ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 12/1 ojú ìwé 30-31
  • Òkè Athos—Ṣé “Òkè Mímọ́” Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òkè Athos—Ṣé “Òkè Mímọ́” Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Òkè Ńlá Mímọ́” Àwọn Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ànìkàngbé
  • Òkè Athos Lónìí
  • “Òkè Ńlá Mímọ́” Kan fún Gbogbo Ènìyàn
  • A Tẹ́ Àìní Rẹ̀ Nípa Tẹ̀mí Lọ́rùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Sinai Oke Mose ati Àánú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • A Gbé Ilé Jèhófà Lékè
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Àwọn Afarapitú Lórí Òkè Ńlá Ti Àpáta Gàǹgà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 12/1 ojú ìwé 30-31

Òkè Athos—Ṣé “Òkè Mímọ́” Ni?

LÓJÚ àwọn okòó-lé-nígba mílíọ̀nù tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, Òkè Athos, òkè gbágungbàgun tó wà ní àríwá ilẹ̀ Gíríìsì ni “òkè mímọ́ jù lọ ní gbogbo àgbègbè tí ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Kristẹni ti fìdí múlẹ̀.” Fún ọ̀pọ̀ lára wọn, rínrin ìrìn àjò lọ sí “òkè mímọ́” Athos jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń wọ̀nà fún, tó sì ń dá wọn lọ́rùn. Kí ni “òkè mímọ́” yìí? Báwo ló ṣe wá gbayì tó bẹ́ẹ̀? Àti pé ṣé òun ni “òkè ńlá” ti àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ní láti máa wò fún ìtọ́ni tẹ̀mí àti ìjọsìn tòótọ́?

Gbólóhùn náà “òkè ńlá mímọ́” fara hàn nínú Bíbélì. Ó so pọ̀ mọ́ ìjọsìn mímọ́, tí kò lábùlà, ìjọsìn táa gbé ga, tó jẹ́ ti Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà. Òkè Síónì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì di “òkè ńlá mímọ́” nígbà tí Dáfídì Ọba gbé àpótí ẹ̀rí wá síbẹ̀. (Sáàmù 15:1; 43:3; 2 Sámúẹ́lì 6:12, 17) Lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì sórí Òkè Mòráyà tán ni “Síónì” di ọ̀kan lára ibi tí tẹ́ńpìlì wà; tí Síónì sì wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ “òkè ńlá mímọ́” ti Ọlọ́run. (Sáàmù 2:6 Jóẹ́lì 3:17) Níwọ̀n bí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ti wà ní Jerúsálẹ́mù, nígbà mìíràn a máa ń pe ìlú yẹn ní “òkè ńlá mímọ́” ti Ọlọ́run.—Aísáyà 66:20; Dáníẹ́lì 9:16, 20.

Lọ́jọ́ òní ńkọ́? Ṣé Òkè Athos—tàbí ṣóńṣó orí òkè mìíràn—ni “òkè ńlá mímọ́” tí àwọn ènìyàn ní láti máa wọ́ tìrítìrí lọ kí wọ́n lè sin Ọlọ́run lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà?

“Òkè Ńlá Mímọ́” Àwọn Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ànìkàngbé

Ìhà ìlà oòrùn Ìyawọlẹ̀ Omi Chalcidice, níbi tí ẹnu ilẹ̀ tóóró tó lọ sínú Òkun Aegean wà ní ìlà oòrùn Thessaloníki òde òní ni Òkè Athos wà. Ó jẹ́ àpáta mábìlì tí ń kọ mànà tó yọ ṣọnṣọ sókè láti inú òkun, tó sì ga tó ẹgbàá àti méjìlélọ́gbọ̀n [2,032] mítà.

Ó pẹ́ tí wọ́n ti ka Athos síbi mímọ́. Nínú ìtàn ìwáṣẹ̀ Gíríìkì ìgbàanì, ibẹ̀ ni ilé àwọn ọlọ́run kí Òkè Olympus tó di ilé wọn. Lákòókò kan lẹ́yìn Kọnsitatáìnì Ńlá (ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì tiwa), Athos di ibi mímọ́ fún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìtàn àtẹnudẹ́nu kan sọ, nígbà tí Màríà “wúńdíá” àti Jòhánù Ajíhìnrere ń lọ sí Kípírọ́sì láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Lásárù, ìjì líle kan ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ tó mú kí wọ́n bára wọn lórí Òkè Athos. Òkè náà wu Màríà gan-an ni, ló bá ní kí Jésù yọ̀ǹda rẹ̀ fún òun. Ìdí nìyẹn táa tún fi mọ Òkè Athos sí “Ọgbà Wúńdíá Mímọ́.” Ìgbà tó fi máa di àkókò tí ilẹ̀ Byzantine ń ṣàkóso, gbogbo ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta náà wá di èyí tí a mọ̀ sí Òkè Ńlá Mímọ́. Àpèlé yìí wá di èyí tí wọ́n fàṣẹ sí tí wọ́n sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní 1046 Sànmánì Tiwa lábẹ́ àṣẹ Olú Ọba Kọnsitatáìnì Kẹsàn-án ti Monomachos.

Nítorí pé Athos rí gbágungbàgun, tí kò sì sí òkè mìíràn lágbègbè rẹ̀, ó wá di ibì kan tí àwọn ènìyàn ti lọ ń dá gbé. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ni àwọn onísìn láti gbogbo ilẹ̀ tó jẹ́ tí Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ń rọ́ wá síbẹ̀—Ìyẹn àwọn ará Gíríìsì, Serb, Róòmù, Bulgaria, Rọ́ṣíà àti àwọn mìíràn—tí wọ́n ti wá kọ́ onírúurú ilé fún àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé, pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn ibùgbé wọn síbẹ̀. Nǹkan bí ogún lára àwọn ilé wọ̀nyí ṣì wà síbẹ̀.

Òkè Athos Lónìí

Lónìí, Athos jẹ́ àgbègbè kan tó ti dá ní ìjọba tirẹ̀, ó ti ní ìwé òfin ìlú táa fọwọ́ sí láti ọdún 1926. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí iye àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé tó wà níbẹ̀ fi ń dín kù, wọ́n tún tí lọ sókè báyìí sí ohun tó lé ní ẹgbàá.

Ọ̀kọ̀ọ̀kan ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé wọ̀nyí lo ní oko, ṣọ́ọ̀ṣì kékeré, àti àwọn ibùgbé tirẹ̀. Ibi mímọ́ jù lọ fún àwọn ànìkàngbé wọ̀nyí wà ní Karoúlia, wọ́n kọ́ ọ sí ṣóńṣó Òkè Anthos, níbi tí òòyì ti lè máa kọ́ èèyàn lójú. Àwọn ahéré tí wọ́n kọ́ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ló wà níhìn-ín, ọ̀nà tóóró kọ́lọkọ̀lọ, táa to òkúta sí, tí ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn la lè bá débẹ̀. Àṣà ìlànà ẹ̀sìn àtijọ́ ni àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé wọ̀nyí ṣì ń tẹ̀ lé nínú ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́ ní Athos, wọ́n ń lo aago Byzantine (tí ọjọ́ ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́) àti kàlẹ́ńdà Julian (tó fi ọjọ́ mẹ́tàlá lé sí ti Gregory).

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin kan ni wọ́n sọ pé àwọn fi “ìjẹ́mímọ́” ibi ìjọsìn yìí fún, síbẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún làwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé àtàwọn ayẹrafẹ́gbẹ́ fi sọ pé ohunkóhun tó bá jẹ́ abo kò gbọ́dọ̀ dé ibi ìyawọlẹ̀ omi náà—yálà ènìyàn tàbí ẹranko—bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò gbà kí ìwẹ̀fà èyíkéyìí tàbí ọkùnrin tí kò dá irùgbọ̀n sí wá sí àgbègbè yìí. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni wọ́n dẹwọ́ òfin tí wọ́n fi de àwọn tí kò dá irùgbọ̀n sí àtàwọn abo ẹranko bíi mélòó kan, ṣùgbọ́n òfin náà ṣì de àwọn obìnrin gan-an tí wọn ò fi lè gbà kí wọ́n dé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] mítà sí èbúté Athos.

“Òkè Ńlá Mímọ́” Kan fún Gbogbo Ènìyàn

Ṣé Athos ni “òkè ńlá mímọ́” tí àwọn Kristẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run ti ní láti máa lọ jọ́sìn ni? Nígbà tí Jésù ń bá obìnrin ará Samáríà yẹn sọ̀rọ̀, ẹni tó gbà gbọ́ pé orí Òkè Gérísímù làwọn èèyàn ti gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn Ọlọ́run, ó mú un ṣe kedere pé kò sí òkè ńlá kan tí a lè fojú rí tí a yà sọ́tọ̀ pé ibẹ̀ ni a ó tí máa jọ́sìn Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí kì í ṣe ní [Gérísímù] tàbí ní Jerúsálẹ́mù ni ẹ ó ti máa jọ́sìn Baba.” Èé ṣe? “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:21, 24.

Nígbà tí wòlíì Aísáyà ń tọ́ka sí àkókò wa, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “òkè ńlá ilé Jèhófà” ìṣàpẹẹrẹ kan yóò “di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá” a ó sì “gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké,” àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ sórí rẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Aísáyà 2:2, 3.

A pé àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí wọ́n fẹ́ ní ìbátan tó ṣètẹ́wọ́gbà pẹ̀lú Ọlọ́run láti wá jọ́sìn Jèhófà ní “ẹ̀mí àti òtítọ́.” Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn káàkiri àgbáyé ló ti rí ọ̀nà gbà dé ‘òkè ńlá Jèhófà.’ Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn mìíràn ń sọ ìmọ̀lára wọn jáde bíi ti agbẹjọ́rò Gíríìkì nì, tó sọ̀rọ̀ nípa Athos pé: “Kò dá mi lójú pé àwọn àgbègbè kan pàtó tàbí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ni nǹkan tẹ̀mí wà.”—Fí wé Ìṣe 17:24.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

A Ti Rí Ohun Ìṣúra Kan Tó Ti Fara Sin Tipẹ́tipẹ́

Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá ni àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé tó wà ní Athos ti ń kó àwọn ìṣúra kan jọ tó ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] ìwé àfọwọ́kọ nínú, àwọn kan sọ pé ohun ni àkójọpọ̀ ìwé tó níye lórí jù lọ ní gbogbo àgbáyé láti ọ̀rúndún kẹrin títí dí ìsinsìnyí. Àwọn àkójọ ìwé wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìdìpọ̀ ìwé lódindi àti àwọn ojú ewé tó wà nínú Ìhìn Rere, àwọn sáàmù àti ìwé orin, bẹ́ẹ̀ la tún rí àwọn àwòrán àtayébáyé, àwọn ère, ohun gbígbẹ́, àti àwọn ohun tí wọ́n fi irin ṣe. Wọ́n fojú bù ú pé Òkè Athos ní ìdá mẹ́rin nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì tó wà lágbàáyé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ṣì wà táa ní láti tò jọ dáradára. Ọdún 1997 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé gbà pé kí a kó lára ìṣúra wọn wọ̀nyí wá fún àfihàn ní Thessaloníki.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Telis/Greek National Tourist Organization

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́