Wíwà Ní Bèbè Ìgbòkègbodò Púpọ̀ Sí I
“KÒ SẸ́NI tó lẹ́mìí ìbánidíje. Olúkúlùkù fẹ́ kí ẹnì kejì ṣàṣeyege,” bí Richard àti Lusia ṣe ṣàpèjúwe àwọn tí wọ́n jọ kẹ́kọ̀ọ́ ní kíláàsì karùnlélọ́gọ́rùn-ún ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead nìyẹn. “Gbogbo wa yàtọ̀ síra pátápátá, ṣùgbọ́n lọ́kàn gbogbo wa, akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n.” Lowell, tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì kan náà gbà pẹ̀lú rẹ̀, ó fi kún un pé: “Ìyàtọ̀ tó wà láàárín wa ti fà wá mọ́ra.”
Lóòótọ́, ẹ̀dá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbogbo àwọn tó wà ní kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní September 12, 1998. Àwọn kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ṣe aṣáájú ọ̀nà ní àwọn àgbègbè tí àìní gbé pọ̀ fún akéde Ìjọba náà; àwọn mìíràn ti fi tọkàntọkàn sìn nítòsí ìlú wọn. Àwọn díẹ̀, bí Mats àti Rose-Marie, ní láti ṣiṣẹ́ kára fún ọ̀pọ̀ àkókò, kí ìmọ̀ wọn nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì lè gbé pẹ́ẹ́lí sí i, kí wọ́n tó wá sí ilé ẹ̀kọ́ náà. Láti ìgbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti wà lọ́mọdé ni wọ́n ti ń ronú nípa iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Ìgbà kejìlá rèé tí tọkọtaya kan yóò gba fọ́ọ̀mù; nígbà tí wọ́n rí ìwé pé kí wọ́n wá sí kíláàsì karùnlélọ́gọ́rùn-ún, báa bá gẹṣin nínú wọn a kò ní kọsẹ̀ rárá!
Àfi bí ẹni pé kí ogun ọ̀sẹ̀ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ náà má parí. Bí eré bí àwàdà, wọ́n ti parí iṣẹ́ wọn tó kẹ́yìn, wọ́n sọ ìròyìn wọn, ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege sì ti wọlé wẹ́rẹ́.
Alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀hún, Albert Schroeder, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, rán kíláàsì náà létí pé, dídara tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ iye tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin (7,000) àwọn tó ti kọ́kọ́ wá sí ilé ẹ̀kọ́ Gilead mú kí wọ́n “wà ní bèbè ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti gbádùn àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́, nípa níní ìfararora pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì ọlọ́jọ́ pípẹ́, nígbà tí àpéjọpọ̀ àgbáyé mú kí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́.
Lẹ́yìn èyí, Arákùnrin Schroeder ké sí Max Larson, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí Sí Ìlọgeere Iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì. Arákùnrin Larson jíròrò ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Tí Ń Sinni Lọ Sí Ìyè Ayérayé.” Ó fa Òwe 1:5 yọ, tó sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.” Ìjáfáfá ṣe pàtàkì láti lè jẹ́ míṣọ́nnárì tó dáńgájíá. Iwájú ọba ni àwọn tó bá jáfáfá ti ń dúró. (Òwe 22:29) Lẹ́yìn tí a dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù márùn-ún, wọ́n ti gbára dì láti lọ ṣojú fún Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù, àwọn Ọba tó ju gbogbo ọba lọ.
David Olson tó wá láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ló sọ̀rọ̀ tẹ̀ lé e, ẹṣin ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ni, “Ṣèrànwọ́ Láti Mú Inú Jèhófà Dùn.” Ó béèrè pé: “Kí ni ènìyàn aláìpé lè ṣe láti mú inú Ọlọ́run dùn?” Kí ni ìdáhùn rẹ̀? Wọ́n lè fi òótọ́-inú, ìdúróṣinṣin, àti ayọ̀ sìn ín. Jèhófà fẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ gbádùn iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ń ṣe fún un. Bí a bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, a ń mú inú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Arákùnrin Olson ka lẹ́tà kan tí tọkọtaya míṣọ́nnárì kan tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹrìnlélọ́gọ́rùn-ún ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead kọ. Ṣé wọ́n ń gbádùn ibi tí a rán wọn lọ? Ohun tí wọ́n kọ nípa ìjọ wọn nìyí: “A ní ogóje akéde, ìpíndọ́gba àádọ́ta lé ní igba sí ọ̀ọ́dúnrún ló sì ń wá sí ìpàdé. Iṣẹ́ ìsìn pápá ló dùn mọ́ni jù lọ. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ìkẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin, àwọn kan lára wọn sì ti ń wá sípàdé.”
Lyman Swingle, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ìgbà Tó Yẹ Kí Ẹ Dúró Díẹ̀, Kí Ẹ Ronú Lórí Ìbùkún Tẹ́ẹ Rí Gbà.” Ẹ̀kọ́ táa ti kọ́ wọn nílé ẹ̀kọ́ Gilead ti mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wa. Ó ti jẹ́ kí ìmọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pọ̀ sí i, ó ti jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọyì ètò àjọ Jèhófà, kí wọ́n mú àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì dàgbà, ànímọ́ bí ìrẹ̀lẹ̀. Arákùnrin Swingle fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Wíwá síhìn-ín láti wá kẹ́kọ̀ọ́ a máa sọni di onírẹ̀lẹ̀. Ìgbà tí ẹ óò bá sì kúrò níhìn-ín, a óò ti túbọ̀ mú yín gbára dì láti gbé Jèhófà ga.”
Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé tí Daniel Sydlik, tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ ni, “Ayọ̀ Yín Ti Kún—Èé Ṣe Tí Ẹ Óò Fi Máa Ṣàníyàn? Ó rọ̀ wọ́n pé, nígbà tí ìṣòro bá dé, kí wọ́n wá ìtọ́sọ́nà láti inú Ìwé Mímọ́. Arákùnrin Sydlik ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa lílo àwọn àṣàyàn ẹsẹ láti inú Mátíù orí 6. Àìnígbàgbọ́ lé mú kí a máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tara, àwọn nǹkan bí oúnjẹ àti aṣọ. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà mọ ohun tí a nílò. (Mátíù 6:25, 30) Ṣe ni àníyàn wulẹ̀ ń fi kún ìyọnu ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan. (Mátíù 6:34) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ìwéwèé kan pọndandan. (Fi wé Lúùkù 14:28.) Arákùnrin Sydlik ṣàlàyé pé: “Jésù kò sọ pé kí a má ronú dáadáa nípa ọjọ́ ọ̀la, àníyàn tí kò bọ́gbọ́n mu nìkan ló lòdì sí. Ọ̀kan lára àwọn ojútùú gbígbéṣẹ́ jù lọ fún àníyàn ni gbígbé ìgbésẹ̀. Nígbà tí àníyàn bá gbà wá lọ́kàn, ohun tó dára ká ṣe ni, kí a bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́.”
Ìmọ̀ràn Ìdágbére Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Olùkọ́
Àsọyé mẹ́ta látẹnu àwọn mẹ́ńbà olùkọ́ àti alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ Gilead ló tẹ̀ lé e. Karl Adams ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, ó sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Kí Ni Ẹ Ó San Padà fún Jèhófà?” Ó gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka Sáàmù 116, tó ṣeé ṣe kí Jésù ti kọ lórin ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀. (Mátíù 26:30, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Kí ni Jésù ní lọ́kàn tó fi ń kọrin yìí pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀”? (Sáàmù 116:12) Ó ti lè máa ronú nípa ara pípé tí Jèhófà fún un. (Hébérù 10:5) Ọjọ́ kejì ni yóò fi ara yìí rúbọ, láti lè fi ẹ̀rí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó ní hàn. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì karùnlélọ́gọ́rùn-ún ti tọ́ ìwà rere Jèhófà wò fún oṣù márùn-ún tó ti kọjá. Àkókò wá tó wàyìí tí wọn yóò wá fi ìfẹ́ wọn hàn fún Ọlọ́run nípa ṣíṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a óò rán wọn lọ.
Mark Noumair, olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gilead tó sọ̀rọ̀ ṣìkejì, rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti “Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣe Ohun Tí Ó Tọ́.” Lẹ́yìn tí wọ́n ta Jósẹ́fù sí oko ẹrú ní Íjíbítì, ọdún mẹ́tàlá gbáko ló fi fara da ìwà àìdáa tí wọ́n hù sí i. Ǹjẹ́ ó jẹ́ kí ìwà àìdáa tí àwọn ẹlòmíràn hù dá òun lọ́wọ́ kọ́? Rárá o, ohun tó tọ́ ló ń ṣe lọ ní tirẹ̀. Nígbà tó wá tó àkókò lójú Ọlọ́run, a kó Jósẹ́fù yọ nínú àdánwò tó há sí. Láìrò ó tẹ́lẹ̀, ẹni tí ń gbénú túbú wá dẹni tí ń gbé láàfin ọba. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 37-50) Olùkọ́ náà wá béèrè lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pé: “Ká ní ohun tẹ́ẹ bá pàdé ní ibi tí wọ́n rán-an yín lọ gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì wá yàtọ̀ sí ohun tẹ́ẹ̀ ń retí ńkọ́, ǹjẹ́ ẹ ò ní sá kúrò níbẹ̀? Ẹ óò ha bọ́hùn bí? Àbí ẹ ó fara dà á, gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti ṣe?”
Láti kádìí apá yìí, akọ̀wé Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, Wallace Liverance, darí ìjíròrò amárayágágá pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà kíláàsì náà lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Polongo Ọba àti Ìjọba Náà.” Díẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé, láti ìsọ̀ dé ìsọ̀, àti lójú pópó. Àwọn mìíràn sọ bí wọ́n ṣe ń jẹ́rìí fún àwọn tí kò gbọ́ èdè wọn. Àwọn mìíràn sì sọ bí wọ́n ṣe wàásù fún àwọn tí ẹ̀sìn tiwọn yàtọ̀. Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ló ń hára gàgà láti nípìn-ín lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ti míṣọ́nnárì.
Àwọn Mísọ́nnárì Ọlọ́jọ́ Pípẹ́ Tí Wọ́n Kún fún Ayọ̀
Robert Wallen ni ó bójú tó apá tí ó tẹ̀ lé e, tí a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Àbájáde Aláyọ̀ Tí Ń Wá Láti Inú Iṣẹ́ Ìsìn Míṣọ́nnárì,” apá yìí tún ní fífọ̀rọ̀ wá àwọn arákùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà ní oríléeṣẹ́ lẹ́nu wò, àwọn tí wọ́n ní ìfararora gbígbéni ró pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì onírìírí láìpẹ́ yìí. Àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyẹn gbà láìjanpata pé kò rọrùn fún wọn láti kọ́ èdè tuntun, láti mú ara wọn bá àṣà ilẹ̀ mìíràn tàbí ipò ojú ọjọ́ tó yàtọ̀ mu. Ká má tilẹ̀ wá sọ ti àárò ilé tó máa ń sọ wọ́n. Nígbà mìíràn pàápàá, ọ̀ràn àìsàn máa ń wáyé. Àmọ́ láìfi gbogbo ìwọ̀nyí pè, àwọn míṣọ́nnárì ní ẹ̀mí rere, a sì bù kún ẹ̀mí ìfaradà wọn. Àwọn kan ti ran ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ Jèhófà. Àwọn mìíràn ti kó ipa pàtàkì ní onírúurú ọ̀nà tó mú àpapọ̀ ìbísí wá nínú iṣẹ́ Ìjọba náà ní ilẹ̀ wọn.
Carey Barber, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ló sọ̀rọ̀ àsọparí. Ó ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́.” Ó béèrè lọ́wọ́ àwùjọ pé: “Ipa wo ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà ní lórí ìbátan yín pẹ̀lú Jèhófà?” Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣèfiwéra àbájáde oníbùkún tí ń jẹyọ nínú títọ ọ̀nà Ọlọ́run àti àjálù tí ń já lu àwọn tí wọ́n ń tọ ọ̀nà ayé. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ Mósè ní Mẹ́ríbà, ó kìlọ̀ pé: “Àní lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti sìn tọkàntọkàn fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá, Jèhófà kì í fojú kékeré wo àṣìṣe bíńtín tí ẹni náà bá ṣe, tó jẹ mọ́ àwọn òfin òdodo Rẹ̀.” (Númérì 20:2-13) Ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ibi gbogbo di àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wọn tó ṣeyebíye mú gírígírí!
Tóò, àkókò tó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò gba ìwé ẹ̀rí dípúlómà wọn. Lẹ́yìn èyí ni aṣojú kíláàsì náà ka lẹ́tà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kọ láti fi ìmọrírì wọn hàn fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti rí gbà. Lẹ́yìn orin àkọparí àti àdúrà àtọkànwá, ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà wá sópin. Àmọ́ ṣá o, lójú àwọn ọmọ kíláàsì karùnlélọ́gọ́rùn-ún, ìbẹ̀rẹ̀ lásán lèyí, nítorí pé àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà “wà ní bèbè ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìsọfúnni Oníṣirò Nípa Kíláàsì
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 9
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yanni sí: 17
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48
Iye àwọn tọkọtaya: 24
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33
Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 16
Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Wọ́n Yan Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún?
Ben, akẹ́kọ̀ọ́yege ní kíláàsì karùnlélọ́gọ́rùn-ún sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, n kò ní in lọ́kàn láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Èrò mi ni pé àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀, tí wọn sì wà ní ipò tó rọ̀ wọ́n lọ́rùn nìkan ló lè ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ṣùgbọ́n mo wá fẹ́ràn lílọ sóde ẹ̀rí. Lọ́jọ́ kan, mo wá ronú kàn án pé, nínípìn-ín púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni ohun tí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà dá lé. Ìgbà yẹn ni mo wá rí i pé mo lè ṣe aṣáájú ọ̀nà.”
Lusia sọ pé: “Bí ọba la ṣe ń tọ́jú àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún nínú ilé wa.” Ó rántí ayọ̀ ńláǹlà tó máa ń wà nínú ìjọ wọn ní gbogbo ìgbà tí àwọn míṣọ́nnárì bá bẹ̀ wọ́n wò. Ó wí pé: “Bí mo ṣe ń dàgbà, ó tètè hàn pé màá wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.”
Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni Theodis nígbà tí màmá rẹ̀ kú. Ó wí pé: “Nígbà yẹn, ìjọ mà tọ́jú mi o, mo wá bi ara mi pé, ‘Kí ni kí n ṣe láti fi ìmọrírì mi hàn o?’” Èyí ló mú kó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, tó sì jẹ́ kó di míṣọ́nnárì báyìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kíláàsì Karùnlélọ́gọ́rùn-Ún ti Watchtower Bible School of Gilead Tí Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege
Nísàlẹ̀ yìí, a fi nọ́ńbà sí ìlà láti iwájú lọ sí ẹ̀yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì lọ sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan
(1) Sampson, M.; Brown, I.; Heggli, G.; Abuyen, E.; Desbois, M.; Pourthié, P. (2) Kassam, G.; Lindberg, R.; Dapuzzo, A.; Taylor, C.; LeFevre, K.; Walker, S. (3) Baker, L.; Pellas, M.; Woggon, E.; Böhne, C.; Asplund, J.; Haile, J. (4) Pourthié, T.; Whittaker, J.; Palmer, L.; Norton, S.; Gering, M.; Haile, W. (5) Walker, J.; Böhne, A.; Groenveld, C.; Washington, M.; Whittaker, D.; Abuyen, J. (6) Gering, W.; Washington, K.; Pellas, M.; Desbois, R.; Heggli, T.; Asplund, Å. (7) Woggon, B.; LeFevre, R.; Taylor, L.; Brown, T.; Groenveld, R.; Palmer, R. (8) Norton, P.; Sampson, T.; Baker, C.; Lindberg, M.; Kassam, M.; Dapuzzo, M.