Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ìrànwọ́ fún Àwọn Tí ‘Òùngbẹ Ń Gbẹ’ Ní Rọ́ṣíà
JÉSÙ wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn wọnnì tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, níwọ̀n bí a óò ti bọ́ wọn yó.” (Mátíù 5:6) Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí ṣàkàwé bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣèrànwọ́ láti pòùngbẹ àwọn tí òùngbẹ nípa tẹ̀mí ń gbẹ ní Rọ́ṣíà, níbi tí kò ti sí òmìnira ìsìn fún èyí tí ó ju 70 ọdún.
▪ Obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Valentina ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè lórí Bíbélì tí ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, tí kò sì rí ìdáhùn sí i fún ọ̀pọ̀ ọdún. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣe kàyéfì pé: ‘Ta ni Jésù gbàdúrà sí?’ Ó ronú pé, Jésù ti ní láti gbàdúrà sí ẹnì kan tí ó ga ju òun fúnra rẹ̀ lọ, ó sì ń ṣe kàyéfì nípa orúkọ Ẹni yìí.
Ó kàn sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Rọ́ṣíà. Ṣùgbọ́n, kò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀ nínú ìsìn yẹn. Níwọ̀n bí kò ti tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó forí lé ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì, ṣùgbọ́n kò tún rí ìdáhùn tí ó ṣe kedere. Nígbà tí kò mọ ibi tí yóò tún lọ sí, Valentina bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, ní gbígbìyànjú láti rí ìdáhùn fúnra rẹ̀—pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ó gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ilẹ̀kùn rẹ̀. Wọ́n fi hàn án láti inú Bíbélì pé, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó mọ ẹni tí Jésù gbàdúrà sí! Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í fojú ba orun títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, ní kíka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watch Tower Society àti ní yíyẹ àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a yàn sí i wò. Kò pẹ́ kò jìnnà, Valentina pinnu pé òun ti rí òtítọ́. Láàárín oṣù mẹ́ta, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, oṣù méjì lẹ́yìn náà, ó ṣe ìrìbọmi. A san èrè fún bí ó ṣe fi tàdúràtàdúrà wá òtítọ́ kiri.
▪ Ẹlẹ́rìí kan wọ bọ́ọ̀sì láti lọ wàásù ní agbègbè àdádó kan. Nígbà ìrìn àjò náà, ó bá obìnrin kan sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí Bíbélì, ṣùgbọ́n obìnrin náà kò nífẹ̀ẹ́ sí i. Oṣù méjì lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí náà rin ìrìn àjò ẹ̀ẹ̀kejì sí agbègbè kan náà láti sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Lẹ́yìn àsọyé náà, ó tọ àlejò kan lọ, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni ha ti bá ọ sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere láti inú Bíbélì rí bí?” Ọkùnrin náà fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, o ti ṣe bẹ́ẹ̀.” Ẹlẹ́rìí náà rò pé ó ń ṣàwàdà ni. Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin náà ṣàlàyé pé ní oṣù méjì sẹ́yìn, òun fetí kọ́ ìjíròrò tí ń lọ láàárín Ẹlẹ́rìí náà àti obìnrin kan, nígbà ìrìn àjò nínú bọ́ọ̀sì. “Mo fẹ́ mọ̀ púpọ̀ sí i, ṣùgbọ́n o sọ̀kalẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì, mo sì rò pé n kò ní rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ láé. Lẹ́yìn náà, ní ibi iṣẹ́ mi, mo bá ọkùnrin kan pàdé tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Bí mo ṣe débí nìyẹn!”
Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ó rí i pé iṣẹ́ rẹ̀ forí gbárí pẹ̀lú ìlànà Bíbélì. Nítorí pé ó fẹ́ ní ẹ̀rí ọ̀kan rere níwájú Ọlọ́run, ó yí iṣẹ́ rẹ̀ padà. Nísinsìnyí, ó ń lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Aya rẹ̀ pẹ̀lú ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú Bíbélì.
Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní agbègbè ìpínlẹ̀ gbígbòòrò ti Rọ́ṣíà dùn láti nípìn-ín nínú sísọ fún gbogbo ènìyàn olóòótọ́ ọkàn pé: “‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìṣípayá 22:17.