Báa Ṣe Lè Mọ Àìlera Tẹ̀mí Kí A sì Borí Rẹ̀
GẸ́GẸ́ BÍ ÌTÀN ÌWÁṢẸ̀ TI ÀWỌN ARÁ GÍRÍÌKÌ TI SỌ, ACHILLES LÓ GBÓYÀ JÙ LỌ NÍNÚ gbogbo àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gíríìsì, nígbà tí wọ́n ń ja Ogun Trojan, ìyẹn logun tí wọ́n fi kọlu ìlú Troy. Ìtàn àtẹnudẹ́nu sọ pé nígbà tí Achilles wà ní pínníṣín, màmá rẹ̀ rì í bọ inú Odò Styx, báyìí ló ṣe di ẹni tí apá ò lè ká, àyàfi tí ohun ìjà bá bà á lójú ibi tí màmá rẹ̀ ti dì í mú lọ́jọ́ náà lọ́hùn-ún ló kù—ìyẹn ni gìgísẹ̀ Achilles, tó ti wá di ohun táwọn ara ibẹ̀ fi ń pòwe báyìí. Bí Paris, ọmọ Priam Ọba Troy, ti ta ọfà oró báyìí, gìgísẹ̀ ọ̀hún gan-an ló bà, bó ṣe pa Achilles nìyẹn.
Àwọn Kristẹni jẹ́ ọmọ ogun Kristi, ogun tẹ̀mí sì ni wọ́n ń jà. (2 Tímótì 2:3) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” Bẹ́ẹ̀ kúkú ni, kò sí ọ̀tá mìíràn táa ní ju Sátánì Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ lọ.—Éfésù 6:12.
Kò sí àní-àní pé, bí kì í bá ṣe ìrànlọ́wọ́ tí a ń rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni, ẹni táa ti ṣàpèjúwe nígbà kan pé ó jẹ́ “akin lójú ogun,” à bá máà rọ́wọ́ mú nínú ìjà náà. (Ẹ́kísódù 15:3) Kí a lè dáàbò bo ara wa nítorí àwọn ọ̀tá wa, àwọn ẹ̀dá abèṣe, a fún wa ní ìhámọ́ra tẹ̀mí. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì náà fi rọ̀ wá pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.”—Éfésù 6:11.
Kò sí iyèméjì pé, ìhámọ́ra tí Jèhófà Ọlọ́run pèsè kò láfiwé, ìhámọ́ra tó jẹ́ pé kò sí ohun ìjà bẹ́ẹ̀ tó lè ràn án. Tiẹ̀ kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù tó lẹ́sẹẹsẹ: àmùrè òtítọ́, àwo ìgbàyà òdodo, bàtà ìhìn rere, apata ńlá ti ìgbàgbọ́, àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí. Ìhámọ́ra wo la tún ń fẹ́, tó tún lè dára ju ìwọ̀nyí lọ? Bí Kristẹni ọmọ ogun kan bá ní irú ìhámọ́ra ogun bẹ́ẹ̀, ó dájú pé yóò jàjàṣẹ́gun, láìka àwọn ìdènà ńlá tó lè bá pàdé sí.—Éfésù 6:13-17.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìhámọ́ra ogun táa lè fi wé ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí tí Jèhófà fún wa, tó sì jẹ́ pé ó lè dáàbò bò wá, a kò gbọ́dọ̀ kà á sí ohun yẹpẹrẹ. Bí a bá rántí Achilles tí àwọn kan gbà pé kò ṣeé pa, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí àwa pẹ̀lú ní ibi táa kù sí, tí a lè pè ní gìgísẹ̀ Achilles nípa tẹ̀mí? Á mà burú jáì bí ọta bá lọ bà wá lójijì o.
Yẹ Ìhámọ́ra Tẹ̀mí Rẹ Wò
Ọkùnrin kan tó ti gba ẹ̀bùn ẹ̀yẹ góòlù nínú eré orí yìnyín ti Òlíńpíìkì lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó sì jọ pé kokooko lara rẹ̀ le, ṣàdédé dìgbò lulẹ̀, ó sì kú fin-ín fin-ín níbi tó ti ń gbára dì fún ìdíje mìíràn. Kété lẹ́yìn èyí, ìwé ìròyìn náà, The New York Times, gbé ìròyìn yìí tí ń múni ronú jáde pé: “Ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] nínú àwọn ará Amẹ́ríkà tí àrùn ọkàn-àyà ń bá jà lọ́dọọdún ni kì í rí àmì àrùn náà tẹ́lẹ̀.” Ó yẹ kó yé wa yéké pé, ìmọ̀lára wa nìkan kò tó láti lè mọ bí ara wa ṣe le tó.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí nígbà táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìlera wa nípa tẹ̀mí. Ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” (1 Kọ́ríńtì 10:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìhámọ́ra tẹ̀mí wa kò láfiwé, ó mà lè luhò láwọn apá ibì kan. Ìdí ni pé inú ẹ̀ṣẹ̀ la bí wa sí, bí a ò bá sì kíyè sára, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ipò ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé wa ti lè borí ìpinnu táa ti ṣe láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 51:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ní ohun rere lọ́kàn, ọkàn-àyà wa tó jẹ́ pé aládàkàdekè ni lè tàn wá jẹ nípa gbígbé àwọn ìrònú tàbí àwáwí tó fẹ̀ jọ òótọ́ kalẹ̀, kí a bàa lè gbójú fo àìlera wa dá, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí tan ara wa jẹ pé kokooko lara wa le nípa tẹ̀mí.—Jeremáyà 17:9; Róòmù 7:21-23.
Láfikún sí i, a ń gbé nínú ayé kan tó jẹ́ pé òye ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ ti pòrúurùu mọ́ni lọ́kàn, a sì ti gbé òye ọ̀hún gbòdì. Èrò tó gbayé kan ni pé ìmọ̀lára ẹnì kan ni yóò pinnu bóyá ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́. Irú ìrònú yìí ni ìpolówó ọjà, eré ìnàjú olókìkí, àti ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé lárugẹ. Ó wá hàn gbangba pé, bí a ò bá ṣọ́ra, a lè fọgbọ́n mú wa, kí a bẹ̀rẹ̀ sí ronú lọ́nà yẹn, ìhámọ́ra wa tẹ̀mí sì lè bẹ̀rẹ̀ sí bà jẹ́.
Kàkà tí a óò fi jìn sínú irú ọ̀fìn bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká kọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì náà pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Nígbà tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò lè rí àìlera èyíkéyìí tí a ti ní, a óò sì lè gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ láti ṣàtúnṣe sí i kó tó di pé àwọn elénìní wa yóò rí i, tí wọn yóò sì ta wá lọ́fà. Ṣùgbọ́n, báwo la ó ṣe ṣe irú àyẹ̀wò yẹn? Àwọn àmì wo ló yẹ ká máa wá lára wa nígbà táa bá ń ṣe irú àyẹ̀wò yìí?
Mímọ Àwọn Àmì Náà
Àmì kan tó sábà máa ń fi hàn pé ara ẹnì kan kò le nípa tẹ̀mí ni dídẹwọ́ nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́. Àwọn kan lè rí i pé ó yẹ káwọn túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i, àmọ́ àyè rẹ̀ ò yọ. Pẹ̀lú ìgbésí ayé kòókòó jàn-án-jàn-án táà ń gbé lónìí, ó rọrùn láti bára wa nínú irú ọ̀fìn bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ohun tó tiẹ̀ tún burú jù lọ ni pé àwọn kan máa ń sọ pé àwọn ń gbìyànjú kẹ̀, ṣe báwọn ń ka àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì nígbàkúùgbà tí ọwọ́ àwọn bá dilẹ̀, tó sì tún jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìpàdé Kristẹni làwọn ń pa jẹ.
Títan ara ẹni jẹ lásán ni irú ìrònú bẹ́ẹ̀ jẹ́. Ṣe ló dà bí ọkùnrin kan tó rò pé ọwọ́ òun ti dí jù láti jókòó jẹ oúnjẹ gidi, bó ṣe ń ti ibì kan lọ sí ibòmíràn bẹ́ẹ̀ ló ń já díẹ̀ jẹ níhìn-ín, tó tún ń já díẹ̀ jẹ lọ́hùn-ún. Lóòótọ́ ebi lè má pa á, àmọ́ ó pẹ́, ó yá, àìsàn lè kọ lù ú. Bákan náà ló rí, bí a kò bá wáyè jókòó ká jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó ṣara lóore, láìpẹ́, ìhámọ́ra wa tẹ̀mí yóò luhò. Nítorí pé ayé kò dáwọ́ ìgbékèéyíde àti ẹ̀mí ìrònú rẹ̀ dúró nígbà kan, ó rọrùn kí àwọn ọta ikú látọ̀dọ̀ Sátánì bà wá.
Àmì mìíràn tí ẹnì kan fi lè mọ̀ pé òun ní àìlera nípa tẹ̀mí ni àìfọwọ́ dan-in dan-in mú ogun tẹ̀mí táà ń jà. Lákòókò tí ìlú bá rójú, tí ìlú ráyè, pákáǹleke àti ìbẹ̀rù ogun kì í sí lọ́kàn ọmọ ogun. Ó lè tipa báyìí rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ pọndandan láti wà ní sẹpẹ́. Báa bá wá pè é lójijì pé ojú ogun yá, ó lè bá a lábo. Bẹ́ẹ̀ náà ni ipò tẹ̀mí ṣe rí. Bí a kò bá fọwọ́ dan-in dan-in mú ogun tẹ̀mí táà ń jà, ìgbà tí ogun bá dé, ó lè bá wa lábo.
Ṣùgbọ́n, báwo la ṣe lè mọ̀ pé a ti jìn sínú ọ̀fìn yìí? A lè bi ara wa láwọn ìbéèrè tó lè fi bí ipò wa ti rí gan-an hàn wá: Ǹjẹ́ bí gbígbafẹ́ jáde ṣe máa ń ká mi lára náà ni lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe máa ń ká mi lára? Ǹjẹ́ bí mo ṣe máa ń fẹ́ lo àkókò mi láti lọ sí ọjà tàbí láti wo tẹlifíṣọ̀n ni mo ṣe máa ń fẹ́ lò ó láti múra àwọn ìpàdé sílẹ̀? Mo ha máa ń ronú àtipadà sídìí àwọn góńgó tàbí àǹfààní tí mo pa tì nígbà tí mo di Kristẹni bí? Ìgbésí ayé fàájì tí àwọn kan sọ pé àwọn ń gbé ha máa ń wù mí bí? Àwọn ìbéèrè tó lè ṣàyẹ̀wò ọkàn ẹni nìyí, ṣùgbọ́n wọ́n wúlò fún rírí ihò èyíkéyìí tó lè wà lára ìhámọ́ra tẹ̀mí wa.
Níwọ̀n bí ìhámọ́ra ààbò wa ti jẹ́ tẹ̀mí, ó ṣe kókó pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run rí àyè dáadáa nínú ìgbésí ayé wa. Èyí yóò hàn nínú bí a ṣe ń fi èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run hàn tó nínú àwọn ìgbòkègbodò wa. Inú ha tètè máa ń bí ọ, tàbí o tètè máa ń gbaná jẹ nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá ṣe tàbí sọ ohun kan tí o kò fẹ́? Ó ha máa ń ṣòro fún ọ láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn, àbí ṣe lò ń rò pé àwọn mìíràn wulẹ̀ ń wẹ́sùn sí ẹ lẹ́sẹ̀? Ìbùkún tàbí àṣeyọrí àwọn ẹlòmíràn ha máa ń mú ọ ṣe ìlara bí? Ó ha ṣòro fún ẹ láti gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pàápàá jù lọ àwọn ojúgbà rẹ? Yíyẹ ara wa wò fínnífínní láìṣàbòsí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i bóyá ìgbésí ayé wa kún fún àwọn èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run tàbí pé àwọn iṣẹ́ ti ẹran ara ti ń yọ́ wọnú ìgbésí ayé wa.—Gálátíà 5:22-26; Éfésù 4:22-27.
Àwọn Ìgbésẹ̀ Rere Láti Lè Borí Àìlera Tẹ̀mí
Ọ̀tọ̀ ni pé ká rí àmì pé ara wa kò le nípa tẹ̀mí; ọ̀tọ̀ sì ni pé ká dojú kọ àmì ọ̀hún, ká sì wá nǹkan ṣe sí i. Ó ṣeni láàánú pé, ọ̀pọ̀ máa ń ṣàwáwí, wọ́n máa ń wáwìíjàre, wọ́n máa ń fojú kéré ìṣòro, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ sọ pé kò síṣòro rárá. Ẹ ò rí i pé ìyẹn léwu gan-an—àfi bí ẹni ń rojú ogun tó lọ gbé ìhámọ́ra tó ní ihò fórofòro wọ̀! Táa bá dánrú ẹ̀ wò, ọwọ́ Sátánì ti tẹ̀ wá tán. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ ní wàràǹṣeṣà láti dí ihò èyíkéyìí tí a bá rí. Kí wá ni ṣíṣe?—Róòmù 8:13; Jákọ́bù 1:22-25.
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ogun tẹ̀mí là ń jà—ogun kan tó wé mọ́ ṣíṣàkóso èrò inú àti ọkàn-àyà Kristẹni—a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti dáàbò bo agbára ìrònú wa. Rántí pé àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ apá kan ìhámọ́ra tẹ̀mí wa, “ìgbàyà òdodo,” tí ń dáàbò bo ọkàn-àyà wa, àti “àṣíborí ìgbàlà,” tí ń dáàbò bo èrò inú wa. Kíkọ́ bí a óò ṣe lo àwọn ìpèsè wọ̀nyí dáadáa lè túmọ̀ sí pé a ó jagun àjàyè tàbí ká bógun lọ.—Éfésù 6:14-17; Òwe 4:23; Róòmù 12:2.
Lílo “ìgbàyà òdodo” lọ́nà yíyẹ ń béèrè pé kí a máa yẹ ara wa wò nígbà gbogbo, kí a lè mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ òdodo, tí a sì kórìíra ìwà àìlófin. (Sáàmù 45:7; 97:10; Ámósì 5:15) Ǹjẹ́ ayé kò ti jẹ́ kí a rẹ ọ̀pá ìdiwọ̀n wa wálẹ̀? Ǹjẹ́ àwọn nǹkan tó máa ń mú wa gbọ̀n rìrì tẹ́lẹ̀ tàbí tó máa ń kó wa nírìíra—yálà nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ tàbí tí a ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá, nínú ìwé àti ìwé ìròyìn—kò ha ti di ohun tí a fi ń najú báyìí? Ìfẹ́ fún òdodo yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé ohun táwọn èèyàn ń gbé gẹ̀gẹ̀ nínú ayé, ohun tí wọ́n kà sí òmìnira àti ìwà ọ̀làjú lè jẹ́ ìwà pálapàla àti ìṣefọ́nńté lásán-làsàn.—Róòmù 13:13, 14; Títù 2:12.
Fífi “àṣíborí ìgbàlà” dé orí wa wé mọ́ fífi àwọn ìbùkún àgbàyanu tí ń bẹ níwájú sọ́kàn dáradára, ká má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun yòdòyindin, àwọn ohun yòyòyò ayé fà wá kúrò lójú ọ̀nà. (Hébérù 12:2, 3; 1 Jòhánù 2:16) Níní ojú ìwòye yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ire tẹ̀mí ṣáájú èrè nípa ti ara tàbí èyí tó jẹ́ fún àǹfààní ara wa. (Mátíù 6:33) Nípa báyìí, láti lè mọ̀ dájú pé àṣíborí yìí bò wá lórí dáadáa, a gbọ́dọ̀ bi ara wa léèrè láìṣàbòsí, pé: Kí ni mò ń lépa nínú ìgbésí ayé mi? Ǹjẹ́ mo tilẹ̀ ní àwọn góńgó tẹ̀mí pàtó? Kí ni mò ń ṣe kí ọwọ́ mi lè tẹ̀ wọ́n? Yálà ọ̀kan lára àṣẹ́kù ẹni àmì òróró Kristẹni ni wá ni o tàbí a wà lára ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ti “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” ó yẹ ká fara wé Pọ́ọ̀lù, ẹni tó sọ pé: “Èmi kò tíì ka ara mi sí ẹni tí ó ti gbá a mú nísinsìnyí; ṣùgbọ́n ohun kan wà nípa rẹ̀: Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó náà nìṣó.”—Ìṣípayá 7:9; Fílípì 3:13, 14.
Àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù fún wa nípa ìhámọ́ra tẹ̀mí wá sí ìparí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí: “Pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí. Àti pé fún ète yẹn, ẹ wà lójúfò pẹ̀lú gbogbo àìyẹsẹ̀ àti pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí gbogbo ẹni mímọ́.” (Éfésù 6:18) Èyí ń fi ìgbésẹ̀ méjì tí ó yẹ kí a gbé hàn láti lè borí àìlera tẹ̀mí tàbí láti lè dènà rẹ̀: Mú ìbátan rere dàgbà pẹ̀lú Ọlọ́run, kí o sì ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ.
Nígbà tí a bá ní ẹ̀mí yíyíjú sí Jèhófà nínú “gbogbo oríṣi” àdúrà (jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, bíbẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, bíbèèrè ìtọ́sọ́nà, dídúpẹ́ fún ìbùkún, yíyìn ín láti ọkàn-àyà wa wá) àti “ní gbogbo ìgbà” (ní gbangba, ní ìdákọ́ńkọ́, láwa nìkan, nígbàkugbà), a óò ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Kò sí ààbò tí a lè ní tó tún lè tóbi ju èyí lọ.—Róòmù 8:31; Jákọ́bù 4:7, 8.
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, a rọ̀ wá láti gbàdúrà “nítorí gbogbo ẹni mímọ́,” ìyẹn ni, àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. Nínú àdúrà wa, a lè rántí àwọn arákùnrin wa nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà ní ilẹ̀ òkèèrè, tí a ń ṣenúnibíni sí tàbí tí wọ́n wà nínú ìṣòro mìíràn. Àwọn Kristẹni tí a jọ ń ṣiṣẹ́, tí a sì ń bá kẹ́gbẹ́ pọ̀ lójoojúmọ́ ńkọ́? Ó yẹ ká gbàdúrà fún àwọn náà pẹ̀lú, àní bí Jésù ti gbàdúrà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Jòhánù 17:9; Jákọ́bù 5:16) Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ ń mú kí a túbọ̀ sún mọ́ra, ó sì ń fún wa lókun láti lè kojú ìgbéjàkò “ẹni burúkú náà.”—2 Tẹsalóníkà 3:1-3.
Paríparí rẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi ìṣílétí onífẹ̀ẹ́ tí àpọ́sítélì Pétérù fún wa sọ́kàn pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Nítorí náà, ẹ yè kooro ní èrò inú, kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn. Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pétérù 4:7, 8) Ó rọrùn láti jẹ́ kí àìpé ẹ̀dá ènìyàn—ti àwọn ẹlòmíràn àti tiwa fúnra wa—ráyè wọnú ọkàn-àyà àti èrò inú wa, kí ó sì wá di ìdènà, òkúta ìkọ̀sẹ̀. Sátánì mọ àwọn àìlera ẹ̀dá ènìyàn yìí dáradára. Bóo ba o pá, bóò ba o bù ú lẹ́sẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ tara ṣàṣà láti jẹ́ kí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún ẹnì kìíní kejì bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀, kí a má ṣe “fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.”—Éfésù 4:25-27.
Jẹ́ Alágbára Nípa Tẹ̀mí Láti Ìsinsìnyí Lọ
Tóo bá ṣàkíyèsí pé irun rẹ rí wúruwùru tàbí tóo ṣàkíyèsí pé táì tóo so mọ́rùn lọ́, kí ni wàá ṣe? Ó dájú pé wàá fẹ́ tètè ṣàtúnṣe sí i. Ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ni yóò fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, tí wọ́n a gbà pé irú nǹkan tí kò bójú mu bẹ́ẹ̀ kò já mọ́ nǹkan kan. Tó bá ti kan ọ̀ràn àìlera wa nípa tẹ̀mí, ẹ máà jẹ́ ká fi ọ̀ràn falẹ̀. Àbùkù ara lè jẹ́ kí àwọn èèyàn fojú burúkú woni, ṣùgbọ́n àbùkù tẹ̀mí tí a kò ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ lè yọrí sí àìrí ojú rere Jèhófà.—1 Sámúẹ́lì 16:7.
Jèhófà ti fi tìfẹ́tìfẹ́ fún wa ní gbogbo ohun tí yóò lè ràn wá lọ́wọ́ láti wú gbogbo àìlera tẹ̀mí kúrò nínú wa tegbòtegbò, kí a sì máa jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí nìṣó. Nípasẹ̀ àwọn ìpàdé Kristẹni, àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì, àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni tí wọ́n dàgbà dénú, tí wọ́n sì bìkítà nípa ẹni, ó ń pèsè ìránnilétí ìgbà gbogbo, ó sì ń tọ́ka wa sí ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe. Ó kù sọ́wọ́ wa láti tẹ́wọ́ gbà á, kí a sì fi wọ́n sílò. Èyí ń béèrè ìsapá àti agbára àtilè ṣàkóso ara ẹni. Àmọ́ ṣá o, rántí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ láìṣàbòsí, pé: “Bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́; ṣùgbọ́n mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.”—1 Kọ́ríńtì 9:26, 27.
Wà lójúfò, má sì ṣe jẹ́ kí ibì kan wà lára rẹ, tí a lè tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bíi gìgísẹ̀ Achilles nípa tẹ̀mí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ àti tìgboyàtìgboyà ṣe ohun tó bá pọndandan nísinsìnyí kí a lè mọ àìlera tẹ̀mí táa ní àti ohun táa lè ṣe láti borí rẹ̀.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
“Ẹ MÁA DÁN ARA YÍN WÒ BÓYÁ Ẹ WÀ NÍNÚ ÌGBÀGBỌ́, Ẹ MÁA WÁDÌÍ OHUN TÍ Ẹ̀YIN FÚNRA YÍN JẸ́.”—2 Kọ́ríńtì 13:5.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
“Ẹ . . . WÀ LÓJÚFÒ NÍ JÍJẸ́ KÍ ÀDÚRÀ JẸ YÍN LỌ́KÀN. LÉKÈ OHUN GBOGBO, Ẹ NÍ ÌFẸ́ GBÍGBÓNÁ JANJAN FÚN ARA YÍN LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ, NÍTORÍ ÌFẸ́ A MÁA BO ÒGÌDÌGBÓ Ẹ̀ṢẸ̀ MỌ́LẸ̀.”—1 Pétérù 4:7, 8.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20)
BI ARA RẸ LÉÈRÈ PÉ . . .
◆ Mo ha ń hára gàgà láti lo àkókò láti múra ìpàdé sílẹ̀ bí mo ti máa ń hára gàgà láti lò ó fún lílọ sọ́jà tàbí wíwo tẹlifíṣọ̀n?
◆ Ìgbésí ayé fàájì tí àwọn kan sọ pé àwọn ń gbé ha máa ń wù mí bí?
◆ Bí àwọn kan bá ṣe ohun kan tí n kò fẹ́ tàbí tí wọ́n bá hùwà tí kò bá mi lára mu, ṣé mo tètè máa ń gbaná jẹ?
◆ Ó ha máa ń ṣòro fún mi láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn, tàbí nígbà mìíràn mo ha máa ń rò pé ṣe ni àwọn mìíràn wúlẹ̀ ń wẹ́sùn sí mi lẹ́sẹ̀?
◆ Ó ha ṣòro fún mi láti máa gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?
◆ Ayé ha ti jẹ́ kí n rẹ ọ̀pá ìdiwọ̀n mi wálẹ̀ bí?
◆ Mo ha ní àwọn góńgó tẹ̀mí pàtó kan bí?
◆ Kí ni mò ń ṣe kí ọwọ́ mi lè tẹ àwọn góńgó mi nípa tẹ̀mí?
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Achilles: Láti inú ìwé náà, Great Men and Famous Women; Àwọn ọmọ ogun Róòmù àti ojú ìwé kọkànlélógún: Historic Costume in Pictures/Dover Publications, Inc., New York