Ẹ Jẹ́ Kí A Kórìíra Ohun Búburú Tẹ̀gàntẹ̀gàn
JÈHÓFÀ jẹ́ Ọlọ́run mímọ́. Ní ìgbàanì, òun ni “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,” ó sì tipa bẹ́ẹ̀ béèrè pé kí Ísírẹ́lì jẹ́ mímọ́, láìléèérí. (Orin Dáfídì 89:18) Ó sọ fún àwọn ènìyàn àyànfẹ́ rẹ̀ pé: “Kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ mímọ́, nítorí pé mímọ́ ni Èmi.” (Léfítíkù 11:45) Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ “gun orí òkè Olúwa lọ” gbọ́dọ̀ “ní ọwọ́ mímọ́, àti àyà funfun.” (Orin Dáfídì 24:3, 4) Ìyẹ́n túmọ̀ sí ju wíwulẹ̀ yẹra fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀. Ó túmọ̀ sí “ìkórìíra ibi.”—Òwe 8:13.
Lọ́nà onífẹ̀ẹ́, Jèhófà gbé àwọn ọ̀rínkinniwín òfin kalẹ̀ kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì baà lè dá ìwà àìtọ́ mọ̀, kí wọ́n sì yẹra fún un. (Róòmù 7:7, 12) Àwọn òfin wọ̀nyí ní àwọn ìlànà tí ó ṣe ṣàkó lórí ìwà híhù nínú. Panṣágà, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, àti ìbẹ́rankolòpọ̀ ni a fi hàn látòkèdélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́ tí ń sọni dèérí nípa tẹ̀mí. (Léfítíkù 18:23; 20:10-17) A ké àwọn tí ó jẹ̀bi irú àwọn ìṣe tí ń rẹni nípò wálẹ̀ bẹ́ẹ̀ kúrò ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.
Nígbà tí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró di “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” a fi àwọn ìlànà ìwà híhù kan náà lélẹ̀ fún wọn. (Gálátíà 6:16) Àwọn Kristẹni pẹ̀lú ní láti “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú.” (Róòmù 12:9) Àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà sí Ísírẹ́lì kan àwọn náà pẹ̀lú: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí tí èmi jẹ́ mímọ́.” (Pétérù Kíní 1:15, 16) Irú àwọn àṣà àìmọ́ bí àgbèrè, panṣágà, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ìbẹ́rankolòpọ̀, àti ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan kò ní láti sọ ìjọ Kristẹni dìbàjẹ́. Àwọn tí wọ́n bá kọ̀ láti ṣíwọ́ lílọ́wọ́ nínú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kì yóò wọ Ìjọba Ọlọ́run. (Róòmù 1:26, 27; 2:22; Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10; Hébérù 13:4) Ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, ìlànà kan náà ni ó kan “àwọn àgùntàn míràn.” (Tímótì Kejì 3:1; Jòhánù 10:16) Ní ìyọrísí rẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn míràn para pọ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn tí ó mọ́ tónítóní, tí wọ́n sì gbámúṣe, tí wọ́n lè jẹ́ orúkọ Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Aísáyà 43:10.
Mímú Kí Ìjọ Wà Ní Mímọ́ Tónítóní
Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ayé fàyè gba gbogbo oríṣi ìwà pálapàla. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀, wọn kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ọ̀pọ̀ tí ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà nísinsìnyí ti fìgbà kan wà nínú ayé rí. Ọ̀pọ̀ wà tí ó jẹ́ pé, kí wọ́n tó mọ Ọlọ́run wa mímọ́, wọn kò rí ìdí tí wọn kò fi ní láti tẹ́ ìfẹ́ ọkàn àti àlá asán ti ẹran ara aláìpé wọn lọ́rùn, ní yíyíràá nínú “kòtò-ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ . . . tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà.” (Pétérù Kíní 4:4) Lẹ́yìn tí ó ti ṣàpèjúwe àwọn àṣà tí ń súni fún ìríra ti àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí a ti rẹ̀ nípò wálẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín . . . ti jẹ́ rí nìyẹn.” Síbẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti sọ pé: “Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—Kọ́ríńtì Kíní 6:11.
Ẹ wo gbólóhùn tí ń tuni nínú tí ìyẹ́n jẹ́! Ohun yòó wù kí ẹnì kan ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìgbésí ayé, ó máa ń yí pa dà nígbà tí ìhìn rere ológo nípa Kristi bá nípa lórí ọkàn àyà rẹ̀. Yóò lo ìgbàgbọ́, yóò sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Láti ìgbà yẹn lọ, yóò máa gbé ìgbésí ayé tí ó mọ́ gaara ní ti ìwà híhù, tí a wẹ̀ mọ́ tónítóní lójú Ọlọ́run. (Hébérù 9:14) A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá tẹ́lẹ̀ jì í, ó sì lè ‘nàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú.’a—Fílípì 3:13, 14; Róòmù 4:7, 8.
Jèhófà dárí ìṣìkàpànìyàn àti panṣágà ji Dáfídì tí ó ronú pìwà dà, Ó sì dárí ìbọ̀rìṣà oníwà-pálapàla àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀ ji Mánásè. (Sámúẹ́lì Kejì 12:9, 13; Kíróníkà Kejì 33:2-6, 10-13) A lè kún fún ìmoore ní tòótọ́ pé ó múra tán láti dárí jì wá pẹ̀lú bí a bá ronú pìwà dà, tí a sì fi òtítọ́ ọkàn àti ìrẹ̀lẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ. Síbẹ̀, láìka dídárí jì tí Jèhófà dárí ji Dáfídì àti Mánásè sí, àwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyí—àti Ísírẹ́lì pẹ̀lú wọn—ní láti nírìírí àbájáde ìgbésẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Sámúẹ́lì Kejì 12:11, 12; Jeremáyà 15:3-5) Lọ́nà kan náà, nígbà tí ó jẹ́ pé Jèhófà ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà, àwọn àbájáde ìgbésẹ̀ wọn lè wà tí kò ní ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn Àbájáde Tí Kò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀
Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tí ó gbé ìgbésí ayé ìwà pálapàla lọ́nà tí ó bùáyà, tí ó sì kó àrùn AIDS lè tẹ́wọ́ gba òtítọ́, kí ó sì yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà dórí ìyàsímímọ́ àti batisí. Nísinsìnyí, ó ti di Kristẹni tí ó mọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí, tí ó ní ipò ìbátan kan pẹ̀lú Ọlọ́run, tí ó sì ní ìrètí àgbàyanu fún ọjọ́ ọ̀la; ṣùgbọ́n ó ṣì ní àrùn AIDS síbẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àrùn náà lè pa á, tí ó jẹ́ àbájáde bíbani nínújẹ́, ṣùgbọ́n tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tí ìwà rẹ̀ àtijọ́ ní. Fún àwọn Kristẹni kan, àbáyọrí ìwà pálapàla bíburú lékenkà tí wọ́n ti hù tẹ́lẹ̀ lè máa bá a nìṣó ní àwọn ọ̀nà míràn. Fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn batisí wọn, bóyá fún ìyókù ìgbésí ayé wọn nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, wọ́n lè ní láti bá àwọn ìrọni nínú ara wọn láti pa dà sí ọ̀nà ìgbésí ayé ìwà pálapàla wọn ti tẹ́lẹ̀ jagun. Nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Jèhófà, ọ̀pọ̀ ṣàṣeyọrí nínú dídènà wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n ní láti máa ja ìjà ogun léraléra.—Gálátíà 5:16, 17.
Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò dẹ́ṣẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ń ṣàkóso ìrọni wọn. Ṣùgbọ́n, bí wọ́n bá jẹ́ ọkùnrin, wọ́n lè fi ọgbọ́n pinnu láti má ṣe “nàgà” fún ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ níwọ̀n bí wọ́n bá ṣì ní láti máa bá ìrusókè lílágbára ní ti ara jìjàkadì. (Tímótì Kíní 3:1) Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n mọ ìgbẹ́kẹ̀lé tí ìjọ ní nínú àwọn alàgbà. (Aísáyà 32:1, 2; Hébérù 13:17) Wọ́n mọ̀ pé a máa ń tọ àwọn alàgbà lọ lórí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀ràn ara ẹni, tí wọ́n sì ní láti bójú tó àwọn ipò ẹlẹgẹ́. Kì yóò fi ìfẹ́, tàbí ọgbọ́n hàn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì yóò lọ́gbọ́n nínú fún ẹnì kan tí ń bá àwọn ìfẹ́ ọkàn àìmọ́ ní ti ẹran ara jagun látìgbàdégbà láti nàgà fún irú ipò ẹrù iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.—Òwe 14:16; Jòhánù 15:12, 13; Róòmù 12:1.
Fún ọkùnrin kan tí ó jẹ́ abọ́mọdélòpọ̀ ṣáájú kí ó tó ṣe batisí, àbájáde mìíràn lè wà. Nígbà tí ó bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, yóò ronú pìwà dà, yóò sì yí pa dà, ní ṣíṣàìmú ẹ̀ṣẹ̀ búburú jáì yẹn wọnú ìjọ. Lẹ́yìn náà, ó lè tẹ̀ síwájú dáradára, ní bíborí ìsúnniṣe rẹ̀ tí kò tọ́ pátápátá, ó sì lè ní ìtẹ̀sí láti “nàgà” fún ipò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Ṣùgbọ́n, bí òkìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí abọ́mọdélòpọ̀ àtijọ́ kò bá tí ì parẹ́ ńkọ́? Òun yóò ha “jẹ́ aláìlẹ́gàn, . . . tí ó ní gbólóhùn ẹ̀rí tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ní òde, . . . [tí] kò . . . sí lábẹ́ ẹ̀sùn”? (Tímótì Kíní 3:1-7, 10; Títù 1:7) Bẹ́ẹ̀ kọ́, òun kì yóò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, òun kì yóò tóótun fún àwọn àǹfààní nínú ìjọ.
Nígbà Tí Kristẹni Olùṣèyàsímímọ́ Bá Dẹ́ṣẹ̀
Jèhófà lóye pé a jẹ́ aláìlera, àti pé lẹ́yìn batisí pàápàá a lè ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ọjọ́ rẹ̀ pé: “Mo ń kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín kí ẹ má baà dá ẹ̀ṣẹ̀ kan. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹnikẹ́ni bá sì dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, àwa ní olùrànlọ́wọ́ kan lọ́dọ̀ Bàbá, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo. Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (Jòhánù Kíní 2:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni, lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù, Jèhófà yóò dárí ji àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ṣe batisí, tí wọ́n ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀—bí wọ́n bá ronú pìwà dà ní tòótọ́, tí wọ́n sì kọ ipa ọ̀nà àìtọ́ wọn sílẹ̀.
A rí àpẹẹrẹ kan nípa èyí nínú ìjọ ọ̀rúndún kìíní ní Kọ́ríńtì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ọ̀ràn àgbèrè láàárín ìbátan nínú ìjọ tuntun yẹn, ó sì pèsè ìtọ́ni pé kí wọ́n yọ ọkùnrin tí ọ̀ràn kàn náà lẹ́gbẹ́. Lẹ́yìn náà, ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà, Pọ́ọ̀lù sì gba ìjọ náà níyànjú láti gbà á pa dà. (Kọ́ríńtì Kíní 5:1, 13; Kọ́ríńtì Kejì 2:5-9) Nípa báyìí, nípasẹ̀ agbára ìwòsàn ìfẹ́ inú rere ti Jèhófà àti ìtóye ńlá ti ẹbọ ìràpadà Jésù, a wẹ ọkùnrin náà mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ lónìí. Ṣùgbọ́n, lẹ́ẹ̀kan sí i, àní bí ẹnì kan tí ó ti ṣe batisí, tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo bá ronú pìwà dà tí Jèhófà sì dárí jì í, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣì lè ní àwọn àbájáde tí ń bá a nìṣó.—Òwe 10:16, 17; Gálátíà 6:7.
Fún àpẹẹrẹ, bí ọ̀dọ́bìnrin kan tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́ bá ṣàgbèrè, ó lè fi ìbìnújẹ́ kábàámọ̀ ìgbésẹ̀ rẹ̀ kí a sì mú un pa dà sí ìlera ti ẹ̀mí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ìjọ. Ṣùgbọ́n bí ó bá lóyún nítorí ìwà pálapàla rẹ̀ ńkọ́? Nígbà náà, ohun tí ó ṣe ti yí gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ọkùnrin kan tí ó ṣe panṣágà lè ronú pìwà dà, a sì lè má yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ṣùgbọ́n alábàá-ṣègbéyàwó rẹ̀ tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ní ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mú láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó sì lè yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 19:9) Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkùnrin náà yóò gbé ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ pẹ̀lú àbájáde búburú jáì tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ní yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti dárí jì í.—Jòhánù Kíní 1:9.
Ọkùnrin tí ó fi àìnífẹ̀ẹ́ kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ láti lè fẹ́ obìnrin mìíràn ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kí ó ronú pìwà dà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, kí a sì gbà á pa dà sínú ìjọ. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó lè tẹ̀ síwájú, ó sì lè “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Hébérù 6:1) Ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí aya rẹ̀ àkọ́kọ́ bá ṣì ń gbé láìní alábàá-ṣègbéyàwó, òun kì yóò tóótun láti ṣiṣẹ́ sìn ní ipò ẹrù iṣẹ́ kan nínú ìjọ. Òun kì í ṣe “ọkọ aya kan” nítorí pé kò ní ìpìlẹ̀ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu láti kọ aya rẹ̀ àkọ́kọ́ sílẹ̀.—Tímótì Kíní 3:2, 12.
Ìwọ̀nyí kò ha jẹ́ ìdí lílágbára tí ó fi yẹ kí Kristẹni kan mú ìkórìíra ohun búburú tẹ̀gàntẹ̀gàn dàgbà bí?
Abọ́mọdé-Ṣèṣekúṣe Ńkọ́?
Bí Kristẹni àgbàlagbà kan tí ó ti ṣe batisí bá bá ọmọdé ṣèṣekúṣe ńkọ́? Ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ha burú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Jèhófà kì yóò fi dárí jì í bí? Kò fi dandan jẹ́ bẹ́ẹ̀. Jésù wí pé ‘ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́’ ni kò ní ìdáríjì. Pọ́ọ̀lù sì wí pé kò sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ fún ẹnì kan tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ ń dá ẹ̀ṣẹ̀, lẹ́yìn tí ó ti mọ òtítọ́. (Lúùkù 12:10; Hébérù 10:26, 27) Ṣùgbọ́n, kò sí ibi tí Bíbélì ti sọ pé Kristẹni àgbàlagbà kan tí ó bá bá ọmọdé ṣèṣekúṣe—bóyá ó jẹ́ láàárín ìbátan tàbí ní ọ̀nà míràn—kò lè ní ìdáríjì. Ní tòótọ́, a lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́ tónítóní bí ó bá ronú pìwà dà tinútinú látọkàn wá, tí ó sì yí ìwà rẹ̀ pa dà. Ṣùgbọ́n, ó ṣì lè ní láti máa bá ìsúnniṣe àìtọ́ nípa ti ara tí ó ti mú dàgbà jìjàkadì. (Éfésù 1:7) Àwọn àbájáde sì lè wà tí òun kò ní lè yẹ̀ sílẹ̀.
Ní sísinmi lórí òfin ilẹ̀ tí ó ń gbé, ó ṣeé ṣe kí abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe náà lọ sẹ́wọ̀n tàbí kí ó dojú kọ àwọn ìjìyà míràn láti ọ̀dọ̀ Ìjọba. Ìjọ kì yóò dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ èyí. Síwájú sí i, ọkùnrin náà tí fi àìlera wíwúwo hàn èyí tí a óò máa ṣírò mọ́ ọ̀ràn rẹ̀ láti ìgbà náà lọ. Bí ó bá dà bí ẹni pé ó ronú pìwà dà, a óò fún un níṣìírí láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, àní láti kópa nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí kò ní kíkọ́ni nínú. Ṣùgbọ́n, èyí kò túmọ̀ sí pé yóò tóótun láti ṣiṣẹ́ sìn ní ipò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Kí ni àwọn ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún èyí?
Ìdí kan ni pé, alàgbà kan gbọ́dọ̀ “kó ara rẹ̀ níjàánu.” (Títù 1:8) Ní tòótọ́, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí ó lè kó ara rẹ̀ níjàánu lọ́nà pípé. (Róòmù 7:21-25) Ṣùgbọ́n Kristẹni àgbàlagbà kan tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́, tí ó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe fi àìlera ti ara tí kò bá ti ẹ̀dá mu hàn. Ìrírí ti fi hàn pé irú àgbàlagbà bẹ́ẹ̀ tún lè bá àwọn ọmọdé mìíràn ṣèṣekúṣe pẹ̀lú. Ní tòótọ́, kì í ṣe gbogbo abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ni ó máa ń tún ẹ̀ṣẹ̀ náà dá, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ìjọ kò sì lè rí ọkàn láti mọ ẹni tí yóò tún bá ọmọdé ṣèṣekúṣe tàbí ẹni tí kì yóò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. (Jeremáyà 17:9) Nítorí náà, ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sí Tímótì fi ìtẹnumọ́ kan ọ̀ràn àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ti ṣe batisí, tí wọ́n sì ti bá ọmọdé ṣèṣekúṣe rí: “Má ṣe fi ìkánjú gbé ọwọ́ rẹ lé ọkùnrin èyíkéyìí láé; bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe jẹ́ alájọpín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn.” (Tímótì Kíní 5:22) Fún ààbò àwọn ọmọ wa, ọkùnrin kan tí a ti mọ̀ pé ó ti jẹ́ abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe kò tóótun fún ipò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Síwájú sí i, òun kò lè jẹ́ aṣáájú ọ̀nà kan, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè ṣiṣẹ́ sìn nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún èyíkéyìí mìíràn.—Fi wé ìlànà tí ó wà nínú Ẹ́kísódù 21:28, 29.
Àwọn kan lè béèrè pé, ‘Àwọn kan kò ha ti dá oríṣi ẹ̀ṣẹ̀ míràn, tí wọ́n sì ronú pìwà dà ní kedere, lẹ́yìn náà, tí wọ́n sì tún dá ẹ̀ṣẹ̀ náà lẹ́ẹ̀kan sí i?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ìyẹ́n ti ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn kókó abájọ mìíràn wà tí a óò gbé yẹ̀ wò. Fún àpẹẹrẹ, bí àgbàlagbà kan bá fi ìwà pálapàla lọ àgbàlagbà míràn, ó yẹ kí àgbàlagbà náà lè dènà ìfilọni rẹ̀. Ó rọrùn gidigidi láti tan àwọn ọmọdé jẹ, láti mú wọn pòrúurùu, tàbí láti dẹ́rù bà wọ́n. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí ọmọdé kò ti ní ọgbọ́n. (Òwe 22:15; Kọ́ríńtì Kíní 13:11) Jésù lo àwọn ọmọdé gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àìmọ̀kan nínú ìrẹ̀lẹ̀. (Mátíù 18:4; Lúùkù 18:16, 17) Ṣíṣàìmọ̀kan tí ọmọdé ṣàìmọ̀kan ní ṣíṣàìnírìírí pátápátá nínú. Ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọdé kì í fi nǹkan pa mọ́, wọ́n máa ń hára gàgà láti tẹ́ni lọ́rùn, wọ́n sì tipa báyìí rọrùn láti di ẹni tí àgbàlagbà tí ń tagbọ́n fún wọn, tí wọ́n mọ̀, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé, lè bá ṣèṣekúṣe. Nítorí náà, ìjọ ní ẹrù iṣẹ́ níwájú Jèhófà láti dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀.
Àwọn ọmọ tí a kọ́ dáradára mọ bí a ti í gbọ́ràn sí òbí wọn, àwọn alàgbà, àti àwọn àgbàlagbà míràn lẹ́nu, àti bí a ti í bọlá fún wọn. (Éfésù 6:1, 2; Tímótì Kíní 5:1, 2; Hébérù 13:7) Yóò jẹ́ ìgbégbòdì tí ń múni gbọ̀n rìrì bí ọ̀kan lára àwọn ẹni pàtàkì wọ̀nyí bá ṣi ìgbẹ́kẹ̀lé tí a ní nínú wọn lò nítorí àìmọ̀kan ọmọdé kan, tí ó sì tàn án tàbí fagbára mú un láti juwọ́ sílẹ̀ fún ìbálòpọ̀. Àwọn tí a ti bá ṣèṣekúṣe lọ́nà yí sábà máa ń jìjàkadì fún ọ̀pọ̀ ọdún láti borí ọgbẹ́ ní ti èrò ìmọ̀lára tí ó jẹ yọ. Nítorí ìdí èyí, irú abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe bẹ́ẹ̀ yẹ fún ìbáwí líle koko àti ìkálọ́wọ́kò gidigidi láti ọ̀dọ̀ ìjọ. Kì í ṣe ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni pàtàkì ni ó ní láti jẹni lógún, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ó jẹ́ ìjẹ́mímọ́ láìlábàwọ́n ìjọ.—Kọ́ríńtì Kíní 5:6; Pétérù Kejì 3:14.
Bí abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, yóò rí ọgbọ́n tí ń bẹ nínú fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Bí òun bá kẹ́kọ̀ọ́ ní tòótọ́ láti kórìíra ohun búburú tẹ̀gàntẹ̀gàn, yóò ka ohun tí ó ṣe sí ohun búburú jáì, yóò sì là kàkà láti dènà títún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dá. (Òwe 8:13; Róòmù 12:9) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, òun dájúdájú, yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìtóbilọ́lá ìfẹ́ Rẹ̀, nítorí èyí tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà, bí òun, ṣì fi lè jọ́sìn Ọlọ́run wa mímọ́, kí ó sì retí láti wà lára àwọn “ẹni ìdúróṣinṣin” tí yóò gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé.—Òwe 2:21.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, May 1, 1996.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà, àwọn àbájáde ìgbésẹ̀ wọn lè wà tí kò ní ṣeé yẹ̀ sílẹ̀