Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí a ti ń gbọ́ nísinsìnyí pé téèyàn bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe láti dá agbára ìbímọ ẹni padà lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ sísọni di aláìlèbímọ, ǹjẹ́ Kristẹni kan ha lè kà á sí ọ̀nà ìfètòsọ́mọbíbí tó bójú mu?
Sísọni di aláìlèbímọ ni ọ̀nà ìfètòsọ́mọbíbí tó gbilẹ̀ jù lọ báyìí. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, bóyá ẹnì kan lè gbà láti ṣe é tàbí kò ní gbà sinmi lórí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ẹ̀kọ́, àti ohun tí ẹ̀sìn onítọ̀hún sọ nípa rẹ̀. Ọ̀ràn ẹ̀sìn jẹ́ kókó pàtàkì lójú ìwòye Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn tí wọ́n ní irú ìfẹ́ tí onísáàmù náà ní, nígbà tó sọ pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rẹ, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán.” (Sáàmù 27:11) Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ abẹ sísọni di aláìlèbímọ?
Vasectomy làwọn eléèbó ń pe iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi ń sọ ọkùnrin di aláìlèbímọ. Wọn á gé iṣan tàbí ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ méjì tó wà nínú ẹpọ̀n tí àtọ̀ ń gba inú rẹ̀ jáde, wọn á sì dí ẹnu wọn pa. Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n lè gbà ṣe èyí lọ́nà ìṣègùn, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ ni láti má ṣe jẹ́ kí àtọ̀ ráyè jáde látinú ẹpọ̀n. Tubal ligation làwọn eléèbó ń pe iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi ń sọ obìnrin di aláìlèbímọ. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé, wọn á gé ọ̀pá tí wọ́n ń pè ní Fallopian tube, tí ẹyin ń gbà látinú ilé ẹyin wá sí ilé ọmọ, wọn á sì dì í (tàbí, kí wọ́n jó o) pa.
Ohun táa mọ̀ tẹ́lẹ̀ ni pé, àṣepa ni irú iṣẹ́ abẹ yìí—olúwarẹ̀ kò lè bímọ mọ́ láé. Ṣùgbọ́n àwọn kan, torí pé wọ́n ń kábàámọ̀ pé àwọn ṣe iṣẹ́ abẹ yìí, tàbí torí ipò tuntun tó dìde, ti padà lọ bá àwọn oníṣègùn pé kí wọ́n tún àwọn ohun tí wọ́n gé so, nígbà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ vasectomy tàbí tubal ligation fún wọn. Pẹ̀lú ìhùmọ̀ àwọn irinṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ àti ṣíṣe iṣẹ́ abẹ nínú ẹ̀yà ara tíntìntín, ó ti ṣeé ṣe lọ́pọ̀ ìgbà láti mú agbára ìbímọ padà bọ̀ sípò. Ọ̀pọ̀ ìgbà là ń rí i kà pé, ní ti àwọn tí ipò wọn bára dé, àwọn oníṣègùn ti kẹ́sẹ járí nínú ìpín àádọ́ta sí àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn táa ti ṣiṣẹ́ abẹ vasectomy fún tẹ́lẹ̀, tó sì fẹ́ lọ́mọ báyìí, wọ́n ti tún ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n gé tẹ́lẹ̀ so. Àwọn kan sọ pé ìpín ọgọ́ta sí ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ló ń kẹ́sẹ járí ní ti àwọn obìnrin tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ tubal ligation fún tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n fẹ́ wá bímọ báyìí. Àwọn kan tó ti gbọ́ nípa èyí wá ń rò pé a ò gbọ́dọ̀ máa fojú ohun tí kò látùn-ún-ṣe wo iṣẹ́ abẹ sísọni di aláìlèbímọ. Wọ́n wá gbà pé kò síyàtọ̀ láàárín iṣẹ́ abẹ vasectomy tàbí tubal ligation àti lílo àwọn oògùn málòóyún, kọ́ńdọ́ọ́mù, àti rọ́bà àfibo àbáwọ ilé-ọmọ—àwọn nǹkan táa lè ṣíwọ́ lílò báa bá fẹ́ lóyún. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ gbójú fo àwọn kókó kan tó yẹ ká fara balẹ̀ ronú lé lórí.
Kókó kan ni pé àwọn ohun kan lè mú kí dídá agbára ìbímọ padà ṣòro, gẹ́gẹ́ bí: bí wọ́n ṣe ba àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ náà jẹ́ tó nígbà tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ abẹ táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, bí ibi tí wọ́n gé sọnù tàbí tí wọ́n dá àpá sí lára ọ̀pá náà ṣe pọ̀ tó, iye ọdún tó ti kọjá lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, àti ní ti iṣẹ́ abẹ vasectomy, bóyá ó ti mú káwọn èròjà inú ara bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àtọ̀. Ohun tí a kò tún ní gbàgbé ni pé kì í ṣe gbogbo ọsibítù ló lè ṣe iṣẹ́ abẹ lórí àwọn ẹ̀yà ara tíntìntín, tàbí bí irú ọsibítù bẹ́ẹ̀ bá tiẹ̀ wà, owó tí wọ́n ń gbà lè kọjá agbára wa. Fún ìdí yìí, ó lè má ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń wá ọ̀nà lójú méjèèjì láti ṣe iṣẹ́ abẹ tí yóò dá agbára ìbímọ wọn padà. Nínú ọ̀ràn tiwọn, ó ti parí nìyẹn.a Nítorí náà, ìpíndọ́gba iye agbára ìbímọ táwọn oníṣègùn sọ pé àwọn ti kẹ́sẹ járí ní dídá padà kò ṣeé gbára lé, ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni.
Àwọn òtítọ́ kan wà tí kò ṣeé já ní koro. Àpilẹ̀kọ kan táa tẹ̀ jáde ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lórí yíyí iṣẹ́ abẹ táa ṣe fún dídènà ìbímọ fún àwọn ọkùnrin padà, sọ pé lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà tó náni ní ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000] dọ́là, “kìkì ìpín mẹ́tàlélọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn táa ṣe iṣẹ́ abẹ náà fún ló lè fún aya wọn lóyún.” Ìyẹn nìkan kọ́, kìkì “ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin tó ṣe iṣẹ́ abẹ vasectomy ló máa ń padà wá fún iṣẹ́ abẹ tí yóò mú agbára ìbímọ wọn padà sípò.” Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Germany nípa àárín gbùngbùn Yúróòpù, nǹkan bí ìdá mẹ́ta àwọn ọkùnrin tó ṣe iṣẹ́ abẹ sísọni di aláìlèbímọ ló padà ń wá ọ̀nà àtibímọ. Bí iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún ìdajì nínú wọ́n bá tilẹ̀ kẹ́sẹ járí, yóò túmọ̀ sí pé ìpín méjìdínlọ́gọ́rùn-ún àtààbọ̀ [98.5] nínú ọgọ́rùn-ún ló jẹ́ pé iṣẹ́ abẹ vasectomy ti sọ wọ́n di ẹni tí kò lè bímọ títí láé. Yóò sì tún pọ̀ ju ìyẹn lọ ní àwọn ilẹ̀ tí kò ní àwọn oníṣẹ́ abẹ tó lè ṣe iṣẹ́ abẹ lórí ẹ̀yà ara tíntìntín.
Fún ìdí yìí, kò bọ́gbọ́n mu láti fojú kékeré wo iṣẹ́ abẹ sísọni di aláìlèbímọ, yálà fọ́kùnrin tàbí fóbìnrin, bí ẹni pé ó jẹ́ ètò ìfètòsọ́mọbíbí fúngbà ráńpẹ́. Ọ̀rọ̀ ò sì tíì tán o, pàápàá fáwọn Kristẹni olóòótọ́ inú.
Kókó pàtàkì kan ni pé agbára ìbímọ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa. Ọ̀kan lára ète ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣe ni pé káwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé máa bímọ, kí wọ́n “kún ilẹ̀ ayé, kí [wọ́n] sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Lẹ́yìn tí Ìkún Omi sọ àwọn olùgbé ayé di èèyàn mẹ́jọ péré, Ọlọ́run tún mẹ́nu kan ìtọ́ni ìpìlẹ̀ yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 9:1) Ọlọ́run kò tún àṣẹ yẹn pa fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà pé ohun tó dáa ni pé kéèyàn bímọ.—1 Sámúẹ́lì 1:1-11; Sáàmù 128:3.
Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì fi hàn pé ó fi ojú ribiribi wo ọ̀ràn ọmọ bíbí. Fún àpẹẹrẹ, bí ọkùnrin kan tó gbéyàwó bá kú kó tó bí ọmọkùnrin tí kò ní jẹ́ kí orúkọ ẹ̀ pa rẹ́, arákùnrin rẹ̀ gbọ́dọ̀ bímọ fún un nípa ṣíṣú ìyàwó rẹ̀ lópó. (Diutarónómì 25:5) Òfin mìíràn tó tún yẹ fún àfiyèsí ni òfin tó sọ̀rọ̀ nípa aya kan tó gbìyànjú láti gbèjà ọkọ rẹ̀. Bó bá rá abẹ́ ẹni tí ń bá ọkọ rẹ̀ jà mú, a gbọ́dọ̀ gé ọwọ́ obìnrin náà ni; ó yẹ kí a kíyè si pé, Ọlọ́run kò sọ pé ẹ̀yà ìbímọ ti obìnrin náà tàbí ti ọkọ rẹ̀ gan-an ni kí a gé dípò, gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ti máa ń rí ní tí òfin ojú-fún-ojú. (Diutarónómì 25:11, 12) Ó dájú pé òfin yìí fi hàn pé ó yẹ kéèyàn bọ̀wọ̀ fún ẹ̀yà ìbímọ; ẹnì kan kò kàn lè bà á jẹ́ bẹ́ẹ̀yẹn.b
A mọ̀ pé àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Ísírẹ́lì mọ́, torí náà, òfin tó wà nínú Diutarónómì 25:11, 12 kò dè wọ́n. Jésù kò pàṣẹ pé dandan ni káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣègbéyàwó, kí wọ́n sì bímọ tó bí wọ́n ṣe fẹ́, èyí tí ọ̀pọ̀ tọkọtaya ti gbé yẹ̀ wò nígbà tí wọ́n fẹ́ pinnu bóyá àwọn yóò lo ọ̀nà ìfètòsọ́mọbíbí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Mátíù 19:10-12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn opó tí kò lè mára dúró, ‘àwọn opó tó kéré lọ́jọ́ orí, níyànjú pé kí wọ́n ṣe ìgbéyàwó, kí wọ́n sì bímọ.’ (1 Tímótì 5:11-14) Kò mẹ́nu kàn án pé káwọn Kristẹni sọ ara wọn di aláìlèbímọ títí láé—kí wọ́n dìídì fi agbára ìbímọ wọn rúbọ.
Ó dára káwọn Kristẹni ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ lórí kókó náà pé Ọlọ́run fi ojú ribiribi wo agbára ìbímọ wọn. Olúkúlùkù tọkọtaya ni yóò pinnu bóyá wọn yóò lo ọ̀nà ìfètòsọ́mọbíbí tó yẹ àti ìgbà tí wọn yóò lò ó. Òtítọ́ ni pé ìpinnu wọn yóò lágbára gidigidi bí àwọn oníṣègùn bá sọ pé bí oyún bá lọ ṣèèṣì wáyé, ẹ̀mí ìyá tàbí ti ọmọ lè wà nínú ewu ńlá, ó tilẹ̀ lè yọrí sí ikú pàápàá. Àwọn kan tó bá ara wọn nínú ipò yẹn ti gba kámú pé àwọn yóò ṣe iṣẹ́ abẹ táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí nípa sísọ ara wọn di aláìlèbímọ láti lè rí i dájú pé oyún kankan kò ní fi ìwàláàyè ìyá (tó lè ti bí àwọn ọmọ mìíràn) sínú ewu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò ní máa fòyà pé wọn lè bí ọmọ kan ní abirùn.
Ṣùgbọ́n ó dájú pé àwọn Kristẹni tí kò dojú kọ irú ewu tó kàmàmà yìí yóò fẹ́ láti lo ‘ìyèkooro èrò inú,’ kí wọ́n sì jẹ́ kí ojú ribiribi tí Ọlọ́run fi ń wo agbára ìbímọ darí ìrònú àti ohun tí wọ́n ń ṣe. (1 Tímótì 3:2; Títù 1:8; 2:2, 5-8) Èyí ni yóò fi hàn pé wọ́n wà lójúfò gidigidi nípa títẹ̀lé àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, bó bá wá di mímọ̀ ńkọ́, pé Kristẹni kan kò bìkítà fún ojú ìwòye Ọlọ́run? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn kò ní máa kọminú nípa bóyá ó ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, bóyá a mọ̀ ọ́n sí ẹni tí ń ṣe àwọn ìpinnu tó wà ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì? Láìsí àní-àní, irú àbààwọ́n burúkú bẹ́ẹ̀ sí orúkọ rere ẹnì kan lè nípa lórí bóyá òjíṣẹ́ ọ̀hún yẹ fún àkànṣe àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn lè máà rí bẹ́ẹ̀ bó bá ṣe pé ìgbà àìmọ̀ ni èèyàn ṣe iṣẹ́ abẹ yìí.—1 Tímótì 3:7.
a “Ìyànjú làwọn oníṣègùn ń gbà láti ṣe àtúnso [iṣan tí ń gbé àtọ̀ wá], a ó fi àṣeyọrí wọn mọ sí ìpíndọ́gba ogójì nínú ọgọ́rùn-ún, ẹ̀rí wà lóòótọ́ pé ó lè kẹ́sẹ járí jù bẹ́ẹ̀ lọ bí àwọn èèyàn ṣe ń gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nípa iṣẹ́ abẹ lórí àwọn ẹ̀yà ara tíntìntín. Àmọ́ o, kí ẹni táa bá ti sọ di aláìlèbímọ nípasẹ̀ iṣẹ́ abẹ vasectomy yáa gba kámú ni o, kó gbà pé kò ṣeé yí padà.” (Encyclopædia Britannica) “Ó yẹ kí á gbà pé iṣẹ́ abẹ sísọni di aláìlèbímọ kò ṣeé yí padà. Láìka ohun tí ẹni táa ṣe é fún lè ti gbọ́ nípa yíyí i padà, iṣẹ́ abẹ títún àwọn iṣan táa ti gé tẹ́lẹ̀ so padà ti gbówó lórí jù, kò sì sí ìdánilójú pé iṣẹ́ abẹ ọ̀hún yóò kẹ́sẹ járí. Ní ti àwọn obìnrin tó ṣe iṣẹ́ abẹ dídá agbára ìbímọ wọn padà lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ wọ́n di aláìlèbímọ, àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé ṣe ni oyún máa lọ bọ́ sẹ́yìn ilé-ọlẹ̀.”—Contemporary OB/GYN, June 1998.
b Òfin mìíràn tó tún jọ pé ó yẹ fún àfiyèsí sọ pé ọkùnrin tí ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ bá ti bà jẹ́ kò gbọ́dọ̀ wọ ìjọ Ọlọ́run. (Diutarónómì 23:1) Àmọ́ o, ìwé náà, Insight on the Scriptures sọ pé, dájúdájú “èyí ní í ṣe pẹ̀lú mímọ̀ọ́mọ̀ tẹni lọ́dàá fún ète àtiṣe ìṣekúṣe, irú bíi bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀.” Nítorí náà, òfin náà kò kan ọ̀ràn ìfètòsọ́mọbíbí. Ìwé Insight tún sọ pé: “Lọ́nà tó tuni nínú, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò tóun yóò tẹ́wọ́ gba àwọn ìwẹ̀fà gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ òun, bí wọ́n bá sì ṣègbọràn, wọn yóò ní orúkọ tó sàn ju àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Nígbà tí Jésù Kristi mú Òfin kúrò, gbogbo èèyàn tó bá ń lo ìgbàgbọ́, láìka ipò wọn àtẹ̀yìnwá sí, ló lè di ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. A ti mú àwọn ìyàtọ̀ ti ẹran ara kúrò.—Aísá 56:4, 5; Jòh 1:12.”