ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 2/15 ojú ìwé 19-20
  • Ìlànà Ìwà Híhù Nínú Ìṣègùn àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìlànà Ìwà Híhù Nínú Ìṣègùn àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìforíkorí
  • Ìtọ́jú àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Laráyé Ń Gba Tiẹ̀ Báyìí
    Jí!—2000
  • Ìgbà Tí Mo Fọ́jú Lojú Mi Tó Là!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀
    Jí!—2003
  • Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀—Àwọn Ènìyàn Ń Mọ Àǹfààní Rẹ̀
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 2/15 ojú ìwé 19-20

Ìlànà Ìwà Híhù Nínú Ìṣègùn àti Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀

ÀWỌN ọdún àìpẹ́ yìí ti rí ìtẹ̀síwájú tí a kò tí ì rí irú rẹ̀ rí nínú ìmọ̀ ìṣègùn. Ṣùgbọ́n, bí a ti ń yanjú àwọn ìṣòro ìṣègùn, àwọn ìtẹ̀síwájú kan ń fa àwọn ìṣòro ìlànà ìwà híhù kan.

Àwọn dókítà ní láti sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí àwọn ẹtì bíi: Nígbà míràn, ó ha yẹ kí a kọ ìtọ́jú ìṣègùn lílágbára sílẹ̀, kí aláìsàn baà lè kú wọ́ọ́rọ́wọ́ bí? Ó ha yẹ kí dókítà fọwọ́ rọ́ ìpinnu aláìsàn kan tì, bí ó bá rò pé ó jẹ́ fún ire aláìsàn náà? Báwo ni ètò ìlera fún gbogbogbòò ṣe lè lọ kárí lọ́gbọọgba, nígbà tí agbára ọ̀pọ̀ ènìyàn kò bá gbé ìtọ́jú tí ó wọ́nwó?

Irú àwọn ọ̀ràn dídíjú bẹ́ẹ̀ ti mú ẹ̀ka ìmọ̀ ìṣègùn kan, tí a ń pè ní, ìlànà ìwà híhù nínú ìṣègùn, wá sójú táyé. A ṣètò ẹ̀ka ìmọ̀ yí láti ran àwọn dókítà àti onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ìṣòro ìlànà ìwà híhù nínú ìwádìí àti ìtẹ̀síwájú ìṣègùn. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìpinnu líle koko jù lọ ti ń wáyé ní àwọn ilé ìwòsàn, ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn ti gbé ìgbìmọ̀ onílànà ìwà híhù nínú ìṣègùn kalẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ náà—tí ó máa ń ní àwọn dókítà àti amòfin nínú—máa ń lọ sí àwọn àpérò lórí ìlànà ìwà híhù nínú ìṣègùn, níbi tí a ti máa ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn ìṣòro ìlànà ìwà híhù nínú ìṣègùn.

Díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí a sábà máa ń gbé dìde nínú àwọn àpérò bẹ́ẹ̀ ni: Dé àyè wo ni ó yẹ kí àwọn dókítà bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀, ní pàtàkì nítorí àwọn ìdí tí ó jẹ mọ́ ti ìsìn? Ó ha yẹ kí dókítà fa ẹ̀jẹ̀ sí aláìsàn lára lòdì sí ìfẹ́ inú aláìsàn náà, bí ó bá jọ bíi pé ìyẹn ni ohun tí ó “dára jù” lọ́nà ìṣègùn bí? Yóò ha bá ìlànà ìwà híhù mu láti ṣe bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ kí aláìsàn agbàtọ́jú náà mọ̀, bíi pé, ‘ohun tí aláìsàn kò mọ̀ kì í pa á lára’?

Láti bójú tó irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ó báa mu wẹ́kú, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn dókítà lóye ojú ìwòye Àwọn Ẹlẹ́rìí dáradára. Ní ìhà tiwọn, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe tán láti ṣàlàyé ìdúró wọn fún àwọn dókítà, ní mímọ̀ pé, kí tọ̀tún tòsì lóye ara wọn yékéyéké lè mú kí wọ́n yẹra fún ìforígbárí.

Ìforíkorí

Ọ̀jọ̀gbọ́n Diego Gracia, ọmọ ilẹ̀ Sípéènì, tí ó jẹ́ abẹnugan nínú ìlànà ìwà híhù nínú ìṣègùn, fẹ́ kí kíláàsì rẹ̀ ní irú ìforíkorí bẹ́ẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n náà sọ pé: “Ó wulẹ̀ tọ̀nà láti fún yín [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ní àǹfààní láti sọ àníyàn yín jáde . . . lójú ìwòye àwọn ìṣòro tí ẹ ti ní ní ti ìfàjẹ̀sínilára.”

Nítorí náà, ní June 5, 1996, a ké sí àwọn mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ aṣojú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí Yunifásítì Complutense ní Madrid, Sípéènì, láti ṣàlàyé ojú ìwòye wọn. Àwọn dókítà bí 40 àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n mìíràn ń bẹ níjokòó.

Lẹ́yìn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣe àlàyé ṣókí, a fún àwùjọ láǹfààní láti béèrè ìbéèrè. Gbogbo àwọn tí ó wà níjokòó ni ó gbà pé, ó yẹ kí aláìsàn tí ó ti dàgbà ní ẹ̀tọ́ láti kọ ìtọ́jú ìṣègùn kan pàtó. Kíláàsì náà tún gbà gbọ́ pé, kò yẹ kí a fa ẹ̀jẹ̀ sí aláìsàn kan lára láìjẹ́ pé ó jọ́hẹn fún gbígba ìtọ́jú náà. Síbẹ̀, àwọn apá kan nínú ìdúró tí Àwọn Ẹlẹ́rìí dì mú ń mú wọn ṣàníyàn.

Ìbéèrè kan ní í ṣe pẹ̀lú owó. Ní àwọn ìgbà míràn, iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ń béèrè fún àwọn irin iṣẹ́ àkànṣe, irú bí iṣẹ́ abẹ ẹlẹ́rọ amútànṣánwá, àti àwọn oògùn olówó gọbọi, bí erythropoietin, tí a ń lò láti mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ara pọ̀ sí i. Dókítà kan ṣe kàyéfì pé, nípa kíkọ ìtọ́jú tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbówó lórí (ẹ̀jẹ̀ irú kan náà), Àwọn Ẹlẹ́rìí lè máa retí pé kí wọ́n jàǹfààní àkànṣe nínú ètò ìlera gbogbogbòò.

Ní gbígbà pé owó jẹ́ kókó kan tí àwọn dókítà ní láti gbé yẹ̀ wò ní tòótọ́, ọ̀kan lára awọn aṣojú Ẹlẹ́rìí náà tọ́ka sí àwọn ìwádìí tí a tẹ̀ jáde, tí ó ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn ìnáwó abẹ́nú tí fífa ẹ̀jẹ̀ irú kan náà síni lára ń náni. Ìwọ̀nyí ní ìnáwó títọ́jú àwọn ìṣòro tí ó wáyé láti inú fífàjẹ̀sínilára nínú, àti ìpàdánù owó tí ń wọlé wá, tí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ ń ṣokùnfà. Ó ṣàyọlò ìwádìí kíkún rẹ́rẹ́ tí a ṣe ní United States, tí ó fi hàn pé, àpò ẹ̀jẹ̀ kan, bí ó tilẹ̀ kọ́kọ́ náni ní 250 dọ́là péré, sábà máa ń náni ní iye tí ó ju 1,300 dọ́là lọ—tí ó fi ìlọ́po márùn-ún ju iye tí ó kọ́kọ́ náni lọ. Nítorí náà, ó tọ́ka sí i pé, nígbà tí a bá gbé gbogbo kókó abájọ yẹ̀ wò, iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ń dínni lówó kù. Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ jù lọ àfikún ìnáwó tí iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ń náni jẹ́ àwọn irin iṣẹ́ tí a lè tún lò.

Ìbéèrè míràn tí ó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ dókítà ní í ṣe pẹ̀lú ìkìmọ́lẹ̀ láti inú ìjọ. Wọ́n ṣe kàyéfì pé, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí Ẹlẹ́rìí kan bá juwọ́ sílẹ̀, tí ó sì gba ẹ̀jẹ̀? Àwọn Ẹlẹ́rìí yóò ha ta á nù lẹ́gbẹ́ bí?

Bí a óò ṣe hùwà pa dà sí i yóò sinmi lórí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an, nítorí rírú òfin Ọlọ́run jẹ́ ọ̀ràn wíwúwo gan-an, ohun kan tí àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò. Àwọn Ẹlẹ́rìí yóò fẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó ti nírìírí onírora ọkàn ti iṣẹ́ abẹ tí ó lè mẹ́mìí lọ, tí ó sì tẹ́wọ́ gba ìfàjẹ̀sínilára. Láìsí àníàní, irú Ẹlẹ́rìí bẹ́ẹ̀ yóò banú jẹ́, yóò sì ṣàníyàn nípa ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìfòyebánilò. Níwọ̀n bí ìfẹ́ ti jẹ́ ìpìlẹ̀ ìsìn Kristẹni, àwọn alàgbà yóò fẹ́ láti lo àánú bí wọ́n ti ń fi ìdúróṣinṣin hàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń rí nínú gbogbo ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́.—Mátíù 9:12, 13; Jòhánù 7:24.

Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìlànà ìwà híhù nínú ìṣègùn, tí ń ṣèbẹ̀wò láti United States, béèrè pé: “Ẹ̀yin kò ha ní tún ìdúró yín lórí ìlànà ìwà híhù gbé yẹ̀ wò láìpẹ́ bí? Àwọn ìsìn míràn ti ṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí.”

A sọ fún un pé, ìdúró Àwọn Ẹlẹ́rìí lórí ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ jẹ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́, kì í ṣe ojú ìwòye ìlànà ìwà híhù, tí a lè máa gbé yẹ̀ wò lóòrèkóòrè. Àṣẹ Bíbélì tí ó ṣe kedere kò fàyè gba ìjuwọ́sílẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Ẹlẹ́rìí kan kì yóò tẹ́wọ́ gba títẹ irú òfin àtọ̀runwá bẹ́ẹ̀ lójú, gẹ́gẹ́ bí òun kì yóò ti tẹ́wọ́ gba gbígbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ìbọ̀rìṣà tàbí àgbèrè.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìmọrírì gidigidi fún ìmúratán àwọn dókítà—bí àwọn tí wọ́n pé jọ sí ibi àpérò ìlànà ìwà híhù nínú ìṣègùn ní Madrid—láti bọ̀wọ̀ fún ìpinnu wọn láti wá àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn, tí ó bá ìdánilójú ìgbàgbọ́ wọn tí a gbé karí Bíbélì mu. Láìsí àníàní, ìlànà ìwà híhù nínú ìṣègùn yóò kó ipa pàtàkì nínú mímú ipò ìbátan láàárín àwọn dókítà àti àwọn aláìsàn sunwọ̀n sí i àti nínú títúbọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìfẹ́ ọkàn aláìsàn.

Gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn pé dókítà olókìkí ará Sípéènì kan sọ, ó yẹ kí àwọn dókítà máa rántí nígbà gbogbo pé “àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò kò pé ní gbogbo ọ̀nà, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń lò ó sì lè já sí pàbó.” Nítorí náà, wọ́n nílò “ìdánilójú pé ìfẹ́ ni a gbọ́dọ̀ fi hàn pàápàá níbi tí òye kò bá lè dé.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́