ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 3/15 ojú ìwé 10-11
  • Ẹrú Ènìyàn Tàbí Ìránṣẹ́ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹrú Ènìyàn Tàbí Ìránṣẹ́ Ọlọ́run?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ewu Títẹ̀lé Ènìyàn
  • Ẹgbẹ́ Awo Ha Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Awọn Kristian ati Ẹgbẹ́ Awujọ Eniyan Lonii
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ṣé Ẹ̀ya Ìsìn Amẹ́ríkà ni Ẹ̀sìn Yín?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Òmìnira Ìsìn—Ìbùkún ni Tàbí Ègún
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 3/15 ojú ìwé 10-11

Ẹrú Ènìyàn Tàbí Ìránṣẹ́ Ọlọ́run?

“ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ yẹ ní ẹni tí a ń kan sáárá sí.” Ohun tí ìwé kan lédè German, Seher, Grübler, Enthusiasten (Àwọn Alárògún, Aláròjinlẹ̀, Àwọn Onítara), sọ nìyẹn. Bí ó tilẹ̀ ṣe lámèyítọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí dé àyè kan, ó gbà pé: “Ní gbogbogbòò, wọ́n ń gbé ìgbésí ayé aláìlẹ́bi, ìgbésí ayé mẹ̀kúnnù. Wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, tí ń ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn, aráàlú tí kì í ṣaápọn, tí ń san owó orí láìṣàbòsí. Wọ́n ń yẹra fún fífi torítọrùn lépa ọrọ̀. . . . Ìwà wọn ní àwọn apéjọpọ̀ yẹ ní gbígbòṣùbà fún. Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọn kò kéré sí ti àwùjọ ìsìn yòókù; ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́, ọ̀gá ni wọ́n. Ṣùgbọ́n ohun tí ó mú kí wọ́n ta gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì àwùjọ Kristẹni yòókù ti òde òní yọ ni ìpinnu tí kò lè yẹ̀ rárá tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn fi ń polongo ìgbàgbọ́ wọn lábẹ́ gbogbo àyíká ipò àti lójú gbogbo ewu.”a

Láìfi irú ọ̀rọ̀ rere bẹ́ẹ̀ pè, àwọn kan ń gbìyànjú láti gbé ojú ìwòye tí ó yàtọ̀ pátápátá dìde nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè yíká ayé, Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń ṣe ìsìn wọn ní gbangba fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún láìsí ìkálọ́wọ́kò. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn mọ̀ wọ́n, wọ́n bọ̀wọ̀ fún wọn, wọ́n sì gbà pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tiwọn. Nígbà náà, èé ṣe tí a fi ń kọminú nípa irú ènìyàn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́?

Ìdí kan fún kíkọminú lè jẹ́ nítorí pé, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí ọ̀pọ̀ àwùjọ ìsìn mìíràn ti lọ́wọ́ nínú híhùwà ìkà sí àwọn ọmọdé, pípara ẹni lọ́pọ̀ yanturu, àti ìkópayàbáni. Àmọ́ ṣáá o, àwọn ìwà tí ó buni kù báwọ̀nyí wà níbi gbogbo, kò mọ sáàárín àwọn tí wọ́n jẹ́ onísìn nìkan. Ṣùgbọ́n, bí ó bá ti di ọ̀ràn ìsìn, ọ̀pọ̀ ń ṣiyèméjì, àwọn kan kò tilẹ̀ fẹ́ gbọ́ nǹkan kan nípa rẹ̀.

Ewu Títẹ̀lé Ènìyàn

“Ẹ̀ya ìsìn” túmọ̀ sí “àwùjọ kan tí ń rọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ yíyàtọ̀ gédégbé tàbí tí ń tẹ̀ lé aṣáájú kan.” Bákan náà, àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ “ẹgbẹ́ awo” ní “ìfọkànsìn ńlá sí ẹnì kan, wọ́n gba èrò kan, tàbí ohun kan gbọ́ gidigidi.” Ní tòótọ́, àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ ìsìn èyíkéyìí tí ó bá ń tẹ̀ lé àwọn aṣáájú tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn àti èrò wọn lọ́nà lílágbára wà nínú ewu dídi ẹrú ènìyàn. Ipò ìbátan lílágbára kan tí a gbé karí títẹ̀lé aṣáájú kan lè yọrí sí gbígbára léni fún èrò ìmọ̀lára àti fún ohun tẹ̀mí lọ́nà tí ó léwu. Ewu náà lè pọ̀ sí i nígbà tí a bá tọ́ ẹnì kan dàgbà ní àgbègbè tí ó kún fún ẹ̀ya ìsìn.

Àwọn tí ń dá irú àníyàn bẹ́ẹ̀ nípa ìsìn nílò ìsọfúnni tí ó ṣeé gbára lé. A ti lè sọ fún àwọn kan pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ètò àjọ ìsìn tí ń sọ àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ di ẹrú, tí ń lo ọlá àṣẹ bóo fẹ́ bóo kọ̀ lórí wọn, tí ó ń ká wọn lọ́wọ́ kò láìnídìí, tí kì í sì í mú kí wọ́n mọ ohun tí ń lọ láwùjọ rárá.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé kò sídìí kankan fún àwọn àníyàn wọ̀nyí. Nítorí náà, wọ́n rọ̀ ọ́ láti fúnra rẹ ṣèwádìí. Lẹ́yìn àyẹ̀wò fínnífínní, fúnra rẹ dé ìparí èrò. Àwọn Ẹlẹ́rìí ha jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ, àbí ẹrú ènìyàn ni wọ́n ní ti gidi? Kí ni orísun okun wọn? Àwọn àpilẹ̀kọ méjì tí ó wà lójú ìwé 12 sí 23 yóò pèsè ìdáhùn tí ó tẹ́ni lọ́rùn sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtẹ̀jáde ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti 1950 kò ní àwọn gbólóhùn tí ó wà lókè yìí nínú. Fífi tí ó fara hàn nínú ìtẹ̀jáde tí a tún kọ ti 1982 tipa báyìí ṣí ìtẹ̀sí náà payá pé a ti túbọ̀ lóye Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́