Ìtànkálẹ̀ Ẹgbẹ́ Arinkinkin-Mọ́lànà
ẸGBẸ́ arinkinkin-mọ́lànà—ní àwọn ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn, èyí wulẹ̀ jẹ́ àjọ ẹlẹ́ni kéréje kan nínú ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ẹ wo bí nǹkan ti yí pa dà tó! Bruce B. Lawrence, akọ̀ròyìn lórí ìsìn, kọ̀wé pé, ní 30 ọdún sẹ́yìn, àwọn díẹ̀ ni ó lè mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé, ní òpin ọ̀rúndún ogún, ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànàa yóò di irú kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì bẹ́ẹ̀ tí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn àti ibùdó ìṣèwádìí yunifásítì yóò máa sọ lásọọ̀yánnu.
Síbẹ̀, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé agbéròyìnjáde nípa ìwọ́de oníwà ipá lójú pópó, ìṣìkàpànìyàn, àjọ àwọn alòdìsí ìṣẹ́yún, ìfọgbọ́ndarí ọ̀ràn ìṣèlú láti ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ tí ń lo agbára ìdarí lórí ìlànà ìjọba, àti dídáná sun àwọn ìwé tí a gbà pé wọ́n kún fún ọ̀rọ̀ òdì ní gbangba wálíà, jẹ́ ìránnilétí léraléra nípa ìgbésẹ̀ àwọn arinkinkin-mọ́lànà. Ìwé agbéròyìnjáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lórí ìṣúnná owó, tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ Ítálì, Mondo Economico, sọ pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ níbi gbogbo ni ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà ti ń “gbéjà koni ní orúkọ Ọlọ́run.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń fi àwọn arinkinkin-mọ́lànà hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣerégèé àti agbawèrèmẹ́sìn, tí wọ́n ń dáná ọ̀tẹ̀, tí wọ́n sì ń darí àwọn ìkọlù akópayàbáni. A ń kó ìdágìrì bá àwọn ènìyàn nítorí ìgbèrú àwọn ẹgbẹ́ bíi Comunione e Liberazione nínú ìsìn Roman Kátólíìkì, Gush Emunim nínú ìsìn àwọn Júù, àti Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan Kristẹni Nínú Ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ti Àríwá America. Èé ṣe tí ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà fi ń tàn kálẹ̀? Kí ní ń sún un ṣiṣẹ́? Ó ha lè jẹ́ “ẹ̀san Ọlọ́run,” gẹ́gẹ́ bí Gilles Kepel, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé, ti sọ bí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Arinkinkin-mọ́lànà jẹ́ ẹnì kan tí ń rọ̀ mọ́ ìlànà àtọwọ́dọ́wọ́, tí ó ti wà tipẹ́, tí ó jẹ́ ti ìsìn láìṣeé tẹ̀ síhìn-ín tàbí sọ́hùn-ún. A óò tú iṣu “ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà” dé ìsàlẹ̀ ìkòkò pátápátá nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Nina Berman/Sipa Press