ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 22
ORIN 15 Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!
Jésù Kọ́ Wa Pé Orúkọ Jèhófà Ló Ṣe Pàtàkì Jù
“Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n.”—JÒH. 17:26.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jésù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, bó ṣe sọ ọ́ di mímọ́ àti bó ṣe dá a láre.
1-2. (a) Kí ni Jésù ṣe lálẹ́ tó ṣáájú ikú ẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ỌJỌ́ Thursday, Nísàn 14, ọdún 33 S.K. lọjọ́ náà. Ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, Júdásì máa tó da Jésù, wọ́n máa ṣẹjọ́ ẹ̀, wọ́n máa dá a lẹ́bi, wọ́n máa fìyà jẹ ẹ́, wọ́n á sì pa á. Òun àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ olóòótọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ oúnjẹ àkànṣe kan tán ní yàrá òkè kan, ìyẹn Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Lẹ́yìn oúnjẹ náà, ó bá wọn sọ̀rọ̀ táá jẹ́ kí wọ́n nígboyà torí pé kò ní pẹ́ kú. Àmọ́ kí wọ́n tó kúrò ní yàrá òkè náà, Jésù gbàdúrà pàtàkì kan. Àpọ́sítélì Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ àdúrà yẹn, ó sì wà nínú Jòhánù orí 17.
2 Àwọn nǹkan wo ló ń da Jésù láàmú lákòókò yẹn? Kí ni àdúrà yẹn fi hàn pé ó ṣe pàtàkì lójú Jésù nígbà tó ń wàásù? Ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
“MO TI JẸ́ KÍ WỌ́N MỌ ORÚKỌ RẸ”
3. Kí ni Jésù sọ nípa orúkọ Jèhófà, kí ló sì fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ̀? (Jòhánù 17:6, 26)
3 Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, ó sọ pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ.” Kódà, ẹ̀ẹ̀mejì ló sọ pé òun ti jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ orúkọ Jèhófà. (Ka Jòhánù 17:6, 26.) Kí ni Jésù fẹ́ kí wọ́n mọ̀? Ṣé orúkọ tí wọn ò mọ̀ ló ń sọ ni? Júù làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, torí náà wọ́n mọ̀ pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ìgbà lorúkọ náà fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Torí náà, kì í ṣe orúkọ Ọlọ́run gangan ni Jésù ń sọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Jésù ló jẹ́ ká mọ Jèhófà dáadáa. Ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó ti ṣe àtàwọn ànímọ́ ẹ̀ títí kan ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé.
4-5. (a) Ṣàpèjúwe bá a ṣe lè túbọ̀ mọ ẹnì kan. (b) Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe túbọ̀ mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́?
4 A lè ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí. Ká sọ pé alàgbà kan níjọ ẹ tó ń jẹ́ David jẹ́ dókítà tó máa ń ṣiṣẹ́ abẹ. Ó ti pẹ́ tó o ti mọ arákùnrin yẹn. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, wọ́n gbé ẹ dìgbàdìgbà lọ sílé ìwòsàn tí arákùnrin náà ti ń ṣiṣẹ́. Ó tọ́jú ẹ, ó sì gba ẹ̀mí ẹ là. Ṣé ohun tí arákùnrin yẹn ṣe jẹ́ kó o túbọ̀ mọ ẹni tó jẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni! Ní báyìí, o ti túbọ̀ mọ ẹni tí David jẹ́ torí ó gbẹ̀mí ẹ là.
5 Lọ́nà kan náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti mọ orúkọ Jèhófà tẹ́lẹ̀. Àmọ́ wọ́n túbọ̀ mọ orúkọ náà nígbà tí Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jésù fìwà jọ Bàbá ẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ṣe àtohun tó sọ. Torí náà, àwọn àpọ́sítélì Jésù túbọ̀ “mọ” Jèhófà bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ohun tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń wo bó ṣe ń hùwà sí wọn.—Jòh. 14:9; 17:3.
“ORÚKỌ RẸ, TÍ O TI FÚN MI”
6. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé Jèhófà ti fún òun ní orúkọ rẹ̀? (Jòhánù 17:11, 12)
6 Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, ó bẹ Jèhófà nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó sọ pé: “Máa ṣọ́ wọn nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi.” (Ka Jòhánù 17:11, 12.) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé òun ni Jèhófà báyìí? Rárá o. Kíyè sí i pé nígbà tí Jésù ń gbàdúrà, ó sọ pé “orúkọ rẹ,” kò sọ pé orúkọ mi. Torí náà, Jésù ò sọ orúkọ Jèhófà di tara ẹ̀. Kí wá ni Jésù ń sọ nígbà tó ní Ọlọ́run ti fún òun ní orúkọ rẹ̀? Ohun àkọ́kọ́ ni pé Jésù ni aṣojú Jèhófà àti Agbẹnusọ rẹ̀. Bàbá rẹ̀ ló rán an wá sáyé, orúkọ Bàbá ẹ̀ ló sì fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe. (Jòh. 5:43; 10:25) Ìkejì, orúkọ Jésù túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Àbẹ́ ò rí nǹkan, Jèhófà tún fara hàn nínú ìtumọ̀ orúkọ Jésù.
7. Ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe jẹ́ aṣojú Jèhófà.
7 Wo àpèjúwe yìí ná. Tí alákòóso kan ò bá lè lọ síbì kan, aṣojú ẹ̀ ló máa ń rán lọ. Torí náà, ohun tí aṣojú yẹn bá sọ níbẹ̀, alákòóso yẹn ló sọ ọ́. Lọ́nà kan náà, aṣojú Jèhófà ni Jésù, ohun tí Jèhófà bá ní kó sọ fáwọn èèyàn ló máa ń sọ.—Mát. 21:9; Lúùkù 13:35.
8. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé orúkọ òun “wà lára” Jésù kó tó wá sáyé? (Ẹ́kísódù 23:20, 21)
8 Bíbélì pe Jésù ní Ọ̀rọ̀ náà torí pé òun ni Agbẹnusọ Jèhófà, Jèhófà sì máa ń lò ó láti sọ ohun tó fẹ́ fáwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn. (Jòh. 1:1-3) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù ni áńgẹ́lì tí Jèhófà ní kó bójú tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń kúrò ní Íjíbítì. Jèhófà sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbọ́ràn sí áńgẹ́lì náà lẹ́nu, ó sọ pé: “Torí pé orúkọ mi wà lára rẹ̀.”a (Ka Ẹ́kísódù 23:20, 21.) Orúkọ Jèhófà “wà lára” Jésù torí pé ó máa ń gbẹnu sọ fún Jèhófà, òun ló sì ń múpò iwájú tó bá di pé ká sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, ká sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́.
“BABA, ṢE ORÚKỌ RẸ LÓGO”
9. Báwo la ṣe mọ̀ pé orúkọ Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù lójú Jésù?
9 Bá a ṣe sọ ṣáájú, orúkọ Jèhófà ṣe pàtàkì gan-an lójú Jésù, kódà kó tó wá sáyé. Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jésù wà láyé, gbogbo nǹkan tó ṣe ló fi hàn pé orúkọ yẹn ló ṣe pàtàkì jù lójú ẹ̀. Nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ń parí lọ, ó sọ pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà fi ohùn tó dún ketekete dá a lóhùn pé: “Mo ti ṣe é lógo, màá sì tún ṣe é lógo.”—Jòh. 12:28.
10-11. (a) Báwo ni Jésù ṣe ṣe orúkọ Bàbá ẹ̀ lógo? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí Jèhófà sọ orúkọ ẹ̀ di mímọ́, kó sì dá a láre?
10 Jésù náà ṣe orúkọ Bàbá ẹ̀ lógo. Báwo ló ṣe ṣe é? Ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní àtàwọn nǹkan àgbàyanu tó ń ṣe. Kò tán síbẹ̀ o, Jésù tún ṣe àwọn nǹkan míì. Ó sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, ó sì dá orúkọ náà láre.b Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn nǹkan yìí ṣe pàtàkì gan-an nígbà tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ní àdúrà Olúwa, ó sọ pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.”—Mát. 6:9.
11 Kí nìdí tó fi yẹ kí Jèhófà sọ orúkọ ẹ̀ di mímọ́, kó sì dá a láre? Ìdí ni pé nínú ọgbà Édẹ́nì, Sátánì Èṣù parọ́ mọ́ Jèhófà, ó sì bà á lórúkọ jẹ́. Sátánì sọ pé irọ́ ni Jèhófà ń pa fún Ádámù àti Éfà, kò sì fún wọn ní ẹ̀tọ́ wọn. (Jẹ́n. 3:1-5) Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé bí Jèhófà ṣe ń ṣàkóso ò dáa. Àwọn ẹ̀sùn yìí fi hàn pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ ni. Nígbà ayé Jóòbù, Sátánì sọ pé àwọn èèyàn ń sin Jèhófà torí ohun tí wọ́n ń rí gbà lọ́wọ́ ẹ̀. Ó tún parọ́ mọ́ wa pé a ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti pé tọ́wọ́ ìyà bá bà wá, a ò ní sin Jèhófà mọ́. (Jóòbù 1:9-11; 2:4) Torí náà, ó máa gba àkókò ká tó lè mọ̀ bóyá Jèhófà ló ń parọ́ àbí Sátánì.
Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ (Wo ìpínrọ̀ 10)
“MO FI Ẹ̀MÍ MI LÉLẸ̀”
12. Kí ni Jésù ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
12 Torí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́ kó sì dá a láre. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé “mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀.” (Jòh. 10:17, 18) Kódà, ó ṣe tán láti kú nítorí orúkọ Jèhófà.c Ádámù àti Éfà ni Jèhófà kọ́kọ́ dá, ẹni pípé ni wọ́n, àmọ́ wọ́n ṣàìgbọràn, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n Jésù yàtọ̀ ní tiẹ̀, ó gbà láti wá sáyé torí ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì fi hàn bẹ́ẹ̀ torí ó jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. (Héb. 4:15; 5:7-10) Kódà, ó ṣe bẹ́ẹ̀ títí tó fi kú lórí òpó igi oró. (Héb. 12:2) Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti orúkọ rẹ̀.
13. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù lẹni tó lè fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Bí Jésù ṣe gbé ìgbé ayé ẹ̀ fi hàn láìkù síbì kan pé òpùrọ́ ni Sátánì, olóòótọ́ sì ni Jèhófà. (Jòh. 8:44) Kò sẹ́ni tó mọ Jèhófà tó Jésù. Tó bá jẹ́ pé òótọ́ làwọn ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà, Jésù máa mọ̀. Torí pé Jésù mọ Jèhófà dáadáa, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ẹni rere ni. Kódà nígbà tó jọ pé Jèhófà ti fi í sílẹ̀, Jésù ṣe tán láti kú dípò kó kẹ̀yìn sí Bàbá ẹ̀.—Mát. 27:46.d
Bí Jésù ṣe gbé ìgbé ayé ẹ̀ fi hàn láìkù síbì kan pé òpùrọ́ ni Sátánì, olóòótọ́ sì ni Jèhófà! (Wo ìpínrọ̀ 13)
“MO TI PARÍ IṢẸ́ TÍ O NÍ KÍ N ṢE”
14. Èrè wo ni Jèhófà san fún Jésù torí pé ó jẹ́ olóòótọ́?
14 Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà ní alẹ́ tó ṣáájú ikú ẹ̀, ó sọ pé: “Mo ti parí iṣẹ́ tí o ní kí n ṣe.” Ó mọ̀ pé Jèhófà máa san èrè fún òun torí òun jẹ́ olóòótọ́. (Jòh. 17:4, 5) Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀ torí pé kò fi í sílẹ̀ sínú isà òkú. (Ìṣe 2:23, 24) Ó jí Jésù dìde, ó sì gbé e sípò gíga lọ́run. (Fílí. 2:8, 9) Nígbà tó yá, Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Àmọ́ àwọn ohun rere wo ni Ìjọba yẹn máa ṣe fáráyé? Ohun kejì tí Jésù sọ nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ní àdúrà Olúwa dáhùn ìbéèrè yìí, ó ní: “Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ [Jèhófà] ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.”—Mát. 6:10.
15. Àwọn nǹkan míì wo ni Jésù máa ṣe?
15 Láìpẹ́, Jésù máa ja ogun Amágẹ́dọ́nì, ó sì máa pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. (Ìfi. 16:14, 16; 19:11-16) Àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà, Jésù máa sọ Sátánì sínú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” níbi tí kò ti ní lè ṣe ohunkóhun mọ́. (Ìfi. 20:1-3) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àlàáfíà máa wà, ó sì máa sọ àwa èèyàn di pípé. Ó máa jí àwọn òkú dìde, ó sì máa sọ gbogbo ayé di Párádísè. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, gbogbo nǹkan máa rí bí Jèhófà ṣe fẹ́!—Ìfi. 21:1-4.
16. Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí?
16 Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí? Kò ní sí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé mọ́. Àwa èèyàn ò ní bẹ Jèhófà mọ́ pé kó dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, a ò ní nílò àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) mọ́ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà, Jésù ò sì ní ṣiṣẹ́ Àlùfáà Àgbà mọ́ láti máa bá wa bẹ̀bẹ̀ ká tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. ‘Ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn, ìyẹn ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù á ti di asán nígbà yẹn.’ Kò ní sí isà òkú mọ́. Àwọn òkú á ti jíǹde. Gbogbo èèyàn tó wà láyé á sì ti di pípé.—1 Kọ́r. 15:25, 26.
17-18. (a) Àwọn nǹkan míì wo ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí? (b) Kí ni Jésù máa ṣe lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso ẹ̀? (1 Kọ́ríńtì 15:24, 28) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
17 Àwọn nǹkan míì wo ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí? Nígbà yẹn, nǹkan àrà ọ̀tọ̀ kan máa ṣẹlẹ̀. Gbogbo èèyàn á ti rí i pé orúkọ Jèhófà ti di mímọ́. Báwo ló ṣe máa ṣẹlẹ̀? Ní ọgbà Édẹ́nì, Sátánì sọ pé òpùrọ́ ni Jèhófà àti pé bó ṣe ń ṣàkóso fi hàn pé kò nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Àtìgbà yẹn làwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn ti ń ṣe ohun tó fi hàn pé orúkọ Jèhófà jẹ́ mímọ́. Tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá fi máa parí, Jèhófà á ti dá orúkọ ẹ̀ láre pátápátá. Gbogbo èèyàn á ti wá rí i nígbà yẹn pé Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà.
18 Lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, gbogbo èèyàn máa mọ̀ pé irọ́ gbuu ni Sátánì ń pa mọ́ Jèhófà. Kí ni Jésù máa ṣe lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso ẹ̀? Ṣé ó máa ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà bíi Sátánì? Rárá o! (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:24, 28.) Jésù máa dá Ìjọba náà pa dà fún Bàbá ẹ̀, á sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà nìṣó. Jésù ò ní fìwà jọ Sátánì torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì máa dá agbára àti gbogbo ohun tó ní pa dà fún Bàbá ẹ̀.
Jésù máa dá Ìjọba pa dà fún Bàbá ẹ̀ lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 18)
19. Báwo la ṣe mọ̀ pé orúkọ Jèhófà ṣe pàtàkì lójú Jésù?
19 Kò yà wá lẹ́nu pé Jèhófà fún Jésù ní orúkọ ẹ̀! Ó ṣe tán, Jésù ló jẹ́ ká mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. Báwo la ṣe mọ̀ pé orúkọ Jèhófà ṣe pàtàkì lójú Jésù? Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé ó ṣe tán láti kú nítorí orúkọ yẹn torí kò sí nǹkan míì tó ṣe pàtàkì lójú Jésù tó orúkọ náà, ìyẹn sì máa mú kó dá ohun gbogbo pa dà fún Jèhófà lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso ẹ̀. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? A máa dáhùn ìbéèrè yẹn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 16 Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn
a Nígbà míì, àwọn áńgẹ́lì máa ń ṣojú Jèhófà tí wọ́n bá ń jíṣẹ́ ẹ̀ fáwọn èèyàn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà míì, táwọn áńgẹ́lì bá ń sọ̀rọ̀, Bíbélì máa ń sọ ọ́ bíi pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ń sọ̀rọ̀. (Jẹ́n. 18:1-33) Òótọ́ ni pé Ìwé Mímọ́ sọ pé Jèhófà ló fún Mósè ní Òfin, àmọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì míì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà lò láti fún Mósè ní Òfin náà.—Léf. 27:34; Ìṣe 7:38, 53; Gál. 3:19; Héb. 2:2-4.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ká ‘sọ nǹkan di mímọ́’ ni pé ká bọ̀wọ̀ fún nǹkan náà, ká kà á sí mímọ́, ká sì gbà pé nǹkan náà ló ṣe pàtàkì jù. Ká ‘dá ẹnì kan láre’ ni pé ká mú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan ẹni náà kúrò, kí wọ́n dá ẹni náà sílẹ̀ pé kò jẹ̀bi tàbí kí wọ́n dá a sílẹ̀ pé kò mọ nǹkan kan nípa irọ́ tí wọ́n pa mọ́ ọn.
c Ikú Jésù ló jẹ́ káwa èèyàn nírètí pé a máa wà láàyè títí láé.
d Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ April 2021, ojú ìwé 30-31.