ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 12/1 ojú ìwé 4-7
  • Orúkọ Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Níní Ojúlówó Ìgbàgbọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orúkọ Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Níní Ojúlówó Ìgbàgbọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Orúkọ Jésù Dúró Fún
  • Ṣé Jésù ni Ká Gbà Gbọ́ ni Tàbí Késárì?
  • Fífarawé Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Lónìí
  • Ohun Tí Níní Ìgbàgbọ́ Nínú Orúkọ Jésù Túmọ̀ Sí
  • Idi Tí A Fi Gbọdọ Mọ Orukọ Ọlọrun
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ṣé O Gbà Pé Orúkọ Jèhófà Ló Ṣe Pàtàkì Jù?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Orúkọ Ọlọ́run
    Jí!—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 12/1 ojú ìwé 4-7

Orúkọ Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Níní Ojúlówó Ìgbàgbọ́

OBÌNRIN kan sọ fún ọkàn lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Ẹ̀yin èèyàn yìí ò gba Jésù àti ẹ̀jẹ̀ ìràpadà rẹ̀ gbọ́.” Ọkùnrin kan sọ pé: “Ẹ̀ ń pe ara yín ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí Jésù lèmi ní tèmi.”

Ojú ìwòye náà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gba Jésù gbọ́, tàbí pé wọn kò gbé e ga tó, tàn kálẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ni òtítọ́ náà gan-an?

Òtítọ́ ni pé orúkọ náà Jèhófà, tí í ṣe orúkọ Ọlọ́run, ká Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára.a Itamar, tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní Brazil, rántí pé: “Ohun tó yí ìgbésí ayé mi padà ni gbígbọ́ tí mo gbọ́ orúkọ Ọlọ́run. Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo kà á, ṣe ni ó dà bí pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ta jí lójú oorun àsùnwọra. Orúkọ náà, Jèhófà, ru mí lọ́kàn sókè, ó wú mi lórí; ó wọ̀ mí lákínyẹmí ara.” Síbẹ̀síbẹ̀, ó fi kún un pé: “Mo tún nífẹ̀ẹ́ Jésù gidigidi látọkànwá.”

Bẹ́ẹ̀ ni, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé láti lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, “orúkọ Ọmọ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 5:13) Ṣùgbọ́n kí ni gbólóhùn náà, ‘lórúkọ Jésù,’ túmọ̀ sí?

Ohun Tí Orúkọ Jésù Dúró Fún

Gbólóhùn náà, “ní orúkọ Jésù” àti àwọn gbólóhùn tó fara pẹ́ ẹ, wọ́pọ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tàbí “Májẹ̀mú Tuntun.” Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ náà, “orúkọ,” nígbà tí a bá lò ó láti fi tọ́ka sí Jésù, fara hàn ní iye ìgbà tó ju ọgọ́rin, ó fara hàn nígbà ọgbọ̀n nínú ìwé Ìṣe nìkan. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe batisí lórúkọ Jésù, wọ́n ṣèwòsàn lórúkọ rẹ̀, wọ́n kọ́ni lórúkọ rẹ̀, wọ́n ké pe orúkọ rẹ̀, wọ́n jìyà nítorí orúkọ rẹ̀, wọ́n sì gbé orúkọ rẹ̀ ga.—Ìṣe 2:38; 3:16; 5:28; 9:14, 16; 19:17.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ Bíbélì kan ti wí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà fún “orúkọ” ni a máa ń lò lọ́pọ̀ ìgbà nínú Bíbélì “fún gbogbo ohun tí orúkọ túmọ̀ sí, ti àṣẹ, ànímọ́, ipò, iyì, agbára, ọlá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú orúkọ náà.” Nítorí náà, orúkọ Jésù dúró fún ọlá àṣẹ gíga lọ́lá tí Jèhófà Ọlọ́run fi síkàáwọ́ rẹ̀. Jésù tìkára rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:18) Lẹ́yìn tí Pétérù àti Jòhánù wo arọ kan sàn, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù béèrè pé: “Agbára wo tàbí orúkọ ta ni ẹ fi ṣe èyí?” Nígbà náà ni Pétérù fi ìgboyà ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ọlá àṣẹ àti agbára tí orúkọ Jésù dúró fún, nígbà tó sọ ọ́ di mímọ̀ pé ó jẹ́ “ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárétì, . . . nípasẹ̀ ẹni yìí ni ọkùnrin yìí fi dúró níhìn-ín pẹ̀lú ara dídá níwájú yín.”—Ìṣe 3:1-10; 4:5-10.

Ṣé Jésù ni Ká Gbà Gbọ́ ni Tàbí Késárì?

Ṣùgbọ́n o, fífi irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ hàn nínú orúkọ Jésù kò rọrùn. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yóò ‘jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ rẹ̀.’ (Mátíù 24:9) Èé ṣe? Nítorí pé orúkọ Jésù dúró fún ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alákòóso tí Ọlọ́run yàn, Ọba àwọn ọba, ẹni tí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè gbọ́dọ̀ wárí fún, wọn kò sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀.—Sáàmù 2:1-7.

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ọjọ́ Jésù pẹ̀lú kò fẹ́ wárí fún Jésù. Wọ́n sọ pé: “Àwa kò ní ọba kankan bí kò ṣe Késárì,” wọ́n sì tipa báyìí kọ Ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀. (Jòhánù 19:13-15) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ náà, ìyẹn ni agbára àti ọlá àṣẹ Késárì àti ìjọba rẹ̀. Wọ́n tilẹ̀ pinnu pé kí wọ́n pa Jésù kí àwọn lè máa wà nìṣó ní ipò àṣẹ wọn.—Jòhánù 11:47-53.

Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ikú Jésù, ọ̀pọ̀ èèyàn tó pe ara wọn ní Kristẹni tún hu irú ìwà tí àwọn aṣáájú Júù hù. Àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ wọ̀nyí ní ìgbàgbọ́ nínú agbára àti ọlá àṣẹ Orílẹ̀-èdè, wọ́n sì lọ́wọ́ nínú àwọn ogun Orílẹ̀-èdè. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kọkànlá, lẹ́yìn tí ṣọ́ọ̀ṣì kó àwọn jàǹdùkú jọ, tí wọ́n sì sọ wọ́n di ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n pè ní militia Christi, tàbí ẹgbẹ́ ogun Kristi, “ó wá di pé ẹgbẹ́ ogun Kristi yìí tí ṣọ́ọ̀ṣì dá sílẹ̀, ló ń gba ìpinnu ṣe lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú Kirisẹ́ńdọ̀mù, àwọn fúnra wọn ló wá bẹ̀rẹ̀ sí pinnu èwo logun tó tọ́ kí àwọn jà.” (The Oxford History of Christianity) Ìwé náà fi kún un pé àwọn ọ̀rọ̀ kan báyìí tí Póòpù sọ ló sún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ajagun ẹ̀sìn láti gbà pé nípa jíjagun ẹ̀sìn, “ṣe ni àwọn ń bá Ọlọ́run ṣòwò, èyí tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Párádísè tààrà làwọn ń lọ.”

Àwọn kan lè máa jiyàn pé ó ṣeé ṣe láti jólóòótọ́ sí Jésù, kí èèyàn sì tún máa kópa nínú ọ̀ràn òṣèlú, títí kan jíja àwọn ogun orílẹ̀-èdè. Wọ́n lè sọ pé ojúṣe Kristẹni ni láti kọjú ìjà sí ìwà ibi níbikíbi tí ó bá ti rí i, bó bá sì wá di ogun, déédéé náà ni. Ṣùgbọ́n, ṣe ojú ìwòye àwọn Kristẹni ìjímìjí nìyí?

Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn náà, The Christian Century sọ pé: “Àwọn Kristẹni ìjímìjí kò gbaṣẹ́ ológun.” Ó ṣàlàyé pé títí di ọdún 170 sí 180 Sànmánì Tiwa, kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn Kristẹni di ọmọ ogun. Àpilẹ̀kọ náà wá fi kún un pé: “Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ló wá ń di pé àwọn Kristẹni kò tako iṣẹ́ ológun mọ́.”

Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Àpilẹ̀kọ náà nínú The Christian Century ṣàlàyé pé: “Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ohun tó ba ẹ̀sìn Kristẹni lórúkọ jẹ́ jù lọ ni mímú tó mú ìdúró tí kò yàtọ̀ sí ti àwọn tí kì í ṣe Kristẹni nínú ọ̀ràn ogun jíjà. Pé àwọn Kristẹni lè máa polongo ẹ̀sìn Olùgbàlà tí í ṣe ẹni pẹ̀lẹ́, lẹ́sẹ̀ kan náà, kí wọ́n sì tún máa fi taratara ṣètìlẹyìn fún àwọn ogun ẹ̀sìn tàbí ti orílẹ̀-èdè, sọ ẹ̀sìn náà dìdàkudà.”

Fífarawé Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Lónìí

Ó ha ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni lónìí láti fara wé àpẹẹrẹ títayọ ti àwọn Kristẹni ìjímìjí? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọ̀rúndún yìí ti fi hàn pé ó ṣeé ṣe. Nígbà tí Olóòtú ìwé náà, Holocaust Educational Digest ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, ó sọ pé: “Kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí yóò jẹ́ gbà láti lọ sógun. . . . Ì bá ṣe pé ẹ̀sìn yìí ni gbogbo àwọn alágbára ayé ń ṣe ni, [Ogun Àgbáyé Kejì] kì bá jà rárá.”

A lè sọ ohun kan náà nípa àwọn ogun abẹ́lé lọ́ọ́lọ́ọ́, irú èyí tó jà ní Àríwá Ireland. Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù láti ilé dé ilé ní àgbègbè Pùròtẹ́sítáǹtì ní ìlú Belfast. Nígbà tí onílé yẹn mọ̀ pé Kátólíìkì ni Ẹlẹ́rìí náà tẹ́lẹ̀ rí, ó bi í pé: “Nígbà tí o jẹ́ Kátólíìkì, ǹjẹ́ o ṣètìlẹyìn fún IRA [Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ajìjàgbara Ireland]?” Ẹlẹ́rìí náà wòye pé ọkùnrin yìí lè yọwọ́ ìjà, nítorí pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ní àtìmọ́lé ni, wọ́n tì í mọ́lé nígbà tí wọ́n mú un pé ó gbébọn, tó fẹ́ lọ fi pa Kátólíìkì kan. Fún ìdí yìí, Ẹlẹ́rìí náà dáhùn pé: “N kì í ṣe Kátólíìkì mọ́. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tòótọ́, láéláé, n kò ní pa ẹnikẹ́ni nítorí ìjọba kankan tàbí nítorí ẹnikẹ́ni.” Látàrí ìyẹn, onílé náà bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, ó ní: “Kò sí ìpànìyàn tó dára. Iṣẹ́ rere lẹ̀ ń ṣe. Kò ní sú yín, kò ní rẹ̀ yín o.”

Ohun Tí Níní Ìgbàgbọ́ Nínú Orúkọ Jésù Túmọ̀ Sí

Àmọ́ ṣá o, níní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù kò mọ sí wíwulẹ̀ yàgò fún ogun. Ó túmọ̀ sí ṣíṣègbọràn sí gbogbo àṣẹ Kristi. Ó ṣe tán, Jésù sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín,” ọ̀kan lára àwọn àṣẹ rẹ̀ sì ni pé kí a ‘nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Jòhánù 15:14, 17) Ìfẹ́ máa ń wá láti ṣe rere fún àwọn ẹlòmíràn. Ó ń fòpin sí gbogbo ẹ̀tanú ẹ̀yà, ti ẹ̀sìn, àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Jésù ṣàṣefihàn èyí.

Àwọn Júù ọjọ́ Jésù kò fẹ́ rí àwọn ará Samáríà sójú rárá. Ní ìfiwéra, Jésù bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, obìnrin náà àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀. (Jòhánù 4:39) Jésù sọ pẹ̀lú pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí òun “ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) A kò gbọ́dọ̀ fi ìhìn rere rẹ̀ tí ń fúnni ní ìyè mọ sọ́dọ̀ àwọn Júù nìkan. Fún ìdí yìí, a fún Pétérù ní ìtọ́ni pé kí ó lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Kọ̀nílíù, tí í ṣe balógun ọ̀rún ará Róòmù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bófin mu pé kí Júù kan lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tó wá láti inú ẹ̀yà mìíràn, Ọlọ́run fi han Pétérù pé “kò gbọ́dọ̀ pe ènìyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.”—Ìṣe 10:28.

Ní àfarawé Jésù, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fínnú fíndọ̀ ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́—láìka ẹ̀yà wọn, ẹ̀sìn wọn, tàbí ipò wọn sí—láti mọ̀ nípa ìgbàlà tí yóò dé nípasẹ̀ orúkọ Jésù. Ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù ń sún wọn láti ‘polongo ní gbangba pé Jésù ni Olúwa.’ (Róòmù 10:8, 9) A rọ̀ ọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ wọn, kí ìwọ náà lè ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù.

Lóòótọ́ ló yẹ kí orúkọ Jésù ru wá sókè láti ní ìmọ̀lára tó kún fún ìyìn, ọ̀wọ̀, àti ìgbọràn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.” (Fílípì 2:10, 11) Bí àwọn tó pọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé kò bá tilẹ̀ fẹ́ láti tẹrí ba fún ìṣàkóso Jésù, Bíbélì fi hàn pé àkókò náà ti sún mọ́lé tí gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wọn yóò ṣègbé. (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Nítorí náà, ìsinsìnyí ló yẹ ká ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù nípa pípa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, ojú ìwé 28 sí 31, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde ní 1987.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti pànìyàn lórúkọ Jésù, a sì ti pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ nítorí orúkọ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jésù kò ní ẹ̀tanú sí ẹ̀yà mìíràn. Ìwọ ńkọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́