Bẹ́tẹ́lì—Ìlú Ohun Rere àti Búburú
ÀWỌN ìlú kan di olókìkí—tàbí olórúkọ burúkú—nítorí àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú wọn. Ṣùgbọ́n, ti Bẹ́tẹ́lì yàtọ̀, nítorí a wá mọ̀ ọ́n fún ohun rere àti búburú. Baba ńlá náà Jékọ́bù ni ó sọ orúkọ ìlú náà ní Bẹ́tẹ́lì, tí ó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún, wòlíì Hóséà pe ìlú náà ní “Ilé Ọṣẹ́.” Báwo ni ìlú yìí ṣe yí padà láti orí ohun rere sí búburú? Kí sì ni a lè rí kọ́ nínú ìtàn rẹ̀?
Bẹ́tẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìsopọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ọdún 1943 ṣááju Sànmánì Tiwa nígbà tí Ábúráhámù ṣì wà láàyè. Ní àkókò yẹn, a mọ ìlú yẹn sí Lúsì, orúkọ tí àwọn ará Kénáánì sọ ọ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ó wà ní ìletò tí ó wà lẹ́bàá òkè, ní nǹkan bí kìlómítà 17 sí àríwá Jerúsálẹ́mù. Fojú inú wo Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì, ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tí ń bojú wo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹlẹ́tù lójú ti ìsàlẹ̀ Àfonífojì Jọ́dánì láti orí òkè ṣóńṣó tí ó yí Bẹ́tẹ́lì ká. Pẹ̀lú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, Ábúráhámù ń pe àfiyèsí Lọ́ọ̀tì sí ìṣòro tí yíyan ibi tí agbo ẹran ńlá wọn yóò ti jẹ́ko yóò mú wá: “Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí aáwọ̀ máa bá a lọ láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn olùṣọ́ agbo ẹran mi àti àwọn olùṣọ́ agbo ẹran rẹ, nítorí arákùnrin ni wá. Gbogbo ilẹ̀ kò ha wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ? Jọ̀wọ́, yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi. Bí ìwọ bá lọ sí apá òsì, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, nígbà náà, èmi yóò lọ sí apá òsì.”—Jẹ́nẹ́sísì 13:3-11.
Ábúráhámù kò lo ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti kọ́kọ́ ṣe yíyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yọ̀ǹda kí ẹni tí ó kéré sí i yan ibì kan. A lè fara wé ìwà rere Ábúráhámù. A lè pẹ̀tù sí aáwọ̀ nípa lílo ọgbọ́n inú nínú ìsọ̀rọ̀ àti híhùwà àìmọtara-ẹni-nìkan.—Róòmù 12:18.
Ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí ọmọ-ọmọ Ábúráhámù náà, Jékọ́bù, pàgọ́ sí Lúsì, ó lá àlá àrà ọ̀tọ̀ kan. Ó rí “àkàsọ̀ kan tí a gbé dúró sórí ilẹ̀ ayé, tí orí rẹ̀ sì kan ọ̀run; sì wò ó! àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run wà, tí wọ́n ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ lórí rẹ̀. Sì wò ó! Jèhófà dúró lókè rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 28:11-19; fi wé Jòhánù 1:51.) Àlá náà ṣe pàtàkì gidigidi. Àwọn áńgẹ́lì tí Jékọ́bù rí yóò ṣe òjíṣẹ́ fún un ní mímú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa irú ọmọ rẹ̀ ṣẹ. Ipò Jèhófà tí a gbé ga ju àkàsọ̀ náà lọ fi hàn pé òun ni yóò máa darí àwọn áńgẹ́lì nínú iṣẹ́ yìí.
Ìdánilójú ìtìlẹyìn àtọ̀runwá yìí ru Jékọ́bù sókè gidigidi. Jíjí tí ó jí láti ojú àlá rẹ̀, ó pe ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, tí ó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run,” ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà pé: “Ní ti ohun gbogbo tí ìwọ yóò sì fi fún mi ni èmi yóò san ìdá mẹ́wàá rẹ̀ fún ọ láìkùnà.”a (Jẹ́nẹ́sísì 28:20-22) Ní mímọ̀ pé ohun gbogbo tí òun ní ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ó fẹ́ dá apá tí ó pọ̀ gan-an padà gẹ́gẹ́ bí ìfìmoore hàn.
Àwọn Kristẹni lónìí pẹ̀lú ní àwọn áńgẹ́lì tí ń tì wọ́n lẹ́yìn. (Sáàmù 91:11; Hébérù 1:14) Àwọn pẹ̀lú lè fi ìmọrírì hàn fún gbogbo ìbùkún tí wọ́n ń rí gbà nípa jíjẹ́ “ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 9:11, 12.
Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù di orílẹ̀-èdè. Jóṣúà, aṣáájú wọn borí kèfèrí ọba Bẹ́tẹ́lì ní ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́gun Kénáánì. (Jóṣúà 12:16) Nígbà àwọn Adájọ́, wòlíì obìnrin náà, Dèbórà, ń gbé nítòsí Bẹ́tẹ́lì, ó sì sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún àwọn ènìyàn náà. Sámúẹ́lì pẹ̀lú ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì déédéé bí ó ti ń ṣèdájọ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.—Onídàájọ́ 4:4, 5; 1 Sámúẹ́lì 7:15, 16.
Bẹ́tẹ́lì Di Ibùdó Ìpẹ̀yìndà
Ṣùgbọ́n ìsopọ̀ tí Bẹ́tẹ́lì ní pẹ̀lú ìjọsìn mímọ́ gaara dẹ́kun nígbà tí a pín Ìjọba náà ní ọdún 997 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ọba Jéróbóámù gbé Bẹ́tẹ́lì kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìjọsìn ọmọ màlúù, tí wọ́n gbà pé ó dúró fún Jèhófà. (1 Àwọn Ọba 12:25-29) Ìdí nìyẹn, nígbà tí Hóséà ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun Bẹ́tẹ́lì, ó pè é ní “Bẹti-Áfénì,” tí ó túmọ̀ sí “Ilé Ọṣẹ́.”—Hóséà 10:5, 8.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bẹ́tẹ́lì ti di ibùdó ọṣẹ́ nípa tẹ̀mí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó so mọ́ ọn ṣì ń pèsè àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. (Róòmù 15:4) Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni ti wòlíì kan tí a kò dárúkọ tí a rán lọ sí Bẹ́tẹ́lì láti Júdà kí ó lọ sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun àwọn pẹpẹ àti àlùfáà ibẹ̀. Jèhófà tún sọ fún un láti padà sí Júdà—nǹkan bí kìlómítà díẹ̀ sí ìhà gúúsù—láìjẹun àti láìmu nǹkan. Wòlíì yìí fi ìgboyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú Jéróbóámù, ọba Ísírẹ́lì, ó sì ké ègbé lórí pẹpẹ Bẹ́tẹ́lì. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nípa jíjẹun ní ilé wòlíì arúgbó kan ní Bẹ́tẹ́lì. Èé ṣe? Wòlíì arúgbó náà parọ́ pé áńgẹ́lì Jèhófà kan ni ó pàṣẹ fóun láti fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí wòlíì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Àìgbọràn tí wòlíì tí ó wá láti Júdà ṣe sún un sí ikú àìtọ́jọ́.—1 Àwọn Ọba 13:1-25.
Bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni bá sọ pé kí a ṣe ohun kan tí ó dà bí pé ó kọ wá lóminú, báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà? Rántí pé ìmọ̀ràn tí a fúnni pẹ̀lú ẹ̀mí rere pàápàá lè ṣèpalára bí ó bá jẹ́ èyí tí kò tọ́. (Fi wé Mátíù 16:21-23.) Nípa wíwá ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a óò yẹra fún àṣìṣe ńlá tí wòlíì tí a kò dárúkọ náà ṣe.—Òwe 19:21; 1 Jòhánù 4:1.
Ní nǹkan bí 150 ọdún lẹ́yìn náà, wòlíì Ámósì tún rin ìrìn àjò lọ sí ìhà àríwá láti sàsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Bẹ́tẹ́lì. Ámósì fi ìdúró gbọn-in fi àwùjọ rẹ̀ oníkanra bú, títí kan àlùfáà Amasááyà, tí ó fi ẹ̀mí ìgbéraga sọ fún Ámósì láti “sá lọ sí ilẹ̀ Júdà.” Ṣùgbọ́n Ámósì fi àìbẹ̀rù sọ fún Amasááyà nípa àjálù tí yóò dé bá agbo ilé àlùfáà náà fúnra rẹ̀. (Ámósì 5:4-6; 7:10-17) Àpẹẹrẹ rẹ̀ rán wa létí pé Jèhófà lè ki àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ láyà.—1 Kọ́ríńtì 1:26, 27.
Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jòsáyà olùṣòtítọ́ Ọba Júdà bi ‘pẹpẹ tí ó wà ní Bẹ́tẹ́lì wó, ó dáná sun ibi gíga, ó lọ̀ ọ́ di ekuru, ó sì fi iná sun òpó ọlọ́wọ̀ náà.’ (2 Àwọn Ọba 23:15, 16) Àwọn alàgbà lónìí lè fara wé àpẹẹrẹ àtàtà rẹ̀ nípa fífi ìtara tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run àti nípa mímú ipò iwájú nínú jíjẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́.
Àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn Bẹ́tẹ́lì fi àbájáde ìwà òdodo àti ìwà burúkú, ti ṣíṣègbọràn àti ṣíṣàìgbọràn sí Jèhófà, hàn lọ́nà ṣíṣe kedere. Ní àwọn ọdún tí ó ṣáájú, Mósè ti fi yíyàn yìí síwájú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Mo fi ìyè àti ire, àti ikú àti ibi, sí iwájú rẹ lónìí.” (Diutarónómì 30:15, 16) Ṣíṣàṣàrò lórí ìtàn Bẹ́tẹ́lì yóò fún wa níṣìírí láti pe ara wa mọ́ “Ilé Ọlọ́run,” ibi ìjọsìn tòótọ́, kàkà tí a óò fi pe ara wa mọ́ “Ilé Ọṣẹ́.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jékọ́bù àti Ábúráhámù fínnúfíndọ̀ san ìdámẹ́wàá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Òkìtì àlàpà Bẹ́tẹ́lì, ibi tí Jéróbóámù gbé ojúbọ ọmọ màlúù kalẹ̀ sí