Ọ̀pọ̀ Ń Pe Ara Wọn Lónígbàgbọ́
OBÌNRIN olùfọkànsìn ará Brazil kan pòkìkí pé: “Jésù yìí o, àgbàyanu ni! Àní kò láfiwé!” Ẹ̀gàn ni hẹ̀, orúkọ Jésù lágbára. Jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn, àwọn ènìyàn ti fara wọn fún ìyà jẹ, wọ́n sì ti kú nítorí rẹ̀.
Àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù wàásù ‘nípa orúkọ Jésù’ ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n mú wọn, wọ́n sì nà wọ́n lọ́rẹ́ nítorí èyí. Síbẹ̀, wọ́n “bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀.”—Ìṣe 5:28, 41.
Kristẹni mìíràn ní ọ̀rúndún kìíní tó gbé orúkọ Jésù gẹ̀gẹ̀ ni Áńtípà. Nínú Ìṣípayá, tí í ṣe ìwé tó gbẹ̀yìn Bíbélì, Jésù pè é ní “ẹlẹ́rìí mi, olùṣòtítọ́, ẹni tí a pa ní ẹ̀gbẹ́ yín, níbi tí Sátánì ń gbé.” (Ìṣípayá 2:13) Bí ti àwọn Kristẹni yòókù ní Pẹ́gámọ́mù, Áńtípà kò sẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Kristi. Típẹ́típẹ́ ni Áńtípà rọ̀ mọ́ orúkọ Jésù, àní dójú ikú!
Ní nǹkan bí àádọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, ní ọdún 155 Sànmánì Tiwa, Polycarp, tí í ṣe Kristẹni, dojú kọ irú ìdánwò bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n ní kí ó bú Kristi. Èsì rẹ̀ nìyí: “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún rèé tí mo ti ń sìn Ín, kò sì ṣe mí ní ibi kankan. Báwo wá ni mo ṣe lè sọ̀rọ̀ òdì sí Ọba mi tó ti gbà mí?” Nítorí pé Polycarp kọ̀ tí kò sẹ́ Kristi, wọ́n dáná sun ún lórí òpó igi.
Àwọn àpọ́sítélì, Áńtípà, àti àwọn mìíràn pinnu pé, ní tàwọn o, bí wọ́n bá fẹ́ pa àwọn kí wọ́n pa àwọn, àwọn ò ní yéé jẹ́rìí nípa Kristi! Àwọn ènìyàn lónìí ńkọ́?
Orúkọ Jésù Lónìí
Orúkọ Jésù ṣì ń ru àwọn èèyàn sókè gidigidi. Ní Latin America, ọ̀nà tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó sọ pé àwọn gba Jésù gbọ́ gbà ń gbèrú ga púpọ̀ a ò rírú ẹ̀ rí ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́. Kódà abúlé tó kéré jù lọ ní ṣọ́ọ̀ṣì Onígbàgbọ́ Wò-ó-sàn tirẹ̀. Bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyẹn ṣe ń pọ̀ sí i ni wọ́n túbọ̀ ń tọrùn bọ ọ̀ràn ìṣèlú. Fún àpẹẹrẹ, ìjókòó mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni àwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí kó nínú Àwọn Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti ilẹ̀ Brazil.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ẹlẹ́sìn tuntun kan ní orílẹ̀-èdè United States gbé Jésù lérí. Àwọn alátẹ̀lé wọn ń pe ara wọn ní Olùpa Ẹ̀jẹ́ Mọ́. Ìwé ìròyìn náà, Time, ròyìn ní ọdún 1997 pé ẹgbàajì ó lé igba (4,200) ní ń lọ sípàdé wọn ní ọdún 1991, ṣùgbọ́n ní ọdún 1996, wọ́n ti pọ̀ tó mílíọ̀nù kan ó lé ọ̀kẹ́ márùn-ún. Ọ̀kan nínú àwọn orin wọn lọ báyìí: “Ìṣẹ́gun lórúkọ Jésù, Olùgbàlà mi títí láé.”
Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ohun tí a ṣe lórúkọ Jésù ló dára. Ọ̀pọ̀ ogun ni a ti jà lórúkọ Jésù. Wọ́n ti pa àwọn Júù ní ìpakúpa, wọ́n ti pa àwọn abọgibọ̀pẹ̀ ní ìpa-ìkà, wọ́n ti dá àwọn tí kò gba tiwọn lóró, wọ́n ti dọ́gbẹ́ sí wọn lára yánnayànna, wọ́n sì ti dáná sun wọ́n lórí òpó igi—gbogbo rẹ̀ náà lórúkọ Jésù ni. Ohun tí ó tilẹ̀ tún wá gbòde kan báyìí ni pé iṣẹ́ ìjíhìnrere ti di òwò. Gbogbo èyí kò bójú mu, àti pé lọ́nà tó burú jáì, ó jẹ́ àṣìlò orúkọ Jésù àti ohun náà gan-an tó dúró fún!
Síwájú sí i, èyí tún gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì kan dìde: Kí ló túmọ̀ sí láti ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù? Kí sì ni ojú ìwòye Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ọ̀ràn yìí? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí.