ẹpafíródítù. Pọ́ọ̀lù ròyìn pé: “Aáyun ti ń yun ún láti rí gbogbo yín ó sì sorí kọ́ nítorí ẹ gbọ́ pé ó ti dùbúlẹ̀ àìsàn.” (Fílípì 2:26) Ẹpafíródítù mọ̀ pé àwọn arákùnrin nínú ìjọ òun ti gbọ́ pé òún dùbúlẹ̀ àìsàn, kò sì ṣeé ṣe fún òun láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ lọ́nà tí wọ́n retí. Ní tòótọ́, ó lè dà bíi pé Ẹpafíródítù ti túbọ̀ kó àníyàn bá Pọ́ọ̀lù. Ǹjẹ́ oníṣègùn náà Lúùkù, alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ Pọ́ọ̀lù, ti ní láti pa àwọn ọ̀ràn míràn tì láti baà lè tọ́jú Ẹpafíródítù bí?—Fílípì 2:27, 28; Kólósè 4:14.
Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àbáyọrí rẹ̀ ni ó mú Ẹpafíródítù sorí kọ́. Bóyá ó ń rò pé àwọn arákùnrin nínú ìjọ òun yóò máa wo òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò tóótun. Bóyá ó nímọ̀lára pé òún jẹ̀bi, tí “aáyun” àtirí wọn sì ń “yun ún” láti lè mú ìṣòtítọ́ rẹ̀ dá wọn lójú. Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tí ó lágbára, a·de·mo·neʹo, “láti sorí kọ́,” láti ṣàpèjúwe ipò Ẹpafíródítù. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ J. B. Lightfoot ṣe sọ, ọ̀rọ̀ yìí lè túmọ̀ sí “ipò ọkàn pípòrúùru, ọkàn tí kò balẹ̀, ọkàn tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ lápá kan, èyí tí ìdílọ́wọ́ ètò ìṣiṣẹ́ ara, tàbí wàhálà ọpọlọ, bí ẹ̀dùn ọkàn, ìtìjú, ìjákulẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ń mú wá.” Ọ̀nà kan ṣoṣo mìíràn tí a tún ti lo ọ̀rọ̀ yìí nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ní í ṣe pẹ̀lú ìrora gógó Jésù nínú ọgbà Gẹtisémánì.—Mátíù 26:37.
Pọ́ọ̀lù parí èrò sí pé ohun dídára jù lọ láti ṣe ni láti rán Ẹpafíródítù padà sí àwọn ará Fílípì pẹ̀lú lẹ́tà kan tí yóò ṣàlàyé pípadà tí òjíṣẹ́ aṣojú wọn padà dé lójijì. Ní sísọ pé: “Mo kà á sí ohun tí ó pọn dandan láti rán Ẹpafíródítù sí yín,” Pọ́ọ̀lù ń sọ pé òun ni òún ní kí ó padà sọ́dọ̀ wọn, ní títipa báyìí mú ìfura èyíkéyìí tí ó lè dìde pé Ẹpafíródítù ti kùnà kúrò. (Fílípì 2:25) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, Ẹpafíródítù fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdánù ìwàláàyè rẹ̀ láti baà lè parí iṣẹ́ rẹ̀! Pọ́ọ̀lù fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà dábàá pé kí wọ́n ‘fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí àṣà nínú Olúwa pẹ̀lú ìdùnnú ayọ̀ gbogbo; kí wọ́n sì máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n, nítorí pé ní tìtorí iṣẹ́ Olúwa ni ó fi sún mọ́ bèbè ikú, ó fi ọkàn rẹ̀ wewu, kí òun ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ lè dí àlàfo àìsí níhìn-ín yín láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ti ara ẹni fún mi.’—Fílípì 2:29, 30.
“Ẹ Máa Ka Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀ Sí Ẹni Ọ̀wọ́n”
Ó yẹ kí a mọyì àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ní ẹ̀mí ìrònú bíi ti Ẹpafíródítù gidigidi. Wọ́n ń fi ara wọn rúbọ láti baà lè ṣiṣẹ́ sìn. Ronú nípa àwọn tí wọ́n ti yọ̀ọ̀da ara wọn láti ṣiṣẹ́ sìn ní ibi jíjìnnà réré sí ilé, bí àwọn míṣọ́nnárì, àwọn alábòójútó arìnrìn àjò, tàbí ní ọ̀kan lára àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society. Bí ọjọ́ orí tàbí ìlera tí ń jó rẹ̀yìn bá ṣèdíwọ́ fún àwọn kan láti ṣe tó bí wọ́n ṣe ń ṣe nígbà kan, wọ́n yẹ fún ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ àti iyì fún àwọn ọdún iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ti fi ìṣòtítọ́ ṣe.
Síbẹ̀, àìsàn tí ń sọni di hẹ́gẹhẹ̀gẹ lè jẹ́ orísun ìsoríkọ́ tàbí ìmọ̀lára ẹ̀bi. Ẹnì kan yóò fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i. Ẹ wo bí ó ṣe lè bani lọ́kàn jẹ́ tó! Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ara rẹ̀ nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Ẹpafíródítù. Ó ṣe tán, ẹ̀bi rẹ̀ ha ni pé ó dùbúlẹ̀ àìsàn bí? Dájúdájú kì í ṣe ẹ̀bi rẹ̀! (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; Róòmù 5:12) Ẹpafíródítù fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run àti àwọn arákùnrin rẹ̀, ṣùgbọ́n àìsàn dá a lọ́wọ́ kọ́.
Pọ́ọ̀lù kò bá Ẹpafíródítù wí fún ipò ìsoríkọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó sọ fún àwọn ará Fílípì pé kí wọ́n dúró tì í gbágbágbá. Lọ́nà kan náà, ó yẹ kí a tu àwọn arákùnrin wa nínú nígbà tí wọ́n bá sorí kodò. Lọ́pọ̀ ìgbà, a lè gbóríyìn fún wọn fún àpẹẹrẹ iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ti fi ìṣòtítọ́ ṣe. Òtítọ́ náà pé Pọ́ọ̀lù mọyì Ẹpafíródítù, tí ó sì sọ̀rọ̀ rere bẹ́ẹ̀ nípa rẹ̀, gbọ́dọ̀ ti tù ú nínú, kí ó sì dín ìsoríkọ́ rẹ̀ kù. Àwa pẹ̀lú lè ní ìdánilójú pé, ‘Ọlọ́run kì í ṣe àìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tí a fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé a ti ṣe ìránṣẹ́ fún awọn ẹni mímọ́ a sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.’—Hébérù 6:10.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Àìbáradé Ìrìn Àjò Náà
Lónìí, ìrìn àjò láàárín ìlú ńlá méjì ní ilẹ̀ Europe, tí ó fẹ́ dà bí èyí tí Ẹpafíródítù rìn lọ́jọ́sí, lè máà gba aápọn tó bẹ́ẹ̀. A lè fìrọ̀rùn parí ìrìn àjò náà nípasẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú ayára-bí-àṣá kán láàárín wákàtí kan sí méjì. Ó jẹ́ àyíká ipò tí ó yàtọ̀ pátápátá láti rin irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Nígbà náà lọ́hùn-ún, kò bára dé láti rìnrìn àjò láti ibì kan sí ìkejì. Arìnrìn àjò kan tí ń fẹsẹ̀ rìn yóò karí nǹkan bí 30 sí 35 kìlómítà lójúmọ́, ní ṣíṣí ara rẹ̀ payá sí ojú ọjọ́ àti àwọn onírúurú ewu mìíràn, títí kan “àwọn dánàdánà.”—Kọ́ríńtì Kejì 11:26.
Àwọn ibi àdúrósí-di-ilẹ̀ẹ́mọ́ àti ìpèsè àwọn ohun tí a nílò ńkọ́?
Òpìtàn Michelangelo Cagiano de Azevedo ṣàlàyé pé ní òpópónà Róòmù, “àwọn ilé àrójẹ wà, àwọn hòtẹ́ẹ̀lì ńláńlá wà, pẹ̀lú àwọn ilé ìtajà, ilé ìtọ́jú ẹran, àti ilé gbígbé fún àwọn òṣìṣẹ́ wọn; láàárín ilé àrójẹ méjì tí ó tẹ̀ léra, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ilé ìṣàyípadà wà, tàbí ibi ìdúrósí, níbi tí ẹnì kan ti lè pààrọ̀ ẹṣin tàbí ọkọ̀, kí ó sì rí àwọn ohun tí ó nílò rà.” Àwọn ilé àrójẹ yìí kò ní orúkọ rere rárá níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn mẹ̀kúnnù ni ó ń yà níbẹ̀. Yàtọ̀ sí jíja àwọn arìnrìn àjò lólè, àwọn olùtọ́jú ilé àrójẹ tún máa ń mú èrè wọn ga sí i nípa èrè tí wọ́n ń rí lórí àwọn aṣẹ́wó. Akéwì èdè Látìnì abẹnuàtẹ́-lùwà-ìbàjẹ́, Juvenal, sọ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá di dandan fún láti dúró ní irú ilé àrójẹ bẹ́ẹ̀ lè rí ara rẹ̀ “lẹ́gbẹ̀ẹ́ oníwàkiwà kan, láàárín àwọn ọ̀gákọ̀ ojú omi, àwọn olè, àti àwọn ẹrú tí ń sá lọ, lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn afokùnpọ̀daràn àti àwọn akanpósí . . . Ife kan náà ni gbogbo wọn yóò jọ lò; kò sí ẹni tí ó dá bẹ́ẹ̀dì tirẹ̀ ní, tàbí dá tábìlì tirẹ̀ ní yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù.” Àwọn òǹkọ̀wé ìgbàanì kan kédàárò nípa omi burúkú àti àwọn yàrá, tí èrò kún bámúbámú, tí ó dọ̀tí, tí ooru ń bì tì ì níbẹ̀, ti yànmùyánmú sì gba ibẹ̀ kan.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Róòmù
[Àwòrán]
Arìnrìn àjò kan nígbà ayé Róòmù
[Àwọn Credit Line]
Àwòrán ilẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.; Arìnrìn àjò: Da originale del Museo della Civiltà Romana, Roma