ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 3/1 ojú ìwé 6-7
  • Ọ̀nà Dídára Jù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Dídára Jù
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ayé Kan Tí Ó Ní Àwọn Ìlànà Tí Ó Mọ́yán Lórí
  • Ẹgbẹ́ Arinkinkin-Mọ́lànà Kí Ni Ó Jẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìjọba Kan Tí Yóò Rọ̀ Mọ́ Àwọn Ìlànà Ọlọ́run
    Jí!—2003
  • Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
    Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
  • Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 3/1 ojú ìwé 6-7

Ọ̀nà Dídára Jù

ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ń ṣàníyàn nípa bí ipò tẹ̀mí nínú ayé ṣe ń yìnrìn àti bí ìwà pálapàla òun àìdánilójú ní ti ìsìn ti gbalé gbòde láwùjọ. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, nígbà míràn, a máa ń pè wọ́n ní arinkinkin-mọ́lànà. Ṣùgbọ́n, ohun tí wọ́n ha jẹ́ nìyẹn bí? Rárá o. Bí wọ́n tilẹ̀ ní ìdánilójú lílágbára ní ti ìsìn, wọn kì í ṣe arinkinkin-mọ́lànà ní ti ọ̀nà tí a ti gbà lo ọ̀rọ̀ náà. Wọn kì í lo agbára ìdarí lórí àwọn aṣáájú òṣèlú láti gbé ojú ìwòye kan pàtó lárugẹ, wọn kì í sì í yíjú sí ìwọ́de àti ìwà ipá lòdì sí àwọn tí wọn kò bá jọ fohùn ṣọ̀kan. Wọ́n ti rí ọ̀nà dídára jù. Wọ́n ń fara wé Aṣáájú wọn, Jésù Kristi.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ dájú pé, òtítọ́ ní ti ìsìn ń bẹ, inú Bíbélì sì ni ó wà. (Jòhánù 8:32; 17:17) Ṣùgbọ́n, Bíbélì ń kọ́ àwọn Kristẹni láti jẹ́ onínú rere, ẹni rere, oníwà tútù, àti afòyebánilò—àwọn ànímọ́ tí kò fàyè gba ìgbawèrèmẹ́sìn. (Gálátíà 5:22, 23; Fílípì 4:5) Nínú ìwé Jákọ́bù nínú Bíbélì, a fún àwọn Kristẹni níṣìírí láti kọ́ “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè,” èyí tí a ṣàpèjúwe pé ó “kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere.” Jákọ́bù fi kún un pé: “Èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn wọnnì tí ń wá àlàáfíà.”—Jákọ́bù 3:17, 18.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rántí pé, Jésù ṣàníyàn gidigidi nípa òtítọ́. Ó sọ fún Pọ́ńtíù Pílátù pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Bí òun tilẹ̀ jẹ́ ògbójúgbóyà alágbàwí fún òtítọ́, kò wá ọ̀nà láti gbé ìdánilójú rẹ̀ karí àwọn ẹlòmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mú wọn ronú jinlẹ̀, ó sì ru ọkàn àyà wọn sókè. Ó mọ̀ pé Bàbá òun tí ń bẹ ní ọ̀run, Ọlọ́run “rere àti dídúróṣinṣin,” yóò pinnu bí ohun yóò ṣe mú èké àti àìṣèdájọ́ òdodo kúrò lórí ilẹ̀ ayé àti ìgbà tí òun yóò ṣe é. (Orin Dáfídì 25:8) Nítorí náà, òun kò wá ọ̀nà láti sọ àwọn tí kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ di àfẹ́kù. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ agbélànàrù, ni wọ́n gbìyànjú láti sọ Jésù di àfẹ́kù.—Jòhánù 19:5, 6.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìdánilójú lílágbára nípa ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìsìn, wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà tí ó mọ́yán lórí hàn nínú ọ̀ràn ìwà rere. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó dá wọn lójú pé, “Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan,” ní ń bẹ. (Éfésù 4:5) Wọ́n tún sọ nípa ọ̀rọ̀ Jésù náà pé: “Tóóró ni ẹnubodè náà àti híhá ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sínú ìyè, ìwọ̀nba díẹ̀ sì ni àwọn ẹni tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Síbẹ̀, wọn kò gbìyànjú láti fipá mú àwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀ lé ìgbàgbọ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fara wé Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì ń ‘bẹ’ gbogbo àwọn ti wọ́n ń fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ láti “pa dà bá Ọlọ́run rẹ́.” (Kọ́ríńtì Kejì 5:20) Ọ̀nà dídára jù nìyí. Ó jẹ́ ọ̀nà Ọlọ́run.

Ìrinkinkin-mọ́lànà ìsìn, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń lo ọ̀rọ̀ náà lónìí, yàtọ̀ pátápátá. Àwọn arinkinkin-mọ́lànà ń lo ọ̀pọ̀ ìwéwèé àfìṣọ́raṣe—títí kan ìwà ipá—láti gbé àwọn ìlànà wọn karí àwùjọ. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n di apá pàtàkì nínú ètò ìṣèlú. Ṣùgbọ́n, Jésù wí pé, àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò ní láti jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19; 17:16; Jákọ́bù 4:4) Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ aláìdásí-tọ̀tún-tòsì rárá nínú awuyewuye ìṣèlú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde ti ilẹ̀ Ítálì náà, Fuoripagina, sì ṣe sọ ọ́, wọn “kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti ṣe ohunkóhun; olúkúlùkù lómìnira láti gba ohun tí wọ́n bá sọ tàbí kí wọ́n kọ̀ ọ́.” Kí ni èyí ti yọrí sí? Ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà láti inú Bíbélì tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń sọ, ń fa àwọn onírúurú ènìyàn mọ́ra, títí kan àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ arinkinkin-mọ́lànà pàápàá.—Aísáyà 2:2, 3.

Ayé Kan Tí Ó Ní Àwọn Ìlànà Tí Ó Mọ́yán Lórí

Àwọn Ẹlẹ́rìí mọ̀ pé, ẹ̀dá ènìyàn kò lè yanjú àwọn ìṣòro tí ó jẹ mọ́ àwọn arinkinkin-mọ́lànà. O kò lè fipá mú ẹnì kan láti gba Ọlọ́run gbọ́ tàbí láti tẹ́wọ́ gba àwọn ìgbàgbọ́ tìrẹ. Ríronú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe yọrí sí díẹ̀ nínú àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ jù lọ nínú ìtàn, irú bí àwọn Ogun Ìsìn, Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ sànmánì agbedeméjì, àti “ìyílọ́kànpadà” ti àwọn Àmẹ́ríńdíà. Ṣùgbọ́n, bí o bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ìwọ yóò múra tán láti fi ọ̀ràn lé e lọ́wọ́.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì sọ, Ọlọ́run ti fòté lé àkókò tí òun yóò fi fàyè gba kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn máa rú òfin òun, kí wọ́n sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fa ìyà àti ìrora. Àkókò yẹn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán báyìí. Ní báyìí, Jésù ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba nínú Ìjọba Ọlọ́run ti òkè ọ̀run, láìpẹ́, Ìjọba yẹn yóò gbégbèésẹ̀ láti mú àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn kúrò, kí ó sì tẹ́wọ́ gba ṣíṣàkóso aráyé lójoojúmọ́. (Mátíù 24:3-14; Ìṣípayá 11:15, 18) Ìyọrísí rẹ̀ yóò jẹ́ párádísè kárí ayé, èyí tí àlàáfíà àti òdodo yóò wà nínú rẹ̀ ní yanturu. Ní àkókò yẹn, kò ní sí àìdánilójú nípa bí ó ṣe yẹ kí a jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ mọ́. “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” (Orin Dáfídì 37:29) Irú àwọn ìlànà ayérayé bẹ́ẹ̀ bí inú rere ìfẹ́, òtítọ́, ìdájọ́ òdodo, àti ìwà rere yóò lékè, fún ire aráyé onígbọràn.

Ní fífojúsọ́nà fún àkókò yẹn, onísáàmù náà fi ewì sọ pé: “Àánú àti òtítọ́ pàdéra; òdodo àti àlàáfíà ti fi ẹnu ko ara wọn ní ẹnu. Òtítọ́ yóò rú jáde láti ilẹ̀ wá: òdodo yóò sì bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá. Ní tòótọ́, Olúwa yóò fúnni ní èyí tí ó dára; ilẹ̀ yóò sì máa mú àsunkún rẹ̀ wá. Òdodo yóò ṣáájú rẹ̀; yóò sì fi ipasẹ̀ rẹ̀ ṣe ọ̀nà.”—Orin Dáfídì 85:10-13.

Bí a kò tilẹ̀ lè yí ayé pa dà, lónìí pàápàá, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè kọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run. Nípa báyìí, a lè gbìyànjú láti jẹ́ irú ẹni tí Ọlọ́run yóò fẹ́ kí ó jọ́sìn òun nínú ayé tuntun yẹn. Nígbà náà, a óò wà lára àwọn ọlọ́kàn tútù tí onísáàmù náà tọ́ka sí pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” (Orin Dáfídì 37:11) Ọlọ́run ń ran àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì ń bù kún wọn, ó sì ṣèlérí àwọn ohun àgbàyanu fún ọjọ́ ọ̀la wọn. Àpọ́sítélì Jòhánù wí pé: “Ayé ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—Jòhánù Kíní 2:17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ké sí gbogbo ènìyàn láti mọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]

Fìtílà tí ó wà ní ojú ìwé 3, 4, 5, àti 6: Printer’s Ornaments/láti ọwọ́ Carol Belanger Grafton/Dover Publications, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́