ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 12/15 ojú ìwé 11-16
  • Líla “Ọjọ́ Jèhófà” Já

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Líla “Ọjọ́ Jèhófà” Já
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Gbégbèésẹ̀ ní Àwọn Ọjọ́ Nóà
  • Ìyà Ìdájọ́ Jèhófà Lórí Sódómù àti Gòmórà
  • Ísírẹ́lì Ká “Ààjà”
  • Ìdájọ́ Jèhófà Lórí Júdà Apẹ̀yìndà
  • “Ìpọ́njú Ńlá” ti Ọ̀rúndún Kìíní
  • A Pa Wọn Mọ́ Láàyè La Ìpọ́njú Ńlá Já
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ṣe Ìpolongo ní Gbangba fún Ìgbàlà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àkókò Yìí Gan-an Ló Yẹ Ká Máa Ṣọ́nà Ju Ti Tẹ́lẹ̀ Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìwọ Ha Wà ní Sẹpẹ́ De Ọjọ́ Jèhófà Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 12/15 ojú ìwé 11-16

Líla “Ọjọ́ Jèhófà” Já

“Ọjọ́ Jèhófà tóbi, ó sì jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù gan-an, ta sì ni ó lè dúró lábẹ́ rẹ̀?”—JÓẸ́LÌ 2:11, NW.

1. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ‘ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà’ jẹ́ àkókò ayọ̀?

“AMÚNIKÚN-FÚN-Ẹ̀RÙ”! Bí Jóẹ́lì, wòlíì Ọlọ́run, ṣe ṣàpèjúwe ‘ọjọ́ ńlá Jèhófà’ nìyẹn. Ṣùgbọ́n, kò sí ìdí fún àwa tí a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí a sì ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní yíya ara wa sí mímọ́ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù láti máa gbọ̀n jìnnìjìnnì bí ọjọ́ Jèhófà ti ń sún mọ́lé. Yóò jẹ́ ọjọ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ní tòótọ́, ṣùgbọ́n yóò tún jẹ́ ọjọ́ ìgbàlà kíkọyọyọ, ọjọ́ ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú kan, tí ó ti pọ́n aráyé lójú fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Ní ìfojúsọ́nà fún ọjọ́ yẹn, Jóẹ́lì sọ pé kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run “kún fún ìdùnnú, kí [wọ́n] sì máa yọ̀; nítorí Jèhófà yóò ṣe ohun ńlá,” ó sì fi ìdánilójú yìí kún un pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” Nígbà náà, nínú ìṣètò Ìjọba Ọlọ́run, “àwọn tí ó sá àsálà yóò wà . . . , gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ, àti lára àwọn olùlàájá, àwọn tí Jèhófà ń pè.”—Jóẹ́lì 2:11, 21, 22, 32, NW.

2. Nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ, kí ní ṣẹlẹ̀ (a) ní “ọjọ́ Olúwa” (b) ní “ọjọ́ Jèhófà”?

2 Kò yẹ kí a fi ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà pe “ọjọ́ Olúwa” inú Ìṣípayá 1:10. Ọjọ́ tí a sọ ṣìkejì yí ní ìmúṣẹ àwọn ìran 16 tí a ṣàpèjúwe nínú Ìṣípayá orí 1 sí 22 nínú. Ó ní àkókò ìmúṣẹ gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn sí ìbéèrè àwọn ọmọ ẹ̀yín rẹ̀ náà pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?” nínú. Lórí ilẹ̀ ayé, ‘ogun, ìyàn, ìkórìíra, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ìwà àìlófin,’ tí ń bani lẹ́rù, ni ó jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín Jésù ní ọ̀run. Bí àwọn ìbànújẹ́ wọ̀nyí ti peléke sí i, Jésù ti pèsè ìtùnú fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run nípa rírán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ òde òní jáde láti wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí òtéńté ọjọ́ Olúwa, “òpin” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà, yóò dé. (Mátíù 24:3-14; Lúùkù 21:11) Ìyẹn yóò jẹ́ ọjọ́ Jèhófà fún mímú ìdájọ́ yíyára kánkán ṣẹ sórí ayé oníbàjẹ́ ti Sátánì. “Àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì: ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Jóẹ́lì 3:16.

Jèhófà Gbégbèésẹ̀ ní Àwọn Ọjọ́ Nóà

3. Báwo ni àwọn ipò nǹkan lónìí ṣe bá ti ọjọ́ Nóà mu?

3 Àwọn ipò ayé lónìí bára dọ́gba pẹ̀lú ti “àwọn ọjọ́ Nóà” ní èyí tí ó lé ní 4,000 ọdún sẹ́yìn. (Lúùkù 17:26, 27) A kà ní Jẹ́nẹ́sísì 6:5 pé: “Ọlọ́run sì rí i pé ìwà búburú ènìyàn di púpọ̀ ní ayé, àti pé gbogbo ìrò ọkàn rẹ̀ kìkì ibi ni lójoojúmọ́.” Ẹ wo bí ó ti dàbí ayé tí a ń gbé lónìí tó! Ìwà búburú, ìwọra, àti àìnífẹ̀ẹ́ pọ̀ níbi gbogbo. Nígbà míràn, a lè rò pé aráyé tí dépẹ̀kun ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àsọtẹ́lẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ṣì ń bá a lọ láti nímùúṣẹ: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà a óò sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.”—Tímótì Kejì 3:1, 13.

4. Ipa wo ni ìsìn èké ní nígbà ìjímìjí?

4 Ṣé ìsìn ì bá mú ìtura wá fún aráyé ní ọjọ́ Nóà? Rárá o, ìsìn apẹ̀yìndà irú èyí tí ó wà nígbà náà ì bá ti dákún ipò ìbàjẹ́ náà gidigidi. Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀kọ́ èké “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì.” Ní ìran kejì láti ọ̀dọ̀ Ádámù, “àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe orúkọ OLÚWA,” èyí tí ó ṣe kedere pé ó jẹ́ lọ́nà ìsọ̀rọ̀ òdì. (Ìṣípayá 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:3-6; 4:26) Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀, tí wọ́n pa ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé sí Ọlọ́run tì, gbé àwọ̀ ènìyàn wọ̀, kí wọ́n lè ní ìbálòpọ̀ atàpásófin pẹ̀lú àwọn arẹwà ọmọbìnrin ènìyàn. Àwọn obìnrin wọ̀nyí bí àwọn àdàmọ̀dì òmìrán, tí a pè ní Néfílímù, tí wọ́n pọ́n ìran ènìyàn lójú, tí wọ́n sì bú mọ́ wọn. Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí èṣù yí, ‘olúkúlùkù ènìyàn ba ìwà rẹ̀ jẹ́ ní ayé.’—Jẹ́nẹ́sísì 6:1-12.

5. Ní títọ́kasí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ Nóà, ìkìlọ̀ agbaniníyànjú wo ni Jésù fún wa?

5 Ṣùgbọ́n, ìdílé kan pa ìwà títọ́ mọ́ sí Jèhófà. Nítorí náà, Ọlọ́run “pa Nóà, oníwàásù òdodo, mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (Pétérù Kejì 2:5) Àkúnya Omi yẹn ṣàpẹẹrẹ ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà, tí yóò sàmì sí òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí, tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn kò sí ẹnì kan tí ó mọ̀, kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì àwọn ọ̀run tàbí Ọmọkùnrin, bí kò ṣe Bàbá nìkan. Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní àwọn ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ náà tí Nóà wọ inú ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:36-39) A wà nínú ipò kan náà lónìí, nítorí náà, Jésù gbà wá níyànjú láti ‘kíyè sí ara wa, kí a sì máa wà lójúfò, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà kí a lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀.’—Lúùkù 21:34-36.

Ìyà Ìdájọ́ Jèhófà Lórí Sódómù àti Gòmórà

6, 7. (a) Kí ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ Lọ́ọ̀tì ṣàpẹẹrẹ? (b) Ìkìlọ̀ ṣíṣe kedere wo ni èyí pèsè fún wa?

6 Ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn Ìkún Omi náà, nígbà tí àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà ti bí sí i lórí ilẹ̀ ayé, Ábúráhámù olùṣòtítọ́ àti Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí sí ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà míràn. Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ gbé ní ìlú Sódómù. Ìlú yìí àti Gòmórà, tí ó wà nítòsí rẹ̀, ti di èyí tí ó kún fún ìwà pálapàla rírínilára. Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì pẹ̀lú jẹ́ góńgó àníyàn wọn, tí ó nípa lórí aya Lọ́ọ̀tì pàápàá nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Jèhófà ti sọ fún Ábúráhámù pé: “Igbe Sódómù òun Gòmórà pọ̀, àti nítorí tí ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n pàpọ̀jù.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20) Ábúráhámù rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà láti dá àwọn ìlú náà sí nítorí àwọn olódodo tí ń bẹ nínú wọn, ṣùgbọ́n Jèhófà sọ kedere pé òun kò lè rí àní olódodo mẹ́wàá níbẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ran Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì lọ́wọ́ láti sá àsálà lọ sí ìlú Sóárì tí ó wà nítòsí.

7 Kí ní ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e? Ní fífi “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wa wé ti Lọ́ọ̀tì, Lúùkù 17:28-30 ròyìn pé: “Bákan náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Lọ́ọ̀tì: wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Sódómù òjò iná àti imí ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run ó sì pa gbogbo wọn run. Bákan náà ni yóò rí ní ọjọ́ náà nígbà tí a óò ṣí Ọmọkùnrin ènìyàn payá.” Àbájáde búburú tí ó dé bá Sódómù àti Gòmórà ní ọjọ́ ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ Jèhófà yẹn jẹ́ kìlọ̀kìlọ̀ ṣíṣe kedere fún wa ní àkókò wíwàníhìn-ín Jésù yí. Ìran ènìyàn òde òní pẹ̀lú ti “ṣe àgbèrè lọ́nà tí ó pọ̀ lápọ̀jù tí wọ́n sì ti jáde tọ ẹran ara lẹ́yìn fún ìlò tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá.” (Júúdà 7) Síwájú sí i, àṣà ìwà pálapàla ọjọ́ wa ni ó fa ọ̀pọ̀ “àjàkálẹ̀ àrùn” tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò yí.—Lúùkù 21:11.

Ísírẹ́lì Ká “Ààjà”

8. Dé ìwọ̀n wo ni Ísírẹ́lì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú Jèhófà?

8 Bí àkókò ti ń lọ, Jèhófà yan Ísírẹ́lì láti jẹ́ “àkànṣe dúkìá [rẹ̀] nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòó kù, . . . ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́.” Ṣùgbọ́n èyí sinmi lórí ‘ṣíṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn rẹ̀ àti pípa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.’ (Ẹ́kísódù 19:5, 6, NW) Wọ́n ha mọyì àǹfààní títóbi lọ́lá yìí bí? Rárá, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀! Ní tòótọ́, àwọn olùṣòtítọ́ kọ̀ọ̀kan nínú orílẹ̀-èdè náà fi ìdúróṣinṣin sìn ín—Mósè, Sámúẹ́lì, Dáfídì, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà, Jòsáyà, àti àwọn wòlíì olùfọkànsìn lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Síbẹ̀, orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ jẹ́ aláìṣòtítọ́. Bí àkókò ti ń lọ, ìjọba náà pín sí méjì—Ísírẹ́lì àti Júdà. Lápapọ̀, orílẹ̀-èdè méjèèjì rì sínú ìjọsìn òrìṣà àti àwọn àṣà míràn tí kò bọlá fún Ọlọ́run, tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká ń lọ́wọ́ sí.—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 23:49.

9. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣèdájọ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ọlọ̀tẹ̀ náà?

9 Kí ni Jèhófà ti ṣe ọ̀ràn náà sí? Gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe, ó ṣèkìlọ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí Ámósì sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.” Ámósì fúnra rẹ̀ ké ègbé lé ìjọba àríwá Ísírẹ́lì lórí pé: “Kí ni èyí yóò já sí fún yín? Ọjọ́ Olúwa òkùnkùn ni, kì í sì í ṣe ìmọ́lẹ̀.” (Ámósì 3:7, NW; 5:18) Síwájú sí i, Hóséà, wòlíì ẹlẹgbẹ́ Ámósì, polongo pé: “Wọ́n ti gbin ẹ̀fúùfù, wọn óò sì ká ààjà.” (Hóséà 8:7) Ní ọdún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà lo àwọn ọmọ ogun Asíríà láti pa ìjọba àríwá Ísírẹ́lì run ráúráú.

Ìdájọ́ Jèhófà Lórí Júdà Apẹ̀yìndà

10, 11. (a) Èé ṣe tí Jèhófà kò fi gbà láti dárí ji Júdà? (b) Àwọn ohun ìríra wo ni ó ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́?

10 Jèhófà tún rán àwọn wòlíì rẹ̀ sí ìjọba gúúsù Júdà. Síbẹ̀, àwọn ọba Júdà bíi Mánásè àti Ámónì, ọba tí ó jẹ tẹ̀ lé e, ń bá a lọ láti ṣe ohun tí ó burú ní ojú Rẹ̀, wọ́n ta ‘ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ jù, wọ́n sì sin àwọn ère, wọ́n sì bọ wọ́n.’ Bí Jòsáyà, ọmọ Ámónì tilẹ̀ ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, àwọn ọba tí ó jẹ tẹ̀ lé e, àti àwọn ènìyàn náà, rì sínú ìwà burúkú lẹ́ẹ̀kan sí i, débi pé “Olúwa kò fẹ́ dárí jì.”—Àwọn Ọba Kejì 21:16-21; 24:3, 4.

11 Jèhófà sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀, Jeremáyà, pé: “Ohun ìyanu àti ìríra ni a ṣe ní ilẹ̀ náà. Àwọn wòlíì sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àti àwọn àlùfáà ṣe àkóso lábẹ́ ọwọ́ wọn, àwọn ènìyàn mi sì fẹ́ kí ó rí bẹ́ẹ̀; kí ni ẹ̀yin óò sì ṣe nígbẹ̀yìn rẹ̀?” Orílẹ̀-èdè Júdà ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lápọ̀jù, olè jíjà, ìpànìyàn, ṣíṣe panṣágà, bíbúra èké, rírìn tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run mìíràn, àti àwọn ohun ìríra mìíràn, sì ti ba àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́. Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ti di “ihò olè.”—Jeremáyà 2:34; 5:30, 31; 7:8-12.

12. Báwo ni Jèhófà ṣe tẹ̀ síwájú láti fìyà jẹ Jerúsálẹ́mù olùyapa?

12 Jèhófà polongo pé: “Èmi óò mú búburú láti àríwá [Kálídíà] wá pẹ̀lú ìbàjẹ́ ńláǹlà.” (Jeremáyà 4:6) Nítorí èyí, ó mú Agbára Ayé Bábílónì, tí ó jẹ́ “olú gbogbo ilẹ̀ ayé” nígbà náà, wá láti run Jerúsálẹ́mù olùyapa àti tẹ́ńpìlì rẹ̀. (Jeremáyà 50:23) Ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, lẹ́yìn ìgbóguntì rírorò kan, ìlú náà ṣubú sọ́wọ́ ọmọ ogun alágbára Nebukadinésárì. “Nígbà náà ni ọba Bábélì pa àwọn ọmọ Sedekáyà [Ọba] ní Ríbúlà, níwájú rẹ̀; ọba Bábélì sì pa gbogbo àwọn ọlọ́lá Júdà pẹ̀lú. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó fọ́ Sedekáyà ní ojú, ó sì fi ẹ̀wọ̀n dè é, láti mú un lọ sí Bábélì. Àwọn ará Kálídíà sì fi ilé ọba àti ilé àwọn ènìyàn jóná, wọ́n sì wó odi Jerúsálẹ́mù lulẹ̀. Nebusarádánì, balógun ìṣọ́, sì kó ìyókù àwọn ènìyàn tí ó kù ní ìlú ní ìgbèkùn lọ sí Bábélì, pẹ̀lú àwọn tí ó ti ya lọ, tí ó ya sọ́dọ̀ rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìyókù tí ó kù.”—Jeremáyà 39:6-9.

13. Àwọn wo ni ó yè bọ́ ní ọjọ́ Jèhófà ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa, èé sì ti ṣe?

13 Ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù mà ni ó jẹ́ ní tòótọ́ o! Síbẹ̀, àwọn ọkàn díẹ̀ tí ó ṣègbọràn sí Jèhófà wà lára àwọn tí ó bọ́ nínú ewú ìdájọ́ gbígbóná janjan náà. Àwọn ọmọ Rékábù, tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgbọràn hàn ní ìyàtọ̀ sí àwọn ọmọ Júdà, wà lára àwọn wọ̀nyí. Lára àwọn tí ó yè bọ́ ni Ebedi-mélékì, ìwẹ̀fà olùṣòtítọ́, tí ó gba Jeremáyà lọ́wọ́ ikú nínú ìkúdú ẹlẹ́rọ̀fọ̀, àti Bárúkù, adúróṣinṣin akọ̀wé Jeremáyà. (Jeremáyà 35:18, 19; 38:7-13; 39:15-18; 45:1-5) Sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà polongo pé: “Èmi mọ ìrò tí mo rò sí i yín, . . . ìrò àlàáfíà, kì í sì í ṣe fún ibi, láti fún yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí.” Ìlérí yẹn nímùúṣẹ ráńpẹ́ ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Ọba Kírúsì, aṣẹ́gun Bábílónì, tú àwọn Júù tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run sílẹ̀, tí wọ́n sì pa dà láti tún ìlú àti tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù kọ́. Lónìí, àwọn tí ó jáde wá láti inú ìsìn Bábílónì, tí a sì mú pa dà bọ̀ sínú ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà pẹ̀lú lè fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la ológo kan ti àlàáfíà ayérayé nínú Párádísè tí Jèhófà mú pa dà bọ̀.—Jeremáyà 29:11; Orin Dáfídì 37:34; Ìṣípayá 18:2, 4.

“Ìpọ́njú Ńlá” ti Ọ̀rúndún Kìíní

14. Èé ṣe tí Jèhófà fi kọ Ísírẹ́lì tì títí lọ gbére?

14 Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Nígbà tí ó máa fi tó àkókò yẹn, àwọn Júù tí a mú pa dà bọ̀ ti tún ṣubú sínú ìpẹ̀yìndà. Jèhófà rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sórí ilẹ̀ ayé láti jẹ́ Ẹni Àmì Òróró, tàbí Mèsáyà rẹ̀. Láàárín ọdún 29 sí 33 Sànmánì Tiwa, Jésù wàásù jákèjádò ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó ń wí pé: “Ẹ ronú pìwà dà, ẹ̀yin ènìyàn, nítorí ìjọba àwọn ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mátíù 4:17) Síwájú sí i, ó kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, ó sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti nípìn-ín nínú pípolongo ìhìn rere Ìjọba náà pẹ̀lú rẹ̀. Báwo ni àwọn olùṣàkóso àwọn Júù ṣe dáhùn pa dà? Wọ́n fojú tín-ínrín Jésù, wọ́n sì jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn tí o burú bùrùjà ti ṣíṣekú oró pa á lórí igi oró nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Jèhófà kọ àwọn Júù tì gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yí, ṣíṣá orílẹ̀-èdè náà tì jẹ́ títí lọ gbére.

15. Kí ni àwọn Júù tí ó ronú pìwà dà láǹfààní láti ṣàṣeparí?

15 Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù tí a ti jí dìde tú ẹ̀mí mímọ́ jáde, èyí sí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lágbára láti fi ìfèdèfọ̀ bá àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe, tí wọ́n ti sáré pé jọ sọ̀rọ̀. Ní bíbá àwùjọ náà sọ̀rọ̀, àpọ́sítélì Pétérù kéde pé: “Jésù yí ni Ọlọ́run jí dìde, òkodoro òtítọ́ tí gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún. . . . Nítorí náà kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú láìsí tàbí ṣùgbọ́n pé Ọlọ́run fi í ṣe Olúwa àti Kristi, Jésù yí tí ẹ̀yin kàn mọ́gi.” Báwo ni àwọn Júù aláìlábòsí ọkàn ti dáhùn pa dà? “Ó gún wọn dé ọkàn àyà,” wọ́n ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a sì batisí wọn. (Ìṣe 2:32-41) Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba yára kánkán, láàárín 30 ọdún, ó ti tàn kálẹ̀ dé “gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kólósè 1:23.

16. Báwo ni Jèhófà ṣe darí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yọrí sí mímú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí Ísírẹ́lì àbínibí?

16 Àkókò ti tó wàyí fún Jèhófà láti mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ti kọ̀ tì, Ísírẹ́lì àbínibí. Ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún, láti inú àwọn orílẹ̀-èdè jákèjádò ayé tí a mọ̀ nígbà yẹn, ti rọ́ wá sínú ìjọ Kristẹni, a sì ti fòróró yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nípa tẹ̀mí. (Gálátíà 6:16) Ṣùgbọ́n, àwọn Júù àkókò yẹn ti rì sínú ìwà ìkórìíra àti ìwà ipá nítorí ẹ̀yà ìsìn. Ní òdì kejì sí ohun tí Pọ́ọ̀lù ti kọ nípa ‘wíwà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,’ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ní gbangba sí agbára Róòmù tí ó ṣàkóso lórí wọn. (Róòmù 13:1) Ó ṣe kedere pé Jèhófà ni ó darí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e. Ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ogun Róòmù lábẹ́ Ọ̀gágun Gallus tẹ̀ síwájú láti sàga ti Jerúsálẹ́mù. Àwọn ará Róòmù tí ń kọluni náà wọnú ìlú náà títí dórí wíwa yàrà yí odi tẹ́ńpìlì ká. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìtàn Josephus ti sọ, ìpọ́njú dé bá ìlú náà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní tòótọ́.a Ṣùgbọ́n, lójijì, àwọn sójà tí ń kọluni náà fẹsẹ̀ fẹ. Èyí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láǹfààní láti “sá lọ sí àwọn òkè ńlá,” gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà wọ́n nímọ̀ràn nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí a kọ sínú Mátíù 24:15, 16.

17, 18. (a) Ìpọ́njú wo ni Jèhófà fi mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn Júù? (b) Ẹran ara wo ni ó “yè bọ́,” kí sì ni èyí jẹ́ òjìji fún?

17 Ṣùgbọ́n, ìmúdàájọ́ Jèhófà ṣẹ pátápátá ní òtéńté ìpọ́njú náà ṣì ń bẹ níwájú. Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ogun Róòmù, tí wọ́n wà lábẹ́ Ọ̀gágun Titus nísinsìnyí, pa dà wá kọ lù wọ́n. Lọ́tẹ̀ yí, ogun àjàmọ̀gá ni! Àwọn Júù, tí wọ́n ti ń jagun, àní láàárín ara wọn pàápàá, kò lè fagagbága pẹ̀lú àwọn ará Róòmù. A pa ìlú náà àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run ráúráú. Iye tí o lé ní mílíọ̀nù kan àwọn Júù, tí wọ́n ti rù kan egungun, jìyà wọ́n sì kú, nǹkan bí 600,000 òkú ni a jù sẹ́yìn ibodè ìlú náà. Lẹ́yìn tí ìlú náà ṣubú, a kó àwọn Júù 97,000 lọ nígbèkùn, tí púpọ̀ nínú wọ́n kú lẹ́yìn náà ní gbọ̀ngàn ìwòran ìjà àjàkú akátá. Ní tòótọ́, kìkì àwọn ẹran ara tí ó la àwọn ọdún ìpọ́njú yẹn já jẹ́ ti àwọn Kristẹni onígbọràn tí wọ́n ti sá lọ sórí àwọn òkè tí ó wà lẹ́yìn Jọ́dánì.—Mátíù 24:21, 22; Lúùkù 21:20-22.

18 Nípa báyìí, àsọtẹ́lẹ̀ ńlá Jésù nípa “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan” ní ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́, ní dídé òtéńté rẹ̀ ní ọjọ́ Jèhófà fún mímú ìdájọ́ ṣẹ sórí orílẹ̀-èdè Júù ọlọ̀tẹ̀, ní ọdún 66 sí 70 Sànmánì Tiwa. (Mátíù 24:3-22) Síbẹ̀, ìyẹn wulẹ̀ jẹ́ kìkì òjìji “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà,” ìpọ́njú ìkẹyìn tí yóò gba gbogbo ayé kan látòkè délẹ̀ láìpẹ́. (Jóẹ́lì 2:31) Báwo ni ìwọ ṣe lè “yè bọ́”? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò sọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Josephus ròyìn pé àwọn ará Róòmù tí ń kọluni náà yí ìlú náà ká, wọ́n wa yàrà yí apá kan odi ìlú náà ká, kí wọ́n dáná sun ẹnubodè tẹ́ńpìlì Jèhófà ló kù. Èyí fa ìbẹ̀rùbojo láàárín àwọn Júù tí a sé mọ́ inú rẹ̀, nítorí tí wọ́n ti rí i pé ikú ti dé.—Wars of the Jews, Ìwé Kejì, orí 19.

Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Báwo ni “ọjọ́ Olúwa” ṣe tan mọ́ “ọjọ́ Jèhófà”?

◻ Ní ṣíṣàyẹ̀wò ọjọ́ Nóà, ìkìlọ̀ wo ni ó yẹ kí a kọbi ara sí?

◻ Báwo ni Sódómù àti Gòmórà ṣe pèsè ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n lílágbára fún wa?

◻ Àwọn wo ni a gbà là nígbà “ìpọ́njú ńlá” ọ̀rúndún kìíní?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jèhófà pèsè ọ̀nà àsálà fún ìdílé Nóà àti Lọ́ọ̀tì, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa àti ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́