ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 23
ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
Ṣé O Gbà Pé Orúkọ Jèhófà Ló Ṣe Pàtàkì Jù?
“‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni Jèhófà wí.”—ÀÌSÁ. 43:10.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa mọ bá a ṣe lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, ká sì dá a láre.
1-2. Báwo la ṣe mọ̀ pé ọwọ́ pàtàkì ni Jésù fi mú orúkọ Jèhófà?
ỌWỌ́ pàtàkì ni Jésù fi mú orúkọ Jèhófà. Kò sẹ́ni tó fọwọ́ pàtàkì mú orúkọ yẹn tó Jésù. Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù kú kó lè fi hàn pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ àti pé gbogbo ohun tó bá ṣe ló tọ́. (Máàkù 14:36; Héb. 10:7-9) Lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Jésù máa dá gbogbo agbára pa dà fún Bàbá ẹ̀ kí orúkọ Jèhófà lè di mímọ́ pátápátá. (1 Kọ́r. 15:26-28) Jésù nífẹ̀ẹ́ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àjọṣe òun àti Bàbá ẹ̀. Ó tún fi hàn gbangba pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Bàbá ẹ̀ gan-an.
2 Jésù wá sáyé kó lè kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà. (Jòh. 5:43; 12:13) Ó jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mọ orúkọ Bàbá ẹ̀. (Jòh. 17:6, 26) Tó bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ tàbí tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló fún òun lágbára tóun fi ṣe àwọn nǹkan yẹn. (Jòh. 10:25) Kódà, Jésù bẹ Jèhófà pé kó máa ṣọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn òun “nítorí orúkọ [Rẹ̀].” (Jòh. 17:11) Torí náà, tí Jésù bá lè fọwọ́ pàtàkì mú orúkọ Jèhófà, báwo lẹni tó sọ pé ọmọlẹ́yìn Jésù lòun ò ṣe ní mọ orúkọ Ọlọ́run, kó sì máa lò ó?
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Àwa Kristẹni tòótọ́ ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, a sì ń fọwọ́ pàtàkì mú orúkọ Jèhófà. (1 Pét. 2:21) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí àwa tá à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà ṣe ń wàásù “ìhìn rere Ìjọba” Ọlọ́run. (Mát. 24:14) A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fọwọ́ pàtàkì mú orúkọ Jèhófà.
ÀWỌN ÈÈYÀN TÓ Ń JẸ́ ORÚKỌ MỌ́ ỌLỌ́RUN
4. (a) Àṣẹ wo ni Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ kó tó pa dà sọ́run? (b) Ìbéèrè wo la máa dáhùn báyìí?
4 Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Torí náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa wàásù ìhìn rere náà láwọn orílẹ̀-èdè míì yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Tó bá yá, àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè máa láǹfààní láti di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mát. 28:19, 20) Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi.” Ṣé ó yẹ káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn yìí mọ orúkọ Jèhófà àbí wọ́n á kàn máa wàásù nípa Jésù nìkan ni? Àkọsílẹ̀ tó wà ní Ìṣe orí 15 máa dáhùn ìbéèrè yẹn.
5. Báwo ni àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù ṣe fi hàn pé ó yẹ kí gbogbo èèyàn mọ orúkọ Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Lọ́dún 49 S. K., àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù ṣèpàdé kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ó yẹ kí àwọn tí kì í ṣe Júù dádọ̀dọ́ kí wọ́n tó lè di Kristẹni. Nígbà tí wọ́n parí ọ̀rọ̀ náà, Jémíìsì àbúrò Jésù sọ pé: “[Pétérù] ti ròyìn ní kíkún bí Ọlọ́run ṣe yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ kí ó lè mú àwọn èèyàn kan jáde fún orúkọ rẹ̀ látinú wọn.” Orúkọ ta ni Jémíìsì ń sọ? Ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ọ̀rọ̀ wòlíì Émọ́sì, ó ní: “Kí àwọn tó ṣẹ́ kù lè máa wá Jèhófà taratara, àwọn àti àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè, àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè, ni Jèhófà” wí. (Ìṣe 15:14-18) Kì í ṣe pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn yìí máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà nìkan ni, àmọ́ wọ́n á tún ‘máa fi orúkọ ẹ̀ pè wọ́n.’ Ìyẹn ni pé wọ́n á máa jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run, àwọn èèyàn á sì tún fi orúkọ yẹn mọ̀ wọ́n.
Nígbà tí ìgbìmọ̀ olùdarí ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣèpàdé, wọ́n rí i pé ó yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa lo orúkọ Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 5)
6-7. (a) Kí nìdí tí Jésù fi wá sáyé? (b) Ìdí pàtàkì míì wo ló jẹ́ kí Jésù wá sáyé?
6 Ìtumọ̀ orúkọ Jésù ni “Jèhófà Ni Ìgbàlà,” òun sì ni Jèhófà ń lò láti gba gbogbo àwọn tó bá nígbàgbọ́ là. Jésù wá sáyé kó lè fi ẹ̀mí ẹ̀ ra aráyé pa dà. (Mát. 20:28) Ìràpadà tó san máa jẹ́ kí aráyé rígbàlà, ká sì lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 3:16.
7 Àmọ́ kí nìdí tí aráyé fi nílò ìràpadà? Torí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì ni. Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Ádámù àti Éfà tó jẹ́ òbí wa àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n sì pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé. (Jẹ́n. 3:6, 24) Àmọ́ ohun míì wà tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé tó ṣe pàtàkì ju bó ṣe gba àwa èèyàn là. Ṣẹ́ ẹ rántí pé Sátánì ti ba orúkọ Jèhófà jẹ́? (Jẹ́n. 3:4, 5) Torí náà, káwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tó lè rígbàlà, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ohun tí Sátánì sọ nípa Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn á sì sọ orúkọ ẹ̀ di mímọ́. Torí pé Jèhófà ló rán Jésù wá, tó sì ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn, ìyẹn jẹ́ kó kópa pàtàkì nínú sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́.
Báwo lẹnì kan tó sọ pé ọmọlẹ́yìn Jésù lòun ò ṣe ní mọ orúkọ Ọlọ́run, kó sì máa lò ó?
8. Kí ló yẹ kí gbogbo àwọn tó gba Jésù gbọ́ mọ̀?
8 Gbogbo ẹni tó bá nígbàgbọ́ nínú Jésù bóyá Júù ni wọ́n tàbí wọn kì í ṣe Júù gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà Bàbá Jésù ló jẹ́ kí wọ́n rígbàlà. (Jòh. 17:3) Bákan náà bíi Jésù, wọ́n á máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí orúkọ Jèhófà di mímọ́, torí tí wọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn ò lè rígbàlà. (Ìṣe 2:21, 22) Torí náà, gbogbo olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù. Abájọ tí Jésù fi parí àdúrà tó gbà ní Jòhánù 17 pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n, kí ìfẹ́ tí o ní fún mi lè wà nínú wọn, kí n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn.”—Jòh. 17:26.
“Ẹ̀YIN NI ẸLẸ́RÌÍ MI”
9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé orúkọ Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù?
9 Ó ti han gbangba pé gbogbo ẹni tó máa di ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́ gbọ́dọ̀ sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. (Mát. 6:9, 10) A gbọ́dọ̀ gbé orúkọ Jèhófà ga ju gbogbo orúkọ míì lọ. Ìyẹn sì gbọ́dọ̀ máa hàn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Àmọ́ báwo la ṣe lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ tàbí mú ẹ̀gàn tí Sátánì kó bá orúkọ náà kúrò?
10. Ẹjọ́ wo ni Àìsáyà orí 42 sí 44 ṣàpèjúwe? (Àìsáyà 43:9; 44:7-9) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Àìsáyà orí 42 sí 44 jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. Nínú àwọn orí Bíbélì yìí, Jèhófà ní káwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run èké wá sọ bóyá Ọlọ́run tòótọ́ làwọn ń jọ́sìn. Ó tún ní káwọn ẹlẹ́rìí wọn wá láti jẹ́rìí. Àmọ́ kò sẹ́nì kankan tó jáde!—Ka Àìsáyà 43:9; 44:7-9.
Oríṣiríṣi ọ̀nà là ń gbà jẹ́rìí pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ (Wo ìpínrọ̀ 10-11)
11. Kí ni Jèhófà sọ fáwa èèyàn ẹ̀ ní Àìsáyà 43:10-12?
11 Ka Àìsáyà 43:10-12. Jèhófà sọ nípa àwa èèyàn ẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, . . . èmi sì ni Ọlọ́run.” Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń bi wá pé: “Ṣé Ọlọ́run kankan wà yàtọ̀ sí mi ni?” (Àìsá. 44:8) Torí náà, a láǹfààní láti dáhùn ìbéèrè yẹn. Ìwà tá a bá ń hù àtohun tá a bá ń ṣe ló máa fi hàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo. Orúkọ ẹ̀ ju gbogbo orúkọ míì lọ. Bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa ló máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an àti pé a jẹ́ olóòótọ́ bí Sátánì tiẹ̀ ń pọ́n wa lójú. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ nìyẹn.
12. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Àìsáyà 40:3, 5 ṣe ṣẹ?
12 Tá a bá ń sọ ohun tó dáa nípa orúkọ Jèhófà, ó fi hàn pé à ń fara wé Jésù. Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹnì kan máa “tún ọ̀nà Jèhófà ṣe [tàbí, “múra ọ̀nà Jèhófà sílẹ̀,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé].” (Àìsá. 40:3) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ṣẹ? Jòhánù Oníbatisí múra ọ̀nà sílẹ̀ de Jésù tó wá ṣojú Jèhófà, tó sì tún sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jèhófà. (Mát. 3:3; Máàkù 1:2-4; Lúùkù 3:3-6) Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ pé: “A máa ṣí ògo Jèhófà payá.” (Àìsá. 40:5) Báwo nìyẹn náà ṣe ṣẹ? Nígbà tí Jésù wá sáyé, ó ṣojú Jèhófà láìkù síbì kan, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló wá sáyé.—Jòh. 12:45.
13. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù?
13 Bíi Jésù, ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. À ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, a sì ń sọ àwọn nǹkan àgbàyanu tó ti ṣe. Àmọ́ ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀ dáadáa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí Jésù ṣe kó lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. (Ìṣe 1:8) Kò sẹ́ni tó lè jẹ́rìí Jèhófà bíi Jésù, a sì ń fara wé e. (Ìfi. 1:5) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé orúkọ Jèhófà ṣe pàtàkì?
ÀWỌN NǸKAN TÁ A LÈ ṢE TÁÁ FI HÀN PÉ ORÚKỌ JÈHÓFÀ ṢE PÀTÀKÌ
14. Bí Sáàmù 105:3 ṣe sọ, báwo ló ṣe rí lára wa torí pé a nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà?
14 À ń fi orúkọ Jèhófà yangàn. (Ka Sáàmù 105:3.) Inú Jèhófà máa ń dùn sí wa tá a bá ń fi orúkọ ẹ̀ yangàn. (Jer. 9:23, 24; 1 Kọ́r. 1:31; 2 Kọ́r. 10:17) Kéèyàn “máa fi Jèhófà yangàn” ni pé kó máa sọ fáwọn èèyàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run òun. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa bọlá fún orúkọ ẹ̀, ká sì máa ṣe ohun tó máa sọ ọ́ di mímọ́. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ tijú rárá láti sọ fáwọn ọmọ ilé ìwé wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn aládùúgbò wa àtàwọn míì pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá! Èṣù ò fẹ́ ká sọ nípa orúkọ Jèhófà fáwọn èèyàn mọ́. (Jer. 11:21; Ìfi. 12:17) Kódà, Sátánì àtàwọn wòlíì èké fẹ́ káwọn èèyàn gbàgbé orúkọ Jèhófà. (Jer. 23:26, 27) Àmọ́ torí pé a nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà, inú wa ń dùn “láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sm. 5:11; 89:16.
15. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé à ń ké pe orúkọ Jèhófà?
15 À ń ké pe orúkọ Jèhófà. (Jóẹ́lì 2:32; Róòmù 10:13, 14) Tá a bá ń ké pe orúkọ Jèhófà, ó ju ká kàn mọ orúkọ ẹ̀, ká sì máa lò ó. Ó yẹ ká mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, ká gbẹ́kẹ̀ lé e, ká jẹ́ kó ràn wá lọ́wọ́, ká sì jẹ́ kó máa tọ́ wa sọ́nà. (Sm. 20:7; 99:6; 116:4; 145:18) Ó tún yẹ ká máa sọ orúkọ ẹ̀ àti ànímọ́ ẹ̀ fáwọn èèyàn, ká máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n rí ojú rere ẹ̀.—Àìsá. 12:4; Ìṣe 2:21, 38.
16. Báwo la ṣe lè fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì?
16 A ṣe tán láti jìyà nítorí orúkọ Jèhófà. (Jém. 5:10, 11) Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà ìṣòro, à ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì nìyẹn. Nígbà ayé Jóòbù, Sátánì sọ nípa àwa ìránṣẹ́ Jèhófà pé: “Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.” (Jóòbù 2:4) Sátánì sọ pé ìgbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa sìn ín. Àmọ́ tọ́wọ́ ìyà bá bà wọ́n, wọ́n á fi Jèhófà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, Jóòbù jẹ́ olóòótọ́, ó sì fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Àwa náà lè fìwà jọ Jóòbù, ká sì fi hàn pé ohun yòówù kí Sátánì ṣe sí wa, a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà á máa dáàbò bò wá nítorí orúkọ rẹ̀.—Jòh. 17:11.
17. Kí ni 1 Pétérù 2:12 sọ pé ká ṣe tá a bá fẹ́ gbé orúkọ Jèhófà ga?
17 À ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Jèhófà. (Òwe 30:9; Jer. 7:8-11) Torí pé à ń ṣojú Jèhófà, a sì ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn, ohun tá a bá ṣe lè yin orúkọ ẹ̀ lógo tàbí tàbùkù sí orúkọ ẹ̀. (Ka 1 Pétérù 2:12.) Torí náà, a fẹ́ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ọ̀rọ̀ wa àti ìwà wa yin Jèhófà lógo. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa gbé orúkọ Jèhófà ga, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá.
18. Nǹkan míì wo la lè ṣe táá fi hàn pé orúkọ Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
18 Orúkọ Jèhófà ṣe pàtàkì ju ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa wa lọ. (Sm. 138:2) Kí nìdí tí orúkọ Jèhófà fi ṣe pàtàkì ju ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa wa lọ? Ìdí ni pé tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, àwọn tó sún mọ́ wa lè máa sọ nǹkan tí ò dáa nípa wa. Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, bá a ṣe máa gbé orúkọ Jèhófà ga ló ṣe pàtàkì jù.a Nígbà tí Jésù kú, àwọn èèyàn fojú ọ̀daràn wò ó, wọ́n sì pẹ̀gàn ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ohun tó ṣe yẹn gbé orúkọ Jèhófà ga. Jésù ò “ka ìtìjú sí” torí pé kò máa ronú ṣáá nípa ohun tí ò dáa táwọn èèyàn ń sọ nípa ẹ̀. (Héb. 12:2-4) Àmọ́ bó ṣe máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló gbájú mọ́.—Mát. 26:39.
19. Báwo ló ṣe rí lára ẹ torí ò ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, kí sì nìdí?
19 A máa ń fi orúkọ Jèhófà yangàn, inú wa sì máa ń dùn pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà. Ìdí nìyẹn tá a fi ń fara dà á táwọn èèyàn bá ń pẹ̀gàn wa. Orúkọ Jèhófà ṣe pàtàkì ju ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa wa lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa yin orúkọ Jèhófà lógo bí Sátánì tiẹ̀ ń pọ́n wa lójú. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa fi hàn pé orúkọ Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù, bó ṣe ṣe pàtàkì lójú Jésù.
ORIN 10 Ẹ Yin Jèhófà Ọlọ́run Wa!
a Olóòótọ́ ni Jóòbù, àmọ́ nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́ta sọ pé ó ti ṣe nǹkan tí ò dáa, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ojú táwọn èèyàn fi ń wo òun. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀ kú, tó sì pàdánù gbogbo ohun ìní ẹ̀, “Jóòbù ò dẹ́ṣẹ̀, kò sì fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé ó ṣe ohun tí kò dáa.” (Jóòbù 1:22; 2:10) Àmọ́ nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án, ó sọ “ọ̀rọ̀ ẹhànnà.” Bó ṣe máa gbèjà ara ẹ̀, tórúkọ ẹ̀ ò sì ní bà jẹ́ ló ṣe pàtàkì lójú ẹ̀ ju bó ṣe máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́.—Jóòbù 6:3; 13:4, 5; 32:2; 34:5.