ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 10/1 ojú ìwé 28-31
  • A Fún Wọn Lókun Láti Sọ Pé A Ò Jẹ́ Hùwà Àìtọ́ Láé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Fún Wọn Lókun Láti Sọ Pé A Ò Jẹ́ Hùwà Àìtọ́ Láé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òde Òní Gan-an Ni Kíkọ̀ Láti Hùwà Àìtọ́ Ṣe Pàtàkì Jù Lọ
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Ọ̀dọ́kùnrin Kan Tó Kọ̀ Láti Hùwà Àìtọ́
  • Sísọ Pé Rárá, A Ò Ní Fàyè Gba Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe
  • Kíkọ̀ Láti Hùwà Àìtọ́ Jẹ́ Ọ̀ràn Ìyè àti Ikú
  • ‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Mímọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ẹrú Tó Ṣègbọràn sí Ọlọ́run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 10/1 ojú ìwé 28-31

A Fún Wọn Lókun Láti Sọ Pé A Ò Jẹ́ Hùwà Àìtọ́ Láé

TIMOTHY ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo ṣì wà ní ọ̀dọ́langba, tí mò ń ṣiṣẹ́ nílé ìtajà kan, ẹnì kan tí a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ pé kí n wá sílé òun. Ó ní àwọn òbí òun kò ní sí nílé, àwọn ọmọge sì máa wà níbẹ̀, a ó sì láǹfààní láti bá wọn ṣe.” Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lónìí ló máa bẹ́ mọ́ irú ìkésíni bẹ́ẹ̀. Àmọ́, báwo ni Timothy ṣe fèsì? Ó ní: “Mo sọ fún un lójú ẹsẹ̀ pé mi ò ní í wá, àti pé ẹ̀rí ọkàn Kristẹni mi kò lè jẹ́ kí n ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya mi.”

Timothy ò mọ̀ pé ọmọbìnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ń gbọ́ nígbà tí òun ń ṣàlàyé ìdí tí òun ò fi ní wá. Ẹ̀mí ìwà mímọ́ tó ní yìí ló mú kí ọmọbìnrin náà wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, kò sì pẹ́ tí Timothy fi dojú kọ ìṣòro sísọ fún un pé òun ò ní bá a hùwà àìtọ́—èyí ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, bí a óò ṣe rí i níwájú.

Dájúdájú kì í ṣe àkókò tiwa yìí ni dídánniwò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún [3,000] sẹ́yìn, Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pe: “Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá gbìyànjú láti sún ọ dẹ́ṣẹ̀, má gbà. . . . Fa ẹsẹ̀ rẹ sẹ́yìn kúrò ní òpópónà wọn.” (Òwe 1:10, 15) Jèhófà fúnra rẹ̀ pàṣẹ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.” (Ẹ́kísódù 23:2) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn àkókò kan wà táa gbọ́dọ̀ sọ pé rárá o, àwa ò ní gbà kí ẹnì kan tàn wá láti hùwà àìtọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun làwọn èèyàn fi ń ṣayọ̀ lágbègbè wa.

Òde Òní Gan-an Ni Kíkọ̀ Láti Hùwà Àìtọ́ Ṣe Pàtàkì Jù Lọ

Kò fìgbà kan rọrùn rí láti kọ̀ láti hùwà àìtọ́, ó sì tún wá ṣòro gan-an nísinsìnyí, nítorí pé a ń gbé ní àkókò kan tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ, àwọn ènìyàn lápapọ̀ ti di olùfẹ́ fàájì, wọ́n ń fi ìwà ipá ṣayọ̀, nǹkan tẹ̀mí ò jọ wọ́n lójú mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò níwà ọmọlúwàbí. (2 Tímótì 3:1-5) Ààrẹ Yunifásítì Jesuit kan sọ pé: “A ti ní àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n kan tó ti wà tipẹ́ táa ti wá ń nàka àbùkù sí, tí a sì ti wá rí i pé wọn ò kún ojú ìwọ̀n mọ́ tàbí ká kúkú sọ pé wọn ò bóde mu mọ́. Ní báyìí, ó dà bí ẹni pé kò sí ìlànà kankan táa fi lè mọ ohun tó jẹ́ ìwà rere mọ́.” Bákan náà ni adájọ́ àgbà kan sọ pé: “Kò sí ìyàtọ̀ tó ṣe gúnmọ́ láàárín rere àti búburú mọ́. Bákan náà ni gbogbo rẹ̀ ṣe rí. . . . Ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ló mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Lóde ìwòyí, ẹni ọwọ́ bá tẹ̀ ló dẹ́ṣẹ̀, kì í ṣe ẹni tó rúfin.”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn èèyàn tí wọ́n nírú ìwà bẹ́ẹ̀ pé: “Wọ́n wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, nítorí àìmọ̀kan tí ń bẹ nínú wọn, nítorí yíyigbì ọkàn-àyà wọn. Níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.” (Éfésù 4:18, 19) Àmọ́, wọ́n máa tó kànjàngbọ̀n. Aísáyà polongo pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń sọ pé ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára, àwọn tí ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn.” (Aísáyà 5:20) Kì í ṣe pé àwọn yẹn ń ká ohun tí wọ́n fúnrúgbìn báyìí nìkan ni, ṣùgbọ́n, wọn óò tún gba “ègbé” tó burú jù lọ—ìdájọ́ búburú látọ̀dọ̀ Jèhófà.—Gálátíà 6:7.

Sáàmù 92:7 sọ pé: “Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bí ewéko, tí gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ bá sì yọ ìtànná, kí a lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú títí láé ni.” Lọ́rọ̀ mìíràn, ìwà ibi tó pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ yìí kò ní í máa báa lọ títí láé, kó sì máa mú ayé nira fáwọn èèyàn láti gbé. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, Jésù sọ pé “ìran” tó ń ṣonígbọ̀wọ́ ìwà ibi yìí gan-an ni Ọlọ́run yóò pa run nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Mátíù 24:3, 21, 34) Nítorí náà, báa bá fẹ́ la ìpọ́njú ńlá yẹn já, a gbọ́dọ̀ mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run; ó sì dájú pé àwa náà nílò agbára láti hùwà rere, èyí tó lè mú ká sọ pé rárá, àwa ò ní hùwà àìtọ́ èyíkéyìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ò rọrùn, Jèhófà ti fún wa ní àwọn àpẹẹrẹ kan tó lè fún wa níṣìírí nínú Bíbélì àti lóde òní pẹ̀lú.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Ọ̀dọ́kùnrin Kan Tó Kọ̀ Láti Hùwà Àìtọ́

Ó dà bí ẹni pé ohun tó ṣòro jù lọ fún àwọn kan ni láti sọ pé rárá o, àwọn ò ní ṣàgbèrè, bẹ́ẹ̀ làwọn ò ní ṣe panṣágà, kódà ó máa ń ṣòro fún àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni pàápàá. Timothy, táa mẹ́nu kàn ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́, fi àpẹẹrẹ Jósẹ́fù tó jẹ́ ọ̀dọ́ sọ́kàn, èyí tí a kọ sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ní Jẹ́nẹ́sísì 39:1-12. Jósẹ́fù fi hàn pé òun ní agbára láti hùwà rere nígbà tí aya ìjòyè Íjíbítì náà, Pọ́tífárì, kò jẹ́ kó gbádùn, tó ṣáà ń pè é pé kó wá ni ìbálòpọ̀ pẹ̀lú òun. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, Jósẹ́fù “yóò kọ̀, yóò sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé: . . . ‘Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?’”

Báwo ni Jósẹ́fù ṣe ní agbára láti hùwà rere, tó fi lè sọ fún ìyàwó Pọ́tífárì lójoojúmọ́ pé, òun ò ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, ó ka ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà sí pàtàkì ju ìgbádùn ìgbà díẹ̀ tí òun yóò rí. Ní àfikún sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò sí lábẹ́ òfin àtọ̀runwá (Òfin Mósè kò tí ì dé nígbà yẹn), Jósẹ́fù lóye ìlànà ìwà rere dáadáa; ó mọ̀ pé kì í ṣe Pọ́tífárì nìkan ni òun yóò dẹ́ṣẹ̀ sí bí òun bá bá ìyàwó rẹ̀, tí ìfẹ́ gbígbóná ti kó sí lórí yìí, ṣe àgbèrè, ṣùgbọ́n òun yóò tún dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run pẹ̀lú.—Jẹ́nẹ́sísì 39:8, 9.

Ó dájú pé Jósẹ́fù lóye ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ náà pé ohun táà bá ní í jẹ, a kì í fi runmú, torí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ìfẹ́ gbígbóná kó sí òun alára lórí, tí kò sì ní lè ṣàkóso rẹ̀. Ó jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu fún Kristẹni láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù. Ilé Ìṣọ́ ti July 1, 1957, (Gẹ̀ẹ́sì) sọ pé “Ó gbọ́dọ̀ mọ àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó tó ní, kò gbọ́dọ̀ rò pé òun lè tẹ́ ìfẹ́ ara òun lọ́rùn dé àyè kan tó bá Ìwé Mímọ́ mu, kí òun sì dúró níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣèyẹn fúngbà díẹ̀, bópẹ́bóyá a ó fà á kúrò níbi tó dúró sí, a sì bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Ó dájú pé bó ṣe máa rí nìyẹn, nítorí pé tí èèyàn bá fàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ́kàn rẹ̀, ṣe ni yóò máa lágbára sí i, yóò sì ṣòro fún onítọ̀hún láti já ara rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀. Yóò wá ṣòro jù fún un láti mọ́kàn kúrò lára rẹ̀. Ohun tó dára jù lọ ni pé kó dènà rẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ pàá.”

Yóò túbọ̀ rọrùn láti dènà rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́ pàá, báa bá nífẹ̀ẹ́ ohun tó tọ́, tí a sì kórìíra ohun tí kò tọ́. (Sáàmù 37:27) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lé e lórí, a ò gbọ́dọ̀ sinmi. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ìfẹ́ wa fún ohun tó tọ́ àti ìkórìíra tí a ní fún ohun tí kò tọ́ yóò máa lágbára sí i. Ní báyìí ná, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Jésù, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò, kí a máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà ká má bàa kó sínú ìdánwò, kí a sì lè bọ́ lọ́wọ́ ẹni ibi nì.—Mátíù 6:13; 1 Tẹsalóníkà 5:17.

Sísọ Pé Rárá, A Ò Ní Fàyè Gba Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe

Ohun mìíràn tí ń múni hùwà àìtọ́ ni ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Ọ̀dọ́ kan jẹ́wọ́ pé: “Ọ̀nà méjì ni mo ń gbà lo ìgbésí ayé mi—tilé ìwé ọ̀kan, ọ̀tọ̀ sì ni tilé. Nílé ẹ̀kọ́, àwọn ọmọ tó jẹ́ pé wọn ò lè ṣe kí wọ́n má sọ̀rọ̀ rírùn ni mò ń bá kẹ́gbẹ́. Èmi náà sì ti ń kọ́ṣé wọn. Kí ni kí n ṣe?” Ó pọndandan pé ká ní ìgboyà láti dá yàtọ̀, ọ̀nà kan táa sì fi lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ka àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì tó sọ fún wa nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, ká sì máa ṣàṣàrò lórí wọn, àwọn bíi Jósẹ́fù. Àwọn àpẹẹrẹ rere mìíràn ni ti Dáníẹ́lì, Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò—àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin tí wọ́n ní ìgboyà láti dá yàtọ̀ sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn.

Nígbà tí wọ́n ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́kùnrin mìíràn ní ààfin ọba Bábílónì, wọ́n sọ pé kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ísírẹ́lì mẹ́rin wọ̀nyí máa jẹ “ohun tí a yọ̀ǹda lójoojúmọ́ fún wọn láti inú àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba.” Kí wọ́n má bàa dẹ́ṣẹ̀ sí apá tí ó ní í ṣe pẹ̀lú oúnjẹ nínú Òfin Mósè, wọ́n kọ̀, wọn ò jẹ oúnjẹ yìí. Ìyẹn gba agbára—pàápàá jù lọ, bó ṣe jẹ́ pé àwọn oúnjẹ náà ní láti jẹ́ èyí tí kò ṣeé wò ní àwòmójúkúrò nítorí pé “àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba,” ni wọ́n. Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyí fi lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni tó lè dojú kọ ìdánwò lónìí, táwọn kan lè fòòró wọn pàápàá láti mu ọtí líle tàbí láti lo oògùn olóró àti láti mu tábà!—Dáníẹ́lì 1:3-17.

Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò tún fi òtítọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi wá sọ níkẹyìn hàn pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) Kò sí àní-àní pé bí wọ́n ṣe fi ìgboyà mú ìdúró wọn lórí ọ̀ràn oúnjẹ tó jẹ́ ohun kékeré àti ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín ti ní láti fún wọn lókun, tí wọ́n fi kojú ìdánwò ńlá tí wọ́n wá rí níkẹyìn. (Dáníẹ́lì 1:18-20) Ìdánwò yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n pàṣẹ fún wọn pé ikú iná ni wọn óò kú bí wọn ò bá dara pọ̀ mọ́ àwọn tó kù láti bọ̀rìṣà. Tìgboyà-tìgboyà ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà fi dúró lórí ìpinnu wọ́n láti sin Jèhófà nìkan ṣoṣo, wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé kíkún sí i láìka ohunkóhun tó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ sí. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà bù kún wọn nítorí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà wọn—lọ́tẹ̀ yìí, ó jẹ́ nípa dídáàbò bò wọ́n lọ́nà ìyanu kúrò lọ́wọ́ ọwọ́ iná náà nígbà tí wọ́n gbé wọn jù sínú àgbáàràgbá iná tó ń jó fòfò.—Dáníẹ́lì 3:1-30.

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ mìíràn nípa àwọn tó sọ pé rárá o, àwọn ò ní hùwà àìtọ́ ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mósè sọ pé rárá o, kí a má ṣe “pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ì bá ti fún un láǹfààní láti lọ́wọ́ nínú “jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀” ní Íjíbítì. (Hébérù 11:24-26) Wòlíì Sámúẹ́lì kọ̀ láti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí ó má bàa ṣi ọlá àṣẹ rẹ̀ lò. (1 Sámúẹ́lì 12:3, 4) Àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi fi ìgboyà dáhùn pé rárá o, àwọn ò ní dẹ́kun àtiwàásù nígbà táa pàṣẹ fún wọn láti dá iṣẹ́ ìwàásù wọ́n dúró. (Ìṣe 5:27-29) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé òun ò jẹ́ hùwà àìtọ́ láé—àní ó dúró ti ìpinnu náà títí dé òpin ìgbésí ayé rẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ ogun fún un ní “wáìnì tí a fi òjíá sọ di líle.” Ká ló mu ún ni, ó ṣeé ṣe kí ó mú kó ba ìpinnu rẹ̀ jẹ́ ní àkókò líle koko yẹn.—Máàkù 15:23; Mátíù 4:1-10.

Kíkọ̀ Láti Hùwà Àìtọ́ Jẹ́ Ọ̀ràn Ìyè àti Ikú

Jésù sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14.

Ọ̀nà gbígbòòrò yìí ni ọ̀pọ̀ ènìyàn fẹ́ máa rìn nítorí pé ó rọrùn láti rìn. Àwọn tó ti fìwàkiwà kẹ́ra wọn bà jẹ́ ló ń rìn ín, àwọn tó ti fara wọn fún ìrònú àti ọ̀nà ti ẹran ara, àwọn tí kò fẹ́ dá yàtọ̀ sí ayé Sátánì, tó jẹ́ pé ohun tí ayé náà ń ṣe ni wọ́n fẹ́ máa ṣe. Wọ́n rò pé àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run lórí ìwà rere ti ká wọn lọ́wọ́ kò jù. (Éfésù 4:17-19) Síbẹ̀, Jésù sọ ni kedere pé ọ̀nà gbígbòòrò náà lọ “sínú ìparun.”

Àmọ́, kí ló dé tí Jésù fi sọ pé díẹ̀ làwọn tó yàn láti rìn lójú ọ̀nà híhá náà? Ìdí pàtàkì ni pé àwọn díẹ̀ ló fẹ́ kí òfin àti ìlànà Ọlọ́run máa darí ìgbésí ayé wọn, kí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dènà ọ̀pọ̀ ìrònú àti àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún wọn láti hùwà àìtọ́ tó wà yí wọn ká. Síwájú sí i, ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ló múra tán láti sapá gidigidi láti borí ẹ̀mí híhùwàkiwà, ṣíṣe ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àti ìbẹ̀rù ìfiṣẹ̀sín tí wọ́n lè bá pàdé nítorí ọ̀nà tí wọ́n ti yàn.—1 Pétérù 3:16; 4:4.

Àwọn wọ̀nyí lóye irú ìmọ̀lára tí Pọ́ọ̀lù ní nígbà tó ń ṣàlàyé bí òun ṣe sapá gidigidi láti sọ pé rárá o, òun kò ní dẹ́ṣẹ̀. Bíi ti ayé òde òní, ayé Róòmù àti ti Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù gbé fúnni láǹfààní láti fi ìwà àìtọ́ kẹ́ra ẹni bà jẹ́, kí onítọ̀hún sì tipa bẹ́ẹ̀ máa rìn ní ọ̀nà gbígbòòrò. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé èrò inú òun, tó mọ ohun tó tọ́, ń gbé ‘ogun’ tí kò dáwọ́ dúró ti ẹran ara òun, tó ń fẹ́ hùwà àìtọ́. (Róòmù 7:21-24) Dájúdájú, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ohun tó dára ni pé kí ara òun di ìránṣẹ́ òun dípò kí ó jẹ ọ̀gá lé òun lórí, nítorí náà, ó kẹ́kọ̀ọ́ láti máa sọ pé rárá, òun ò ní tẹ̀ sí ibi tó fẹ́. Ó kọ̀wé pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.” (1 Kọ́ríńtì 9:27) Báwo ló ṣe rọ́nà kápá rẹ̀? Kì í ṣe agbára ti ara rẹ̀ ló fi ṣe é, nítorí agbára ẹ ò gbe, àmọ́, ẹ̀mí Ọlọ́run ló ràn án lọ́wọ́.—Róòmù 8:9-11.

Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́ títí dé òpin, bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ẹ̀dá ni. Nígbà tí ikú rẹ̀ ti ń sún mọ́lé, ó ṣeé ṣe fún un láti kọ̀wé pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo pa mọ́ dè mí.”—2 Tímótì 4:7, 8.

Bí a ti ń bá àìpé ara wa jagun, ẹ wo àwọn àpẹẹrẹ oníṣìírí tí a ní, kì í ṣe ti Pọ́ọ̀lù nìkan o, àmọ́, a tún ní ti àwọn tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ fún òun náà—Jósẹ́fù, Mósè, Dáníẹ́lì, Ṣádírákì, Méṣákì, Àbẹ́dínígò, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni àwọn náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́ wọ̀nyí ló sọ pé àwọn ò jẹ́ hùwà àìtọ́ láé, kì í ṣe nítorí pé wọ́n lágídí tàbí wọ́n jẹ́ olóríkunkun, àmọ́, ó jẹ́ nítorí agbára tí ẹ̀mí Jèhófà fún wọn láti hùwà rere. (Gálátíà 5:22, 23) Wọ́n jẹ́ ọkùnrin tẹ̀mí. Gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá ti ẹnu Jèhófà jáde ni wọ́n máa ń fẹ́ gbọ́. (Diutarónómì 8:3) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn ní ìyè. (Diutarónómì 32:47) Lékè gbogbo rẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀, ìrànlọ́wọ́ tí ó ń fún wọn sì ń jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún wọn láti fi sùúrù kọ́ bí a ṣe ń kórìíra ìwà àìtọ́.—Sáàmù 97:10; Òwe 1:7.

Ẹ jẹ́ kí àwa náà dà bíi tiwọn. Ní gidi, kí a tó lè máa sọ pé rárá o, àwa ò ní hùwà àìtọ́ èyíkéyìí, a nílò ẹ̀mí Jèhófà bí àwọn náà ti nílò rẹ̀. Jèhófà ń fún wà ní ẹ̀mí rẹ̀ ní fàlàlà, bí a bá fi tòótọ́tòótọ́ béèrè fún un, tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé.—Sáàmù 119:105; Lúùkù 11:13; Hébérù 10:24, 25.

Inú Timothy, táa mẹ́nu kan níbẹ̀rẹ̀, dùn pé òun kò gbójú fo àìní òun nípa tẹ̀mí dá. Lọ́jọ́ kan, ọmọbìnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tó gbọ́ ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tíyẹn sì wá jẹ́ kí ìfẹ́ Timothy kó sí i lórí, wá rọra ké sí Timothy pé kó wá sí ilé òun nígbà tí ọkọ rẹ̀ kò sí nílé. Timothy kọ̀, ó lóun ò ní wá. Obìnrin yìí kò sì ṣeé sá fún, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ń rọ ọmọkùnrin yìí pé kó wá sẹ́ẹ̀, bíi ti aya Pọ́tífárì. Timothy mú ìdúró rẹ̀ gbọn-in, gbogbo ìgbà tí obìnrin yìí bá ti ń rọ̀ ọ́, ló ń rọ́ra sọ fún un pé rárá o. Ó tilẹ̀ jẹ́rìí dáadáa fún obìnrin yìí láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Timothy dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gan-an pé ó fún òun ní agbára láti hùwà rere, láti lè sọ pé, òun ò jẹ́ hùwà àìtọ́ láé, Timothy sì ti gbé Kristẹni kan tó dáa bí tirẹ̀ níyàwó ní báyìí, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì fi ń gbé pọ̀. Ní tòótọ́, Jèhófà yóò bù kún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ìwà títọ́ Kristẹni wọn mọ́ nípa sísọ pé, àwọn ò jẹ́ hùwà àìtọ́ láé, yóò sì fún wọn lókun láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Sáàmù 1:1-3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́