Kérésìmesì ní Ìlà Oòrùn Ayé
• NÍ NǸKAN BÍ IGBA ỌDÚN SẸ́YÌN, gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan láti Korea ṣèbẹ̀wò sí Peking, nílẹ̀ China. Bó ṣe ń wo àwòrán tó wà lábẹ́ òrùlé ṣọ́ọ̀ṣì ńlá kan ló rí àwòrán Màríà tó gbé Jésù ọmọ kékeré lọ́wọ́. Ohun tó sọ nípa àwòrán amúnitagìrì yìí ni pé:
“Obìnrin kan gbé ọmọ lẹ́sẹ̀, ọmọ náà dà bí aláàárẹ̀, kò sì tíì lè ju ọmọ ọdún márùn-ún sí mẹ́fà lọ. Ó jọ pé obìnrin náà kò lè gbórí sókè, tí ẹ̀mí rẹ̀ ò gbé wíwo ọmọ náà ní ipò tó wà yìí. Lẹ́yìn wọn lọ́hùn-ún sì rèé, àwọn iwin àtàwọn ọmọ kéékèèké tó ní ìyẹ́ lápá ló ń fò kiri níbẹ̀. Bí mo ṣe ǹ wò wọ́n lókè orí mi, ó dà bí ẹni pé ìgbàkigbà ni wọ́n lè já lù mí lórí. Èyí ló mú kí n fòyà, ni mo bá nawọ́ mi sókè kí n lè dì wọ́n mú.”
ÌYẸN ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe ti bẹ̀rẹ̀ ní Yúróòpù, ìyẹn jẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú ti bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ lójú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Ìlà Oòrùn ayé, bí àwòrán yẹn ṣe ṣàjèjì ni ìsìn Kristẹni pàápàá ṣe ṣàjèjì. Ìyẹn ti wá yí padà ṣá o! Gbogbo àkókò Kérésìmesì ni wọ́n máa ń fi àwòrán Jésù kékeré jòjòló hàn. Irú àwòrán bẹ́ẹ̀ ti mọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn ayé lára, ọ̀pọ̀ àdúgbò wọn ló sì ti dà bíi ti Yúróòpù báyìí.
Ní alẹ́ November 25, 1998, ìyẹn nígbà tí Kérésìmesì ku oṣù kan ni Champs Élysées ní Paris mọ́lẹ̀ yòò nígbà tí wọ́n tan ohun tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún gílóòbù sórí ọ̀ọ́dúnrún igi tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà àdúgbò lílókìkí yẹn. Ní ìfiwéra pẹ̀lú ìyẹn, ní ojú pópó kan tó wà ní àgbègbè káràkátà ní ìlú Seoul, Korea, ilé ìtajà ńlá kan gbé igi Kérésìmesì ńlá kan jáde, èyí ló wá mú kí ibi gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí mọ́lẹ̀ yòò nínú olú ìlú náà ní alaalẹ́. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n ti fi igi Kérésìmesì ṣe gbogbo ojú pópó rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.
Ojoojúmọ́ ni tẹlifíṣọ̀n, rédíò, àti àwọn ìwé ìròyìn ń gbé àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ní í ṣe pẹ̀lú Kérésìmesì jáde. Bí pọ̀pọ̀ṣìnṣìn Kérésìmesì ti ń lọ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè náà ń yọ̀ ṣìnkìn pé àwọn rí òpin ọdún. Ní wàràǹṣeṣà, wọ́n ti ṣe àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní Seoul lọ́ṣọ̀ọ́, ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ pé iye wọn máa ń ṣe àwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sí ìlú náà ní kàyéfì. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ìgbà tí ojú àwọn ará Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà bá kódí fún ṣíṣayẹyẹ Ọjọ́ Ìdúpẹ́ nígbà tí oṣù November bá ń parí lọ ni pọ̀pọ̀ṣìnṣìn Kérésìmesì máa ń gba àwọn ará Korea àti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tó wà ní apá Ìlà Oòrùn ayé lọ́kàn.
Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìlà Oòrùn ayé la ò kà sí ilẹ̀ ẹlẹ́sìn Kristi. Fún àpẹẹrẹ, nǹkan bí ìpín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ààbọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún péré ló sọ pé Kristẹni làwọn ní Korea. Nǹkan bí ìpín mẹ́jọ ló sọ bẹ́ẹ̀ ní Hong Kong, ti Taiwan jẹ́ nǹkan bí ìpín méje ààbọ̀, díẹ̀ ló sì fi lé ní ìpín kan péré nínú ọgọ́rùn-ún ní Japan. Ní kedere, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Ìlà Oòrùn ayé ni kì í ṣe Kristẹni, àmọ́, wọn ò rí ohun tó burú nínú ṣíṣe ayẹyẹ Kérésìmesì. Ká sọ tòótọ́, ó dà bí ẹni pé ó sábà máa ń ká wọn lára ju ti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, Hong Kong la mọ̀ bí ẹní mowó nítorí ayẹyẹ Kérésìmesì tí wọ́n máa ń ṣe lọ́nà tó peléke, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé ibẹ̀ ló jẹ́ onísìn Búdà tàbí ti Táò. Kódà, Kérésìmesì ti wá di ohun tí àwọn ènìyàn gba wèrè rẹ̀ ní China, níbi tó jẹ́ pé ẹ̀sún kan péré nínú ọgọ́rùn-ún ló jẹ́wọ́ pé Kristẹni làwọn.
Èé ṣe ti ayẹyẹ Kérésìmesì fi wá di ohun tó gbalẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní Ìlà Oòrùn ayé? Èé ṣe tí àwọn tí kò gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà ṣe ń bá wọn ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì, tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn kà sí ọjọ́ ìbí rẹ̀? Ṣé ojú tí àwọn ènìyàn fi ń wo Kérésìmesì ló yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ máa fi wò ó? A óò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí báa ti ń ṣàgbéyẹ̀wò bí Kérésìmesì ṣe wá di ohun tí wọ́n gba wèrè rẹ̀ ní Korea, tó jẹ́ orílẹ̀-èdè àtayébáyé ní Ìlà Oòrùn ayé.