ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 9/1 ojú ìwé 25
  • Bíbomi Rin Àwọn Irúgbìn Òtítọ́ ní Chile

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbomi Rin Àwọn Irúgbìn Òtítọ́ ní Chile
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjẹ́rìí Orí Tẹlifóònù Tó Ń Yọrí sí Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Fífi Fóònù Wàásù Máa Ń Gbéṣẹ́ Gan-an
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Orí Ìdúró àti Ti Orí Tẹlifóònù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Nípa Àwọn Àṣìṣe Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 9/1 ojú ìwé 25

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Bíbomi Rin Àwọn Irúgbìn Òtítọ́ ní Chile

Ọ̀PỌ̀ ọdún lè kọjá kí òjò tó rọ̀ ní aṣálẹ̀ àríwá Chile. Àmọ́ nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, ńṣe ni ilẹ̀ gbígbẹ táútáú, ilẹ̀ yangí, á wá di ilẹ̀ tí àwọn òdòdó aláwọ̀ mèremère bò wẹ̀lẹ̀mù. Ìran àrímáleèlọ yìí ló ń mú kí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa wá síbẹ̀ láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin orílẹ̀-èdè náà.

Àmọ́ o, ohun àrà kan tó tún ń gbàfiyèsí ju ìyẹn lọ, ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ láàárín àwọn èèyàn Chile. Omi òtítọ́ Bíbélì ń ṣàn dé gbogbo igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn sì “ń yọ ìtànná,” wọ́n ń gbèrú di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Tẹlifóònù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí omi òtítọ́ yìí gbà ń ṣàn dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. Àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí dá lórí bí ọ̀nà ìjẹ́rìí yìí ti gbéṣẹ́ tó.

• A sọ fún ajíhìnrere alákòókò kíkún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Karina pé kó ṣe àṣefihàn kan nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan nínú àpéjọ àyíká, nípa báa ṣe ń fi tẹlifóònù jẹ́rìí. Ṣùgbọ́n Karina kò fi tẹlifóònù jẹ́rìí rí. Láti lè fún un níṣìírí láti kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká náà, alàgbà kan àtìyàwó rẹ̀ ṣàlàyé àwọn kókó kan fún Karina nípa báa ṣe ń fi tẹlifóònù jẹ́rìí. Wọ́n tún rọ̀ ọ́ pé kó gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí. Nítorí náà, ó ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì wá pinnu níkẹyìn pé òun máa gbìyànjú láti fóònù sí ẹnì kan.

Karina lo nọ́ńbà tẹlifóònù kan tó jẹ́ ti abúlé kan tó wà nítòsí. Alámòójútó tẹlifóònù ló gbé e, Karina sì ṣàlàyé ìdí tí òun fi fóònù. Inú alámòójútó náà dùn sí ìpè yìí, wọ́n sì ṣètò pé kí wọ́n tún bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta. Ìpadàbẹ̀wò tó ṣe lórí tẹlifóònù yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ni wọ́n fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí. Látìgbà yẹn ni wọ́n ti ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń wọni lọ́kàn, tó sì ń wúni lórí, Karina sì ti fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí obìnrin náà láti fi dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀.

• Bernarda lo àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ láti fi jẹ́rìí fún ọkùnrin kan tó ṣèèṣì tẹlifóònù rẹ̀. Dípò tí Bernarda ì bá fi bínú, ṣe ló sọ fún ọkùnrin náà pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, òun sì ṣe tán àtiràn án lọ́wọ́ tó bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ òun. Bí wọ́n ṣe tẹnu bọ̀rọ̀ nìyẹn, ọkùnrin náà sì fetí sílẹ̀ bó ṣe ń ṣàlàyé bí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe mú ìwà ìrẹ́jẹ kúrò láìpẹ́. Ọkùnrin náà fún Bernarda ní nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ̀, Bernarda sì ń padà bẹ̀ ẹ́ wò nípasẹ̀ tẹlifóònù. Nínú ọ̀kan lára àwọn ìjíròrò wọn, ó ka ibì kan fún un nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ọkùnrin náà wá béèrè bóun ṣe lè rí ìwé yẹn gbà, Bernarda sì fi ìwé náà àti Bíbélì ránṣẹ́ sí i. Wọ́n ṣètò pé kí arákùnrin kan ládùúgbò rẹ̀ máa wá bẹ̀ ẹ́ wò, arákùnrin yìí sì ti “ń bomi rin” “ohun ọ̀gbìn” tí ń rúwé yìí.

Bẹ́ẹ̀ ni o, àní látinú ilẹ̀ gbígbẹ táútáú nípa tẹ̀mí ti ayé yìí, àwọn irúgbìn tó fara sin ń retí àtihù nígbà tí omi òtítọ́ tí ń fúnni ní ìyè bá kàn wọ́n lára. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ ń “rú yọ,” wọ́n sì ń “yọ ìtànná” tí ń gbèrú di àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run.—Aísáyà 44:3, 4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́