Ẹgbẹ́ Arinkinkin-Mọ́lànà Kí Ni Ó Jẹ́?
IBO ni ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà ti bẹ̀rẹ̀? Ní òpin ọ̀rúndún tí ó kọjá, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tí wọ́n jẹ́ olójú ìwòye gbígbòòrò ń yí ìgbàgbọ́ wọn pa dà láti fàyè gba ṣíṣe lámèyítọ́ Bíbélì àti àwọn àbá èrò orí tí ó jẹ́ ti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, irú bí ẹfolúṣọ̀n. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ìgbọ́kànlé àwọn ènìyàn nínú Bíbélì mì. Àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n jẹ́ arọ̀mọ́pìlẹ̀ ní United States hùwà pa dà nípa gbígbé ohun tí wọ́n pè ní àwọn ìlànà àrinkinkinmọ́ ní ti ìgbàgbọ́ kalẹ̀.a Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, wọ́n tẹ ìjíròrò kan jáde nípa àwọn ìlànà àrinkinkinmọ́ wọ̀nyí nínú ọ̀wọ́ àwọn ìdìpọ̀ tí wọ́n pè ní, The Fundamentals: A Testimony to the Truth (Àwọn Ìlànà Àrinkinkinmọ́: Ẹ̀rí sí Òtítọ́). Láti inú àkọlé yìí ni ọ̀rọ̀ náà “ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà” ti jáde.
Ní apá ìlàjì àkọ́kọ́ ti ọ̀rúndún ogún, ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà di kókó ọ̀rọ̀ ìjíròrò látìgbàdégbà. Fún àpẹẹrẹ, ní 1925, àwọn arinkinkin-mọ́lànà tí wọ́n jẹ́ onísìn wọ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Scopes, tí ń gbé ní Tennessee, U.S.A., lọ sí kóòtù fún ohun tí a wá mọ̀ sí ìgbẹ́jọ́ Scopes. Ọ̀ràn wo ni ó dá? Ó ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ìyẹn sì lòdì sí òfin ìpínlẹ̀ náà. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn kan gbà gbọ́ pé ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà kò lè tọ́jọ́. Ní 1926, Christian Century, ìwé ìròyìn Pùròtẹ́sítáǹtì kan, wí pé, “ohun tí kò nítumọ̀ rárá, tí ó jẹ́ ẹ̀tàn” ni ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà jẹ́, “kò sì ní àmì kíkẹ́sẹjárí kan pàtó tàbí pé yóò lè tọ́jọ́.” Ẹ wo bí èrò yẹn ti kùnà tó!
Láti àwọn ọdún 1970, ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà ti fìgbà gbogbo jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ ìjíròrò. Ọ̀jọ̀gbọ́n Miroslav Volf, ti Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Àlùfáà Ní Kíkún, ní California, U.S.A., sọ pé: “Kì í ṣe pé ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà ti tọ́jọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.” Lónìí, kì í ṣe àwọn àjọ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì nìkan ni a ń lo ọ̀rọ̀ náà “ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà” fún, ṣùgbọ́n a tún ń lò ó fún àjọ tí ń bẹ nínú àwọn ẹ̀sìn míràn, irú bíi ti ẹ̀sìn Kátólíìkì, ẹ̀sìn Ìsìláàmù, ẹ̀sìn àwọn Júù, àti ẹ̀sìn Híńdù.
Ó Jẹ́ Ìhùwàpadà sí Àkókò Wa
Èé ṣe tí ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà fi ń tàn kálẹ̀? Àwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ sọ pé, lọ́nà kan, àìdánilójú ní ti ìwà rere àti ìsìn ní àkókò wa ni ó fà á. Ní àwọn ọdún ìjímìjí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwùjọ ń gbé ní àyíká tí ó ní ìdánilójú ní ti ìwà rere tí a gbé karí ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́. Wàyí o, a ti gbé ìbéèrè dìde sí àwọn ìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn tàbí kí a sọ pé a ti pa wọ́n tì. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀dá olóye fi ìtẹnumọ́ kéde pé, Ọlọ́run kò sí àti pé, ènìyàn nìkan ni ó dá wà nínú àgbáálá ayé aláìbìkítà. Ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kọ́ni pé, aráyé jẹ́ àbájáde èèṣì ẹfolúṣọ̀n, kì í ṣe ìgbésẹ̀ Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́. Ẹ̀mí ìrònú onígbọ̀jẹ̀gẹ́ ń gbalé gbòde. Ìlànà ìwà rere tí ń dín kù sí i ń jẹ ayé níyà ní gbogbo ìpele àwùjọ.—Tímótì Kejì 3:4, 5, 13.
Àwọn arinkinkin-mọ́lànà ń yán hànhàn fún àwọn ìdánilójú ti àtijọ́, àwọn kan lára wọn sì ń tiraka láti mú kí àwùjọ àti orílẹ̀-èdè wọn pa dà sí ohun tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ìpìlẹ̀ ìwà rere àti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́. Wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí ó wà níkàáwọ́ wọn láti fipá mú àwọn ẹlòmíràn láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin ìwà rere “tí ó tọ́” àti ètò ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́. Arinkinkin-mọ́lànà máa ń ní ìdánilójú gidigidi pé, òun tọ̀nà, àwọn yòó kù sì kùnà. Ọ̀jọ̀gbọ́n James Barr, nínú ìwé rẹ̀, Fundamentalism, sọ pé ọ̀rọ̀ náà, ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà “ni a sábà máa ń kà sí ọ̀rọ̀ àtakò àti ẹ̀gàn gbáà, tí ń ṣàfihàn ojú ìwòye tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, tí kì í gba ti ẹlòmíràn rò, tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí ìrakaka lé ìmọ̀ àti ojú ìwòye tèmi lọ̀gá.”
Níwọ̀n bí kò ti sí ẹnì kan tí yóò fẹ́ kí a pe òun ní olójú ìwòye tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, aláìgbatẹnirò, tàbí olójú ìwòye tèmi lọ̀gá, gbogbo ènìyàn kò fohùn ṣọ̀kan nípa ẹni tí a lè pè ní arinkinkin-mọ́lànà tàbí ẹni tí a kò lè pè bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn apá kan pàtó wà tí a fi ń dá ìrinkinkin-mọ́lànà ìsìn mọ̀.
Dídá Arinkinkin-Mọ́lànà Mọ̀
Ìrinkinkin-mọ́lànà ìsìn sábà máa ń jẹ́ ìgbìdánwò láti má ṣe jẹ́ kí ohun tí a gbà gbọ́ pé ó jẹ́ ojúlówó àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tàbí ìgbàgbọ́ ìsìn ti ẹgbẹ́ àwùjọ kan pa run àti láti ta ko ohun tí a wòye pé ó jẹ́ ẹ̀mí ayé. Ìyẹn kì í ṣe láti sọ pé àwọn arinkinkin-mọ́lànà ta ko gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti òde òní. Àwọn kan ń lo ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ti òde òní lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti gbé ojú ìwòye wọn lárugẹ. Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbógun dìde sí ìsọditayé ní ti ẹgbẹ́ àwùjọ.b
Kì í ṣe kìkì pé àwọn kan tí wọ́n jẹ́ arinkinkin-mọ́lànà pinnu láti má ṣe jẹ́ kí ìgbékalẹ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tàbí ọ̀nà ìgbésí ayé kan pa run ni, ṣùgbọ́n, wọ́n tún ń gbé èyí ka àwọn ẹlòmíràn lórí, láti yí ìgbékalẹ̀ àwùjọ pa dà kí ó baà lè bá ìgbàgbọ́ àwọn arinrinkin-mọ́lànà mu. Nítorí náà, arinkinkin-mọ́lànà tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, kò ní fi ara rẹ̀ mọ sórí títako ìṣẹ́yún. Ó ṣeé ṣe kí ó lo agbára ìdarí lórí àwọn aṣòfin orílẹ̀-èdè rẹ̀ láti gbé àwọn òfin tí ó ka ìṣẹ́yún léèwọ̀ dìde. Ní Poland, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé agbéròyìnjáde náà, La Repubblica sọ, kí a baà lè fọwọ́ sí òfin tí ó lòdì sí ìṣẹ́yún, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti gbé “ogun” dìde “nínú èyí tí ó ti lo gbogbo agbára àti ipò rẹ̀.” Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì náà ń hùwà bí àwọn arinkinkin-mọ́lànà gẹ́lẹ́. Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan Kristẹni ti Pùròtẹ́sítáǹtì ní United States ja irú “ogun” kan náà.
Ní pàtàkì, a ń fi ìdánilójú wọn jíjinlẹ̀ ní ti ìsìn dá àwọn arinkinkin-mọ́lànà mọ̀. Nípa báyìí, arinkinkin-mọ́lànà kan, tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì yóò jẹ́ alágbàwí tí ó ní ìdánilójú ní ti fífún Bíbélì ní ìtumọ̀ òwuuru, ó ṣeé ṣe kí ó wé mọ́ ìgbàgbọ́ náà pé, ọjọ́ mẹ́fà ní ti gidi ni a fi dá ilẹ̀ ayé. Arinkinkin-mọ́lànà kan, tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kì í ṣiyè méjì kankan nípa jíjẹ́ tí póòpù jẹ́ aláìlèṣàṣìṣe.
Nígbà náà, a lè lóye ìdí tí ọ̀rọ̀ náà, “ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà,” fi gbé èrò agbawèrèmẹ́sìn yọ àti ìdí tí ara àwọn tí kì í ṣe arinkinkin-mọ́lànà kì í fi í balẹ̀, nígbà tí wọ́n bá rí i tí ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà ń tàn kálẹ̀. Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a lè ṣàìfohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn arinkinkin-mọ́lànà, kí ìfọgbọ́ndarí ọ̀ràn wọn ní ti ìṣèlú àti nígbà míràn, àwọn ìgbésẹ̀ oníwà ipá wọn, mú wa gbọ̀n rìrì. Ní tòótọ́, jìnnìjìnnì lè bá àwọn arinkinkin-mọ́lànà tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìsìn kan nítorí ìgbésẹ̀ àwọn arinkinkin-mọ́lànà tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìsìn míràn! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn onílàákàyè ni wọ́n ń ṣàníyàn nípa ohun tí ń súnná sí ìtànkálẹ̀ ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà—ìwà ìbàjẹ́ tí ń gogò sí i, àìnígbàgbọ́, àti pípa ohun tẹ̀mí tì láwùjọ òde òní.
Ìrinkinkin-mọ́lànà nìkan ha ni ojútùú sí àwọn ìtẹ̀sí wọ̀nyí bí? Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀nà míràn wo ni a lè gbé e gbà?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Kókó Márùn-ún ti Ẹgbẹ́ Arinkinkin-Mọ́lànà, gẹ́gẹ́ bí a ti sábà máa ń pè é, tí a túmọ̀ ní 1895, ni “(1) jíjẹ́ tí Ìwé Mímọ́ jẹ́ ìwé onímìísí látòkè délẹ̀, tí kò sì ní àṣìṣe kankan; (2) jíjẹ́ tí Jésù Kristi jẹ́ Ọlọ́run; (3) ìbí Kristi nípasẹ̀ wúńdíá; (4) ètùtù àfidípò tí Kristi ṣe lórí àgbélébùú; (5) àjíǹde sí ipò ẹlẹ́ran ara àti bíbọ̀ Kristi sí orí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan àti lọ́nà tí yóò ṣeé fojú rí.”—Studi di teologia (Ẹ̀kọ́ Nípa Ìsìn).
b “Ìsọditayé” túmọ̀ sí títẹnumọ́ ohun ti ayé, dípò ohun ti ẹ̀mí tàbí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀. Ohun ti ayé kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìsìn tàbí ìgbàgbọ́ ìsìn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ní 1926 ìwé ìròyìn Pùròtẹ́sítáǹtì kan ṣàpèjúwe ẹgbẹ́ arinkinkin-mọ́lànà gẹ́gẹ́ bí ‘ohun tí kò nítumọ̀ rárá, tí ó sì jẹ́ ẹ̀tàn’ tí ‘kò sì ní àmì kíkẹ́sẹjárí kan pàtó rárá tàbí pé yóò lè tọ́jọ́’