Ìṣúra Fífarasin kan Wá Sí Ojútáyé
Ìtàn Bíbélì Makarios
NÍ ỌDÚN 1993, olùwádìí kan rí àkójọ ìwé ìròyìn Orthodox Review tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́, tí àwọ̀ rẹ̀ sì ti di ràkọ̀ràkọ̀, nínú Ilé Ìkówèésí ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní St. Petersburg. Ohun ìṣúra kan tí ó ti fara sin fún àwọn ará Rọ́ṣíà fún ohun tí ó lé ní ọ̀rúndún kan ń bẹ nínú àwọn ojú ewé ìwé ìròyìn náà ti ọdún 1860 sí 1867. Ó jẹ́ ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù látòkè délẹ̀, tàbí “Májẹ̀mú Láéláé,” ti Bíbélì ní èdè Rọ́ṣíà!
Mikhail Iakovlevich Glukharev, tí a mọ̀ sí Àlùfáà Makarios, àti Gerasim Petrovich Pavsky ni olùtumọ̀ Ìwé Mímọ́ náà. Àwọn méjèèjì jẹ́ gbajúmọ̀ mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà, wọ́n sì tún jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú èdè. Nígbà tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tí ó kọjá, a kò tí ì tú Bíbélì lódindi sí èdè Rọ́ṣíà.
Lóòótọ́, Bíbélì náà wà lédè Slavic, èdè tí ó jẹ́ òléwájú fún èdè Rọ́ṣíà òde òní. Ṣùgbọ́n, nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún kọkàndínlógún, èdè Slavic ti di èyí tí a kò sọ mọ́ fún ìgbà pípẹ́ àfi níbi ààtò ìsìn, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń lò ó. Irú ipò kan náà wáyé ní Ìwọ̀ Oòrùn, níbi tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ti gbìyànjú láti jẹ́ kí Bíbélì mọ sí èdè Látìn nìkan ṣoṣo fún ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn tí èdè Látìn ti di òkú èdè.
Makarios àti Pavsky gbìdánwò láti mú kí Bíbélì wà ní àrọ́wọ́tó àwọn gbáàtúù. Nítorí náà, ṣíṣàwárí iṣẹ́ wọn tí a ti gbàgbé fún ìgbà pípẹ́ ti mú kí mímú apá pàtàkì nínú àṣà àjogúnbá ti ìtàn alákọsílẹ̀ àti ti ìsìn ilẹ̀ Rọ́ṣíà pa dà bọ̀ sípò ṣeé ṣe.
Ṣùgbọ́n, ta ni Makarios àti Pavsky? Èé sì ti ṣe tí ìsapá wọn láti mú kí Bíbélì wà ní èdè àwọn gbáàtúù fi dojú kọ irú àtakò bẹ́ẹ̀? Ìtàn wọn fa gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Bíbélì lọ́kàn mọ́ra, ó sì fún ìgbàgbọ́ wọn lókun.
Bíbélì Lédè Rọ́síà Pọn Dandan
Kì í ṣe Makarios àti Pavsky ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóò rí i pé Bíbélì lédè àwọn gbáàtúù pọn dandan. Ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà náà, olú ọba Rọ́ṣíà, Peter Kìíní, tàbí Peter Ńlá, rí i pé ó pọn dandan pẹ̀lú. Lọ́nà tí ó ṣe pàtàkì, ó bọ̀wọ̀ fún Ìwé Mímọ́, wọ́n sì sọ pé ó wí pé: “Bíbélì jẹ́ ìwé kan tí ó ta àwọn yòó kù yọ, ó sì kún fún gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ojúṣe ènìyàn sí Ọlọ́run àti sí aládùúgbò rẹ̀.”
Nípa báyìí, ní ọdún 1716, Peter pàṣẹ pé kí ìgbìmọ̀ òun tẹ Bíbélì jáde ní Amsterdam, ó sì gbé ìnáwó rẹ̀. Ojú ìwé kọ̀ọ̀kan yóò ní abala kan fún èdè Rọ́ṣíà àti abala kan fún èdè Dutch. Ọdún kan péré lẹ́yìn náà, ní ọdún 1717, a parí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tàbí “Májẹ̀mú Tuntun.”
Nígbà tí yóò fi di ọdún 1721 a ti tẹ abala ti èdè Dutch onídìpọ̀ mẹ́rin ti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù jáde. A fi abala kan sílẹ̀ báláú, a pète láti tẹ èdè Rọ́ṣíà sí i lẹ́yìn náà. Peter fi àwọn Bíbélì náà ránṣẹ́ sí “Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Mímọ́” ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà—ọlá àṣẹ gíga jù lọ ní ti ìsìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà—láti parí ọ̀ràn lórí títẹ̀ ẹ́ jáde àti bíbójútó ìpínkiri rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn kò ṣiṣẹ́ lé e lórí.
Kó tó ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, Peter kú. Kí ní ṣẹlẹ̀ sí Bíbélì rẹ̀? A kò tẹ ohunkóhun sí abala báláú tí a fi sílẹ̀ fún èdè Rọ́ṣíà mọ́ títí di òní olónìí. A to àwọn Bíbélì náà jọ gègèrè gegere sí ìsàlẹ̀ ilé kan, níbi tí wọ́n bà jẹ́ sí—lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn a kò rí ẹyọ ẹ̀dà kan tí kò bà jẹ́! Ìpinnu ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn ni láti “ta gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù fún àwọn oníṣòwò.”
Ìsapá Láti Ṣètumọ̀ Bẹ̀rẹ̀
Ní ọdún 1812, John Paterson, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Ilẹ̀ Britain àti Ilẹ̀ Àjèjì wá sí Rọ́ṣíà. Paterson ru ìfẹ́ ọkàn àwọn ọ̀mọ̀ràn St. Petersburg sókè láti dá ẹgbẹ́ atúmọ̀ Bíbélì kan sílẹ̀. Ní December 6, 1812—ọdún kan náà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Rọ́ṣíà gbéjà ko ẹgbẹ́ ọmọ ogun Napoléon Kìíní tí ó gbógun tì wọ́n—Olú Ọba Alexander Kìíní fọwọ́ sí àkọsílẹ̀ ète ẹgbẹ́ atúmọ̀ Bíbélì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Ní ọdún 1815, olú ọba náà pàṣẹ pé kí alága ẹgbẹ́ náà, Ọmọ Ọba Aleksandr Golitsyn, dábàá fún ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn pé “ó yẹ kí àwọn ará Rọ́ṣíà pẹ̀lú ní àǹfààní láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè Rọ́ṣíà tí í ṣe èdè àbínibí wọn.”
Lọ́nà tí ó yẹ fún oríyìn, a fọwọ́ sí títú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Rọ́ṣíà ní tààràtà láti inú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ìwé Gíríìkì ti Septuagint ìgbàanì ni ó ti jẹ́ ìpìlẹ̀ fún títú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Slavic. A sọ fún àwọn tí yóò tú Bíbélì náà sí èdè Rọ́ṣíà pé ìlànà pàtàkì ti yóò darí ìtumọ̀ náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣewẹ́kú, ìṣekedere, àti àìlábùlà. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìsapá ìjímìjí wọ̀nyí láti pèsè Bíbélì lédè Rọ́ṣíà?
Aburú Ha Dé Bá Ìtumọ̀ Bíbélì Bí?
Kò pẹ́ kò jìnnà tí àwọn kan tí wọ́n jẹ́ arọ̀mọ́pìlẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í fọgbọ́n sá fún ipa tí ìsìn àti ìṣèlú ilẹ̀ òkèèrè ń ní. Àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì kan sọ síwájú sí i pé èdè Slavic—èdè ààtò ìsìn—gbé ìhìn iṣẹ́ Bíbélì jáde ju èdè Rọ́ṣíà lọ.
Nítorí náà, a tú Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ká ní ọdún 1826. A dáná sun ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀dà ìtumọ̀ tí ẹgbẹ́ atúmọ̀ Bíbélì náà ti mú jáde. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ààtò ìsìn àti òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wá gbapò iwájú mọ́ Bíbélì lọ́wọ́. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì fi lélẹ̀, ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn pàṣẹ ní ọdún 1836 pé: “A yọ̀ǹda fún ọmọ ìjọ èyíkéyìí tí ó bá jẹ́ olùfọkànsìn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́, ṣùgbọ́n a kò yọ̀ǹda fún ẹnikẹ́ni láti ka apá kan Ìwé Mímọ́, ní pàtàkì Májẹ̀mú Láéláé, láìgba ìtọ́sọ́nà.” Ó dà bíi pé aburú ti dé bá ìtumọ̀ Bíbélì.
Iṣẹ́ Pavsky
Láàárín àkókò náà, Gerasim Pavsky, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú èdè Hébérù, dáwọ́ lé iṣẹ́ títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Rọ́ṣíà. Ní ọdún 1821 ó parí títúmọ̀ Orin Dáfídì. Kíá ní olú ọba fọwọ́ sí i, nígbà tí yóò sì fi di January 1822, a ti mú ìwé Orin Dáfídì jáde fáráyé. Kíá ni wọ́n tẹ́wọ́ gbà á, a sì ní láti tún un tẹ̀ nígbà 12—àpapọ̀ ẹ̀dà tí a tẹ̀ jẹ́ 100,000!
Akitiyan Pavsky nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ mú kí ó jèrè ọ̀wọ̀ ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú èdè àti àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. A ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin onínú kan, aláìlábòsí, tí gbogbo rìkíṣí tí a dì mọ́ ọn kò tu irun kankan lára rẹ̀. Láìfi títa tí ṣọ́ọ̀ṣì ta ko Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì Lédè Rọ́ṣíà àti òtítọ́ náà pé àwọn kan rò pé ó ń ṣojú fún ìfẹ́ ọkàn ilẹ̀ òkèèrè pè, Ọ̀jọ̀gbọ́n Pavsky kò dáwọ́ títú àwọn ẹsẹ Bíbélì sí èdè Rọ́ṣíà nígbà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dúró. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tí wọ́n ń kan sáárá sí i fi ọwọ́ da àwọn ìtumọ̀ tí ó ṣe kọ, bí ọjọ́ sì ti ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe fún wọn láti kó iṣẹ́ rẹ̀ jọ. Ní ọdún 1839, wọ́n fi ìgboyà tẹ 150 ẹ̀dà jáde ní ilé ìtẹ̀wé ilé ẹ̀kọ́ gíga náà—láìgba àṣẹ àwọn ayẹ̀wéwò.
Ìtumọ̀ ti Pavsky wu àwọn òǹkàwé lórí gidigidi, iye tí wọ́n ń béèrè fún sì ń pọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n ní ọdún 1841, ẹnì kan tí ó forúkọ ara rẹ̀ pa mọ́ ṣàròyé nípa “ewu” tí ń bẹ nínú ìtumọ̀ yí fún ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn, ó sọ pé ìtumọ̀ náà ti yà bàrà kúrò nínú ẹ̀kọ́ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn pàṣẹ pé: “Ẹ gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo ẹ̀dà ìtumọ̀ G. Pavsky ti Májẹ̀mú Láéláé tí a fọwọ́ kọ àti èyí tí a fẹ̀rọ tẹ̀, kí ẹ sì run wọ́n.”
Fífi Ògo fún Orúkọ Ọlọ́run
Síbẹ̀síbẹ̀, Pavsky ti ru ìfẹ́ fún títúmọ̀ Bíbélì sókè. Ó tún ti fi ìpìlẹ̀ pàtàkì kan lélẹ̀ fún àwọn olùtumọ̀ tí ń bọ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la, ti ọ̀ràn pàtàkì míràn—orúkọ Ọlọ́run.
Ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà olùṣèwádìí náà, Korsunsky, ṣàlàyé pé: ‘Orúkọ Ọlọ́run gan-an, orúkọ mímọ́ jù lọ nínú gbogbo orúkọ rẹ̀, ní lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin יהוה nínú a sì ń pè é ní Jèhófà nísinsìnyí.’ Nínú àwọn ẹ̀dà Bíbélì ìgbàanì, orúkọ Ọlọ́run náà tí ó tayọ lọ́lá fara hàn nígbà ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nìkan ṣoṣo. Ṣùgbọ́n, àwọn Júù ṣàṣìṣe láti wá gbà gbọ́ pé orúkọ àtọ̀runwá náà jẹ́ mímọ́ ju ohun tí a lè máa kọ sílẹ̀ tàbí tí a lè máa fẹnu pè lọ. Nípa èyí, Korsunsky ṣàkíyèsí pé: ‘Nínú ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí èyí tí a kọ sílẹ̀, a sábà máa ń fi Adonai rọ́pò rẹ̀, ní gbogbogbòò ọ̀rọ̀ kan tí a tú sí “Olúwa.”’
Ó ṣe kedere pé, pípa lílo orúkọ àtọ̀runwá tì jẹ́ nítorí ìbẹ̀rù ìgbàgbọ́ asán—kì í ṣe nítorí ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run. Kò sí ibì kan tí Bíbélì fúnra rẹ̀ ti ní kí a má lo orúkọ Ọlọ́run. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ fún Mósè pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, . . . ni ó rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” (Ẹkísódù 3:15, NW) Léraléra, Ìwé Mímọ́ rọ àwọn olùjọsìn pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà! Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀.” (Aísáyà 12:4, NW) Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ olùtumọ̀ Bíbélì yàn láti tẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù, wọ́n sì yẹra fún lílo orúkọ àtọ̀runwá náà.
Àmọ́, Pavsky, kò tẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyí. Nínú ìtumọ̀ Orin Dáfídì rẹ̀ nìkan, orúkọ náà, Jèhófà, fara hàn nígbà tí ó lé ní 35. Ìgboyà rẹ̀ máa tó nípa pàtàkì lórí ọ̀kan lára àwọn alájọgbáyé rẹ̀.
Àlùfáà Makarios
Alájọgbáyé rẹ̀ yí ni àlùfáà Makarios, míṣọ́naárì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan tí ó ní òye èdè gígadabú. Nígbà tí ó ṣì wà lọ́mọdé ni ọmọ ọdún méje, ó ti lè tú ọ̀rọ̀ ṣókí ní èdè Rọ́ṣíà sí èdè Látìn. Nígbà tí yóò fi di ẹni 20 ọdún, ó ti gbọ́ èdè Hébérù, German, àti èdè Faransé. Ṣùgbọ́n, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti òye tí ó ní nípa ojúṣe rẹ̀ sí Ọlọ́run ràn án lọ́wọ́ láti yẹra fún kíkó sínú ọ̀fìn ìjọra-ẹni-lójú. Ìgbà gbogbo ni ó máa ń wá ìmọ̀ràn lọ sọ́dọ̀ àwọn mìíràn tí wọ́n mọ tìfun tẹ̀dọ̀ èdè àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀.
Makarios fẹ́ tún ìgbòkègbodò míṣọ́nnárì ṣe nílẹ̀ Rọ́ṣíà. Ó ronú pé kí a tó le mú ẹ̀sìn Kristẹni tọ àwọn Mùsùlùmí àti àwọn Júù lọ nílẹ̀ Rọ́ṣíà, ṣọ́ọ̀ṣì ní láti “la àwọn ènìyàn lóye nípa dídá ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ àti pínpín Bíbélì kiri ní èdè Rọ́ṣíà.” Ní March 1839, Makarios gúnlẹ̀ sí St. Petersburg, ní ríretí láti gba àṣẹ láti tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Rọ́ṣíà.
Tẹ́lẹ̀rí, Makarios ti tú àwọn ìwé Aísáyà àti Jóòbù inú Bíbélì. Ṣùgbọ́n, ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn kọ̀ láti fún un láṣẹ láti tú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Rọ́ṣíà. Àní, a sọ fún Makarios láti gbàgbé nípa títú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Rọ́ṣíà. Ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn gbé ìlànà kan kalẹ̀, ní April 11, 1841, ní pípàṣẹ fún Makarios “láti lọ ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí mẹ́fà nílé bíṣọ́ọ̀bù kan ní Tomsk kí ó baà lè fi àdúrà àti ìkúnlẹ̀ wẹ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mọ́.”
Ìdúró Onígboyà Ti Makarios
Láti December 1841 títí dé January 1842, Makarios ṣe ààtò ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, gbàrà tí ó sì ti yanjú ìyẹn, lójú ẹsẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ títúmọ̀ ìyókù Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó ti gba ẹ̀dà ìtumọ̀ Pavsky ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó sì lò ó láti fi ṣàyẹ̀wò ìtumọ̀ tirẹ̀. Bíi Pavsky, ó kọ̀ láti jẹ́ kí orúkọ àtọ̀runwá fara sin. Àní, orúkọ náà, Jèhófà, fara hàn ju ìgbà 3,500 lọ nínú ìtumọ̀ Makarios!
Makarios fi ọ̀pọ̀ ẹ̀dà iṣẹ́ rẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jẹ́ afẹ́nifẹ́re. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pín ẹ̀dà àfọwọ́kọ díẹ̀, ṣọ́ọ̀ṣì kò dẹ́kun dídí títẹ ìwé rẹ̀ jáde lọ́wọ́. Makarios wéwèé láti gbé Bíbélì rẹ̀ lárugẹ nílẹ̀ òkèèrè. Ní alẹ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí yóò lọ, àìsàn kì í, ó sì kú kété lẹ́yìn náà, ní ọdún 1847. A kò tẹ ìtumọ̀ Bíbélì rẹ̀ jáde ní ojú rẹ̀.
A Tẹ̀ Ẹ́ Jáde Lẹ́yìn-Ọ̀-Rẹyìn!
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọ̀ràn òṣèlú àti ìsìn yí pa dà. Ojú ìwòye gbígbòòrò tuntun gba ilẹ̀ náà kan, lẹ́ẹ̀kan sí i, ní ọdún 1856, ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn fọwọ́ sí títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Rọ́ṣíà. Nínú àyíká tí ó sunwọ̀n sí i yìí, a tẹ Bíbélì Makarios jáde ní ìpele ìpele nínú ìwé ìròyìn Orthodox Review láàárín ọdún 1860 sí 1867, lábẹ́ àkòrí náà, An Experiment of Translation Into the Russian Language.
Bíṣọ́ọ̀bù Filaret ti Chernigov, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ìwé ìsìn ilẹ̀ Rọ́ṣíà, sọ ohun tí ó rí nípa Bíbélì Makarios pé: “Ìtumọ̀ rẹ̀ rọ̀ pinpin mọ́ èyí tí ó ti wà ní èdè Hébérù, ọ̀rọ̀ inú ìtumọ̀ rẹ̀ kò lábùlà, ó sì bá kókó ọ̀rọ̀ mu.”
Ṣùgbọ́n, a kò fìgbà kankan mú Bíbélì Makarios jáde fún gbogbo ènìyàn. Àní, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbàgbé rẹ̀ pátápátá. Ní ọdún 1876, pẹ̀lú ìfọwọ́sí ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn, a parí títú Bíbélì lódindi, tí ó ní Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Gíríìkì nínú, sí èdè Rọ́ṣíà. Odindi Bíbélì yí ni a sábà ń pè ní ìtumọ̀ ti ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn. Lọ́nà títakora, ìtumọ̀ Makarios, pẹ̀lú ti Pavsky, jẹ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì fún ìtumọ̀ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà yí “tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.” Ṣùgbọ́n ìwọ̀nba ibi díẹ̀ ni a ti lo orúkọ àtọ̀runwá náà lára ibi tí ó ti fara hàn nínú èdè Hébérù.
Bíbélì Makarios Lónìí
Bíbélì Makarios ṣì fara sin títí di ọdún 1993. Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nu kàn án ní ìbẹ̀rẹ̀, lákòókò yẹn, a rí ẹ̀dà kan rẹ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn ògbólógbòó ti Orthodox Review ní ẹ̀ka ti àwọn ìwé tí ó ṣọ̀wọ́n ní Ilé Ìkówèésí ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì mímú kí Bíbélì yí wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo ènìyàn. Ilé ìkówèésí náà fún Ètò Ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Rọ́ṣíà láṣẹ láti ní ẹ̀dà kan Bíbélì Makarios kí wọn lè ṣètò fún títẹ̀ ẹ́ jáde.
Lẹ́yìn náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò láti tẹ nǹkan bí ẹ̀dà 300,000 Bíbélì yí jáde ní Ítálì, fún ìpínkiri jákèjádò ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn tí a ti ń sọ èdè Rọ́ṣíà. Ní àfikún sí ìtumọ̀ Makarios ti ọ̀pọ̀ jù lọ rẹ̀ jẹ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ìtẹ̀jáde Bíbélì yí ní ìtumọ̀ Orin Dáfídì tí Pavsky ṣe àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ti ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn, tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì fọwọ́ sí, nínú.
Ní January ọdún yìí, a mú un jáde nígbà ìpàdé pẹ̀lú àwọn oníròyìn ní St. Petersburg, Rọ́ṣíà. (Wo ojú ìwé 26.) Ó dájú pé pẹ̀lú Bíbélì tuntun yìí, a óò la àwọn òǹkàwé èdè Rọ́ṣíà lóye sí i, ìmọ̀ wọn yóò sì pọ̀ sí i.
Nípa bẹ́ẹ̀, ìtẹ̀jáde Bíbélì yí jẹ́ ìjagunmólú ti ìsìn àti ìtàn alákọsílẹ̀! Ó tún jẹ́ ohun aránnilétí tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun tí ó fi òtítọ́ tí ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ Aísáyà 40:8 hàn pé: “Koríko ń rọ, ìtànná ń rẹ̀: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa yóò dúró láéláé.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn Aṣelámèyítọ́ Gbóṣùbà fún Bíbélì
“A TÚN ti mú ohun arabaríbí mìíràn nínú ìtàn alákọsílẹ̀ jáde: Bíbélì Makarios.” Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ yẹn ni ìwé agbéròyìnjáde Komsomolskaya Pravda fi kéde ìmújáde Bíbélì Makarios.
Lẹ́yìn sísọ pé nǹkan bí “120 ọdún sẹ́yìn” ni Bíbélì tó wà lédè Rọ́ṣíà, ìwé agbéròyìnjáde yìí kédàárò pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ṣọ́ọ̀ṣì tako títúmọ̀ ìwé mímọ́ sí èdè tí ó rọrùn láti kà. Lẹ́yìn tí ó ti kọ ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ sílẹ̀, ṣọ́ọ̀ṣì gbà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pẹ̀lú ọ̀kan lára wọn ní ọdún 1876, ó sì di èyí tí a mọ̀ sí ìtumọ̀ ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn. Ṣùgbọ́n, a kò gbà kí a mú un wọnú ṣọ́ọ̀ṣì. Títí di òní olónìí, kìkì Bíbélì tí a gbà wọlé níbẹ̀ ni ti èdè Slavic.”
Ìwé agbéròyìnjáde Echo pẹ̀lú tọ́ka sí ìníyelórí títẹ Bíbélì Makarios jáde, ní sísọ pé: “Àwọn abẹnugan ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ láti Yunifásítì Ìpínlẹ̀ St. Petersburg, Yunifásítì Àwọn Olùkọ́ ti Herzen, àti Ilé Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Nípa Ìtàn Ìsìn gbóríyìn gidigidi fún ìtẹ̀jáde tuntun ti Bíbélì yí.” Ní títọ́ka sí títú tí Makarios àti Pavsky tú Bíbélì náà sí èdè Rọ́ṣíà ní apá àkọ́kọ́ ọ̀rúndún tí ó kọjá, ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Títí di ìgbà yẹn, èdè kan ṣoṣo tí a ti lè rí Bíbélì kà ní Rọ́ṣíà ni èdè Slavic, èyí tí ó jẹ́ pé kìkì àwọn mẹ́ńbà àwùjọ àlùfáà nìkan ni ó gbọ́ ọ.”
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, nígbà ìpàdé pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní St. Petersburg a ròyìn mímú tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Bíbélì Makarios jáde. Ìwé agbéròyìnjáde ládùúgbò Nevskoye Vremya sọ pé: “Àwọn abẹnugan ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ . . . tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí a yẹ ìtẹ̀jáde náà wò gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ tí ó ṣe pàtàkì gidigidi nínú ìṣẹ̀dálẹ̀ ìgbésí ayé Rọ́ṣíà àti ti St. Petersburg. Láìka ohun tí ẹnì kan lè rò nípa ìgbòkègbodò ètò àjọ yìí sí, kò sí iyè méjì pé ìmújáde ìtumọ̀ Bíbélì náà tí a kò mọ̀ títí di àkókò yí ṣeni láǹfààní tí ó pọ̀ jọjọ.”
Dájúdájú, inú gbogbo ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń dùn nígbà tí a bá mú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè kan tí àwọn ènìyàn gbáàtúù lè kà kí ó sì yé wọn. Níbi gbogbo, inú àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ Bíbélì dùn pé ìtumọ̀ Bíbélì míràn ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí ń sọ èdè Rọ́ṣíà yíká ayé.
[Àwòrán]
A kéde ìmújáde Bíbélì Makarios níbi ìpàdé pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn yí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ilé Ìkówèésí ti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà níbi tí a ti rí ìṣúra tí ó fara sin náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Peter Ńlá gbìyànjú láti mú kí a tẹ Bíbélì jáde lédè Rọ́ṣíà
[Credit Line]
Corbis-Bettmann
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Gerasim Pavsky, tí ó kó ipa pàtàkì nínú títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Rọ́ṣíà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àlùfáà Makarios, tí a fi orúkọ rẹ̀ sọ Bíbélì tuntun ní èdè Rọ́ṣíà